2018
Pinnu láti Ronúpìwàdà
January 2018


Ọdọ

Pinnu láti Ronúpìwàdà

Ààrẹ Monson ṣe àlàyé pé “ojúṣe wa ni láti dìde kúrò nínú àìjáfáfá sínú ìjáfáfá, láti inú ìjákulẹ̀ sínú àṣeyege. Iṣẹ́ wa ni láti dà bí a ti lè dára jùlọ tó . Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ènìyàn nya Oṣù Kínní sọ́tọ̀ láti ṣe àwọn ìlepa àti ìpinnu ti gbígbèrú: láti rẹrin síi, jẹun tí ó ní ókun, tàbí kọ́ iṣẹ́ titun kan. Nígbàtí àwọn ìlépa wọ̀nyí lè ràn yín lọ́wọ́ lati yípadà sí dáradára, ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti yípada ni nípa ìrònúpìwàdà.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìrònúpìwàdà lè ṣòro, ó jẹ́ ẹ̀bùn! Bí a ṣe ngbáralé Jésù Krístì nípa ríronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, yío lè ṣeéṣe fún wa lati dàgbà kí a sì ní ìlọsíwájú. Ààrẹ Monson sọ pé, “Pàtàkì sí ètò [ti ìgbàlà] náà ni Olùgbàlà wa, Jésù Krístì. Láìsí ètùtù ìrúbọ Rẹ̀, gbogbo ohun yíò sọnù. Nípa ìrònúpìwàdà, ẹ lè gba ìwẹ̀nùmọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín kí ẹ sì ní ìlọsíwájú láti dà bíi Tirẹ̀.

Ẹ ronú nípa ohunkan tí ó lè máa mú yín kúrò ní dídà bíi ti Olùgbàlà. Ṣe èdè yín ni? Bí ẹ ṣe nbá àwọn ọ̀rẹ́ tàbí ẹbí yín lo? Lẹ́hìn ríronú nípa ohun tí ẹ lè túnṣe, ẹ gbàdúrà sí Bàbá Ọ̀run kí ẹ sì fi ìfẹ́ yín láti yípadà hàn. Ẹ rántí pé nípa agbára Ètùtù Rẹ̀, Jésù Krístì lè ràn yín lọ́wọ́ láti borí àìlera yín. Gẹ́gẹ́bí Ààrẹ Monson ṣe kọ́ni pé, “Ẹ̀bùn ìrònúpìwàdà, tí Olùgbàla wa pèsè, fún wá lágbára láti tun àgbékalẹ̀ èrò wa ṣe.”

Tẹ̀