2018
Máa gburo Rẹ̀ Nígbàkugbà, Níbikíbi, Ọ̀nà-kọnà
January 2018


Ọ̀rọ̀ Ìbẹniwò Kíkọni Oṣù, Kìnní 2018

Máa Gburo Rẹ̀ Nígbàkugbà, Níbikíbi, Ní Ọ̀nàkọnà

Ìbẹniwò kíkọ́ni jẹ́ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́. Jésù ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ nígbàkugbà àti níbikíbi. A lè ṣe bákannáà.

Láti “ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́” ni láti fúnni ní iṣẹ́ ìsìn, ìtọ́jú, tàbí ìrànwọ́ tí ó ndá kún ìtùnú tàbí ìdùnnú ẹlòmíràn. Ìbẹniwò kíkọ́ni jẹ́ nípa ṣíṣe àwárí àwọn ọ̀nà tí a fi lè ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn wọnnì tí à nbẹ̀wò. Jésù Krístì ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ sí gbogbo ènìyàn—nígbàkugbà àti nìbikíbi. Ó bọ́ àwọn ẹgbẹ̀rún marun, Ó tu Màríà àti Máthà nínú níbi ikú arákùnrin wọn, Ó fi ìhìnrere Rẹ̀ kọ́ obìnrin ní ibi kànga…Ó ṣe é nítorí ìfẹ́ òdodo Rẹ̀.

Títẹ̀lé àpẹrẹ Rẹ̀, bí olùkọni ìbẹniwò a lè mọ̀ kí a sì ní ìfẹ́ arábìnrin kọ̀ọ̀kan tí à nbẹ̀wò, ní rírántí pé ìfẹ́ ni ìpìlẹ̀ gbogbo ohun tí a nṣe. Nígbàtí a bá gbàdúrà fún ìmísí láti mọ̀ bí a ó ti sìn ín kí a ràn án lọ́wọ́ láti fún ìgbàgbọ́ rẹ̀ lókun, “àwọn ángẹ́lì kò lè dáwọ́ dúró ní jíjẹ́ alábárìn [wa] ”1

Láti inú ìṣètò Ẹgbẹ́ Ìrànlọ́wọ́ ní 1842 di òní, ìṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn arábìnrin ti bùkún àwọn ìgbe aye. Fún àpẹrẹ, Joan Johnson, opó ẹni ọdún méjì lé lọ́gọ́rin, àti ẹnìkejì ìbẹniwò kíkọni rẹ̀ ṣe ìbẹ̀wò ìkọ́ni sí aladugbo wọn tí ó jẹ́ ẹni ọdún mọ́kàndínláàdọ́rin tí ó sì ní òtútù-àyà. Wọn ri pè aladugbo wọn kò nílò wọn ni ẹ̀ẹ̀kan lóṣù nìkan, nítorínáà wọn bẹ̀rẹ̀ sí nbẹ̀ẹ́ wò ní ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ní ti ara àti nípa ẹ̀rọ̀ ìbánisọ̀rọ̀ .

Fún àwọn ìbẹniwò olùkọ́ni míràn, fifi àtẹ̀kọ tàbí àtẹ̀jíṣẹ́ ayélujára ránṣẹ́ láti funní ní ìgbani níyànjú lè jẹ́ ohun tí ó dára jùlọ láti ṣe fún arábìnrin kan ní oṣù náà. Ṣíṣe àwọn ìsopọ̀ araẹni àti fífi etí sílẹ̀ pẹ̀lú ìwà ìfẹ́ ni àkójá ìbẹniwò kíkọ́ni. Àwọn ẹ̀ro ìgbàlódé àti àwọn ìbẹ̀wò ìgbà-tí-o-níyi ojú-ko-ju nràn wá lọ́wọ́ láti ṣeé ni ìgbàkugbà, níbikíbi, àti ní àwọn ọ̀nà púpọ̀.2 Èyíinì ni ṣíṣe ìṣẹ́ ìránṣẹ́ bí Jésù ti ṣe.

Àwọn Àkọssílẹ̀ ráńpẹ́

  1. Àwọn Ìkọ́ni ti Àwọn Ààre ti Ìjọ: Joseph Smith (2007), 475.

  2. Wo Handbook 2: Administering the Church (2010), 9.5.1.

Tẹ̀