“Àwọn Èrò-inú fún Lílo Áàpù Yàrá Ìkàwé Ìhìnrere,” Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ (2021)
“Àwọn Èrò-inú fún Lílo Áàpù Yàrá Ìkàwé Ìhìnrere,” Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ
Àwọn Èrò-inú fún Lílo Áàpù Yàrá Ìkàwé Ìhìnrere
Fetísílẹ̀
Ọ̀kan nínú àwọn ọ̀nà tí ó dára jùlọ láti ṣàṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ ni láti fetísí àwọn gbígbàsílẹ̀. Ẹ lè ṣe èyí ní ilé yín tàbí o fẹ́rẹ̀ tó níbikíbi. Ẹ tún lè fetísí ní àwọn yíyára ìyípadà àti ní àwọn oríṣiríṣi èdè.
Ṣàṣàrò nípa àkòrí
Ẹ lè wa àwọn ìwé-mímọ́ nípa àkòrí tí a fún ni nípa lílo ìṣe ìwákiri ati lẹ́hìnnáà ṣíṣe àtúnyẹ̀wò àwọn àbájáde ìwákiri tí ó yẹ. Ẹ tún le lo àtẹ̀jáde Àwọn Àkòrí Ìhìnrere tí ó pèsè àwọn kókó ìwé-mímọ́ fún àkòrí kan tí a fún ni.
Ṣe Ètò nípasẹ̀ Àkòrí
Ẹ lè ṣe ètò àkóónú nípasẹ̀ àwọn àkórí nípa lílo “Àwọn Àlẹ̀mọ́” àti “Àwọn ìwé Àkọsílẹ̀.” Àwọn àkòrí wọ̀nyí lè wúlò nígbàtí ẹ bá nṣe ìgbáradì ìsọ̀rọ̀ tàbí ẹ̀kọ́ kan.
Ṣe Ìdámọ̀ Sí
Ẹ lè ṣe ìdámọ̀ tàbí àmì sí àwọn ìwé-mímọ́ yín nípa yíyan ẹsẹ kan lẹ́hìnnáà yan àrà kan. Àrà náà lè jẹ́ àpapọ̀ ti àwọn oríṣiríṣi àwọ̀ àti fífàlàsí lábẹ́ tàbí ṣe ìdámọ̀ sì.
Ṣe ẹ̀dá Àwọn Àsopọ̀
Ẹ lè ṣe ẹ̀dá àwọn àsopọ̀ laarin àwọn ìwé-mímọ́, àwọn ọ̀rọ̀ ìpàdé àpapọ̀ gbogbogbo, àti àkóónú míràn. Èyí lè ṣe ìrànlọ́wọ́ fún yín láti rántí àti láti yára dé ibi àwọn àsopọ̀ tí ẹ ti ṣe.
Wo Àwọn Ìtumọ̀
Ẹ lè fi ìrọ̀rùn wo ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ kan nínú àwọn ìwé-mímọ́ nípa yíyan án àti títẹ̀ bọ́tìnì “Ṣè-Ìtumọ̀”.
Lo Àwọn Àmì-iwé àti Àwọn Ẹ̀rọ-Àwòrán
Ẹ lè yára padà láti yan àkóónú nípa lílo àwọn búkúmaàkì láti tọ ipasẹ̀ àwọn ààyè àti àwọn ẹ̀rọ àwòrán kan pàtó. Lílo àwọn àmì-ìwé lè gbà yín láàyè láti tọ́jú àwọn oríṣiríṣi orí àti àkóónú míràn ní àkokò kanna.
Gbé Ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan Kalẹ̀
Ẹ lè ṣe ẹ̀dá ètò àṣàro kan tí ó nràn yín lọ́wọ́ láti tọ ipasẹ̀ ìlọsíwájú yín nípa ṣíṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́. Ẹ tún lè ṣètò àwọn ìránnilétí láti ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àṣeyọrí àwọn àfojúsùn àṣàrò yín. Ìtòlẹ́sẹẹsẹ kan lè ràn yín lọ́wọ́ láti ṣe àtẹ̀lé pẹ̀lú ìtòlẹ́sẹẹsẹ Wá, Tẹ̀lé Mi tàbí láti fúnra yín ka Ìwé ti Mọ́rmọ́nì.