“Kíni ìdí Àṣàrò Ìwé-mímọ́?” Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ (2021)
“Kíni ìdí Àṣàrò Ìwé-mímọ́?” Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ
Kíni ìdí Àṣàrò Ìwé-mímọ́?
Nígbàtí a bá fi aápọn ṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́, a nsúnmọ́ Jésù Krístì a sì nní òye ìhìnrere àti ìrúbọ ètùtù Rẹ̀ dáradára síi. Wòlíì Néfì gbà wa ní ìyànjú ní ọ̀nà yìí:
“Nítorí-èyi, ẹ̀yin kò lè ṣai tẹ̀síwájú pẹ̀lú ìdúróṣinṣin nínú Krístì, kí ẹ ní ìrètí dídán, àti ìfẹ́ ti Ọlọ́run àti ti gbogbo àwọn ènìyàn. Nítorí-èyi, bí ẹ̀yin yíò bá tẹ̀síwájú, tí ẹ̀ nṣe àpéjẹ lórí ọ̀rọ̀ Krístì, tí ẹ sì forítì í dé òpin, ẹ kíyèsĩ i, báyĩ í ni Baba wí: Ẹ̀yin yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun”(2 Néfì 31:20).
Àwọn ẹ̀kọ́ láti inú àwọn ìwé-mímọ́ yíò ràn wá lọ́wọ́ láti padà sọ́dọ̀ Baba wa Ọ̀run. Àwọn wòlíì wa ọjọ́-ìkẹhìn ti wí fún wa láti ṣe àṣàrò wọn déédé bí ẹnì kọ̀ọ̀kan àti, níbití ó wúlò, bí àwọn ẹbí. Wọ́n ti pè wá láti kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àwọn ìrírí ti àwọn wọnnì tí wọ́n wà nínú àwọn ìwé-mímọ́ kí a sì ṣe àmúlo àwọn àkọsílẹ̀ àti àwọn ìkọ́ni inú ìwé-mímọ́ sí àwọn ìgbésí ayé wa ti òde òní, bí Néfì ti dámọ̀ràn nínú 1 Néfì 19:23. Méjèèjì àwọn wòlíì àtijọ́ àti ti òde òní ti pè wá láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ àti láti ṣe “àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì” (2 Néfì 32:3).
Ààrẹ Russell M. Nelson bákannáà kọ́ni ní òtítọ́ pàtàkì yí nípa “ṣíṣe àpèjẹ” lórí àwọn ìwé-mímọ́ náà:
“Láti ṣe àpèjẹ ní ìtúmọ̀ ju títọ́wò lọ. Láti ṣe àpèjẹ túmọ̀ sí láti gbádùn. A ngbádùn àwọn ìwé-mímọ́ nípa ṣíṣe àṣàrò wọn nínú ẹ̀mí àwárí dídùn àti ìgbọràn tòótọ́. Nígbàtí a bá ṣe àpèjẹ lórí àwọn ọ̀rọ̀ Krístì, wọ́n nwà ‘lórí àwọn tábìlì tó lẹ́ran ti ọkàn’[2 Kọ́ríntì 3:3]. Wọ́n di apákan pàtàkì ti àdánidá wa” (“Gbígbé Nípa Ìtọ́ni Ìwé-Mímọ́,” Ẹ́nsáìn, Oṣù kọkànlá 2000, 17).
Nígbàtí a bá kópa léraléra nínú ṣíṣe àṣàrò ìwé-mímọ ti ara ẹni àti ti ẹbí àwa àti àwọn ẹbí wa lè di títọ́sọ́nà, dídààbò bò, àti ríró ní agbára lòdì sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìpèníjà ti ọjọ́ wa.