“Àwọn Èrò-inú láti Mú Àṣàrò Ìwe-Mímọ́ Yín Gbèrú,” Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ (2021)
“Àwọn Èrò-inú láti Mú Àṣàrò Ìwe-Mímọ́ Ẹbí Yín Gbèrú,” Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ
Àwọn Èrò-inú láti Mú Àṣàrò Ìwé-Mímọ́ Ara-ẹni Yín Gbèrú
Nihin ni àwọn ọ̀nà tí ó rọrùn làti mú àṣàrò ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú àwọn ìwé-mímọ́ yín gbòòrò.
Gbàdúrà fún ìmísí.
Àwọn ìwé-mímọ́ jẹ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Lákokò tí ẹ̀ nṣe àṣàro wọn, ẹ bèèrè lọ́wọ́ Baba yín Ọ̀run fún ìtọ́sọ́nà Rẹ̀ kí ẹ sì gba Ẹ̀mí Rẹ̀ láti ran yín lọ́wọ́ ní òye wọn.
Wá àwọn Òtítọ́ nípa Jésù Krístì
Àwọn ìwé-mímọ kọ́ wa pé ohun gbogbo jẹri nípa Krístì (wo 2 Néfì 11;4; Mósè 6:63), nítorínáà wá A nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀, àwọn ìtàn, àti àwọn ìkọ́ni inú àwọn iwe-mimọ. Ẹ wòye ṣíṣe àmì sí àwọn ẹsẹ tí ó kọ́ni nípa Olùgbàlà àti bí a ṣe lè tẹ̀lé E.
Wá Àwọn Ọ̀rọ̀ àti Àwọn Gbólóhùn tó ní Ìmísí
Ẹ lè ri pé àwọn ọ̀rọ̀ àti àwọn gbólóhùn nínú àwọn ìwé-mímọ́ wú yín lórí, bí ẹni pé a kọ wọ́n ní pàtàkì fún yín. Wọ́n lè ní ìmọ̀lára ìwúlò ti ara ẹni kí ó sì ṣe ìmísí àti ìwúrí fún yín. Ẹ wòye ṣíṣe àmì sí wọn nínú àwọn ìwé-mímọ́ yín tàbí kíkọ nípa wọn nínú ìwé-àkọọ́lẹ̀ àṣàrò.
Wá Àwọn Òtítọ́ Ìhìnrere
Nígbà míràn àwọn òtítọ́ ìhìnrere (nígbàgbogbo tí a pè ní ẹ̀kọ́ tàbí àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀) ni a sọ ní tààrà, àti nígbà míràn wọ́n jẹ́ mímọ̀ nípasẹ̀ àpẹẹrẹ tàbí ìtàn. Ẹ bèèrè lọ́wọ́ ara yín, “Àwọn òtítọ́ ìhìnrere wo ni a kọ́ ní àwọn ẹsẹ wọ̀nyí?”
Ẹ fétísílẹ̀ sí Ẹ̀mí
Ẹ fojúsí àwọn èrò àti àwọn ìmọ̀lára yín, pàápàá tí wọ́n bá dàbí ẹnipé kò bá ohun tí ẹ nkà mu. Àwọn ìwúnilórí wọ̀nyí lè jẹ́ àwọn ohun tí Baba yín Ọ̀run fẹ́ kí ẹ kọ́ kí ẹ sì ní ìmọ̀lára rẹ̀.
Fífi Àwọn Ìwé-mímọ́ ṣe Àkàwé Ìgbésí ayé Yín
Ẹ wòye bí àwọn ìtàn àti ẹ̀kọ́ tí ẹ nkà ṣe wúlò sí ìgbésí ayé yín. Fún àpẹẹrẹ, ẹ lè bi ara yín léèrè, “Àwọn ìrírí wo ni mo ní tí o jọra pẹ̀lú ohun tí mo nkà?” tàbí “Báwo ni mo ṣe lè tẹ̀lé àpẹẹrẹ ènìyàn yí ninú awọn iwe-mimọ náà?”
Bèèrè Àwọn ìbéèrè
Bíbèèrè àwọn ìbéèrè nípa ìhìnrere lè ràn yín lọ́wọ́ láti pinnu ohun ti ẹ ó ṣe àṣàrò rẹ̀. Bí ẹ ṣe nṣàṣàrò àwọn ìwé-mímọ́, àwọn ìbéèrè tún lè wá sí ọkàn. Àwọn ìbéèrè wọ̀nyí lè bá ohun tí ẹ̀ nka tàbí ìgbésí ayé yín mu ní àpapọ̀. Ro àwọn ìbéèrè wọ̀nyí, kí o sì wá ìdáhùn bí o ti nbá àṣàrò ìwé-mímọ́ lọ. Lẹ́hìn àṣàrò yín, ẹ béèrè ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí ẹ́ kọ́ sii, kí ẹ wo àwọn ìdáhùn ní àwọn wákàtí àti àwọn ọjọ́ tó nbọ̀.
Ẹ Lo Ìrànwọ́ Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ
Láti jèrè àwọn òye sí àwọn ẹsẹ tí ẹ kà, lo àwọn àlàyé ẹsẹ̀-ìwé, Àkòrí Ìtọ́sọ́nà Àkòrí, Ìtumọ̀ Bíbélì náà, Ìtọ́sọ́nà sí Àwọn Ìwé-Mímọ́ náà (scriptures.ChurchofJesusChrist.org), àti àwọn ìrànwọ́ àṣàrò míràn.
Yẹ Ọ̀rọ̀ kíkà inú Awọn Ìwé-Mímọ́ wò
Ẹ lè wá àwọn òye tí ó nítumọ̀ nípa ìwé-mímọ́ kan bí ẹ bá gbèrò ọ̀rọ̀ kíkà rẹ̀—awọn ipò tàbí ètò ìwé-mímọ́ náà. Fún àpẹrẹ, mímọ̀ ìpìlẹṣẹ̀ àti ìgbàgbọ́ àwọn ènìyàn náà tí wòlíì kan sọ̀rọ̀ sí lè ṣèrànwọ́ fún yín láti ní òye ìdí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ.
Ẹ Ṣe Àkọsílẹ̀ àwọn Èrò àti àwọn Ìmọ̀lára Yín
Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà ló wà láti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ìwúnilórí tí ó wá bí ẹ ṣe nṣe àṣàrò. Fún àpẹrẹ, ẹ lè sàmì sí ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn tí ó nítumọ̀ kí ẹ sì ṣe àkọsílẹ̀ àwọn èrò yín bíi àkọsílẹ̀ ránpẹ́ kan nínú àwọn ìwé-mímọ́ yín. Ẹ tún lè tọ́jú ìwé-àkọọ́lẹ̀ àwọn òye, àwọn ìmọ̀lára, àti àwọn ìwúnilórí tí ẹ gbà. Tàbí ẹ lè ṣe àkọsílẹ̀ ìbéèrè tí ẹ bèrè ṣáájú ìbẹ̀rẹ̀ àṣàrò yín, àwọn ìdáhùn tí a darí yín láti ṣe ni ó tẹ̀le.
Ẹ Ṣe àṣàrò Àwọn Ọ̀rọ̀ Wòlíì àti Àwọn Àpóstélì Ọjọ-Ìkẹhìn.
Ẹ Ka ohun tí àwọn wòlíì àti àwọn àpóstélì ọjọ-ìkẹhìn ti kọ́ni nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí ẹ rí nínú àwọn ìwé-mímọ́. Àwọn ọ̀rọ̀ wọn wà ní “Ìpàdé Àpapọ̀ Gbogbogbò,” “Àwọn ìwé-ìròhìn,” ati awọn ìkójọpọ̀ míràn nínú Yàrá Ìkàwé Ìhìnrere.
Ka àwọn Ìtàn
Ka àwọn ìtàn inú àwọn ìwé-mímọ́, ní wíwá láti ní òye ọ̀rọ̀-kíkà wọn (àkókò, ibẹ̀, olùsọ̀rọ̀, àti olùgbó). Àwọn ìtàn tí a júwe jẹ́ orísun nlá fún èyí, ní pàtàkì fún àwọn ọmọdé àti àwọn ọmọ ijọ tí kò fi bẹ́ẹ̀ mọ àwọn ìwé-mímọ́.
Pín Àwọn Òye
Sísọ̀rọ̀ àwọn òye láti inú àṣàrò ara ẹni jẹ́ ọ̀nà tí ó dára láti kọ́ àti láti ran àwọn míràn lọ́wọ́ ó sì nfún òye yín ní okun ohun tí ẹ ti kà.
Ẹ Gbe nípa Ohun tí Ẹ Kọ́
Àṣàrò ìwé mímọ lè ṣe ìmísí fún wa kí ó sì darí wa láti yí bí a ṣe ngbé ìgbésí-ayé padà. Ẹ fetísílẹ̀ sí ohun tí Ẹ̀mi nṣí yín létí láti ṣe bí ẹ ṣe nkàá, àti lẹ́hìnnáà kí ẹ ṣe ìpinnu láti ṣe ìṣe lórí àwọn ìṣílétí wọ̀nnì.