Àwọn Ìwé Mímọ́
Àwọn Èrò-inú làti Mú Àṣàrò Ìwe Mímọ́ Ẹbí Yín Gbèrú Síi


“Àwọn Èrò-inú làti Mú Àṣàrò Ìwe Mímọ́ Ẹbí Yín Gbèrú Síi,” Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ (2021)

“Àwọn Èrò-inú làti Mú Àṣàrò Ìwe Mímọ́ Ẹbí Yín Gbèrú Síi,” Àwọn Èrò-inú Àṣàrò Ìwé-mímọ

àwọn ẹbí nṣe àṣàrò Ìwé-mímọ́

Àwọn Èrò-inú làti Mú Àṣàrò Ìwe Mímọ́ Ẹbí Yín Gbèrú Síi

Àṣàrò ìwé mímọ ẹbí dèèdé jẹ́ ọ̀nà kan tí ó lágbára láti ṣe ìrànlọ́wọ́ fún ẹbí yín láti kọ́ ẹ̀kọ́ ìhìnrere. Bí ó ti pọ̀ tó àti bí ó ṣe pẹ́ tó tí ẹ ti kà bí ẹbí kò ṣe pàtàkì bíi dídúróṣinṣin nínú àwọn ìgbìyànjú yín. Bí ẹ ṣe nfi àṣàrò ìwé mímọ ṣe apákan pàtàkì ìgbésí ayé ẹbí yín, ẹ̀yin yìó ran àwọn ọmọ ẹbí yín lọ́wọ́ láti súnmọ́ Jésù Krístì síi, àti láti kọ́ àwọn ẹ̀rí wọn lé orí ìpìlẹ̀ ọ̀rọ̀ Rẹ̀.

Gbé àwọn ìbéèrè wọ̀nyí yẹ̀ wò:

  • Báwo ni ẹ ṣe lè gba àwọn ọmọ ẹbí níyànjú láti ṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́ fúnrawọn?

  • Kíni ẹ lè ṣe láti gbà àwọn ọmọ ẹbí níyànjú láti pín ohun tí wọ́n nkọ́?

  • Báwo ni ẹ ṣe lè tẹnumọ́ àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí ẹ̀ nkọ́ nínú àwọn ìwé-mímọ́ nínú àwọn àkókò ìkọ́ni ojoójúmọ́?

Ẹ rántí pé ilé ni ibi tí ó tọ́ fún kíkọ́ ẹkọ àti kìkọ́ni ní ìhìnrere. Ẹ lè kọ́ ẹkọ kí ẹ sì kọ́ni ní ìhìnrere nínú ilé ní àwọn ọ̀nà tí kò ṣeéṣe nínú kíláásì Ìjọ. Ẹ ṣe àtinúdá bí ẹ ṣe nronú nípa àwọn ọ̀nà láti ran ẹbí yín lọ́wọ́ kọ́ ẹ̀kọ́ láti inú àwọn ìwé mímọ́. Wo díẹ̀ nínú àwọn èrò-inú tí ó tẹ̀lée láti mú àṣàrò ìwé mímọ ẹbí yín gbòòrò.

Lo Orin

Kọ àwọn orin tí ó fi agbára kún àwọn ẹ̀kọ́ ìpìlẹ̀ tí a kọ́ nínú ìwé mímọ́.

ọkùnrin ati ọmọdébìnrin nṣe àṣàrò àwọn ìwé-mímọ́

Pín Àwọn Ìwé Mímọ́ tí ó Nítumọ̀

Fún àwọn ọmọ ẹbí ní àkókò láti ṣe àjọpín àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n ti rí tí ó nítumọ̀ nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ ti ara wọn.

Ẹ Lo Àwọn Ọrọ̀ ti Ara Yín.

Pe àwọn ọmọ ẹbí láti ṣàkópọ̀ nínú àwọn ọ̀rọ̀ tiwọn ohun tí wọ́n kọ́ láti inú àṣàrò àwọn ìwé mímọ́.

Ẹ Ṣe Àmúlò Àwọn Ìwé Mímọ́ sí Ìgbésí Ayé Yín

Lẹ́hìn kíka ẹsẹ ìwé-mímọ́ kan, ẹ bèèrè lọ́wọ́ àwọn ọmọ ẹbí láti pín àwọn ọ̀nà tí ẹsẹ náà fi kan ìgbésí ayé wọn.

Bèèrè Ìbéère kan

Pe àwọn ọmọ ẹbí láti bèèrè ìbéèrè ìhìnrere kan, àti lẹ́hìnnáà kí wọn ó lo àkókò láti wá àwọn ẹsẹ tí ó lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dáhùn ìbéèrè náà.

Ṣe Àfihàn Ìwé-mímọ kan

Ẹ yan ẹsẹ kan tí ẹ ríi pé ó nítumọ̀, kí ẹ ṣe àfihàn rẹ níbití àwọn ọmọ ẹbí yíò ti máa rí i nígbàgbogbo. Ẹ pe àwọn ọmọ ẹbí láti ṣe àyídà síra fún yíyan ìwé mímọ́ láti ṣe àfihàn.

Ṣe Ìtòsílẹ̀ Ìwé-mímọ́ kan

Gẹ́gẹ́bí ẹbí kan, ẹ yan oríṣiríṣi àwọn ẹsẹ ti ẹ̀yin yìó fẹ́ láti jíròrò lé lórí nínú ọ̀sẹ̀ tó nbọ̀.

Kọ́ àwọn Ìwé Mímọ́ Sórí

Ẹ yan ẹsẹ ìwé mímọ́ kan tí ó ní ìtumọ̀ sí ẹbí yín, kí ẹ sì pe àwọn ọmọ ẹbí láti kọ́ ọ sórí nípa ṣíṣe àtunsọ rẹ̀ lójoójúmọ́ tàbí ṣíṣe eré ìdárayà àkọ́sórí kan.

Pín Àwọn Ẹ̀kọ́ tó ní Ohun Èlò

Ẹ wá àwọn nkan èlò tí ó bá àwọn orí-ìwé àti ẹsẹ tí ẹ nkà bíi ẹbí kan mu. Ẹ pe àwọn ọmọ ẹbí láti sọ̀rọ̀ nípa bí ohun èlò kọ̀ọ̀kan ṣe bá àwọn ẹ̀kọ́ inú àwọn ìwé-mímọ́ mu.

obìnrin nkọ́ ọmọ

Ẹ Mú Àkòrí kan

Ẹ jẹ́ kí àwọn ọmọ ẹbí to tọ́ọ̀nù láti yan àkòrí kan tí ẹbí yíò ṣe àṣàrò papọ̀. Lo Àkòrí Ìtọ́sọ́nà, Ìtumọ̀ Bíbélì, tabi Ìtọ́sọ́nà sí Ìwé Mímọ́ (scriptures.ChurchofJesusChrist.org) láti wá àwọn ẹsẹ ìwé mímọ́ nípa àkòrí náà.

Ya Àwòrán kan

Ẹ ka àwọn ẹsẹ díẹ̀ bí ẹbí kan, lẹ́hìnnáà ẹ fi àyè gba àwọn ọmọ ẹbí láti ya àwòrán ohun kan tí ó bá ohun ti ẹ ka mu. Ẹ lo àkókò láti jíròrò lóri àwọn ohun tí ẹnìkọ̀ọ̀kan yín yà.

Ẹ Ṣe Itan kan Jáde Bí Eré

Lẹ́hìn kíka ìtàn kan, ẹ pe àwọn ọmọ ẹbí láti ṣe eré rẹ̀. Lẹ́hìnnáà, ẹ sọ̀rọ̀ nípa bí ìtàn náà ṣe bá àwọn ohun tí ẹ nni ìriri rẹ̀ bí ẹnìkọ̀ọkan àti bí ẹbí.

Alàgbà David A. Bednar kọ́ni pé: “Àdúrà ẹbí kọ̀ọ̀kan, ìṣẹ̀lẹ̀ kọ̀ọ̀kan ti àṣàrò ìwé mímọ́ ẹbí, àti ìpàdé ilé nírọ̀lẹ́ kọ̀ọ̀kan jẹ́ ìmúdára kan sí órí àwòrán ọkàn wa. Kò sí ìṣẹ̀lẹ̀ kan tí ó lè farahàn bíi wíwúnilórí tàbí mánigbàgbé gidi. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́bí àwọn kíkùn ọ̀dà òféefèé àti wúrà ati búráhùn ti bu iyì kún ara wọn tí ó sì pèsè iṣẹ́ ọnà àfọwọ́ṣe wíwúnilórí kan jáde, bẹ́ẹ̀ náà ni ìdúróṣinṣin wa ní ṣíṣe àwọn ohun tí ó dàbí ẹni pé ó kéré lè já sí àwọn àbájáde pàtàkì ti ẹ̀mí” (“Alãpọn Díẹ̀ síi àti Ìfiyèsí ní Ilé,” Làìhónà, Oṣù kọkànlá 2009, 19–20).