Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 10


Orí 10

Ìdákẹ́rọ́rọ́ wà lórí ilẹ̀ nã fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí—Ohùn Krístì ṣe ìlérí pé òun yíò ràdọ̀ bò àwọn ènìyàn rẹ̀ bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ lábẹ́ apá rẹ̀—Àwọn tí ó se olódodo jùlọ nínú àwọn ènìyàn nã ni a ti dá sí. Ní ìwọ̀n ọdún 34–35 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ó sì ṣe tí gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ nã gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, tí wọ́n sì jẹ́rĩ síi. Lẹ́hìn sísọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ìdákẹ́rọ́rọ́ sì wà lórí ilẹ̀ nã fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí;

2 Nítorítí ìyàlẹ́nu àwọn ènìyàn nã pọ̀ tóbẹ̃ tí wọn dẹ́kun ìpohùnréré ẹkún àti híhu fún àdánù wọn lórí àwọn ìbátan wọn tí ó ti kú; nítorínã ni ìdákẹ́rọ́rọ́ ṣe wà lórí gbogbo ilẹ̀ nã fún ìwọ̀n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wákàtí.

3 Ó sì ṣe tí ohùn kan tún tọ àwọn ènìyàn nã wá, gbogbo àwọn ènìyàn nã sì gbọ́; wọn sì jẹ́rĩ nípa rẹ̀, tí ó wípé:

4 A! ẹ̀yin ènìyàn tĩ ṣe ti ìlú nlá tí ó ti subú wọ̀nyí; tĩ ṣe àtẹ̀lé Jákọ́bù, bẹ̃ni, tĩ ṣe ti ìdílé Isráẹ́lì, báwo ni èmi tií ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ lábẹ́ apá rẹ̀, tí èmi sì tọ́ nyín dàgbà.

5 Àti síbẹ̀síbẹ̀, báwo ni èmi ìbá tún ti ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ lábẹ́ apá rẹ̀, bẹ̃ni, A! ẹ̀yin ènìyàn ìdílé Isráẹ́lì, tí ó ti subú; bẹ̃ni, A! ẹ̀yin ènìyàn ìdílé Isráẹ́lì, ẹ̀yin ti ńgbé inú Jerúsálẹ́mù, àti ẹ̀yin tí ó ti subú; bẹ̃ni, báwo ni èmi ìbá tún ti ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ rẹ̀, ṣùgbọ́n tí ẹ̀yin kò sì fẹ́.

6 A! ẹyin ìdílé Isráẹ́lì èyítí èmi ti dásí, báwo ni èmi ìbá ti ràdọ̀ bò yín nígbà-kũgbà bí àgbébọ̀ tií ràdọ̀ bò àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ apá rẹ̀, bí ẹ̀yin yíò bá ronúpìwàdà kí ẹ sì padà sí ọ̀dọ̀ mi tọkàn-tọkàn.

7 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá ṣe bẹ̃, A! ẹyin idile Israẹli àwọn ibùgbé yín gbogbo ni yíò di ahoro títí di àkokò ìmúṣẹ májẹ̀mú tí èmi Olúwa bá àwọn bàbá yín dá.

8 Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn nã ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ẹ kíyèsĩ, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí sọkún wọn sì tún nhu nítorí ìpàdánù àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ wọn.

9 Ó sì ṣe tí ọjọ́ mẹ́ta nã kọjá lọ báyĩ. Òwúrọ̀ ni í sì í ṣe, òkùnkùn sì ká kúrò lórí ilẹ̀ nã, ilẹ̀ sì dáwọ́ mimì dúró, àwọn àpáta sì dáwọ́ lílà sí méjì dúró, àwọn ìkérora búburú sì dáwọ́ dúró, gbogbo àwọn ariwo ìrúkèrúdò sì dáwọ́ dúró.

10 Ilẹ̀ sì tún lè papọ̀ mọ́ ara wọn tí ó sì dúró gbọingbọin; àwọn ìkẹ́dùn ọkàn, àti ẹkún sísun, àti ìpohùnréré ẹkún àwọn ènìyàn nã tí a dá sí tí ó sì wà lãyè sì dáwọ́ dúró; ìkẹ́dùn ọkàn wọn sì di ayọ̀, ìpohùnréré ẹkún wọn sì di ìyìn àti ọpẹ́ sí Jésù Krístì Olúwa, Olùràpadà wọn.

11 Bãyĩ sì ni àwọn ọ̀rọ̀ ìwé-mímọ́ di mímúṣẹ èyítí a ti sọ láti ẹnu àwọn wòlĩ.

12 Àwọn tí ó sì jẹ́ olódodo jùlọ nínú àwọn ènìyàn nã ni a gbàlà, àwọn sì ni ó gba àwọn wòlĩ tí wọ́n kò sì sọ wọ́n ní òkúta pa; àwọn sì ni àwọn tí kò ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́ sílẹ̀, ni a dá sí—

13 A sì dá wọn sí, a kò sì tẹ̀ wọ́n rì sínú ilẹ̀ àti kí a bò wọ́n mọ́lẹ̀; a kò sì rì wọ́n sínú ibú omi òkun; a kò sì jó wọn nínú iná, bẹ̃ ni a kò wó lù wọ́n kí a sì tẹ̀ wọ́n pa; a kò sì gbé wọn lọ nínú ìjì: bẹ̃ ni a kò bò wọ́n mọ́lẹ̀ pẹ̀lú ìkũkù ẽfín àti òkùnkùn.

14 Àti nísisìyí, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ka àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, kí ó ní ìmọ̀ wọn; ẹnití ó ní àwọn ìwé-mímọ́, kí ó wá inú wọn, kí ó ríi kí ó sì ṣe àkíyèsí bí gbogbo àwọn ikú àti ìparun nípasẹ̀ iná, àti nípasẹ̀ ẽfín, àti nípasẹ̀ èfũfù nlá, nípasẹ̀ ìjì, àti nípasẹ̀ ìṣísílẹ̀ ilẹ̀ láti gbe wọn mì, àti gbogbo ohun wọ̀nyí kò bá já sí mímúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ púpọ̀ nínú àwọn wòlĩ mímọ́.

15 Ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ti jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí ní àkókò bíbọ̀ Krístì, tí a sì pa wọ́n nítorípé wọ́n jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí.

16 Bẹ̃ni, wòlĩ Sénọ́sì jẹ́rĩ sí àwọn ohun wọ̀nyí, Sénọ́kì nã pẹ̀lú sọ nípa àwọn ohun wọ̀nyí, nítorípé wọ́n jẹ́rĩ ní pàtàkì nípa wa, tĩ ṣe ìyókù àwọn irú-ọmọ wọn.

17 Ẹ kíyèsĩ, Jákọ́bù bàbá wa pẹ̀lú jẹ́rĩ nípa ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù kan. Ẹ sì kíyèsĩ, àwa kò há íṣe ìyókù irú-ọmọ Jósẹ́fù kan bí? Àwọn ohun wọ̀nyí tí ó sì jẹ́rĩ nípa wa, njẹ́ a kò kọ wọ́n lé àwọn àwo idẹ nnì èyítí Léhì bàbá wa mú jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù bí?

18 Ó sì ṣe ní òpin ọdún kẹ́rìnlélọ́gbọ̀n, ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fihàn yín pé àwọn ènìyàn Nífáì tí a dá sí, àti àwọn tí a ti pè ní ará Lámánì, tí a ti dá sí, sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ojúrere Krístì, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìbùkún ni ó rọ̀ lé wọn lórí, tóbẹ̃ tí ó ṣe wípé ní kété lẹ́hìn ìgòkè Krístì lọ sí ọ̀run, ó fi ara rẹ̀ hàn sí wọn nítõtọ́—

19 Tí ó fi ara rẹ̀ hàn sí wọ́n, tí ó sì nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún wọn; a ó sì mu ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ rẹ̀ wá lẹ́hìn èyí. Nítorínã fun àkókò yĩ, mo mú awọn ọ̀rọ̀ mi wá sí ópin ná.