Orí 15
Jésù wípé a mú òfin Mósè ṣẹ nínú òun—Àwọn ará Nífáì ni àwọn àgùtàn míràn nã nípa èyítí ó sọ ní Jerúsálẹ́mù—Nítorí àìṣedẽdé wọn, àwọn ènìyàn Olúwa tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù kò mọ̀ nípa àwọn àgùtàn Ísráẹ́lì tí a ti fọ́nká. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti parí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọ̀nyí ó wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã yíká, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti gbọ́ àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi ti kọ́ kí èmi ó tó gòkè lọ sí ọ́dọ̀ Bàbá mi; nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá rántí àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí tí ó sì nṣe wọ́n, òun ni ẹnití èmi yíò gbé dìde ní ọjọ́ ìkẹhìn.
2 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó wòye pé àwọn kan wà lãrín wọn tí ẹnu nyà wọ́n, tí wọ́n sì nṣe hà nípa ohun tí ó fẹ́ kí àwọn ó ṣe nípa òfin Mósè; nítorí ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó sọ wípé àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, àti pé ohun gbogbo ti di titun kò yé wọn.
3 Ó sì wí fún wọn pé: Ẹ máṣe jẹ́ kí ó yà yín lẹ́nu pé mo wí fún yín pé àwọn ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, àti pé ohun gbogbo ti di titun.
4 Ẹ kíyèsĩ, mo wí fún yín pé; òfin tí a fi fún Mósè ti di ìmúṣẹ.
5 Ẹ kíyèsĩ, èmi ni ẹnití ó fi òfin nã fún wọn, èmi sì ni ẹnití ó dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi Ísráẹ́lì; nítorínã, òfin nã nínú mi ó ti di mímúṣẹ, nítorítí mo wá láti mú òfin nã ṣẹ; nítorínã ni ó ní òpin.
6 Ẹ kíyèsĩ, èmi kò ṣá àwọn wòlĩ tì, nítorí gbogbo àwọn ohun tí a kò ì múṣẹ nínú mi, lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọn yíò di mímúṣẹ pátápátá.
7 Àti nítorípé èmi ti wí fún yín pé ohun àtijọ́ ti kọjá lọ, èmi kò ṣá àwọn ohun tí a ti sọ nípa àwọn ohun tí nbọ̀ tì.
8 Nítorí ẹ kíyèsĩ, májẹ̀mú èyítí èmi ti bá àwọn ènìyàn mi dá kò ì di mímúṣẹ tán; ṣùgbọ́n òfin èyítí a fún Mósè ní òpin nípasẹ̀ mi.
9 Ẹ kíyèsĩ, èmi ni òfin, àti ìmọ́lẹ̀ nã. Ẹ gbẹ́kẹ̀ lé mi, kí ẹ sì forítì í dé òpin, ẹ̀yin yíò sì yè; nítorí ẹnití ó bá forítĩ dé òpin ni èmi yíò fún ní ìyè àìnípẹ̀kun.
10 Ẹ kíyèsĩ, èmi ti fún yín ní àwọn òfin; nítorínã ni kí ẹ pa àwọn òfin mi mọ́. Èyí sì ni òfin àti àwọn wòlĩ, nítorítí nwọ́n jẹ́risí mi nítòọ́tọ́.
11 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọn yĩ tán, ó wí fún àwọn méjìlá nnì àwọn ẹnití ó ti yàn:
12 Ẹ̀yin ni ọmọ-ẹ̀hìn mi; ẹ̀yin sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn yĩ, àwọn tí íṣe ìyókù ti ilé Jósẹ́fù.
13 Ẹ sì kíyèsĩ, ilẹ̀ ìní yín ni èyí; Bàbá sì ti fi fún yín.
14 Bàbá kò sì fi ìgbà kan fún mi ní àṣẹ pé kí èmi ó sọọ́ fún àwọn arákùnrin yín tí nbẹ ní Jerúsálẹ́mù.
15 Bẹ̃ni kò sì sí ìgbà tí Bàbá fún mi ní àṣẹ pé kí èmi ó sọ fún wọn nípa àwọn ẹ̀yà ìdílé Ísráẹ́lì, àwọn tí Bàbá ti darí wọn jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã.
16 Èyí ni Bàbá pàṣẹ fún mi, pé kí èmi ó sọ fún wọn:
17 Pé èmi ní àwọn àgùtàn míràn tí wọn kì íṣe ti agbo yĩ; àwọn pẹ̀lú ni èmi níláti mú wá, wọn yíò sì gbọ́ ohùn mi; agbo kanṣoṣo ni yíò sì wà, àti olùṣọ́-àgùtàn kanṣoṣo.
18 Àti nísisìyí, nítorí ọrùnlíle àti àìgbàgbọ́, ọ̀rọ̀ mi kò yé wọn; nítorínã ni Bàbá pàṣẹ fún mi láti ma sọ nípa ohun yĩ mọ́ fún wọn.
19 Ṣùgbọ́n, lóotọ́, èmi wí fún yín pé Bàbá ti pàṣẹ fún mi, èmi sì sọọ́ fún yín, pé a pín yín níyà kúrò lãrín wọn nítorí àìṣedẽdé wọn; nítorínã ni ó ṣe jẹ́ nítorí àìṣedẽdé wọn ni wọn kò mọ̀ nípa yín.
20 Àti lóotọ́, mo tún wí fún yín pé àwọn ẹ̀yà míràn ni Bàbá ti pínníyà kúrò lãrín wọn; àti pé nítorí àìṣedẽdé wọn ni wọn kò fi mọ̀ nípa wọn.
21 Àti lóotọ́ ni mo wí fún yín, pé ẹ̀yin ni àwọn ẹnití èmi sọ nípa wọn pé: Èmi ní àwọn àgùtàn míràn tí wọn kì íṣe ti agbo yĩ; àwọn pẹ̀lú ni èmi ní láti mú wá, wọn yíò sì gbọ́ ohùn mi; agbo kanṣoṣo ni yíò sì wà, àti olùṣọ́-àgùtàn kanṣoṣo.
22 Ọ̀rọ̀ mi kò sì yé wọn, nítorítí wọ́n rò wípé àwọn Kèfèrí ni; nítorítí kò yé wọn pé àwọn Kèfèrí yíò yí lọ́kàn padà nípasẹ̀ ìwãsù wọn.
23 Ọ̀rọ̀ mi kò sì yé wọn nígbàtí èmi wípé wọn yíò gbọ́ ohùn mi; ọ̀rọ̀ mi kò sì yé wọn pé àwọn Kèfèrí kò lè gbọ́ ohùn mi ni gba kankan—pé èmi kò lè fi ara mi hàn sí wọn bíkòṣe nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́.
24 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ti gbọ́ ohun mi pẹ̀lú, ẹ sì ti rí mi; àgùtàn mi ni ẹ̀yin sì íṣe, a sì ti kà yín mọ́ ara àwọn tí Bàbá ti fifún mi.