Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 16


Orí 16

Jésù yíò bẹ̀ àwọn míràn nínú àwọn àgùtàn Ísráẹ́lì tí ó sọnù wò—Ní àwọn ọjọ́ ti ìkẹhìn ìhìn-rere nã yíò lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn Kèfèrí lẹ́hìnnã yíò lọ sí ìdílé Ísráẹ́lì—Àwọn ènìyàn Olúwa yíò ríi ní ojúkojú nígbàtí yíò mú Síónì padà bọ̀ wá. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín pé èmi ní àwọn àgùtàn míràn, tí wọn kò sí nínú ilẹ̀ yĩ, bẹ̃ni wọn kò sí nínú ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, bẹ̃ni wọn kò sí nínú ilẹ̀ nnì tí ó wà ní àyíká ibití èmi ti lọ jíṣẹ́ ìránṣẹ́.

2 Nítorí àwọn tí èmi nsọ̀rọ̀ nípa wọn ni àwọn tí wọn kò ì gbọ́ ohùn mi; bẹ̃ni èmi kò ì fi ìgbà kan fi ara hàn sí wọn.

3 Ṣùgbọ́n èmi ti gba òfin kan láti ọ̀dọ̀ Bàbá mi pé kí èmi ó lọ sí ọ̀dọ̀ wọn, àti pé wọn yíò gbọ́ ohùn mi, a ó sì kà wọ́n mọ́ àwọn àgùtàn mi, láti lè jẹ́ kí agbo kanṣoṣo ó wà àti olùṣọ́-àgùtàn kanṣoṣo; nítorínã ni èmi yíò lọ láti fi ara mi hàn sí wọn.

4 Èmi sì pàṣẹ fún yín pé kí ẹ̀yin ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ mi wọ̀nyí lẹ́hìn tí èmi bá ti lọ, pé bí àwọn ènìyàn mi tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, àwọn tí ó ti rí mi tí wọ́n sì ti wà pẹ̀lú mi nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi, bí wọn kò bá bẽrè lọ́wọ́ Bàbá ní orúkọ mi, kí wọn ó ní ìmọ̀ nípa yín nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, àti nípa àwọn ẹ̀yà míràn nnì tí wọn kò mọ̀ nípa wọn, pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tí ẹ̀yin yíò kọ yíò wà ní ìpamọ́ a ó sì fi wọ́n hàn fún àwọn Kèfèrí, pé nípasẹ̀ ẹ̀kún àwọn Kèfèrí, ìyókù irú-ọmọ wọn, àwọn tí a ó fọ́nká kiri orí ilẹ̀ ayé nítorí àìgbàgbọ́ wọn, ki wọ́n lè wọle a ó mú wọn sínú ìmọ̀ nípa mi, Olùrapadà wọn.

5 Nígbànã ni èmi yíò sì kó wọn jọ láti igun mẹ́rẹ̃rin ayé; nígbànã ni èmi yíò sì mú májẹ̀mú nã èyítí Bàbá ti dá pẹ̀lú gbogbo àwọn ènìyàn ìdílé Ísráẹ́lì ṣẹ.

6 Alabukun sì ni fún àwọn Kèfèrí, nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi, nínú àti nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́, èyítí o jẹ̃rí sí wọn nípa mi àti nípa Bàbá.

7 Ẹ kíyèsĩ, nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi, bẹ̃ni Bàbá wí, àti nítorí àìgbàgbọ́ rẹ, A! ìdílé Ísráẹ́lì, ní ọjọ́ ìkẹhìn ni òtítọ́ yíò tọ àwọn Kèfèrí wá, kí ẹ̀kún àwọn ohun wọ̀nyí ó lè di mímọ̀ sí wọn.

8 Ṣùgbọ́n ègbé ni, bẹ̃ni Bàbá wí, fún àìgbàgbọ́ àwọn Kèfèrí—nítorípé l’áìṣírò wọ́n ti jáde wá sí orí ilẹ̀ yĩ, tí wọ́n sì fọ́n àwọn ènìyàn mi tí wọn jẹ́ ti ìdílé Ísráẹ́lì ká; àwọn ènìyàn mi tí wọ́n jẹ ti ìdílé Ísráẹ́lì ni wọ́n ti lé jáde kúrò lãrín wọn. tí wọ́n sì di ìtẹ̀mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ wọn;

9 Àti nítorí ãnú Bàbá sí àwọn Kèfèrí, àti ìdájọ́ Bàbá pẹ̀lú, lórí àwọn ènìyàn mi tí wọ́n jẹ́ ti ìdílé Ísráẹ́lì, lóotọ́, lóotọ́ ni mo wí fún yín, pé lẹ́hìn gbogbo èyí, tí èmi sì ti mú kí wọn ó kọlù àwọn ènìyàn mi tí wọn jẹ́ ti ìdílé Ísráẹ́lì, àti kí wọn ó pọ́n wọn lójú, àti kí wọn ó pa wọ́n, àti kí wọn ó lé wọn jáde kúrò lãrín wọn, àti kí wọn ó kórìra wọn, àti kí wọn ó di òṣé àti ìfiṣẹ̀sìn lãrín wọn—

10 Báyĩ sì ni Bàbá pàṣẹ pé kí èmi ó wí fún yín: Ní ọjọ́ nã nígbàtí àwọn Kèfèrí yíò ṣẹ̀ sí ìhirere mi, àti tí wọn yíò kọ ẹ̀kún ìhìn-rere mi, tí wọn yíò sì rú ọkàn wọn sókè nínú ìgbéraga ọkàn wọ́n lórí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti lórí gbogbo ènìyàn tí ó wà nínú gbogbo ayé, àti nígbàtí wọn yíò kún fún onírurú irọ́ pípa, àti ẹ̀tàn, àti ìwà ìkà, àti onírurú ìwà àgàbàgebè, àti ìpànìyàn, àti iṣẹ́ àlùfã àrekérekè, àti ìwà àgbèrè, àti ti ohun ìríra ìkọ̀kọ̀; àti ti wọ́n bá sì ṣe gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí àti pé bí wọ́n bá sì kọ ẹ̀kún ìhìn-rere mi nã, ẹ kíyèsĩ, ni Bàbá wí, èmi yíò mú ẹ̀kún ìhìn-rere mi kúrò lãrín wọn.

11 Àti nígbànã ni èmi yíò rántí májẹ̀mú mi èyítí èmi ti bá àwọn ènìyàn mi dá, A! ìdílé Ísráẹ́lì, èmi yíò sì mú ìhìn-rere mi tọ̀ wọ́n wá.

12 Èmi yíò sì fi hàn ọ́, A! ìdílé Ísráẹ́lì, pé àwọn Kèfèrí kì yíò ní agbára lórí rẹ; ṣùgbọ́n èmi yíò rántí májẹ̀mú mi sí ọ, A! ìdílé Ísráẹ́lì, ìwọ yíò sì wá sínú ìmọ̀ ẹkun ìhìn-rere mi.

13 Ṣùgbọ́n bí àwọn Kèfèrí yíò bá ronúpìwàdà tí wọn sì padà sí ọ̀dọ̀ mi, ni Bàbá wí, ẹ kíyèsĩ a ó kà wọ́n mọ́ àwọn ènìyàn mi A! ìdílé Ísráẹ́lì.

14 Èmi kò sì ní gbà kí àwọn ènìyàn mi, tí wọn jẹ́ ti ìdílé Ísráẹ́lì, ó kọjá lãrín wọn, kí wọn ó tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀ ni Bàbá wí.

15 Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá yí padà sí ọ̀dọ̀ mi, kí wọn ó sì fetísílẹ̀ sí ohùn mi, èmi yíò jẹ́ kí wọn, bẹ̃ni, èmi yíò jẹ́ kí àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì, kí wọn ó kọjá lọ lãrín wọn, kí wọn ó sì tẹ̀ wọ́n mọ́lẹ̀, wọn ó sì dà bí iyọ̀ tí ó ti sọ adùn rẹ̀ nù, tí kò sì dára mọ́ fún ohunkóhun ṣùgbọ́n kí a dã sóde, àti kí a tẹ̃ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mi, A! ìdílé Ísráẹ́lì.

16 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, báyĩ ni Bàbá ti pãláṣẹ fún mi—pé kí èmi ó fún àwọn ènìyàn yí ní ilẹ̀ yĩ fún ìní wọn.

17 Nígbànã ni ọ̀rọ̀ wòlĩ Isaiah yíò di mìmúṣẹ, èyítí ó wípé:

18 Àwọn àlóre rẹ yíò gbé ohùn sókè; wọn yíò jùmọ̀ kọrin pẹ̀lú ohùn nã, nítorítí wọn yíò ríi ní ojúkojú nígbàtí Olúwa yíò mú Síónì padà.

19 Ẹ bú sí ayọ̀, ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù; nítorítí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó ti ra Jerúsálẹ́mù padà.

20 Olúwa ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; gbogbo ìkangun ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run.