Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 3


Orí 3

Gídíánhì, olórí àwọn Gádíátónì, fi agbára bẽrè pé kí Lákónéúsì àti àwọn ará Nífáì jọ̀wọ́ ara nwọn àti àwọn ilẹ̀ nwọn sílẹ̀—Lákónéúsì yàn Gídgídónì gẹ́gẹ́bí olórí-ológun àgbà fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun—Àwọn ará Nífáì péjọ pọ̀ sí Sarahẹ́múlà àti Ibi-Ọ̀pọ̀ láti dãbò bò ara wọn. Ní ìwọ̀n ọdún 16 sí 18 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe ní ọdún kẹrìndínlógún sí ìgbà tí Krístì ti dé, Lákónéúsì, bãlẹ̀ ilẹ̀ nã, sì rí ìwé kan gbà láti ọwọ́ olórí àti bãlẹ àwọn ẹgbẹ́ ọlọ́ṣà yĩ; àwọn wọ̀nyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ, wípé:

2 Lákónéúsì, bãlẹ àgbà ilẹ̀ wa àti ẹni olọ́lá jùlọ, kíyèsĩ, mo kọ èpístélì yĩ sí ọ́, mo sì yìn ọ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìdúróṣinṣin rẹ, àti ìdúróṣinṣin àwọn ènìyàn rẹ pẹ̀lú, ní dídi èyítí ẹ̀yin rò wípé ó jẹ́ ẹ̀tọ́ àti òmìnira nyín mú; bẹ̃ni, ẹ̀yin duro gbọin-gbọin, bí ẹnipé òrìṣà kan ràn nyín lọ́wọ́, nínú ìdãbò òmìnira nyín, àti ohun ìní nyín, àti ìlú nyín, tàbí èyítí ẹ̀yin npè bẹ̃.

3 Ó sì jẹ́ ohun ìkãnú fún mi, Lákónéúsì ẹni ọlọ́lá jùlọ, pé ìwọ yíò jẹ́ aṣiwèrè àti agbéraga tóbẹ̃ tí o lè rò pé ìwọ lè dojúkọ àwọn ẹnití ó ní ìgboyà tí ó pọ̀ báyĩ tí ó wà ní abẹ́ àṣẹ mi, tí nwọ́n duro ni àkókò yi nínú ohun ìjà nwọn, tí nwọ́n sì ndúró pẹ̀lú ìtara fún àṣẹ nã pé—Ẹ lọ láti kọlu àwọn ará Nífáì kí ẹ sì pa nwọ́n run.

4 Nítorípé èmi sì mọ̀ nípa ìgboyà nwọn pé kò sí ẹnití ó lè borí nwọn; nítorítí mo ti dán wọn wò lójú ogun, àti nítorípé èmi mọ̀ nípa ìkórira títí ayé tí nwọ́n ní sí yín nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìwà ìpanilára tí ẹ̀yin ti hù sí wọn, nítorínã bí nwọ́n bá wá láti kọlù yín nwọn yíò bẹ̀ yín wò pẹ̀lú ìparun pátápátá.

5 Nítorínã ni èmi ṣe kọ èpístélì yĩ, tí mo fi èdìdí dĩ pẹ̀lú ọwọ́ ara mi, nítorípé mo ní ìtara fún àlãfíà yín, nítorí ìdúróṣinṣin yìn nínú èyítí ẹyìn gbàgbọ́ pé ó tọ̀nà, àti ẹ̀mí yín tí ó lọ́lá ní ojú ogun.

6 Nítorínã ni èmi ṣe kọ ìwé sí yín, nítorípé mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó jọ̀wọ́ àwọn ìlú-nlá yín, àwọn ilẹ̀ yín, àti àwọn ohun ìní yín fún àwọn ènìyàn mi yĩ, ju kí nwọn ó fi idà bẹ̀ yín wò tí ìparun yíò sì bá yín.

7 Tàbí ní ọ̀rọ̀ míràn, ẹ jọ̀wọ́ ara yín sílẹ̀ fún wa; kí ẹ sì darapọ̀ mọ́ wa kí ẹ sì ní òye nípa àwọn iṣẹ́ òkùnkùn wa, kí ẹ sì di arákùnrin wa kí ẹ̀yin ó lè rí bí àwa ti rí—kĩ ṣe ẹrú wa, ṣùgbọ́n arákùnrin wa àti alábãpín nínú gbogbo ohun-ìní wa.

8 Sì kíyèsĩ, mo búra pẹ̀lú rẹ, bí ẹ̀yin o bá ṣe eleyĩ, pẹ̀lú ìbúra, a kò ní pa yín run; ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá ní ṣe eleyĩ, èmi búra fún ọ pẹ̀lú ìbúra, pé ní oṣù èyítí nbọ̀ èmì yíò pàṣẹ fún àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun mi kí wọn ó sọ̀ka lẹ̀ wá láti kọlũ ọ́, nwọn kò sì ní dáwọ́ dúró, nwọn kò sì ní dá ẹnìkẹ́ni sí, ṣùgbọ́n wọn yíò pa yín, wọn yíò sì mú kí idà wọn ó ṣubú lù yín àní títí ẹ̀yin ó fi di aláìsí.

9 Sì kíyèsĩ, èmi ni Gídíánhì; èmi sì ni bãlẹ̀, ẹgbẹ́ òkùnkùn Gádíátónì yĩ; ẹgbẹ́ àti iṣẹ́ èyítí èmi mọ̀ wípé ó dára; nwọ́n sì jẹ́ ti ìgbà àtijọ́ tí nwọ́n sì ti fií lé wa lọ́wọ́.

10 Èmi sì kọ èpístélì yĩ sí ọ, Lákónéúsì, èmi sì ní ìrètí pé ẹ̀yin yíò fi àwọn ilẹ̀ yín àti àwọn ohun-ìní yín lé wa lọ́wọ́, láìsí ìtàjẹ̀sílẹ̀, kí àwọn ènìyàn mi yĩ ó lè gba ẹ̀tọ́ àti ìjọba wọn padà, àwọn ẹni ti wọn ti yapa kúrò lára yín nítorí ìwà búburú yín láti fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n nínú ìjọba, bí ẹ̀yin kò bá sì ṣe èyí, èmi yíò gbẹ̀san. Ẹmí ni Gídíánhì.

11 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Lákónéúsì gba èpístélì yĩ, ẹnu yã lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ìgboyà tí Gídíánhì ní láti fi agbára bẽrè fún níní ilẹ̀ àwọn ará Nífáì ní ìní, àti láti kìlọ̀ fún àwọn ènìyàn nã àti láti gbẹ̀san àwọn tí a kò ṣẹ̀, bíkòṣe pé àwọn ni ó ṣẹ ara wọn nípa yíyapa kúrò lọ sí ọ́dọ̀ àwọn ọlọ́ṣà oníwà búburú àti oníríra ènìyàn nnì.

12 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, Lákónéúsì yĩ, tí íṣe bãlẹ̀, jẹ́ ènìyàn tí ó tọ́, àwọn ìbẽrè àti ìkìlọ̀ ọlọ́ṣà kò sì lè dẹ́rùbà á; nítorínã kò fetísílẹ̀ sí èpístélì Gídíánhì, bãlẹ̀ àwọn ọlọ́ṣà nã, ṣùgbọ́n ó mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ ó kígbe pe Olúwa fún agbára fún àkokò nã tí àwọn ọlọ́ṣà nã yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti kọlù wọ́n.

13 Bẹ̃ni, ó fi ìkéde ránṣẹ́ sí ãrín àwọn ènìyàn gbogbo, pé kí wọn ó kó àwọn obìnrin wọn jọ, àti àwọn ọmọ wọn, àti àwọn ọ̀wọ́ ẹran wọn àti àwọn agbo ẹran wọn, àti gbogbo ohun-ìní wọn, bíkòṣe ilẹ̀ wọn nikan, sí ojúkan.

14 Ó sì mú kí wọn ó mọ́ àwọn odi yí wọn ká, kí agbára nwọn ó sì pọ̀ púpọ̀. Ó sì mú kí àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun, àti ti àwọn ará Nífáì àti ti àwọn ará Lámánì, tàbí tí gbogbo àwọn tí a kà mọ́ àwọn ará Nífáì, kí a fi wọ́n ṣe ẹ̀ṣọ́ yíká kiri láti ṣọ́ wọn, àti láti dãbò bò wọ́n lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà nã ní ọ̀sán àti ní òru.

15 Bẹ̃ni, ó wí fún wọn pé: Bí Olúwa ti wà lãyè, bí kò ṣe pé ẹ̀yin bá ronúpìwàdà gbogbo àìṣedẽdé yín, tí ẹ sì kígbe pe Olúwa, kò sí ọ̀nà tí a fi lè gbà yín kúrò lọ́wọ́ àwọn ọlọ́ṣà Gádíátónì nnì.

16 Títóbi àti ìyàlẹ́nu ni àwọn ọ̀rọ̀ àti àsọtẹ́lẹ̀ Lákónéúsì sì jẹ́ tóbẹ̃ ti wọn mú kí ẹ̀rù kí ó bá gbogbo àwọn ènìyàn nã; tí wọ́n sì sa gbogbo agbára wọn láti ṣe gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ Lákónéúsì.

17 Ó sì ṣe tí Lákónéúsì yan àwọn olórí-ogun àgbà lórí gbogbo awọn egbẹ́ ọmọ-ogun Nífáì, láti darí wọn ní àkokò tí àwọn ọlọ́ṣà nã yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti inú aginjù láti kọlù wọ́n.

18 Nísisìyí a yàn èyítí ó ga jùlọ nínú gbogbo àwọn olórí-ogun àgbà nã àti olùdarí-àgbà gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun àwọn ará Nífáì, orúkọ rẹ̀ sì ni Gídgídónì.

19 Nísisìyí ojẹ àṣà lãrín gbogbo àwọn ará Nífáì láti yàn gẹ́gẹ́bí olórí-ogun àgbà wọn, (àfi ní àkokò ìwà búburú wọn) ẹnití ó ní ẹ̀mí ìfihàn àti ìsọtẹ́lẹ̀; nítorínã, Gídgídónì yĩ jẹ́ wòlĩ ńlá lãrín wọn, gẹ́gẹ́bí onidajọ àgbà nã ti jẹ́.

20 Nísisìyí àwọn èniyàn nã wí fún Gídgídónì pé: Gbàdúrà sí Olúwa, kí o sì jẹ́ kí àwa ó lọ sí órí àwọn òkè gíga àti sínú aginjù, kí àwa ó lè kọ lu àwọn ọlọ́ṣà nã kí a sì pa wọ́n run nínú ilẹ̀ wọn.

21 Ṣùgbọ́n Gídgídónì wí fún wọn pé: Olúwa kà á lẽwọ̀; nítorítí bí àwa bá gòkè lọ láti kọlù wọ́n Olúwa yíò fi wá lé wọn lọ́wọ́; nítorínã àwa yíò múrasílẹ̀ ní ãrín àwọn ilẹ̀ wa, àwa yíò sì kó gbogbo àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa jọ, àwa kò sì ní lọ láti kọlù wọ́n, ṣùgbọ́n àwa yíò dúró de ìgbà tí wọn yíò wá kọlù wá; nítorínã bí Olúwa ṣe wà lãyè, bí àwa bá ṣe èyí òun yíò fi wọ́n lé wa lọ́wọ́.

22 Ó sì ṣe ní ọdún kẹtàdínlógún, nígbati ọdún nã fẹ́rẹ̀ parí, ìkéde Lákónéúsì ti kọjá lọ jákè-jádò orí ilẹ̀ nã, tí wọ́n sì ti kó àwọn ẹṣin wọn, àti àwọn kẹ̀kẹ́-ogun wọn, àti àwọn ẹran ọ̀sìn wọn, àti gbogbo ọ̀wọ́ ẹran wọn, àti gbogbo agbo ẹran wọn, àti àwọn ọkà wọn, àti gbogbo ohun-ìní wọn, tí wọ́n sì kọjá lọ ní ẹgbẹ̃gbẹ̀rún àti ẹgbẹ̃gbẹ̀rún mẹ́wã, títí gbogbo wọn fi kọjá lọ sí ibití a ti yàn fún wọn láti kó ara wọn jọ sí, láti dãbò bò ara wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn.

23 Ilẹ̀ tí a sì ti yàn nã sì ni ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti ilẹ̀ tí ó wà lãrín ilẹ̀ Sarahẹ́múlà àti ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀, bẹ̃ni, títí dé ãlà-ilẹ̀ tí ó wà lãrín ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀ àti ilẹ̀ Ibi-Ahoro.

24 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹgbẹ̀rún nlá ènìyàn ni a sì npè ní ará Nífáì, tí wọ́n sì kó ara wọn jọ pọ sínú ilẹ̀ yĩ. Nísisìyí Lákónéúsì sì mú kí wọn ó kó ara wọn jọ sínú ilẹ̀ ti apá gúsù nítorí ègún nlá tí ó wà lórí ilẹ̀ ti apá àríwá.

25 Wọ́n sì dãbò bò ara wọn lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wọn; wọ́n sì ngbé inú ilẹ̀ kanṣoṣo, àti ní ìsọ̀kán, wọn sì bẹ̀rù àwọn ọ̀rọ̀ ti Lákónéúsì ti sọ, tóbẹ̃ tí wọ́n ronúpìwàdà gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn; wọ́n sì gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run wọn, pé kí ó gbà wọ́n ní àkokò tí àwọn ọ̀tá wọn yíò sọ̀kalẹ̀ wá dojú ogun kọ wọ́n.

26 Wọ́n sì kún fún ìbànújẹ́ gidigidi nítorí àwọn ọ̀tá wọn. Gídgídónì sì mú kí wọ́n rọ àwọn ohun-ìjà ogun lónírũrú, pé kí wọn ó sì wà ní ipò agbára pẹ̀lú àwọn ìhámọ́ra, àti pẹ̀lú àwọn oun ìdábò bò wọn, àti pẹ̀lú àwọn asà, ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ rẹ̀.