Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 28


Orí 28

Mẹ́sán nínú àwọn ọmọ-ẹ̀hìn nã fẹ́ láti ní ogún nínú ìjọba Krístì nígbàtí wọ́n bá kú, a sì pinnu rẹ̀ fún wọn—Àwọn ọmọ-ẹ̀hìn mẹ́ta tí ó kù fẹ́ láti ní agbára lórí ikú kí wọn ó lè wà láyé títí Jésù yíò tún padà bọ̀, a sì fún wọn—A ṣí wọn nípò padà wọ́n sì rí àwọn ohun tí ó lòdì si òfin lati sọ, wọ́n sì nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn. Ní ìwọ̀n ọdún 34 sí 35 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó bá àwọn ọmọ-ẹ̀hìn rẹ̀ sọ̀rọ̀, ní ọ̀kọ̀kan, wípé: Kíni ìwọ fẹ́ kí èmi ó fún ọ, lẹ́hìn tí èmi yíò ti lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá?

2 Gbogbo wọn ní ó sì sọ̀rọ̀, àfi àwọn mẹta, wípé: Àwa fẹ́ lẹ́hìn tí àwa ó bá ti lo ọjọ́ orí wa tán, tí iṣẹ́ ìránṣẹ́ wa, èyítí ìwọ pè wá sí, yíò ti parí, kí àwa ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ nínú ìjọba rẹ ní kánkán.

3 Ó sì wí fún wọn pé: Alábùkún-fún ni ẹ̀yin íṣe nítorítí ẹ̀yin fẹ́ èyí láti ọwọ́ mi; nítorínã, lẹ́hìn tí ẹ̀yin báti pé ọmọ ọdún méjì lé ní ãdọ́rin ẹ́ ó wá sí ọ̀dọ̀ mi nínú ìjọba mi; ẹyin yíò sì rí ìsimi ní ọ̀dọ̀ mi.

4 Nígbàtí ó sì ti bá wọn sọ̀rọ̀ tán, ó dojú kọ àwọn mẹ́ta nnì, ó sì wí fún wọn pé: Kíni ẹ̀yin fẹ́ kí èmi ó ṣe fún yín, lẹ́hìn tí èmi yíò ti lọ sí ọ̀dọ̀ Bàbá?

5 Wọn sì kẹ́dùn nínú ọkàn wọn, nítorípé wọn kò jẹ́ sọ ohun tí wọn fẹ́ fún un.

6 Ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, mo mọ́ èrò ọkàn yín, ẹ̀yin sì ti fẹ́ ohun nã èyítí Jòhánnù, àyànfẹ́ mi, ẹnití ó wà pẹ̀lú mi nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ mi kí àwọn Jũ ó tó gbé mi sókè, fẹ́ kí èmi ó ṣe fún òun.

7 Nítorínã, alábùkún-fún jùlọ ni ẹ̀yin íṣe, nítorípé ẹ̀yin kò ní rí ikú; ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò wà lãyè láti lè rí gbogbo ìṣe Bàbá sí àwọn ọmọ ènìyàn, àní títí a ó fi mú ohun gbogbo ṣẹ ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́ Bàbá, nígbàtí èmi yíò dé nínú ògo mi pẹ̀lú àwọn agbára ọ̀run.

8 Ẹ̀yin kì yíò sì rí ìrora ikú; ṣùgbọ́n nígbàtí èmi yíò bá dé nínú ògo mi, a ó pa yín láradá ní ìṣẹ́jú láti inú ara kíkú sí ara àìkú; nígbànã ni ẹ̀yin o di alábùkún-fún nínú ìjọba Bàbá mi.

9 Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin kì yíò sì rí ìrora ní àkokò tí ẹ̀yin ó wà nínú ara, bẹ̃ni ẹ̀yin kì yíò ní ìrora-ọkàn bíkòṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé; gbogbo ohun wọ̀nyí ni èmi yíò sì ṣe nítorí ohun tí ẹ̀yin bẽrè lọ́wọ́ mi, nítorípé ẹ̀yin ti fẹ́ kí ẹ̀yin ó lè mú ọkàn àwọn ènìyàn wá sí ọ̀dọ̀ mi, nígbàtí ayé bá sì wà.

10 Àti nítorí ìdí èyí, ẹ̀yin ó ní ẹ̀kún ayọ̀; ẹ̀yin ó sì joko nínú ìjọba Bàbá mi; bẹ̃ni, ayọ̀ yín yíò kún, gẹ́gẹ́bí Bàbá ti fún mi ní ẹ̀kún ayọ̀; ẹ̀yin ó sì rí gẹ́gẹ́ bí èmi ti rí, èmi sì rí gẹ́gẹ́ bí Bàbá; ọ̀kan sì ni Bàbá àti èmi jẹ́.

11 Ẹ̀mí Mímọ́ sì njẹ́rĩ nípa Bàbá àti èmi; Bàbá sì nfi Ẹ̀mí Mímọ́ fún àwọn ọmọ ènìyàn, nítorí mi.

12 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, ó fi ọwọ́ rẹ̀ kan olúkúlùkù wọn, àfi àwọn mẹ́ta nnì tí yíò kù lẹ́hìn, nígbànã ni ó lọ kúrò.

13 Ẹ sì kíyèsĩ, awọn ọ̀run sí sílẹ̀, a sì gbé wọn lọ sínú ọ̀run, wọn sì ri, wọ́n sì gbọ́ àwọn ohun tí a kò lè sọ.

14 A sì dá wọn lẹ́kun láti fọhùn; bẹ̃ni a kò fún wọn ní agbára láti lè sọ àwọn ohun tí wọn rí àti tí wọn gbọ́;

15 Àti bóyá nínú ara ni tàbí kúrò nínú ara ni, wọn kò mọ̀; nítorítí wọ́n dàbí èyítí ó yípadà tí a yí wọn padà kúrò láti inú ipò àgọ́ ara sínú ipò ara àìkú, kí wọn ó lè rí àwọn ohun ti Ọlọ́run.

16 Ṣùgbọ́n ó sì ṣe tí wọ́n tún njíṣẹ́ ìránṣẹ́ ní orí ilẹ̀ ayé; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò jíṣẹ́ ìránṣẹ́ nípa àwọn ohun tí wọ́n ti gbọ́ àti tí wọn ti rí, nítorí àṣẹ tí a fi fún wọn ní ọ̀run.

17 Àti nísisìyí, bóyá wọ́n wà ní ipò ìdibàjẹ́ tàbí ní àìkú, láti àkokò ìyípadà-ara wọn, èmi kò mọ̀;

18 Ṣùgbọ́n èyí ni èmi mọ̀, gẹ́gẹ́bí àkọsílẹ̀ tí a ti kọ—wọn nlọ kiri lórí ilẹ̀ nã, wọ́n sì njíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún gbogbo àwọn ènìyàn nã, tí wọ́n sì nda ọ̀pọ̀lọpọ̀ mọ́ ìjọ onígbàgbọ́ nã, gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ìwãsù wọn; tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi fún wọn, gbogbo àwọn tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi fun ni ó gba Ẹ̀mí Mímọ́.

19 Àwọn tí kò darapọ̀ mọ́ ìjọ onígbàgbọ́ nã sì gbé wọn sọ sínú túbú. Àwọn túbú kò sì lè gbà wọ́n, nítorítí wọ́n sì ya sí méjì.

20 Wọn sì gbé wọn sọ sínú ihò ilẹ̀; ṣùgbọ́n wọn bá ilẹ̀ nã jà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run; tóbẹ̃ tí a fi kó wọn yọ kúrò nínú jíjìn ilẹ̀ nã nípa agbára rẹ̀; àti nítorínã wọn kò lè gbẹ́ ihò ilẹ̀ jìn tó tí yíò le sé wọn mọ́.

21 Ìgbà mẹ́ta ni wọ́n sì gbé wọn sọ sínú iná ìléru tí wọn kò sì rí ìpalára.

22 Ìgbà méjì ni wọ́n sì gbé wọn jù sínú ihò àwọn ẹranko búburú; ẹ sì kíyèsĩ wọn bá àwọn ẹranko búburú nã ṣeré bí ọmọdé ti íbá ọ̀dọ́-àgùtàn ṣeré, wọn kò sì rí ìpalára.

23 Ó sì ṣe tí wọ́n nlọ kiri lãrín àwọn ènìyàn Nífáì báyĩ, tí wọ́n sì nwãsù ìhìn-rere Krístì fún gbogbo ènìyàn ní orí ilẹ̀ nã; a sì yí wọn padà sí Olúwa, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ ìjọ Krístì, báyĩ sì ni àwọn ènìyàn ìran nnì di alábùkún-fún, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Jésù.

24 Àti nísisìyí èmi, Mọ́mọ́nì, mú ọ̀rọ̀ mi wá sí òpin nípa àwọn ohun wọ̀nyí ná.

25 Ẹ kíyèsĩ, èmi ti fẹ́rẹ̀ kọ orúkọ àwọn wọnnì tí kì yíò tọ́ ikú wò, ṣùgbọ́n Olúwa dá mi lẹ́kun rẹ̀; nítorínã ni èmi kò kọ wọ́n, nítorítí a ti fi wọ́n pamọ́ kúrò fún aráyé.

26 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ èmi ti rí wọn, wọ́n sì ti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún mi.

27 Ẹ sì kíyèsĩ, wọn yíò wà lãrín àwọn Kèfèrí, àwọn Kèfèrí kò sì ní mọ̀ wọ́n.

28 Wọn yíò sì wà lãrín àwọn Jũ pẹ̀lú, àwọn Jũ kò sì ní mọ̀ wọ́n.

29 Yíò sì ṣe, nígbàtí Olúwa yíò ríi pé ó tọ́ nínú ọgbọ́n rẹ̀ ni wọn yíò jíṣẹ́ ìránṣẹ́ sí àwọn ẹ̀yà ìdílé Ísráẹ́lì tí ó ti fọ́nká, àti sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn, tí yíò sì mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọkàn jáde kúrò nínú wọn sí ọ̀dọ̀ Jésù, kí ìfẹ́ wọn ó lè di mímúṣẹ, àti nítorí agbára ti ìyínilọ́kàn padà èyítí íṣe ti Ọlọ́run tí ó wà nínú wọn.

30 Wọ́n sì dàbí àwọn ángẹ́lì Ọlọ́run, bí wọn ó bá sì gbàdúrà sí Bàbá ní orúkọ Jésù, wọn lè fi ara hàn sí ẹnìkẹ́ni tí ó bá dára ní ojú wọn.

31 Nítorínã, wọn yíò ṣe àwọn iṣẹ́ nlá èyítí ó yanilẹ́nu, kí ọ̀jọ́ nlá tí nbọ̀wá nnì nígbàtí gbogbo ènìyàn yíò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Krístì;

32 Bẹ̃ni ní ãrin àwọn Kèfèrí pãpã ni wọn ó ti ṣe iṣẹ́ nlá èyítí ó yanilẹ́nu, kí ọjọ́ ìdájọ́ nnì ó tó dé.

33 Bí ẹ̀yin bá sì ní gbogbo àwọn ìwé-mímọ́ tí ó sọ nípa gbogbo iṣẹ́ ìyàlẹ́nu Krístì, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé àwọn ohun wọ̀nyí yíò ṣẹ dájúdájú, gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ tí Krístì ti sọ.

34 Ègbé sì ni fún ẹnìkẹ́ni tí yíò ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Jésù, àti sí ọ̀rọ̀ àwọn tí ó ti yàn tí ó sì rán lọ sí ãrin wọn; nítorípé ẹnití kò bá gba ọ̀rọ̀ Jésù àti ti ọ̀rọ̀ àwọn tí ó ti rán kò gbã; nítorínã, òun kò ní gbà wọ́n ní ọjọ́ ìkẹhìn;

35 Ìbá sì sàn fún wọn bí a kò bá bí wọn. Njẹ́ ẹ̀yin ha rò pé ẹ̀yin lè sọ àìṣègbè Ọlọ́run tí a ti ṣẹ̀ sí di asán, ẹnití a tì tẹ mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ ènìyàn, pé ní ọ̀nà yĩ ni ìgbàlà yíò wá?

36 Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, bí èmi ti sọ nípa àwọn wọnnì tí Olúwa ti yàn, bẹ̃ni, àní àwọn mẹ́ta wọnnì tí a gbé lọ sínú àwọn ọ̀run, pé èmi kò mọ̀ bóyá a wẹ̀ wọ́n mọ́ kúrò láti inú ara kíkú sí ara àìkú—

37 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ, láti àkokò tí èmi ti kọ àkọsílẹ̀ yĩ, ni èmi ti wádĩ láti ọ̀dọ̀ Olúwa, òun sì ti sọọ́ di mímọ̀ fún mi pé ó di dandan kí ara wọn ó yí padà, bí kò bá sì rí bẹ̃ wọn níláti tọ́ ikú wò;

38 Nítorínã, kí wọn ó má bãtọ́ ikú wò ni a ṣe mú kí ara wọn ó yípadà, kí wọn ó má bá ní ìrora tàbí ìrora-ọkàn bíkòṣe nítorí ẹ̀ṣẹ̀ aráyé.

39 Nísisìyí ìyípadà yĩ kò tóbi tó èyítí yíò bá wọn ní ọjọ́-ìkẹhìn; ṣùgbọ́n a mú ìyípadà nlá bá wọn, tóbẹ̃ tí Sátánì kò lè ní agbára rárá lórí wọn, tí kò lè dán wọn wò; tí a sì yà wọ́n sí mímọ́ nípa ti ara, tí wọ́n sì jẹ́ mímọ́, àti tí àwọn agbára inú ayé kò lè dí wọn lọ́nà.

40 Èyí sì ni ipò tí wọn yíò wà títí di ọjọ́ ìdájọ́ Krístì; ní ọjọ́ nã wọn yíò rí ìyípadà nlá gbà, a ò sì gbà wọ́n sínú ìjọba Bàbá, tí wọn kò sì ní jáde kúrò níbẹ̀ mọ́, ṣùgbọ́n wọn yíò gbé pẹ̀lú Ọlọ́run títí ayérayé nínú òkè-ọ̀run.