Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 12


Orí 12

Jésù pe àwọn Méjìlá ó sì fi àṣẹ fún wọn—Ó fi ìdáni-lẹ́kọ fún àwọn ará Nífáì èyítí ó jọ Ìwãsù lórí Òkè—Ó sọ ọ̀rọ̀ Ìbùkún nnì—Ìkọ́ni rẹ̀ tayọ òfin Mósè ó sì tún ṣíwájú rẹ̀—A pàṣẹ fún gbogbo ènìyàn láti wà ní pípé àní gẹ́gẹ́bí òun àti Bàbá rẹ̀ ti wà ní pípé—A fi orí ìwé yĩ wé Máttéù 5. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí parí fún Nífáì, àti fún àwọn tí a ti pè, (báyĩ iye àwọn tí a ti pè, tí nwọ́n sì ti gba agbára àti àṣẹ láti ṣe ìrìbọmi, jẹ́ méjìlá) sì kíyèsĩ, ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde sí àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, ó sì gbé ohùn rẹ̀ sókè sí wọn, wípé: Alábùkún-fún ni ẹ̀yin bí ẹ̀yin ó bá ṣe àkíyèsí àwọn ọ̀rọ̀ àwọn méjìlá tí èmi ti yàn lãrín yín láti ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún yín, àti láti jẹ́ ìránṣẹ̃ yín; àwọn ni èmi sì fi agbára fún láti lè ṣe ìrìbọmi fun yín pẹ̀lú omi; lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá sì ti ṣe ìrìbọmi pẹ̀lú omi, ẹ kíyèsĩ, èmi yíò ṣe ìrìbọmi fun yín pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́; nítorínã alábùkún-fún ni ẹ̀yin bí ẹ̀yin ó bá gbà mí gbọ́ tí a sì rì yín bọmi, lẹ́hìn tí ẹ̀yin ti rí mi tí ẹ sì mọ̀ pé èmi ni.

2 Àti pẹ̀lú, alábùkún-fún jùlọ ni àwọn tí yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ yín gbọ́ nítorítí ẹ̀yin ó jẹ́rĩ pé ẹ̀yin ti rí mi, àti pé ẹ̀yin mọ̀ pé èmi ni. Bẹ̃ni, alábùkún-fún ni àwọn tí yíò gba àwọn ọ̀rọ̀ yín gbọ́, tí wọn ó sì rẹ ara wọn sílẹ̀ nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrẹ̀lẹ̀, tí a ó sì rì wọn bọmi, nítorítí a ó bẹ̀ wọ́n wò pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn yíò sì gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn.

3 Bẹ̃ni, alábùkún-fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí tí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.

4 Àti pẹ̀lú, alábùkún-fún ni gbogbo àwọn ẹnití nkẹ́dùn ọkàn, nítorítí a ó tù wọ́n nínú.

5 Alábùkún-fún sì ni àwọn ọlọ́kàn tútù, nítorí àwọn ni yíò jogún ayé.

6 Alábùkún-fún sì ni gbogbo àwọn tí ebi npa àti àwọn tí òungbẹ ngbẹ sí ipa òdodo, nítorí a ó yó wọn pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́.

7 Alábùkún-fún sì ni àwọn alãnú-ènìyàn, nítorí wọn yíò rí ãnú gbà.

8 Alábùkún-fún sì ni gbogbo àwọn onínú funfun, nítorí wọn yíò rí Ọlọ́run.

9 Alábùkún-fún sì ni gbogbo àwọn onílàjà, nítorí ọmọ Ọlọ́run ni a ó máa pè wọ́n.

10 Alábùkún-fún sì ni gbogbo àwọn tí a ṣe inúnibíni sí nítorí orúkọ mi, nítorí tiwọn ni ìjọba ọ̀run.

11 Alábùkún-fún sì ni ẹ̀yin, nígbati àwọn ènìyàn bá nkẹgan yin, ti wọn si nṣe ínuníbíní si yín, tí wọn sì nfi èké sọ onirũru ohun búburú si yin, nitori mi;

12 Nítorítí ẹ̀yin ó láyọ̀ púpọ̀ ẹ̀yin ó sì ní inú dídùn tí ó pọ̀, nítorí èrè nyín yíò pọ̀ ní ọ̀run; nítorí bẹ̃ni wọ́n ṣe inúnibíni àwọn wòlĩ tí ó ti nbẹ ṣãjú yín.

13 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, mo fií fún yín kí ẹ̀yin ó jẹ́ iyọ̀ ayé; ṣùgbọ́n bí iyọ̀ nã bá sọ adùn rẹ̀ nù báwo ni ayé yíò ṣe ní iyọ̀? Iyọ̀ nã láti ìgbà nã lọ kò sì ní dára fún ohunkóhun, bíkòṣe kí a sọọ́ sóde kí a sì tẹ̃ mọ́lẹ̀ lábẹ́ àtẹ́lẹsẹ̀ ènìyàn.

14 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, mo fi fún yín kí ẹ̀yin ó jẹ́ ìmọ́lẹ̀ àwọn ènìyàn yĩ. Ìlú tí a tẹ̀dó lórí òkè kò lè farasin.

15 Ẹ kíyèsĩ, njẹ́ ènìyàn ha lè tan iná fìtílà kí ó sì gbée sábẹ́ agbọ̀n bí? Rárá, ṣùgbọ́n yíò gbée lé orí ọ̀pa fìtílà, tí yíò sì fi ìmọ́lẹ̀ fún gbogbo ẹnití nbẹ nínú ilé;

16 Nítorínã ẹ jẹ́ kí ìmọ́lẹ̀ yín ó mọ́lẹ̀ tóbẹ̃ níwájú àwọn ènìyàn yĩ, kí wọn ó lè rí iṣẹ́ rere yín, kí wọn ó sì máa yin Bàbá yín tí nbẹ lọ́run lógo.

17 Ẹ máṣe rò wípé èmi wá láti pa òfin tàbí àwọn wòlĩ run. Èmi kò wá láti parun, bíkòṣe láti múṣẹ;

18 Nítorí lóotọ́ ni mo wí fún yín, ohun kíkiní kan nínú òfin ko tĩ kọjá, bí ó ti wù kí ó kéré tó, sugbọn nínú mi a ti múu ṣẹ.

19 Ẹ sì kíyèsĩ, èmi ti fún yín ní òfin àti àwọn àṣẹ Bàbá mi, kí ẹ̀yin ó lè gbàgbọ́ nínú mi, kí ẹ̀yin ó sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́. Ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ní àwọn àṣẹ nã níwájú yín, a sì ti mú òfin nã ṣẹ.

20 Nítorínã ẹ wá sí ọ̀dọ̀ mi kí a sì gbà yín là; nítorí lóotọ́ ni mo wí fún yín, pé bíkòṣepé ẹ̀yin pa àwọn àṣẹ mi mọ́, èyítí èmi ti pa láṣẹ fún yín ni àkokò yí, ẹ̀yin kò lè wọ ìjọba ọ̀run bí ó ti wù kí ó rí.

21 Ẹ̀yin ti gbọ́ pé a ti sọọ́ láti ẹnu àwọn ará ìgbà nnì, a sì tún kọ́ọ fún yín, pé ìwọ kò gbọ́dọ̀ pànìyàn, ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì pànìyàn yíò wà nínú ewu ìdájọ́ Ọlọ́run;

22 Ṣùgbọ́n mo wí fún yín, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá bá arákùnrin rẹ̀ bínú yíò wà nínú ewu ìdájọ́ Ọlọ́run. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì wí fún arákùnrin rẹ̀, pé: Rákà, yíò wà nínú ewu ọwọ́ àwọn àjọ ìgbìmọ̀; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì wípé, Ìwọ aṣiwèrè, yíò wà nínú ewu iná ọ̀run àpãdì.

23 Nítorínã, bí ẹ̀yin yíò bá wá sí ọ̀dọ̀ mi, tàbí bí ẹ bá ní ìfẹ́ láti wá sí ọ̀dọ̀ mi, tí ẹ sì rántí pé arákùnrin yín ní ohun kan nínú sí yín—

24 Ẹ sì tọ arákùnrin yin lọ kí ẹ sì kọ́ bá arákùnrin yín làjà ná, nígbànã ni kí ẹ tó wá sí ọ́dọ̀ mi tọkàn-tọkàn, èmi yíò sì gbà yín,

25 Bá ọ̀tá rẹ rẹ́ kankan nígbàtí ìwọ wà ní ọ̀nà pẹ̀lú rẹ̀, kí o má bã rí ọ mú kí a sì gbé ọ sọ sínú túbú.

26 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, ẹ̀yin kì yíò jáde kúrò níbẹ̀ títí ẹ̀yin ó fi san gbogbo owó rẹ̀ láìku ẹyọ sẹ́nínì kan. Nígbàtí ẹ̀yin bá sì wà nínú túbú njẹ́ ẹ̀yin ha lè san ẹyọ sẹ́nínì bí? Lóotọ́, lóotọ́, mo wí fún yín, Rárá.

27 Ẹ kíyèsĩ, a ti kọọ́ láti ọwọ́ àwọn ará ìgbà nnì, pé ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ ṣe panṣágà;

28 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, pé ẹnìkẹ́ni tí ó bá wo obìnrin kan, láti ṣe ìfẹ́-kúfẹ síi, ó ti bã ṣe panṣágà tán ní ọkàn rẹ̀.

29 Ẹ kíyèsĩ, èmi fún yín ní òfin kan, pé kí ẹ̀yin ó máṣe jẹ́ kí ọ̀kan nínú àwọn ohun wọ̀nyí ó wọ inú ọkàn yín lọ;

30 Nítorítí ó sàn kí ẹ̀yin ó sẹ́ ara yín pẹ̀lú àwọn ohun wọ̀nyí nínú èyítí ẹ̀yin ó gbé àgbélèbú yín, dípò èyítí a ó fi sọ yín sínú ọ̀run àpãdì.

31 A ti kọọ́, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀, jẹ́ kí ó fi ìwé ìkọ̀sílẹ̀ lée lọ́wọ́.

32 Lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, pé ẹnikẹ́ni tí ó bá kọ aya rẹ̀ sílẹ̀ bíkòṣe nítorí àgbèrè, ó múu ṣe panṣágà; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ẹnití a kọ̀ sílẹ̀ ní ìyàwó, ó ṣe panṣágà.

33 Àti pẹ̀lú, a ti kọọ́, ìwọ kò gbọ́dọ̀ búra, bíkòṣe kí ìwọ ó sì mú ìbúra rẹ ṣẹ fún Olúwa;

34 Ṣùgbọ́n lóotọ́, lóotọ́, ni mo wí fún yín, ẹ máṣe búra rárá; ìbã ṣe ìfi ọ̀run búra, nítorí ìtẹ́ Ọlọ́run ni íṣe;

35 Tàbí ayé, nítorí àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀ ni íṣe;

36 Bẹ̃ni ìwọ kò gbọ́dọ̀ fi orí rẹ búra, nítorí ìwọ kò lè sọ irun kan di dúdú tàbí funfun;

37 Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín jẹ́ Bẹ̃ni, bẹ̃ni; Bẹ̃kọ́, bẹ̃kọ́; nítorípé ohunkóhun tí a bá sọ tí ó bá ju ìwọ̀nyí lọ jẹ́ ti ibi.

38 Sì kíyèsĩ, a ti kọọ́, ojú kan fún ojú kan, àti ehín kan fún ehín kan;

39 Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín, pé kí ẹ máṣe fi ibi san ibi, ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá gbá ọ ní ẹ̀rẹ̀kẹ́ ọ̀tún, yí ti èkejì síi pẹ̀lú;

40 Bí ẹnikẹ́ni bá sì fi ọ́ sùn ní ilé ẹjọ́ tí ó sì gbà ọ́ ní ẹ̀wù lọ, jọ̀wọ́ agbádá rẹ fún un pẹ̀lú;

41 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì fi agbára mú ọ rin ìbùsọ̀ kan, bã dé méjì.

42 Fifún ẹnití ó bẽrè lọ́wọ́ rẹ, àti ẹnití ó nfẹ́ láti tọrọ lọ́wọ́ rẹ kí ìwọ ó máṣe yí ojú rẹ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀.

43 Kí ẹ sì kíyèsĩ a ti kọọ́ pẹ̀lú, pé ìwọ gbọ́dọ̀ fẹ́ràn ọmọnìkejì rẹ kí o sì kórìra ọ̀tá rẹ;

44 Ṣùgbọ́n ẹ kíyèsĩ mo wí fún yín, ẹ fẹ́ràn àwọn ọ̀tá yín, ẹ súre fún àwọn ẹnití nfi yín ré, ẹ máa ṣe õre fún àwọn tí ó kórìra yín, kí ẹ sì máa gbàdúrà fún àwọn tí nfi àránkan bá yín lò tí wọn nṣe inúnibíni sí yín;

45 Kí ẹ̀yin ó lè jẹ́ ọmọ Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run; nítorítí ó mú òòrùn rẹ̀ ràn sí órí ẹni búburú àti ẹni rere.

46 Nítorínã àwọn ohun ti ìgbà nnì, tí íṣe èyítí ó wà lábẹ́ òfin, nínú mi ni a mú ṣẹ.

47 Ohun ti àtijọ́ ti dópin, ohun gbogbo sì di titun.

48 Nítorínã, mo fẹ́ kí ẹ̀yin ó wà ní pípé àní gẹ́gẹ́bí èmi, tàbí Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run ti wà ní pípé.