Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 13


Orí 13

Jésù kọ́ àwọn ará Nífáì ní Àdúrà Olúwa—Pé kí wọn ó to ìṣúra jọ ní ọ̀run—A pàṣẹ fún Àwọn Méjìlá nnì nínú iṣẹ́ ìránṣẹ́ wọn láti máṣe àníyàn nítorí ohun ti ara—A fi orí ìwé yĩ wé Máttéù 6. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Lóotọ́, lóotọ́, mo wípé èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó máa ṣe ìtọrẹ-ãnú fún àwọn òtòṣì; ṣùgbọ́n ẹ ṣe àkíyèsí láti má ṣe ìtọrẹ-ãnú níwájú ènìyàn kí wọn ó lè rí yín; bíkòṣe bẹ̃ ẹ̀yin kò ní èrè lọ́dọ̀ Bàbá yín tí nbẹ ní ọ̀run.

2 Nítorínã, nígbàtí ẹ̀yin yíò bá ṣe ìtọrẹ-ãnú yín, ẹ máṣe fun fèrè níwájú yín, bí àwọn àgàbàgebè ti íṣe ní sínágọ́gù àti ní òpópó ọ̀nà, kí wọn ó lè gba ìyìn ènìyàn. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ná.

3 Ṣùgbọ́n nígbàtí ẹ̀yin bá nṣe ìtọrẹ-ãnú, ẹ máṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì yín kí ó mọ́ ohun tí ọwọ́ ọ̀tun yín nṣe;

4 Kí ìtọrẹ-ãnú yín ó lè wà ní ìkọ̀kọ̀; tí Bàbá yín tí ó ri ní ìkọ̀kọ̀, òun tìkararẹ̀ yíò san án fún yín ní gbangba.

5 Nígbàtí ẹ̀yin bá sì ngbàdúrà, ẹ máṣe dàbí àwọn àgàbàgebè, nítorí wọ́n fẹ́ láti máa dúró gbàdúrà nínú sínágọ́gù, àti ní ìkángun òpópó ọ̀nà, kí ènìyàn bã lè rí wọn. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ná.

6 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, nígbàtí ẹ̀yin bá ngbàdúrà, ẹ wọ inú ìyẹ̀wù yín lọ, nígbàtí ẹ̀yin bá sì ti sé ilẹ̀kùn yín, ẹ gbàdúrà sí Bàbá yín tí nbẹ ní ìkọ̀kọ̀; Bàbá yín, ẹnití ó ri ní ìkọkọ̀, yíò san án fún yín ní gbangba.

7 Ṣùgbọ́n nígbàtí ẹ̀yin bá ngbàdúrà, ẹ má ṣe àtúnwí asán, bí àwọn kèfèrí, nítorítí wọ́n ṣèbí a ó ti ìtorí ọ̀rọ̀ púpọ̀ wọn gbọ́ tiwọn.

8 Nítorínã, kí ẹ̀yin ó máṣe dàbí wọn, nítorítí Bàbá yín mọ́ ohun tí ẹ̀yin ṣe aláìní kí ẹ̀yin ó tó bẽrè lọ́wọ́ rẹ̀.

9 Nítorínã báyĩ ni kí ẹ̀yin ó máa gbàdúrà: Bàbá wa tí nbẹ ní ọ̀run, ọ̀wọ̀ ni fún orúkọ rẹ.

10 Ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe ní ayé bí a ti íṣe ní ọ̀run.

11 Dárí igbèsè wa jì wá, bí àwa ti ndáríjì àwọn onígbèsè wa.

12 Ma sì fà wá sínú ìdánwò, ṣùgbọ́n gbà wá lọ́wọ́ bìlísì.

13 Nítorí tìrẹ ni ìjọba, àti agbára, àti ògo títí láé. Àmín.

14 Nítorí, bí ẹ̀yin bá dárí ìrékọjá àwọn ènìyàn jì wọ́n, Bàbá yín ti ọ̀run nã yíò dáríjì yín;

15 Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin kò bá dárí ìrékọjá àwọn ènìyàn jì wọ́n, bákannã ni Bàbá yín kò ní dári ìrékọjá yín jì yín.

16 Àti pẹ̀lú, nígbàtí ẹ̀yin bá ngbãwẹ̀, ẹ máṣe dàbí àwọn àgàbàgebè tí nfajúro, nítorítí wọn a bá ojú jẹ́, kí wọn ó lè fihàn fún àwọn ènìyàn pé wọn ngbãwẹ̀. Lóotọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè wọn ná.

17 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin, nígbàtí ẹ̀yin bá ngbãwẹ̀, ẹ fi òróró kun orí yín, kí ẹ sì bọ́jú yín;

18 Kí ẹ̀yin kí ó máṣe fi ara hàn fún ènìyàn pé ẹ ngbãwẹ̀, bíkòṣe fún Bàbá yín, ẹnití nbẹ ní ìkọ̀kọ̀; Bàbá yín tí í sì ri ní ìkọ̀kọ̀, yíò sì san án fún yín ní gbangba.

19 Ẹ máṣe to ìṣura jọ fún ara yín ní ayé, níbití kòkòrò àti ìpãrà yíò bã jẹ́, àti tí àwọn olè yíò wọlé wá tí wọn ó sì jalè;

20 Ṣùgbọ́n ẹ to ìṣura yín jọ fún ara yín ní ọ̀run, níbití kòkòrò àti ìpãrà kò lè bã jẹ́, àti níbití àwọn olè kò lè wọlé wá kí wọn ó sì jalè.

21 Nítorí níbití ìṣúra yín bá gbé wà, níbẹ̀ ni ọkàn yín yíò wà pẹ̀lú.

22 Ojú ni fìtílà ara; nítorínã, bí ojú rẹ bá mọ́lẹ̀, gbogbo ara rẹ ni yíò kún fún ìmọ́lẹ̀.

23 Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ bá ṣókùnkùn, gbogbo ara rẹ ni yíò kún fún òkùnkùn. Nítorínã, bí ìmọ́lẹ̀ ti nbẹ nínú yín bá jẹ́ òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn nã yíò ti tó!

24 Kò sí ẹnití ó lè sìn olúwa méjì; nítorí yálà yíò kórìra ọ̀kan, kí ó sì fẹ́ èkejì, tàbí kí ó faramọ́ ọ̀kan kí ó sì fi èkejì ṣẹ̀sín. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti Mámónì.

25 Àti nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó kọ ojú sí àwọn méjìlá nnì tí ó ti yàn, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ rántí àwọn ọ̀rọ̀ tí èmi ti sọ. Nítorí ẹ kíyèsĩ, ẹ̀yin ni èmi ti yàn láti jíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn yĩ. Nítorínã ni mo wí fún yín, pé kí ẹ máṣe ṣe àníyàn nítorí ẹ̀mí yín, ohun tí ẹ̀yin yíò jẹ, tàbí ohun tí ẹ̀yin yíò mu; tàbí fún ara yín, ohun tí ẹ̀yin yíò fi bora. Njẹ́ ẹ̀mí kò ha ju oúnjẹ lọ bí, tàbí ara kò ha ju aṣọ lọ bí?

26 Ẹ kíyèsí àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run, wọn kĩ fúrúgbìn, bẹ̃ni wọn kĩ kórè tàbí kí wọn kójọ sínú abà; síbẹ̀ Bàbá yín ti ọ̀run a máa bọ́ wọn. Ẹ̀yin kò ha dára jù wọ́n lọ bí?

27 Tani nínú yín nípa àníyàn ṣíṣe tí ó lè fi ìgbọ̀nwọ́ kan kún gíga rẹ̀?

28 Èéṣe tí ẹ̀yin sì fi nṣe àníyàn nítorí ẹ̀wù? Ẹ kíyèsí àwọn lílì tí nbẹ ní ọ̀dàn bí wọ́n ti ndàgbà; wọn kĩ ṣiṣẹ́, bẹ̃ni wọn kĩ rànwú;

29 Síbẹ̀ èmi wí fún yín, pé a kò ṣe Sólómọ́nì pãpã, ní ọ̀ṣọ̀ nínú gbogbo ògo rẹ̀, tó bí ọ̀kan nínú àwọn yĩ.

30 Nítorí-eyi, bí Ọlọ́run bá wọ koríko ìgbẹ́ ní aṣọ bẹ̃, èyítí ó wà lóni, tí a sì fií ṣe ohun ìdáná lọ́la, melomelo ni kì yíò fi lè wọ̀ yín láṣọ, bí ẹ̀yin kò bá jẹ onigbagbọ kekere.

31 Nítorínã ẹ máṣe ṣe àníyàn, wípé, Kíni a ó jẹ? Tàbí, Kíni a ó mu? Tàbí, Aṣọ wo ni àwa ó wọ̀?

32 Nítorítí Bàbá yín ti ọ̀run mọ̀ pé ẹ̀yin kò lè ṣe aláìní gbogbo ohun wọ̀nyí.

33 Ṣùgbọ́n ẹ tètè máa wá ìjọba Ọlọ́run ná, àti òdodo rẹ̀, gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí ni a ó sì fi fún yín.

34 Nítorí kí ẹ máṣe ṣe àníyàn fún ọ̀la, nítorítí ọ̀la yíò ṣe àníyàn fún ohun tirẹ̀. Búburú ti ọjọ́ òní sã tó fún un.