Orí 17
Jésù sọ fún àwọn ènìyàn nã kí wọn ó ronú nípa ọ̀rọ̀ rẹ̀, kí wọn ó sì gbàdúrà fún òye nípa wọn—Ó wo àwọn aláìsàn wọn sàn—Ó gbàdúrà fún àwọn ènìyàn nã, ó sì lo èdè tí ẹnikẹ́ni kò lè kọ sílẹ̀—Àwọn ángẹ́lì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, iná sì yí wọn ká. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.
1 Ẹ kíyèsĩ, nísisìyí ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó tún wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã yíká, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ àsìkò mi ti dé tan.
2 Mo wòye pé ẹ wà láìlágbára, pé ẹ kò lè ní òye nípa gbogbo ọ̀rọ̀ mi èyítí Bàbá pàṣẹ fún mi láti wí fún yín ní àkokò yìi.
3 Nítorínã, ẹ lọ sínú ilé yín, kí ẹ sì ronú lé àwọn ohun tí èmi ti sọ, kí ẹ sì bẽrè lọ́wọ́ Bàbá, ní orúkọ mi, kí ó lè yé yín, kí ẹ sì palẹ̀ ọkàn yín mọ́ fún ọ̀la, èmi yíò sì tún tọ̀ yín wá.
4 Ṣùgbọ́n nísisìyí èmi ó tọ Bàbá lọ, àti láti fi ara mi hàn fún àwọn ẹ̀yà Ísráẹ́lì tí ó sọnù, nítorítí wọn kò sọnù sí Bàbá, nítorítí ó mọ́ ibití òun ti mú wọn lọ.
5 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti sọ̀rọ̀ báyĩ tán, ó wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã yíká, ó sì ríi pé wọn nsọkún, wọ́n sì wõ ní ìtẹjúmọ́ bí ẹnipé kí wọn ó rọ̃ láti dúró tì wọn fún ìgbà díẹ̀ si.
6 Ó sì wí fún wọn pé: Ẹ kíyèsĩ, inú mi kún fún ìyọ́nú sí yín.
7 Njẹ́ ẹ̀yin ní aláìsàn lãrín yín? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi. Njẹ́ ẹ̀yin ní àwọn amúkun, tàbí afọ́jú, tàbí arọ, tàbí akéwọ́, tàbí adẹ́tẹ̀, tàbí àwọn gbígbẹ, tàbí adití, tàbí tí a pọ́n lójú ní onírurú ọ̀nà? Ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi èmi yíò sì wò wọ́n sàn, nítorítí èmi ní ìyọ́nú sí yín; inú mi kún fún ãnú.
8 Nítorítí mo woye pé ẹyin nfẹ́ kí èmi ó fi hàn yín ohun tí èmi ti ṣe fún àwọn arákùnrin yín ní Jerúsálẹ́mù, nítorítí mo ríi pé ìgbàgbọ́ yín tó kí èmi lè wò yín sàn.
9 Ó sì ṣe nígbàtí ó ti sọrọ báyĩ tán, gbogbo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, jùmọ̀ jáde lọ pẹ̀lú àwọn aláìsàn wọn àti àwọn tí a pọ́n lójú, àti àwọn amúkun wọn, àti pẹ̀lú àwọn afọ́jú wọn àti pẹ̀lú àwọn odi wọn, àti pẹ̀lú gbogbo àwọn tí a pọn lójú ní onírurú ọ̀nà; ó sì wò olúkúlùkù wọ́n sàn, bí wọn ṣe nmú wọn wá sí ọdọ rẹ̀.
10 Gbogbo wọn, àti àwọn tí ó ti wò sàn àti àwọn tí ó wà ní pípé, ni ó wólẹ̀ sí abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n sì bù ọlá fún un; gbogbo àwọn tí ó lè wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ ni ó wá, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã fi ẹnu ko ẹsẹ̀ rẹ, tóbẹ̃ tí wọn fi omijé ẹkún wọn wẹ ẹsẹ̀ rẹ̀.
11 Ó sì ṣe tí ó pàṣẹ pé kí wọn ó gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn wá.
12 Bẹ̃ni wọn gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn wá, wọ́n sì gbé wọn kalẹ̀ yíká, Jésù sì dìde dúró lãrín wọn; àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì fi ãyè sílẹ̀ títí wọ́n fi gbé gbogbo àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀.
13 Ó sì ṣe nígbàtí wọn ti gbé gbogbo nwọn wá, Jésù sì dìde dúró lãrín wọn, ó pàṣẹ fún àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã pé kí wọn ó kúnlẹ̀ lé orí ilẹ̀ nã.
14 Ó sì ṣe nígbàtí wọ́n ti kúnlẹ̀ lé orí ilẹ̀, Jésù kérora nínú ara rẹ̀, ó sì wípé: Bàbá, inú mi bàjẹ́ nítorí ìwà búburú àwọn ènìyàn ìdílé Ísráẹ́lì.
15 Nígbàtí ó sì ti sọ awọn ọ̀rọ̀ wọnyi tán, òun tìkararẹ̀ pẹ̀lú kunlẹ lé órí ilẹ̀; ẹ sì kíyèsĩ ó gbàdúrà sí Bàbá, àwọn ohun tí ó sì gbàdúrà fún ni ẹnìkẹ́ni kò lè kọ sílẹ̀, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã tí ó gbọ́ọ sì jẹ́ ẹ̀rí síi.
16 Báyĩ sì ni ọ̀nà tí wọ́n fi jẹ̃rí síi: Ojú kò ríi rí, bẹ̃ni etí kò gbọ́ọ rí, àwọn ohun nlá àti ohun ìyanu irú èyítí àwa rí àti tí a gbọ́ tí Jésù bá Bàbá sọ;
17 Kò sì sí ahọ́n tí ó lè sọọ́, tàbí kí ẹnìkẹ́ni ó lè kọọ́, tàbí kí ọkàn ẹnìkẹ́ni ó lè ròo nípa àwọn ohun nlá àti ohun ìyanu gẹ́gẹ́bí àwa ti ríi àti tí a sì gbọ́ọ tí Jésù sọ; kò sì sí ẹnìkẹ́nì tí ó lè mọ̀ irú ayọ̀ tí ó kún ọkàn wa ní àkokò tí àwa gbọ́ọ tí ó gbàdúrà sí Bàbá fún wa.
18 Ó sì ṣe nígbàtí Jésù ti parí àdúrà rẹ̀ sí Bàbá, ó dìde; ṣùgbọ́n ayọ̀ àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã pọ̀ tóbẹ̃ tí wọn kò lè dìde dúró.
19 Ó sì ṣe tí Jésù bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì ní kí wọn ó dìde.
20 Wọn sì dìde kúrò ní ilẹ́, ó sì wí fún wọn pé: Alábùkún-fún ni ẹ̀yin nítorí ìgbàgbọ́ yín. Àti nísisìyí ẹ kíyèsĩ, ayọ̀ mi kún.
21 Nígbàtí ó sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó sọkún, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì jẹ̃rí síi, ó sì gbé àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ wọn, ní ọ̀kọ̃kan, ó sì súre fún wọn, ó sì gbàdúrà sí Bàbá fún wọn.
22 Nígbàtí ó sì ti ṣe èyí tán ó tún sọkún;
23 Ó sì bá àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sọ̀rọ̀, ó sì wí fún wọn pé: Ẹ wo àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ yín.
24 Bí wọn sì ti wò láti kíyèsí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ nã, wọn gbé ojú wọn sókè sí ọ̀run, wọ́n sì ríi tí ọ̀run ṣí sílẹ̀, wọ́n sì rí àwọn ángẹ́lì tí wọn nsọ̀kalẹ̀ jáde láti ọ̀run bí èyítí iná yí wọn ká; wọn sì sọ̀kalẹ̀ wa, wọn sì yí àwọn ọmọ wẹ́wẹ́ nnì ká, iná sì yí wọn ká; àwọn ángẹ́lì nã sì ṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú wọn.
25 Àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã sì ríi, wọ́n sì gbọ́ọ, wọ́n sì jẹ̃rí síi; wọ́n sì mọ̀ pé òtítọ́ ni ẹ̀rí wọn nítorítí ẹnìkọ̃kan wọn ni ó rí tí ó sì gbọ́, olúkúlùkù fúnrarẹ̀; wọn sì pọ̀ níye ní ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún méjì àti ẹ̃dẹ́gbẹ̀ta ẹ̀mí; wọn sì jẹ́ àwọn ọkùnrin, àwọn obìnrin, àti àwọn ọmọdé wẹ́wẹ́.