Orí 7
Wọ́n pá adájọ́ àgbà, wọ́n pa ìjọba rẹ̀ run, àwọn ènìyàn nã sì pín sí àwọn ẹ̀yà—Jákọ́bù, aṣòdìsí-Krístì kan, di ọba fún ẹgbẹ́ òkùnkùn kan—Nífáì nwãsù ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Krístì—Àwọn ángẹ́lì nṣiṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un lójojúmọ́, ó sì jí arákùnrin rẹ̀ dìde kúrò nínú ipò òkú—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó ronúpìwàdà tí a sì rì wọn bọmi. Ní ìwọ̀n ọdún 30–33 nínú ọjọ́ Olúwa wa.
1 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, èmi yíò fi hàn nyín pé wọn kò fi ọba jẹ lórí ilẹ̀ nã; ṣùgbọ́n nínú ọdún kannã yĩ, bẹ̃ni, ọgbọ̀n ọdún, wọ́n pã run lórí ìtẹ́ ìdájọ́, bẹ̃ni, wọ́n pa adájọ agbà ilẹ̀ nã.
2 Àwọn ènìyàn nã sì wà ní ìpinyà ní ọ̀kan sí òmíràn; wọ́n sì ya ara wọn sọ́tọ̀ sí ẹ̀yà-ẹ̀yà, olúkúlukù gẹ́gẹ́bí ìdílé rẹ̀ àti ìbátan rẹ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́; báyĩ ni wọ́n sì pa ìjọba ilẹ̀ nã run.
3 Gbogbo ẹ̀yà kọ̃kan sì yan olórí tàbí olùdarí lórí wọn; báyĩ ni wọ́n sì di ẹ̀yà àti olórí àwọn ẹ̀yà-ẹ̀yà.
4 Nísisìyí ẹ kíyèsĩ, kò sí ẹnìkẹ́ni lãrín wọn tí kò ní ìdílé tí ó pọ̀ àti ìbátan púpọ̀ àti àwọn ọ̀rẹ́; nítorínã ni àwọn ẹ̀yà-ẹ̀yà wọn di púpọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.
5 Nísisìyí wọ́n ṣe gbogbo eleyĩ, kò sì tĩ sí ogun lãrín wọn; gbogbo àwọn àìṣedẽdé yĩ dé bá àwọn ènìyàn nã nítorípé wọ́n jọ̀wọ́ ara wọn fún agbára Sátánì.
6 Wọ́n pa àwọn ìlànà ìjọba nã run, nítorí ẹgbẹ́ òkùnkùn àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn ìbátan àwọn wọnnì tí ó pa àwọn wòlĩ.
7 Nwọ́n sì dá ìjà nlá sílẹ̀ ní ilẹ̀ nã, tóbẹ̃ tí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã tí wọ́n jẹ́ olódodo jùlọ ti fẹ́rẹ̀ di ènìyàn búburú; bẹ̃ni, àwọn olódodo díẹ̀ ni ó wà lãrín wọn.
8 Báyĩ ọdun mẹ́fà kò ì tĩ kọjá lọ tí púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn nã ti yí kúrò nínú ìwà òdodo wọn, bí ajá tí ó padà sí ẽbì rẹ̀, tàbí ẹlẹ́dẹ̀ sínú ìpàfọ̀ nínú ẹrẹ̀ rẹ̀.
9 Nísisìyí ẹgbẹ́ òkùnkùn yĩ, tí ó ti mú àìṣedẽdé nlá bá àwọn ènìyàn nã, sì kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ọkùnrin kan ṣe olórí wọn ẹnití wọn npè ní Jákọ́bù;
10 Wọn sì pè é ní ọba wọn; nítorínã ó di ọba lórí ẹgbẹ́ búburú yĩ; ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn olórí tí ó sọ̀rọ̀ tako àwọn wòlĩ tí ó jẹ́rĩ nípa Jésù.
11 Ó sì ṣe tí wọn kò pọ̀ níye tó àwọn ẹ̀yà-ẹ̀yà àwọn ènìyàn nã, tí wọ́n parapọ̀ àfi ní ti pé àwọn olórí wọn ni ó fi àwọn òfin wọ́n lélẹ̀, olúkúlukù gẹ́gẹ́bí ẹ̀yà tirẹ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọ́n jẹ́ ọ̀tá; l’áìṣírò wọn kĩ ṣe olódodo ènìyàn, síbẹ̀síbẹ̀ wọ́n parapọ̀ nínú ìkórira àwọn tí ó ti bá ara wọn dá májẹ̀mú láti pa ìjọba nã run.
12 Nítorínã, Jákọ́bù, nítorítí ó ríi pé àwọn ọ̀tá wọn pọ̀ jù wọ́n lọ, nítorítí òun ni ọba àwọn ẹgbẹ́ nã, nítorínã ó ṣe pàṣẹ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pé kí wọn ó sálọ sí apá àríwá ilẹ̀ nã níbití ó jìnà jù, kí wọn ó sì fi ìjọba lélẹ̀ fún ara wọn níbẹ̀, títí àwọn olùyapa yíò fi darapọ̀ mọ́ wọn, (nítorítí ó tàn wọ́n pé àwọn olùyapa púpọ̀ yíò wà), tí wọn yíò fi lágbára tó láti dojúkọ àwọn ẹ̀yà-ẹ̀yà àwọn ènìyàn nã; wọ́n sì ṣe bẹ̃.
13 Ìrìn-àjò wọn nã sì yá tóbẹ̃ tí kò sí ohun tí ó lè dí wọn lọ́wọ́ tàbí fà wọ́n sẹ́hìn títí wọ́n fi kọjá lọ kúrò ní ìkáwọ́ àwọn ènìyàn nã. Báyĩ sì ni ọgbọ̀n ọdún parí; àti báyĩ sì ni ìṣe àwọn ènìyàn Nífáì.
14 Ó sì ṣe ní ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n tí wọ́n pín ara wọn sí ẹ̀yà-ẹ̀yà, olúkúlukù gẹ́gẹ́bí ìdílé rẹ̀, ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọ́n ti jọ ní àdéhùn pè wọn kò ní bá ara wọn jagun; ṣùgbọ́n wọn kò darapọ̀ ní ti àwọn òfin wọn, àti bí wọ́n ṣe nṣe ìjọba wọn, nítorí wọ́n fi wọ́n lélẹ̀ gẹ́gẹ́bí ọkàn àwọn tí wọn jẹ olórí wọn àti àwọn adarí wọn. Ṣugbọn wọn fi àwọn òfin tí ó múná púpọ̀púpọ̀ lélẹ̀ pé kí ẹ̀yà kan ó máṣe ré òmíràn kọjá, tóbẹ̃ tí wọ́n fi ní àlãfíà níwọ̀n díẹ̀ ní ilẹ̀ nã; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ọkàn wọn yí kúrò lọ́dọ̀ Olúwa Ọlọ́run wọn, tí wọ́n sì sọ àwọn wòlĩ ní òkúta tí wọ́n sì lé wọn kúrò lãrín wọn.
15 Ó sì ṣe tí Nífáì—nítorítí àwọn ángẹ́lì ti bẹ̃ wò àti ohùn Olúwa pẹ̀lú, nítorínã nítorítí ó ti rí àwọn ángẹ́lì, àti nítorípé ó jẹ́ ẹlẹ́rĩ, àti nítorítí ó ní agbára tí a ti fi fún un kí ó lè mọ̀ nípa iṣẹ́ ìránṣẹ́ Krístì, àti nítorípé ó jẹ́ ẹlẹ́rĩ sí yíyára kúrò nínú òdodo sínú ìwà búburú àti ìwà ìríra wọn;
16 Nítorínã, nítorítí ó banújẹ́ nítorí ọkàn wọ́n tí ó le àti ọkàn wọn tí o fọ́jú—ó kọjá lọ lãrín wọn nínú ọdún kannã, ó sì bẹ̀rẹ̀sí jẹ́rĩ pẹ̀lú ìgboyà, sí ìrònúpìwàdà àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa.
17 Ó sì jíṣẹ́ nípa ohun púpọ̀ fún wọn; a kò sì lè kọ gbogbo wọn sílẹ̀, díẹ̀ nínú wọn kò sí tó láti kọ, nítorínã a kò kọ wọn sínú ìwé yĩ. Nífáì sì jíṣẹ́ ìránṣẹ́ pẹ̀lú agbára àti àṣẹ nlá.
18 Ó sì ṣe tí wọ́n bínú síi, àní nítorípé ó ní agbára ti o tobi jù wọ́n lọ, nítorítí kò ṣeéṣe fún wọ́n láti má gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú Jésù Krístì Olúwa pọ̀ tóbẹ̃ tí àwọn ángẹ́lì njíṣẹ́ ìránṣẹ́ fún un lójojúmọ́.
19 Àti ní orúkọ Jésù ni ó lé àwọn èṣù àti àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde; àti pãpã ó jí arákùnrin rẹ̀ dìde kúrò nínú ipò òkú, lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn nã sọọ́ ní òkúta tí ó sì ti kú.
20 Àwọn ènìyàn nã sì ríi, ó sì ṣe ojú wọn, wọ́n sì bínú síi nítorí agbára rẹ̀; ó sì ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu síi, lójú àwọn ènìyàn nã, ní órúkọ Jésù.
21 Ó sì se tí ọdún kọkànlélọ́gbọ̀n kọjá lọ,tí ó sì jẹ́ wípé àwọn díẹ̀ ni ó yí ọkàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa; sùgbọ́n gbogbo àwọn tí a yí lọkan padà ni ó fi hàn fún àwọn ènìyàn nã pé agbára àti Ẹ̀mí Ọlọ́run ti bẹ̀ wọ́n wò, èyítí ó wà nínú Jésù Krístì, ẹnití wọ́n gbàgbọ́.
22 Gbogbo àwọn tí a sì lé àwọn èṣù jáde kúrò nínú wọn, tí wọ́n sì gba ìwòsàn nínú àwọn àìsàn wọn àti àwọn àìlera wọn, ni wọ́n fihàn lõbọ fún àwọn ènìyàn nã pé Èmí Ọlọ́run ti ṣiṣẹ́ lórí wọn, tí a sì ti wò wọ́n sàn; wọ́n sì fi àwọn àmì hàn pẹ̀lú tí wọ́n sì ṣe àwọn isẹ́ ìyanu díẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã.
23 Báyĩ sì ni ọdún kejìlélọ́gọ̀n kọjá lọ pẹ̀lú. Nífáì sì kígbe sí àwọn ènìyàn nã ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún ketàlélọ́gbọ̀n; ó sì wãsù ìrònúpìwàdà sí wọn àti ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀.
24 Nísisìyí èmi fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí pẹ̀lú pé kò sí ẹnìkẹ́ni tí a mú wá sí ìrònúpìwàdà tí a kò rìbọmi pẹ̀lú omi.
25 Nítorínã ni Nífáì yan àwọn ọkùnrin sí iṣẹ́ ìránṣẹ́ yĩ, pé gbogbo àwọn tí ó bá tọ̀ wọ́n wá ni wọ́n ní láti rìbọmi pẹ̀lú omi, èyí ni ó sì dúró gẹ́gẹ́bí ẹlẹ́rĩ àti ìjẹ́rií níwájú Ọlọ́run, àti sí àwọn ènìyàn nã, pé wọ́n ti ronúpìwàdà tí wọ́n sì ti gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wọn.
26 Àwọn tí ó rìbọmi sí ìrònúpìwàdà ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún yĩ sì pọ̀; báyĩ sì ni púpọ̀ nínú ọdún nã ṣe kọjá lọ.