Àwọn Ìwé Mímọ́
3 Nífáì 9


Orí 9

Nínú òkùnkùn nã, ohùn Krístì kéde nípa ìparun ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti àwọn ìlú-nlá nítorí ìwà búburú wọn—Ó tun kéde nípa bí òun ti wà bí Ọlọ́run, ó sọọ́ ní gbangba pé òfin Mósè ti di ìmúṣẹ, ó sì pe gbogbo ènìyàn láti wá sí ọ́dọ̀ òun kí wọn ó sì rí ìgbàlà. Ní ìwọ̀n ọdún 34 nínú ọjọ́ Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí a gbọ́ ohùn kan lãrín gbogbo àwọn olùgbé inú ayé, lórí gbogbo ilẹ̀ yĩ, tí ó nkígbe wípé:

2 Ègbé, ègbé, ègbé ni fún àwọn ènìyàn yĩ, ègbé ni fún àwọn ènìyàn tí ńgbé inú gbogbo ayé àfi bí wọ́n bá ronúpìwàdà; nítorítí èṣù nrẹ̃rín, àwọn ángẹ́lì rẹ̀ sì nyọ̀, nítorí àwọn tí a pa nínú àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin tí ó lẹ́wà nínú àwọn ènìyàn mi; tí ó sì jẹ́ nítorí ìwà àìṣedẽdé wọn àti ìwà ìríra wọn ni wọn ṣe kú!

3 Ẹ kíyèsĩ, ìlú-nlá Sarahẹ́múlà títóbi nnì ni èmi ti fi iná jó, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀.

4 Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú-nlá Mórónì títóbi nnì ni èmi ti mú kí ó rì nínú ibú òkun, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀ ni èmi mú kí wọn ó rì.

5 Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Móróníhà títóbi nnì ni èmi ti bò mọ́lẹ̀ pẹ̀lú erupẹ, àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, láti mú àwọn ìwà àìṣedẽdé wọn àti ìwà ẽrí wọn pamọ́ kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti ti àwọn ènìyàn mímọ́ nnì ó má bã tọ̀ mí wá mọ́ ni ìtakò sí wọn.

6 Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Gílgálì ni èmi ti mú kí ó rì, àwọn olùgbé inú rẹ̀ ni èmi sì mú kí a bò mọ́lẹ̀ nínú ilẹ̀ jínjìn;

7 Bẹ̃ni, àti ìlú nlá Oníhà àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, àti ìlú nlá Mókúmì àti àwọn olùgbé inú rẹ̀, àti ìlú nlá Jerúsálẹ́mù àti àwọn olùgbé inú rẹ; omi ni ẹmí sì fi dípò wọn, láti mú àwọn ìwà búburú àti ìwà ẽrí wọn pamọ́ kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti àwọn ènìyàn mímọ́ nnì ó má bã gòkè wá sí ọ́dọ̀ mi mọ́ ní ìtakò sí wọn.

8 Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Gádíándì, àti ìlú nlá Gádíómnáhì, àti ìlú nlá Jákọ́bù, àti ìlú nlá Gímgímnò, gbogbo àwọn wọ̀nyí ni èmi ti mú kí wọn ó rì, tí èmi sì fi àwọn òkè àti àfonífojì sí ipò wọn; àti àwọn olùgbé inú wọn ni èmi sì bò mọ́lẹ̀ nínú ilẹ̀ jíjìn, láti mú àwọn ìwà búburú àti àwọn ìwà ẽrí wọn pamọ́ kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti àwọn ènìyàn mímọ́ nnì ó má bã gòkè wá sí ọ́dọ̀ mi mọ́ ní ìtakò sí wọn.

9 Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Jákọ́bùgátì, èyítí àwọn ènìyàn ọba Jákọ́bù a máa gbé inú rẹ̀, ni èmi ti mú kí a jó niná nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn àti àwọn ìwà búburú wọn, èyítí ó tayọ gbogbo ìwà búburú ayé gbogbo, nítorí àwọn ìpànìyàn ní ìkọ̀kọ̀ àti awọn ẹgbẹ́ òkùnkùn wọn; nítorítí àwọn ni ó pa àlãfíà àwọn ènìyàn mi run àti ijọba ilẹ̀ nã; nítorínã ni èmi ṣe mú kí a jó wọn níná, láti pa wọn run kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti àwọn ènìyàn mímọ́ nnì ó má bã gòkè wá sí ọ́dọ̀ mi mọ́ ni ìtakò sí wọn.

10 Ẹ sì kíyèsĩ, ìlú nlá Lámánì, àti ìlú nlá Jọ́ṣì, àti ìlú nlá Gadì, àti ìlú nlá Kíṣkúmẹ́nì, ni èmi ti mú kí a jó níná, àti àwọn olùgbé inú wọn, nítorí ìwà búburú wọn ní lílé àwọn wòlĩ jáde, àti sísọ lokuta àwọn tí èmi rán láti sọ nípa ìwà búburú àti ìwà ẽrí wọn fún wọn.

11 Àti nítorípé wọ́n lé gbogbo wọn jáde, tí kò sì sí ẹnití ó jẹ́ olódodo lãrín wọn, èmi sọ iná kalẹ̀ mo sì pa wọ́n run, kí ìwà búburú àti ìwà ẽrí wọn ó lè pamọ́ kúrò níwájú mi, kí ẹ̀jẹ̀ àwọn wòlĩ àti àwọn ènìyàn mímọ́ tí èmi rán sí ãrin wọn ó má lè ké pè mí láti inú ilẹ̀ wá ní ìtakò sí wọn.

12 Àwọn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìparun nlá ni èmi sì ti mú wá sí órí ilẹ̀ yĩ, àti sí órí àwọn ènìyàn yĩ, nítorí ìwà búburú wọn àti ìwà ẽrí wọn.

13 A! gbogbo ẹ̀yin tí a dá sí nítorípé ẹ̀yin jẹ́ olódodo jù wọ́n lọ, ẹ̀yin kò ha ní padà sí ọ́dọ̀ mi nísisìyí, kí ẹ sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín, kí ẹ sì yípadà, kí èmi ó lè wò yín sàn bí?

14 Bẹ̃ni, lõtọ́ ni mo wí fún yín, bí ẹ̀yin yíò bá wá sí ọ́dọ̀ mi ẹ̀yin yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ kíyèsĩ, apá ãnú mi nã síi yín, ẹnikẹ́ni tí yíò bá sì wá sí ọ̀dọ̀ mi, òun ni èmi yíò gbà; alábùkún-fún sì ni àwọn tí ó wá sí ọ̀dọ̀ mi.

15 Ẹ kíyèsĩ, èmi ni Jésù Krístì Ọmọ Ọlọ́run. Èmi ni ó dá àwọn ọ̀run àti ayé, àti ohun gbogbo tí ó wà nínú wọn. Èmi wà pẹ̀lú Bàbá láti ìbẹ̀rẹ̀ wá. Mo wà nínú Bàbá, Bàbá nã sì wà nínú mi; nínú mi sì ni Bàbá ti ṣe orúkọ rẹ̀ lógò.

16 Mo tọ àwọn tèmi wa, àwọn tèmi kò sì gbà mí. Àwọn ìwé-mímọ́ nípa bíbọ̀ mi sì di mìmúṣẹ.

17 Gbogbo àwọn tí ó sì ti gbà mí, ni èmi ti fi fún láti di ọmọ Ọlọ́run; bẹ̃ nã sì ni èmi yíò fi fún gbogbo àwọn tí yíò gba orúkọ mi gbọ́, nítorí ẹ kíyèsĩ, nípasẹ̀ mi ni ìràpadà yíò wa, àti nínú mi ni a mú òfin Mósè ṣẹ.

18 Èmi ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé. Èmi ni Álfà àti Òmégà, ìpilẹ̀sẹ̀ àti òpin.

19 Ẹ̀yin kò sì ní rú ẹbọ ìtàjẹ̀sílẹ̀ sí mi mọ; bẹ̃ni, àwọn ọrẹ ẹbọ yín àti àwọn ọrẹ ẹbọ sísun yín yíò dópin, nítorí èmi kò ní tẹwọ́gba ọ̀kan nínú àwọn ọrẹ ẹbọ nyín tàbí àwọn ọrẹ ẹbọ sísun yín.

20 Ẹ̀yin yíò sì rú ẹbọ ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́ sí mi fún ọrẹ ẹbọ. Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì tọ̀ mí wá pẹ̀lú ìrora ọkàn àti ẹ̀mí ìròbìnújẹ́, òun ni èmi yíò rìbọmi pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, àní bí àwọn ará Lámánì, nítorí ìgbàgbọ́ wọn nínú mi ní ìgbà ìyílọ́kànpadà wọn, tí a sì rì wọn bọmi pẹ̀lú iná àti pẹ̀lú Ẹ̀mí Mímọ́, tí wọ́n kò sì mọ̃.

21 Ẹ kíyèsĩ, èmi wá sínú ayé láti mú ìràpadà wá sínú ayé, láti gba ayé là kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀.

22 Nítorínã, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ronúpìwàdà tí ó sì tọ̀ mí wá bí ọmọdé; òun ni èmi yíò gbà, nítorí ti irú rẹ̀ ni ìjọba Ọlọ́run. Ẹ kíyèsĩ, nitori irú rẹ̀ ni emí fi ẹ̀mí mi lélẹ̀, èmi sì tún tí mú u padà; nítorínã, ẹ ronúpìwàdà, kí ẹ sì wá sí ọ̀dọ̀ mi ẹ̀yin ìkangun ayé, kí a sì gbà yín là.