Àwọn Ìwé Mímọ́
Mósè 4


Orí 4

(Oṣù Kẹfà–Oṣù Kẹwã 1830)

Bi Sátánì ṣe di èṣù—Ó dán Éfà wò—Ádámù àti Éfà ṣubú, ikú sì wọ inú ayé.

1 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì wí fún Mósè, wípé: Sátánì èyìinì, ẹnití ìwọ ti pàṣẹ fún ní orúkọ Ọmọ Bíbi mi Kanṣoṣo, jẹ́ ọ̀kan náà èyítí ó ti wà láti àtètèkọ́ṣe, òun sì wá síwájú mi, tí ó wípé—Kíyèsíi, èmi nìyìí, rán mi, èmi yíò jẹ́ ọmọ rẹ, èmi yíò sì ra gbogbo ọmọ ènìyàn padà, pé ọkàn kan kì yíò sọnù, dájúdájú èmi yíò sì ṣe é; nítorínáà fún mi ní ọlá rẹ.

2 Ṣùgbọ́n, kíyèsíi, Àyànfẹ́ Ọmọ mi, èyítí ó jẹ́ Àyànfẹ́ mi àti Yíyàn láti àtètèkọ́ṣe, wí fún mi—Bàbá, ìfẹ́ tìrẹ ni ṣiṣe, kí ògo sì jẹ́ tìrẹ títí láé.

3 Nísisìyí, nítorítí Sátànì ṣe ọ̀tẹ̀ sí mí, àti tí ó wá ọ̀nà láti ṣe ìparun agbára ènìyàn láti yàn, èyítí èmi, Olúwa Ọlọ́run, ti fi fún un, àti bákannáà, pé kí èmi kí ó lè fi agbára tèmi fún un; nípa agbára Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo, mo mú kí á jù ú sí ìsàlẹ̀;

4 Òun sì di Sátánì, bẹ́ẹ̀ni, àní èṣù, bàbá gbogbo àwọn èké, láti tànjẹ àti láti mú àwọn ènìyàn fọ́jú, àti láti darí wọn ní ìgbèkùn bí ìfẹ́ inú rẹ̀, àní bí iye àwọn tí wọn kò fetísílẹ̀ sí ohùn mi.

5 Àti nísisìyí ejò jẹ́ alárékérekè ju èyíkéyìí ẹranko ìgbẹ lọ èyítí èmi, Olúwa Ọlọ́run, ti dá.

6 Sátánì sì fi í sínú ọkàn ejò náà, (nítorí òun ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò lẹ́hìn rẹ̀,) ó sì wá ọ̀nà bákannáà láti tan Éfà jẹ, nítorí òun kò mọ èrò inú Ọlọ́run, nítorínáà ó wá ọ̀nà láti pa ayé run.

7 Ó sì wí fún obìnrin náà: Bẹ́ẹ̀ni, njẹ́ Ọlọ́run ti wípé—Ìwọ kì yíò jẹ èso olukúlùkù igi ọgbà náà? (òun sì sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ẹnu ti ejò náà.)

8 Òbìnrin náà sì wí fún ejò náà pé: A lè jẹ nínú èso ti àwọn igi ọgbà náà;

9 Ṣùgbọ́n ní ti èso igi èyítí ìwọ rí ní ààrin ọgbà náà, Ọlọ́run ti wí pé—Ìwọ kì yíò jẹ nínú rẹ̀, tàbí kí ìwọ fi ọwọ́ kan án, bíbẹ́ẹ̀kọ́ ìwọ yíò kú.

10 Ejò náà sì wí fún obìnrin náà pé: Ìwọ kì yíò kú dájúdájú;

11 Nítorí Ọlọ́run ti mọ̀ pé ní ọjọ́ tí ìwọ bá jẹ nínú rẹ̀, nígbànáà ni ojú rẹ yíò là, ìwọ yíò sì dàbí àwọn ọlọ́run, ní mímọ rere àti buburú.

12 Nígbàtí obìnrin náà sì ríi pé igi náà dára fún oúnjẹ, àti pé ó wuni lójú, àti igi tí ó yẹ ní fífẹ́ kí òun lè gbọ́n, ó mú nínú èso náà, ó sì jẹ, bákannáà ó sì fi fún ọkọ rẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀, òun sì jẹ.

13 Ojú àwọn mejẽjì sì là, wọ́n sì mọ̀ pé àwọn ti wà ní ìhòhò. Wọ́n sì rán ewé igi ọ̀pọ̀tọ́ papọ̀ wọ́n sì ṣe ìbàntẹ́ fún ara wọn.

14 Wọ́n sì gbọ́ ohùn Olúwa Ọlọ́run, bí wọ́n ṣe nrìn nínú ọgbà náà, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́; Ádámù àti ìyàwó rẹ̀ sì lọ láti fi ara wọn pamọ́ kúrò níwájú Olúwa Ọlọ́run ní àárin àwọn igi ọgbà náà.

15 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì pe Ádámù, mo sì wí fún un pé: Níbo ni ìwọ nlọ?

16 Òun sì wí pé: Mo gbọ́ ohùn rẹ nínú ọgbà, ẹ̀rù sì bà mí, nítorítí mo rí pé èmi wà ní ìhòhò, mo sì fi ara pamọ́.

17 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì wí fún Ádámù pé: Tani ó sọ fún ọ pé ìwọ wà ní ìhòhò? Ìwọ ha ti jẹ ní ti igi èyí tí mo pàṣẹ fún ọ pé ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ, bí ó bá rí bẹ́ẹ̀ ìwọ yíò kú dájúdájú?

18 Ọkùnrin náà sì wípé: Obìnrin tí ìwọ fi fún mi, tí o sì pàṣẹ pé kí ó dúró pẹ̀lú mi, òun ni ó fún mi ní èso igi náà tí mo sì jẹ.

19 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì wí fún obìnrin náà: Kínni ohun yìí tí ìwọ ṣe? Obìnrin náà sì wí pé: Ejo ni ó tàn mí, èmi sì jẹ.

20 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, sì wí fún ejò náà pé: Nítorítí ìwọ ti ṣe èyí ìwọ yíò di ẹni ìfibú ju gbogbo ẹran ọ̀sìn lọ, àti ju olukúlùkù ẹranko ìgbẹ́; inú rẹ ni ìwọ yíò máa fi wọ́, erùpẹ̀ ilẹ̀ ni ìwọ yíò sì máa jẹ́ ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ;

21 Èmi yíò sì fi ọ̀tá sí ààrin ìwọ àti obìnrin náà, sí ààrin irú ọmọ rẹ àti irú ọmọ rẹ̀; òun yíò sì fọ́ ọ ní orí, ìwọ yíò sì pa á ní gìgísẹ̀.

22 Sí obìnrin náà, èmi, Olúwa Ọlọ́run, wípé: Èmi yíò sọ ìpọ́njú àti ìlóyún rẹ di púpọ̀. Nínú ìpọ́njú ni ìwọ yíò máa bímọ, ọ̀dọ̀ ọkọ rẹ ni ìfẹ́ rẹ yíò sì máa fà sí, òun ni yíò sì máa ṣe olorí rẹ.

23 Àti sí Ádámù, èmi, Olúwa Ọlọ́run, wípé: Nítorítí ìwọ fetísílẹ̀ sí ohùn aya rẹ, àti tí o ti jẹ nínú èso igi náà èyítí mo ti pàṣẹ fún ọ, wípé—Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ nínú rẹ̀, ìfibú ni ilẹ̀ yío jẹ́ nítorí rẹ; nínú ìpọ́njú ni ìwọ yíò máa jẹ nínú rẹ̀ ní gbogbo àwọn ọjọ́ ayé rẹ.

24 Ẹ̀gún bákannáà, àti òṣùṣu ni yíò máa hù jade fún ọ, ìwọ ó sì máa jẹ ewéko ìgbẹ́.

25 Nípa òógùn ojú rẹ ni ìwọ yíò máa jẹun, títí tí ìwọ ó fi padà sí ilẹ̀—nítorí ìwọ yíò kú dájúdájú—nítorí láti inú rẹ̀ ni a ti mú ọ wá: nítorí erùpẹ̀ ṣá ni ìwọ, ìwọ yíò sì padà di erùpẹ̀.

26 Ádámù sì pe orúkọ ìyàwó rẹ̀ ní Éfà, nítorítí òun jẹ́ ìyá gbogbo alààyè; nítorí báyìí ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, pe àkọ́kọ́ gbogbo àwọn obìnrin, tí wọ́n jẹ́ púpọ̀.

27 Fún Ádámù, àti pẹ̀lú fún ìyàwó rẹ̀, ni èmi, Olúwa Ọlọ́run, ṣe ẹ̀wù awọ, mo sì fi wọ̀ wọ́n.

28 Èmi, Olúwa Ọlọ́run, wí fún Ọmọ Bíbí mi Kanṣoṣo: Kíyèsíi, ọkùnrin náà ti dàbí ọ̀kan nínú wa láti mọ rere àti búburú; àti nísisìyí kí ó máṣe na ọwọ́ rẹ̀ kí ó sì mú nínú èso igi ìyè pẹ̀lú, kí òun sì jẹ kí ó sì yè títí láé,

29 Nítorínáà èmi, Olúwa Ọlọ́run, yíò lé e jade kúrò nínú Ọgbà Édẹ́nì, láti ro ilẹ̀ náà nínú èyítí a ti mú un jáde;

30 Nítorí bí èmi, Olúwa Ọlọ́run, ṣe wà láàyè, àní bẹ́ẹ̀ni àwọn ọ̀rọ̀ mi kì yíò padà lófo, nítorí bí wọ́n ṣe jáde lọ láti ẹnu mi ní wọ́n gbọ́dọ̀ wá sí ìmúṣẹ.

31 Bẹ́ẹ̀ni mo lé ènìyàn jade, mo sì fi kérúbù àti idà iná kan sí apá ìhà ìlà oòrùn Ọgbà Édẹ́nì, èyítí nyí káàkiri ọ̀nà láti máa ṣọ ọ̀nà igi ìyè náà.

32 (Ìwọnyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ èyítí mo sọ fún ìránṣẹ́ mi Mósè, wọ́n sì jẹ́ òtítọ́ àní bí ìfẹ́ inú mi; èmi sì ti sọ wọ́n fún ọ. Ríi pé ìwọ̀ kò fi hàn sí ènìyàn kankan, títí tí èmi yíò pàṣẹ fún ọ, bíkòṣe sí àwọn tí wọ́n gbàgbọ́. Àmín.)