Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 12


Orí 12

A ju Ábínádì sínú tũbú fún sísọtẹ́lẹ̀ ti ìparun àwọn ènìyàn àti ti ikú ọba Nóà—Àwọn àlùfã èké ntún ọ̀rọ̀ wí jáde láti inú àwọn ìwé-mímọ́, nwọ́n sì nṣe àṣehàn pípa òfin Mósè mọ́—Ábínádì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ nwọn ní òfin mẹ́wã nã. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe lẹ́hìn ìwọ̀n ọdún méjì, tí Ábínádì jáde wá sí ãrín nwọn ní ìparadà, tí nwọn kò mọ̃, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọ tẹ́lẹ̀ lãrín nwọn, ó wípé: Báyĩ ni Olúwa pã láṣẹ fún mi, tí ó wípé Ábínádì, lọ kí o sì sọtẹ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí, nítorítí nwọn ti sé àyà nwọn le sí ọ̀rọ̀ mi; nwọ́n kò sì tĩ ronúpìwàdà kúrò nínú ìwà búburú nwọn; nítorínã èmi yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìbínú mi, bẹ̃ni, nínú ìbínú tí ó gbóná ni èmi yíò bẹ̀ nwọ́n wò nínú ìwà àìṣedẽdé àti ìríra nwọn.

2 Bẹ̃ni, ègbé ni fún ìran yĩ! Olúwa sì wí fún mi pé: Na ọwọ́ rẹ jáde, kí ó sì sọtẹ́lẹ̀, wípé: Báyĩ ni Olúwa wí, yíò sì ṣe tí ìran yĩ, nítorí ìwà àìṣedẽdé nwọn, a ó mú nwọn bọ́ sí oko-ẹrú, a ó sì gbá nwọn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́; bẹ̃ni, a ó sì lé nwọn nípasẹ̀ àwọn ọmọ ènìyàn, a ó sì pa nwọ́n; àwọn ẹyẹ igún ojú ọ̀run, àti àwọn ajá, bẹ̃ni, àti àwọn ẹranko búburú, yíò jẹ ẹran ara nwọn.

3 Yíò sì ṣe tí a o ka ìgbésí ayé ọba Nóà sí aṣọ inú iná ìléru; nítorítí òun yíò mọ̀ pé èmi ni Olúwa.

4 Yíò sì ṣe tí èmi yíò bá àwọn ènìyàn mi wọ̀nyí jà pẹ̀lú ìpọ́njú kíkorò, bẹ̃ni, pẹ̀lú ìyàn, àti pẹ̀lú àjàkálẹ̀-àrùn; èmi yíò sì mú kí nwọ́n payinkeke ní gbogbo ọjọ́.

5 Bẹ̃ni, èmi yíò mú kí nwọ́n gbé ẹrù àjàgà lé nwọn lẹ́hìn; a ó sì tì nwọ́n síwájú bĩ odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

6 Yíò sì ṣe tí èmi yíò wọ̀ yìnyín sí ãrín nwọn, yíò sì pa nwọ́n; èmi yíò sì bá nwọn jà pẹ̀lú ìjì láti ilẹ̀ ìlà oòrùn; àwọn kòkòrò yíò sì yọ ilẹ̀ nwọn lẹ́nu pẹ̀lú, nwọ́n ó sì jẹ ọkà nwọn run.

7 A ó sì bá nwọn jà pẹ̀lú àjàkálẹ̀ àrùn nlá—gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí ni èmi yíò sì ṣe nítorí ìwà àìṣedẽdé àti ìwà ìríra nwọn.

8 Yíò sì ṣe, pé bí nwọn kò bá ronúpìwàdà, èmi yíò pa nwọ́n run pátápátá kúrò lórí ilẹ̀ ayé; síbẹ̀ nwọn yíò fi àkọsílẹ̀ hàn, èmi yíò sì pa nwọ́n mọ́ fún àwọn orílẹ̀-èdè míràn tí yíò ní ilẹ̀ nã ní ìní; bẹ̃ni, èyí nã ni èmi yíò ṣe kí èmi lè fi ìwà ìríra àwọn ènìyàn wọ̀nyí hàn fún àwọn orílẹ̀-èdè míràn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sì ni Ábínádì sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yĩ.

9 Ó sì ṣe tí nwọ́n ṣe inúnibíni sí i; nwọ́n sì mú u, nwọ́n gbé e ní dídè lọ sí iwájú ọba, nwọ́n sì wí fún ọba pé: Kíyèsĩ, àti mú ọkùnrin kan wá sí iwájú rẹ èyítí ó ti sọtẹ́lẹ̀ ohun búburú sí àwọn ènìyàn rẹ, tí ó sì wípé Ọlọ́run yíò pa nwọ́n run.

10 Ó sì tún ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ búburú nípa ìgbésí ayé rẹ, ó sì sọ wípé ayé rẹ yíò dà gẹ́gẹ́bí aṣọ nínú iná ilẽru.

11 Àti pẹ̀lú, ó sọ wípé ìwọ yíò dàbí igi gbígbẹ́ nínú oko, èyítí àwọn ẹranko nrékọjá tí nwọ́n sì ntẹ̀ mọ́lẹ̀.

12 Àti pẹ̀lú, ó sọ wípé ìwọ yíò dàbí ìtànná igi ẹ̀gún, èyítí ó jẹ́ wípé tí ó bá dàgbà tán, tí afẹ́fẹ́ sì fẹ́, yíò di gbígba kiri lórí ilẹ̀. Òun sì nsọ ọ́ bí ẹni pé Olúwa ni ó sọ ọ́ òun sì sọ wípé gbogbo nkan yĩ yíò ṣẹ lé ọ lórí àfi ti ìwọ bá ronúpìwàdà, àti pé èyí rí bẹ̃ nítorí àìṣedẽdé rẹ.

13 Àti nísisìyí, A! ọba, irú ìwà búburú wo ni ìwọ ti hù, tàbí irú ẹ̀ṣẹ̀ ribiribi wo ni àwọn ènìyàn rẹ̀ ṣẹ̀, tí àwa yíò gba ìdálẹ́bi láti ọwọ́ Ọlọ́run tàbí tí àwa yíò gba ìdájọ́ láti ọwọ́ okùnrin yĩ?

14 Àti nísisìyí A! ọba, kíyèsĩ àwa jẹ́ aláìlẹ́bi, àti ìwọ, A! ọba, kò dẹ́ṣẹ̀; nítorínã, ọkùnrin yĩ ti purọ́ nípa rẹ, ó sì ti sọtẹ́lẹ̀ ní asán.

15 Sì kíyèsĩ, àwa lágbára, àwa kò lè bọ́ sí oko-ẹrú, tàbí kí ọ̀tá wa kó wa ní ìgbèkùn; bẹ̃ni, ìwọ sì ti ṣe rere ní ilẹ̀ nã, ìwọ yíò sì tún ṣe rere síi.

16 Kíyèsĩ, ọkùnrin nã nì èyí, àwa fà á lé ọ lọ́wọ́; ìwọ sì lè ṣe sí i gẹ́gẹ́bí ó ti tọ́ ní ojú rẹ.

17 Ó sì ṣe tí ọba Nóà mú kí a gbé Ábínádì jù sínú tũbú; ó sì pàṣẹ kí àwọn àlùfã pé jọ kí ó lè ní àjọ ìgbìmọ̀ pẹ̀lú nwọn nípa ohun tí òun yíò fií ṣe.

18 Ó sì ṣe tí nwọ́n sọ fún ọba, wípé: Mú u wá sí ìhín, kí àwa lè ṣe ìwãdí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ̀; ọba sì pa á láṣẹ pé kí nwọ́n mú u wá sí iwájú nwọn.

19 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìwãdí ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ, pé kí nwọ́n lè mú u ṣì sọ, pé nípa èyí nwọn yíò ní èrè-ìdí láti fi ẹ̀sùn kàn án; ṣùgbọ́n ó dá nwọn lóhùn pẹ̀lú ìgboyà, ó sì dojúkọ nwọn lórí gbogbo ìbẽrè nwọn, bẹ̃ni, sì ìyalẹ́nu nwọn; nítorítí ó dojúkọ nwọ́n nínú gbogbo ìbẽrè nwọn, ó sì da gbogbo ọ̀rọ̀ nwọn rú mọ́ nwọn lọ́kàn.

20 Ó sí ṣe tí ọ̀kan nínú nwọn wí fún un pé: Kíni ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tí a kọ, àti ti àwọn bàbá wa kọ́, wípé:

21 Báwo ni ẹsẹ̀ ẹni tí ó mú ìhìn-rere ti dára tó lórí àwọn òkè; tí ó nkede àlãfíà; tí ó mú ìhìn-rere ohun rere wá; tí ó nkede ìgbàlà; tí ó wí fún Síónì, Ọlọ́run rẹ̀ njọba;

22 Àwọn alore yíò gbé ohùn sókè; nwọn ó jùmọ̀ fi ohùn kọrin; nítorítí nwọn yíò rí i ní ojúkojú, nígbàtí Olúwa yíò mú Síónì padà bọ̀ wá.

23 Bú sí ayọ̀; ẹ jùmọ̀ kọrin, ẹ̀yin ibi ahoro Jerúsálẹ́mù; nítorítí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rẹ̀ nínú, ó sì ti ra Jerúsálẹ́mù padà;

24 Olúwa ti fi apá rẹ̀ mímọ́ hàn ní ojú gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, gbogbo ìkangun ayé ni yíò sì rí ìgbàlà Ọlọ́run wa?

25 Àti nísisìyí ni Ábínádì sọ fún nwọn wípé: Ẹ̀yin ha íṣe àlùfã bí, tí ẹ̀yin sì nṣe bí ẹni pé ẹ̀ nkọ́ àwọn ènìyàn yí, àti pé ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ yé yín, síbẹ̀síbẹ̀ ẹ̀yin fẹ́ láti wádĩ lọ́wọ́ mi ohun tí àwọn nkan wọ̀nyí túmọ̀ sí?

26 Èmi wí fún nyín, ègbé ni fún nyín nítorítí ẹ̀yin ti yí ọ̀nà Olúwa po! Nítorípé bí àwọn ohun wọ̀nyí bá yé nyín, ẹ̀yin kò kọ nwọn; nítorínã, ẹ̀yin ti yí ọ̀nà Olúwa po.

27 Ẹ̀yin kò tĩ fi iyè nyín sí òye; nítorínã ẹ̀yin kò tĩ gbọ́n. Nítorínã, kíni ẹ̀yin nkọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí?

28 Nwọ́n sì wí pé: Àwa nkọ́ òfin Mósè.

29 Òun sì tún wí fún nwọn pé: Bí ẹ̀yin bá nkọ́ òfin Mósè kíni èrè-ìdí rẹ tí ẹ̀yin kò pã mọ́? Kíni èrè-ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin ṣe kó ọkàn nyín lé ọ̀rọ̀? Kíni èrè-ìdí rẹ̀ tí ẹ̀yin ṣe nhùwà àgbèrè tí ẹ̀yin sì nlo agbára yín dànù pẹ̀lú àwọn panṣágà obìnrin, bẹ̃ní, tí ẹ̀yin sì njẹ́ kí àwọn ènìyàn yí dá ẹ̀ṣẹ̀, tí Olúwa fi ní ìdí fún pé kí ó rán mí láti sọtẹ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yí, bẹ̃ni, àní ohun búburú sí àwọn ènìyàn yí?

30 Ẹ̀yin kò ha mọ̀ pé òtítọ́ ni èmi nsọ? Bẹ̃ni, ẹ̀yin mọ̀ pé òtítọ́ ni èmi nsọ; ó sì tọ pé kí ẹ wárìrì níwájú Ọlọ́run.

31 Yíò sì ṣe tí a ó jẹ yín níyà fún àwọn àìṣedẽdé nyín, nítorípé ẹ̀yin ti wí pé ẹ̀yin nkọ́ òfin Mósè. Kí ni ẹ̀yin sì mọ̀ nípa òfin Mósè? Njẹ́ ìgbàlà lè wà nípasẹ̀ òfin Mósè? Kíni ẹ̀yin wí?

32 Nwọ́n sì dáhùn, nwọ́n wípé ìgbàlà wá nípasẹ̀ òfin Mósè.

33 Ṣùgbọ́n nísisìyí Ábínádì wí fún nwọn pé: Èmi mọ̀ pé tí ẹ̀yin bá pa awọn òfin Ọlọ́run mọ́, a ó gbà nyín là; bẹ̃ni, tí ẹ̀yin bá pa awọn òfin ti Olúwa gbé lé Mósè lọ́wọ́ ní orí òkè Sínáì mọ, tí ó wípé:

34 Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín, tí ó ti mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Égíptì, kúrò nínú oko-ẹrú jáde wá.

35 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní Ọlọ́run míràn pẹ̀lú mi.

36 Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ya ère-kére fún ara rẹ̀, tàbí àwòrán ohun kan tí mbẹ lókè ọ̀run, tàbí ohun kan tí mbẹ ní ìsàlẹ̀ ilẹ̀.

37 Nísisìyí, Ábínádì wí fún nwọn pé, njẹ́ ẹ̀yin ti ṣe gbogbo èyí? Èmi wí fún yín, Rárá, ẹ̀yin kò ì tĩ ṣe é. Njẹ́ ẹ̀yin sì ti kọ́ àwọn ènìyàn yí pé kí nwọ́n ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí? Èmi wí fún nyin, Rárá, ẹ̀yin kò ì tĩ ṣe é.