Àwọn Àkọsílẹ̀ Sẹ́nífù—Ìtàn nípa àwọn ènìyàn rẹ, láti ìgbà tí nwọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, títí dé ìgbà tí a fi gbà nwọ́n lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.
Èyítí a kọ sí àwọn orí 9 títí ó fi dé 22 ní àkópọ̀.
Orí 9
Sẹ́nífù darí àwọn ọ̀wọ́ ènìyàn jáde kúrò ní Sarahẹ́múlà láti lọ jogún ilẹ̀ Léhì-Nífáì—Ọba àwọn ará Lámánì gbà fún nwọn láti jogún ilẹ̀ nã—Ogun bẹ́ sílẹ̀ lãrín àwọn ará Lámánì àti àwọn ènìyàn Sẹ́nífù. Ní ìwọ̀n ọdún 200 sí 187 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Èmi, Sẹ́nífù, tí a ti kọ́ ní gbogbo èdè àwọn ará Nífáì, àti tí mo ní ìmọ̀ nípa ilẹ̀ ti Nífáì, tàbí pé nípa ilẹ̀ akọ́jogún fún àwọn bàbá wa, àti ti a rán mi gẹ́gẹ́bí amí lãrín àwọn ará Lámánì, kí èmi kí ó lè ṣe alámí sí ohun agbára nwọn, kí ẹgbẹ́ ọmọ ogun wa lè kọlù nwọ́n, kí ó sì pa nwọ́n run—ṣùgbọ́n nígbàtí mo rí ohun rere lãrín nwọn, èmi kò fẹ́ kí a pa nwọ́n run.
2 Nítorínã, mo bá àwọn arákùnrin mi gbèrò nínú aginjù, nítorítí èmi fẹ́ kí olórí wa bá nwọn ṣe ìpinnu; ṣùgbọ́n bí ó ti jẹ́ ènìyàn tí ó rorò, tí ó sì ní ìfẹ́ láti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ó pàṣẹ pé kí a pa mí; ṣùgbọ́n a gbà mí là nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ púpọ̀ tí a ta sílẹ̀; nítorítí bàbá bá bàbá jà, arákùnrin sì bá arákùnrin jà, títí dé ìgbà ti púpọ̀ nínú àwọn ọmọ ogun wa parun nínú aginjù; a sì padà, àwa tí nwọn kò pa, lọ sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, kí a lè ròhìn nã fún àwọn ìyàwó nwọn àti àwọn ọmọ nwọn.
3 Síbẹ̀síbẹ̀, bí èmi ti ní ìtara tí ó tayọ láti jogún ilẹ̀ àwọn bàbá wa, mo sì ṣe àkójọ gbogbo àwọn tí nwọ́n ní ìfẹ́ láti gòkè lọ láti ní ilẹ nã ní ìní, a sì tún bẹ̀rẹ̀ ìrìnàjò wa lọ sínú aginjù kí a lè kọjá lọ sínú ilẹ̀ nã; ṣùgbọ́n, a fi ìyàn bẹ̀ wá wò, pẹ̀lú ìjìyà tí ó pọ̀ púpọ̀; nítorítí àwa lọ́ra láti rántí Olúwa Ọlọ́run wa.
4 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn ọjọ́ púpọ̀ tí àwa ti rìn kiri nínú aginjù, a pagọ́ sí ibi tí nwọ́n ti pa àwọn arákùnrin wa, èyítí ó sún mọ́ ilẹ̀ àwọn bàbá wa.
5 Ó sì ṣe tí èmi tún lọ pẹ̀lú mẹ́rin nínú àwọn ará mi sínú ìlú nlá nã, tí mo tọ ọba lọ, kí èmi lè mọ́ èrò ọkàn ọba nã, àti kí èmi lè mọ̀ bóyá mo lè lọ pẹ̀lú àwọn ènìyàn mi, kí a sì jogún ilẹ̀ nã ní ìrọ̀rùn.
6 Mo sì wọlé tọ ọba lọ, òun sì bá mi dá májẹ̀mú pé èmi lè ní ilẹ̀ ti Léhì-Nífáì ní ìní, àti ilẹ̀ ti Ṣílómù.
7 Òun sì pàṣẹ pẹ̀lú pé kí àwọn ènìyàn rẹ̀ jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã, èmi àti àwọn ènìyàn mi sì lọ sínú ilẹ̀ nã, kí àwa lè nĩ ní ìní.
8 Àwa sì bẹ̀rẹ̀sí kọ́ àwọn ilé, a sì tún àwọn ògiri ilú nã kọ́, bẹ̃ni, àní àwọn ògiri ìlú ti Léhì-Nífáì, àti ti Ṣílómù.
9 Àwa sì bẹ̀rẹ̀sí ro oko, bẹ̃ni, àní pẹ̀lú onírurú èso, pẹ̀lú èso àlìkámà, àti ti ọkà, àti pẹ̀lú bãlì, àti pẹ̀lú neasi, àti pẹ̀lú seumu, àti pẹ̀lú àwọn oríṣiríṣi èso míràn; àwa sì bẹ̀rẹ̀sí bí síi, àwa sì nṣe rere lórí ilẹ̀ nã.
10 Nísisìyí, ó jẹ́ ọ̀nà ọgbọ́n àrekérekè fún ọba Lámánì, láti mú àwọn ènìyàn mi wá sí oko-ẹrú, ni ó ṣe jọ̀wọ́ ilẹ̀ nã pé kí àwa fi nĩ ni ìní.
11 Nítorínã, ó sì ṣe, nígbàtí àwa ti tẹ ilẹ̀ nã dó fún ìwọ̀n ọdún méjìlá, tí ara ọba Lámánì bẹ̀rẹ̀sí wà ní àìrọrùn, pé ní ọ̀nà-kọnà, kí àwọn ènìyàn mi má lọ di alágbára ní orí ilẹ̀ nã, tí nwọn kò sì ní lè borí nwọn, kí nwọ́n sì mú nwọn wá sí óko-ẹrú.
12 Nísisìyí, nwọ́n jẹ́ ọ̀lẹ àti abọ̀rìṣà ènìyàn; nítorínã nwọ́n fẹ́ láti mú wa wá sí oko-ẹrú, kí nwọ́n lè máa jẹ́ àjẹkì nínú èrè iṣẹ́ ọwọ́ wa; bẹ̃ni, kí nwọ́n lè máa bọ́ ara nwọn pẹ̀lú àwọn agbo-ẹran inú pápá wa.
13 Nítorínã, ó sì ṣe tí ọba Lámánì bẹ̀rẹ̀sí rú àwọn ènìyàn rẹ̀ sókè kí nwọ́n lè bá àwọn ènìyàn mi jà; nítorínã ogun àti ìjà bẹ̀rẹ̀sí bẹ́ sílẹ̀ ní ilẹ̀ nã.
14 Nítorí, ní ọdún kẹtàlá ìjọba mi ni ilẹ̀ ti Nífáì, ní ìhà gúsù ilẹ̀ Ṣílómù, nígbàtí àwọn ènìyàn nfún àwọn agbo ẹran nwọn lómi, tí nwọ́n sì nbọ́ nwọn, tí nwọ́n sì nro oko nwọn, ogunlọ́gọ̀ àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì kọ lu nwọ́n, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí npa nwọ́n, nwọ́n sì nkó àwọn agbo-ẹran nwọn, àti ọkà inú oko nwọn.
15 Bẹ̃ni, ó sì ṣe tí nwọ́n sálọ, gbogbo àwọn tí nwọn kò lè bá, àní lọ sí inú ilú nlá Nífáì, nwọ́n sì ké pè mí fún ãbò.
16 Ó sì ṣe, tí mo di ìhámọ́ra ogun fún wọn pẹ̀lú ọrún, àti ọfà, pẹ̀lú idà, ati pẹlu símẹ́tà àti pẹ̀lú kùmọ̀, àti pẹ̀lú kànnà-kànnà, àti pẹ̀lú onírurú ohun ìjà èyí tí a lè ṣe, èmi àti àwọn ènìyàn mi si jáde tọ àwọn ará Lámánì lọ ní ogun.
17 Bẹ̃ni, nínú agbára Olúwa ni àwa fi jáde lọ láti kọjú ìjà sí àwọn ará Lámánì; nítorítí èmi àti àwọn ènìyàn mi ké rara pe Olúwa kí ó lè gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa, nítorítí a ta wá jí sí ìrántí àkóyọ àwọn bàbá wa.
18 Ọlọ́run sì gbọ́ igbe wa, ó sì dáhùn àdúrà wa; àwa sì jáde lọ nínú agbára rẹ̀; bẹ̃ni, àwa lọ kọlũ àwọn ará Lámánì, ní ọjọ́ kan àti òru kan ni àwa pa ẹgbẹ̀rún mẹ́ta àti ogójì àti mẹ́ta; àwa sì pa nwọ́n, títí àwa fi lé nwọn jáde kúrò ní ilẹ̀ wa.
19 Èmi, tìkalára mi, pẹ̀lú ọwọ́ mi, sì ṣe ìrànlọ́wọ́ láti gbé àwọn òkú nwọn sin, sì kíyèsĩ; sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora-ọkàn àti ìpohùn-réré ẹkún wa, igba àti ãdọ́rin àti mẹ́sán nínú àwọn arákùnrin wa ni nwọ́n pa.