Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 28


Orí 28

Àwọn ọmọkùnrin Mòsíà lọ láti wãsù sí àwọn ará Lámánì—Nípa lílo àwọn òkúta aríran nnì, Mòsíà ṣe ìyípadà àwọn àwo Járẹ́dì. Ní ìwọ̀n ọdún 92 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ọmọ Mòsíà ti ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí, nwọ́n mú àwọn díẹ̀ pẹ̀lú nwọn, nwọ́n sì padà sí ọ̀dọ̀ bàbá nwọn, ọba, nwọ́n sì rọ̀ ọ́ pé kí ó gbà fún nwọn kí nwọ́n kọjá lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì pẹ̀lú àwọn tí nwọn ti yàn, kí nwọn lè wãsù àwọn ohun tí nwọ́n ti gbọ́, kí nwọ́n sì lè kọ́ àwọn arákùnrin nwọn, àwọn ará Lámánì, ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run—

2 Pé, bóyá, nwọ́n lè mú nwọn wá sí ìmọ̀ Olúwa Ọlọ́run nwọn, kí nwọ́n sì jẹ́ kí nwọ́n mọ̀ dájú nípa àìṣedẽdé àwọn bàbá nwọn; àti pé, bóyá, nwọn yíò gbà nwọ́n kúrò nínú ikorira wọn sí àwọn ará Nífáì, pé kí a lè mú àwọn nã wá sí ipò ayọ̀ nínú Olúwa Ọlọ́run nwọn, pé kí nwọ́n lè mú ara nwọn lọ́rẹ́, àti kí ìjà kí ó dẹ́kun ní gbogbo ilẹ̀ nã èyítí Olúwa Ọlọ́run nwọn ti fún nwọn.

3 Nísisìyí, nwọ́n fẹ́ kí a kéde ìgbàlà sí gbogbo ẹ̀dá, nítorítí nwọn kò lè gbà pé kí ẹ̀mí ènìyàn kan kí ó parun; bẹ̃ni, àní pé ẹ̀mí kan lè faradà oró àìnípẹ̀kun mú kí nwọ́n gbọ̀n, kí nwọ́n sì wá rìrì.

4 Báyĩ sì ni Ẹ̀mí Olúwa ṣiṣẹ́ lórí nwọn, nítorítí nwọ́n jẹ́ ẹlẹ́ṣẹ̀ tí ó burú jùlọ. Olúwa sì rí i pé ó tọ́ nínú ãnú rẹ̀ tí kò lópin pé kí a dá nwọn sí; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n ṣe àròkàn ọkàn nítorí àìṣedẽdé nwọn, tí nwọn njìyà púpọ̀, tí nwọ́n sì nbẹ̀rù pé a ó ta nwọ́n nù, títí láé.

5 Ó sì ṣe tí nwọ́n ṣípẹ̀ fún bàbá nwọn fún ọjọ́ púpọ̀ pé kí nwọ́n lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì.

6 Ọba Mòsíà sì lọ bẽrè lọ́wọ́ Olúwa bí òun bá lè jẹ́ kí àwọn ọmọ òun lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ará Lámánì kí nwọ́n lè wãsù ọ̀rọ̀ nã.

7 Olúwa sì wí fún Mòsíà pé: Jẹ́ kí nwọ́n kọjá lọ nítorípé ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni yíò gba ọ̀rọ̀ nwọn gbọ́, nwọn ó sì ní ìyè àìnípẹ̀kun; èmi yíò sì yọ àwọn ọmọ rẹ̀ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.

8 Ó sì ṣe tí Mòsíà jẹ́ kí nwọ́n lọ, kí wọ́n sì ṣe bí nwọ́n ti bẽrè.

9 Nwọ́n sì mú ìrìnàjò nwọn pọ̀n kọjálọ sínú aginjù, láti lọ wãsù ọ̀rọ̀ nã lãrín àwọn ọmọ Lámánì; èmi yíò sì sọ nípa ìṣe nwọn lẹ́hìn èyí.

10 Nísisìyí ọba Mòsíà kò rí ẹnití yíò gbé ìjọba lé lórí, nítorí kò sí nínú àwọn ọmọ rẹ̀ tí ó fẹ́ gba ìjọba nã.

11 Nítorínã, ó gbé ìwé ìrántí nã èyítí a fin sí órí àwọn àwo idẹ, pẹ̀lú àwọn àwo ti Nífáì, àti gbogbo ohun tí ó fi pamọ́ gẹ́gẹ́bí àṣẹ Ọlọ́run, lẹ́hìn tí ó ti ṣe ìyírọ̀-padà, tí ó sì jẹ́ kí a kọ àwọn ìwé ìrántí èyítí ó wà lórí àwọn-àwo wúrà, èyítí àwọn ará Límháì wá rí, èyítí a gbé lé e lọ́wọ́ nípasẹ̀ ọwọ́ Límháì;

12 Èyí ni ó sì ṣe nítorí àníyàn àwọn ènìyàn rẹ̀; nítorítí nwọ́n ní ìfẹ́ èyítí ó rékọjá láti mọ̀ nípa àwọn ènìyàn nã tí a ti parun.

13 Àti nísisìyí ni ó sì ṣe yíyí ọ̀rọ̀ nã padà sí èdè míràn nípa àwọn òkúta méjì nnì tí a wé mọ́ etí méjẽjì ọpọn kan.

14 Nísisìyí àwọn ohun wọ̀nyí ni a ti pèsè sílẹ̀ láti ìbẹ̀rẹ̀ wá, tí a sì gbé lélẹ̀ láti ìran dé ìran, fún ìtumọ̀ èdè gbogbo;

15 A sì ti pa nwọ́n mọ́ nípa ọwọ́ Olúwa, pé kí ó lè fi han gbogbo ẹ̀dá tí yíò jogún ilẹ̀ nã, gbogbo àìṣedẽdé àti ìwà ìríra àwọn ènìyàn rẹ̀.

16 Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ní àwọn ohun wọ̀nyí ni á npè ní aríran gẹ́gẹ́bí ti ìgbà àtijọ́.

17 Nísisìyí, lẹ́hìn tí Mòsíà ti parí yíyí ọ̀rọ̀ àwọn ìwé ìrántí wọ̀nyí padà sí èdè míràn, kíyèsĩ, ó sọ nípa àwọn ènìyàn nã tí a parun, láti ìgbà tí nwọ́n ti pawọ́n run títí padà sí ìgbà kíkọ́ ilé ìṣọ́ gíga nnì, ní àkokò tí Olúwa da èdè àwọn ènìyàn nã rú, tí a sì tú nwọn ká lórí ilẹ̀ ayé gbogbo, bẹ̃ni, àní láti àtẹ̀hìnwá, títí lọ sí ìgbà dídá Ádámù.

18 Nísisìyí ọ̀rọ̀ yí jẹ́ kí àwọn ènìyàn Mòsíà ṣọ̀fọ̀ gidigidi, bẹ̃ni, nwọ́n kún fún ìrora-ọkàn; bíótilẹ̀ríbẹ̃ ó fún nwọn ní ìmọ̀ púpọ̀, nínú èyí tí nwọ́n yọ̀.

19 Ọ̀rọ̀ yí ni a ó sì kọ lẹ́hìn èyí; nítorí kíyèsĩ, ó jẹ́ ohun tí ó yẹ pe kí gbogbo ènìyàn mọ àwọn ohun tí a kọ sínú àkọsílẹ̀ yí.

20 Àti nísisìyí, gẹ́gẹ́bí mo ti wí fún yín lẹ́hìn tí ọba Mòsíà ti ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, ó mú àwọn àwo idẹ nã, àti gbogbo àwọn ohun tí ó kó pamọ́, ó sì gbé nwọn lé ọwọ́ Álmà, ẹnití íṣe ọmọ Álmà; bẹ̃ni, gbogbo ìwé ìrántí, pẹ̀lú àwọn olùtumọ̀-èdè, ó sì gbé nwọn lé e lọ́wọ́, ó sì pàṣẹ pé kí ó pa nwọ́n mọ́, kí ó sì ṣe ìwé ìrántí àwọn ènìyàn nã, kí ó sì gbé nwọn lé ọwọ́ ìran kan dé òmíràn, àní gẹ́gẹ́bí a ṣe gbé nwọn lé ọwọ́ àwọn ènìyàn láti ìgbà ti Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.