Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 20


Orí 20

Àwọn ọmọbìnrin Lámánì kan di jíjígbé láti ọwọ́ àwọn àlùfã Nóà—Àwọn ará Lámánì gbógun ti Límháì àti àwọn ènìyàn rẹ̀—Á dá àwọn ọmọ ogun Lámánì padà, a sì tù nwọ́n nínú. Ní ìwọ̀n ọdún 145 sí 123 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Nísisìyí, agbègbè kan wà ní Ṣẹ́múlónì tí àwọn ọmọbìnrin Lámánì a máa péjọpọ̀ sí fún orin kíkọ, àti fún ijó, àti láti dá inú ara nwọn dùn.

2 Ó sí ṣe ní ọjọ́ kan tí díẹ̀ nínú nwọn ti péjọpọ̀ fún orin kíkọ́ àti ijó.

3 Àti nísisìyí àwọn àlùfã ọba Nóà, nítorípé ojú tì nwọ́n láti padà sí ìlú ti Nífáì, bẹ̃ni, àti nítorípé nwọ́n sì bẹ̀rù pé àwọn ènìyàn yíò pa nwọ́n, nítorínã nwọn kò padà sọ́dọ̀ àwọn ìyàwó àti ọmọ nwọn.

4 Nítorípé nwọ́n ti dúró sínú aginjù, tí nwọ́n sì ti wá àwọn ọmọbìnrin Lámánì rí, nwọ́n sá pamọ́ nwọ́n sì nṣọ́ nwọn;

5 Nígbàtí àwọn díẹ̀ nínú nwọn sì péjọpọ̀ láti jó, nwọ́n jáde síta kúrò ní ibití nwọ́n sá pamọ́ sí, nwọ́n mú nwọn, nwọ́n sì gbé nwọn lọ sínú aginjù; bẹ̃ni, ogún àti mẹ́rin àwọn ọmọbìnrin Lámánì ni nwọ́n gbé lọ sínú aginjù.

6 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì rí i pé nwọn kò rí àwọn ọmọbìnrin nwọn mọ́, nwọ́n bínú sí àwọn ará Límháì, nítorítí nwọ́n rò wípé àwọn ará Límháì ni.

7 Nítorínã, nwọ́n fi àwọn ọmọ ogun nwọn ránṣẹ́; bẹ̃ni, àní ọba fúnrarẹ̀ lọ níwájú àwọn ènìyàn rẹ̀; nwọ́n sì kọjá lọ sí ilẹ̀ Nífáì láti lọ kọlũ àwọn ará Límháì.

8 Àti nísisìyí, Límháì ti rí nwọn láti orí ilé ìṣọnà, àní gbogbo ìmúrasílẹ̀ fún ogun tí nwọn nṣe ní ó rí; nítorínã ó pe àwọn ènìyàn rẹ̀ jọ, nwọ́n sì ba pamọ́ dè nwọn nínú pápá àti nínú igbó.

9 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ará Lámánì ti gòkè wá, ni àwọn ènìyàn Límháì bẹ̀rẹ̀sí kọ lù nwọ́n ní ibi tí nwọ́n dúró sí, nwọ́n sì npa nwọ́n.

10 Ó sì ṣe tí ogun nã gbóná púpọ̀púpọ̀, nítorípé nwọ́n jà bĩ awọn kìnìún fún ohun ọdẹ wọn.

11 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Límháì bẹ̀rẹ̀sí lé àwọn ará Lámánì lọ níwájú nwọn; síbẹ̀síbẹ̀, nwọn kò pọ̀ tó ìdajì àwọn ará Lámánì. Ṣùgbọ́n nwọ́n jà fún ẹ̀mí nwọn, àti fún àwọn ìyàwó nwọn, àti fún àwọn ọmọ nwọn; nítorínã, nwọ́n lo gbogbo agbára nwọn, gẹ́gẹ́bí drágónì ni nwọn sì jà.

12 Ó sì ṣe, tí nwọ́n rí ọba àwọn Lámánì lãrín àwọn tí ó tí kú; síbẹ̀ kò ì tĩ kú, títorítí ó ti fara gbọgbẹ́, tí a sì ti fi sílẹ̀ lẹ́hìn, tí àwọn ènìyàn rẹ̀ ti sálọ kankan.

13 Nwọ́n sì mú u, nwọ́n sì di ọ́gbẹ́ rẹ̀, nwọ́n sì mú u wá sí iwájú Límháì, nwọ́n sì wípé: kíyèsĩ, èyí yĩ ni ọba àwọn ará Lámánì; ẹnití ó ti gbọgbẹ́ tí ó sì ṣubú sí ãrin àwọn ènìyàn nwọn tí ó kú, tí nwọ́n sì fĩ sílẹ̀; sì kíyèsĩ, àwa mú u wá sí iwájú rẹ; àti nísisìyí, jẹ́ kí àwa kí ó pa á.

14 Ṣùgbọ́n Límháì wí fún nwọn pé: Ẹ̀yin kò ní pa á, ṣùgbọ́n ẹ mú u wá sí ìhín, kí èmi kí ó lè rí i. Nwọ́n sì mú u wá. Límháì sì wí fún un pé: Kíni ìdí rẹ̀ tí ìwọ fi wá bá àwọn ènìyàn mi jagun? Kíyèsĩ àwọn ènìyàn mi kò sẹ́ májẹ̀mú nã tí èmi dá pẹ̀lú yín; nítorínã, kíni ìdí rẹ tí ẹ̀yin fi sẹ́ májẹ̀mú nã tí ẹ̀yin bá àwọn ènìyàn mi dá?

15 Àti nísisìyí ọba nã sì wípé: Èmi sẹ́ májẹ̀mú nã nítorípé àwọn ènìyàn rẹ jí àwọn ọmọbìnrin àwọn ènìyàn mi gbé sálọ; nítorínã, nínú ìbínú mi ni èmi mú kí àwọn ènìyàn mi wá bá àwọn ènìyàn rẹ jà.

16 Àti nísisìyí Límháì kò tĩ gbọ́ ohunkóhun nípa ọ̀rọ̀ yíi; nítorínã ó wípé: Èmi yíò ṣe ìwãdí lãrín àwọn ènìyàn mi, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì ṣe èyí yíò parun. Nítorínã ó pàṣẹ pé kí a ṣe ìwãdí lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀.

17 Nísisìyí, nígbàtí Gídéónì ti gbọ́ ohun wọ̀nyí, nítorítí òun jẹ́ balógun ọba, ó tọ ọba lọ, ó sì wí fún un pé: Èmi bẹ̀ ọ́, dáwọ́ dúró, kí o máṣe ṣe ìwãdí lãrín àwọn ènìyàn yí, kí ìwọ kí ó máṣe dáwọn lẹ́bi lórí àwọn ohun wọ̀nyí.

18 Njẹ́ ìwọ kò ha rántí àwọn àlùfã bàbá à rẹ, tí àwọn ènìyàn wọ̀nyí lépa láti pa bí? Njẹ́ nwọn kò ha wà nínú aginjù bí? Njẹ́ àwọn kọ́ ni nwọ́n ha jí àwọn ọmọbìnrin àwọn ará Lámánì gbé bí?

19 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, kí o sì sọ àwọn nkan wọ̀nyí fún ọba nã, kí òun kí ó lè sọ ọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, kí inú nwọn kí ó lè rọ̀ sí wa; nítorítí kíyèsĩ, nwọ́n ti ngbáradì fún ìgbógun ti wa; sì kíyèsĩ, àwa kò pọ̀ mọ́.

20 Sì kíyèsĩ, nwọn yíò wá pẹ̀lú ogunlọ́gọ̀ ọmọ ogun nwọn; àti láìjẹ́wípé ọba tù nwọ́n nínú sí wa, àwa yíò parun.

21 Nítorítí njẹ́ ọ̀rọ̀ Ábínádì kò ha ṣẹ bí, èyítí ó sọtẹ́lẹ̀ sí wa—gbogbo èyí nítorítí àwa ṣe àìgbọràn sí ọ̀rọ̀ Olúwa, kí àwa sì yípadà kúrò nínú àìṣedẽdé?

22 Àti nísisìyí ẹ jẹ́ kí a rọ ọba, kí a sì pa májẹ̀mú èyítí a ti dá mọ́; nítorítí ó sàn kí àwa wà nínú oko-ẹrú ju kí a pàdánù ẹ̀mí wa; nítorínã, ẹ jẹ́ kí àwa fi òpin sí ìtàjẹ̀sílẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

23 Àti nísisìyí Límháì wí fún ọba nã nípa gbogbo ohun nípa bàbá rẹ̀, àti àwọn àlùfã tí nwọ́n ti sálọ sínú aginjù, ó sì dá nwọn lẹ́bi fún gbígbé lọ tí nwọ́n gbé àwọn ọmọbìnrin nwọn lọ.

24 Ó sì ṣe, tí inú ọba nã rọ̀ sí àwọn ènìyàn nã; ó sì wí fún nwọn pé: Ẹ jẹ́ kí a jáde lọ bá àwọn ènìyàn mi, láìmú ohun-ìjà dání; mo sì búra fún nyín, pẹ̀lú ìbúra wípé àwọn ènìyàn mi kò ní pa àwọn ènìyàn rẹ.

25 Ó sì ṣe tí nwọ́n tẹ̀lé ọba nã, tí nwọ́n sì jáde lọ, láìmú ohun-ìjà dání, lọ pàdé àwọn ará Lámánì. Ó sì ṣe tí nwọ́n pàdé àwọn ará Lámánì; ọba àwọn ará Lámánì sì tẹríba níwájú nwọn, ó sì bẹ̀bẹ̀ fún àwọn ará Límháì.

26 Nígbàtí àwọn ará Lámánì sì rí àwọn ará Límháì, pé nwọn kò ní ohun-ìjà dání, nwọ́n ṣãnú fún nwọn, inú nwọn sì rọ̀ sí nwọn, nwọ́n sì padà pẹ̀lú ọba nwọn sí ilẹ̀ nwọn ní àlãfíà.