Orí 8
Ámọ́nì nkọ́ àwọn ará Límháì—Ó gbọ́ nípa àwọn àkọsílẹ̀ mẹ́rìnlélógún ti Járẹ́dì—Àwọn aríran lè ṣe ìtumọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ ti àtijọ́—Kò sí ẹ̀bùn tí ó tayọ ti aríran. Ní ìwọ̀n ọdún 121 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Ó sì ṣe pé lẹ́hìn tí ọba Límháì ti dẹ́kun ọ̀rọ̀ sísọ sí àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorítí ó sọ ohun púpọ̀ fún nwọn, díẹ̀ nínú nwọn ni èmi sì kọ sínú ìwé yĩ, ó sì sọ fún àwọn ènìyàn rẹ̀ ohun gbogbo nípa àwọn arákùnrin nwọn tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà.
2 Ó sì mú kí Ámọ́nì kí ó dìde níwájú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã, kí ó sì sọ gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí àwọn arákùnrin nwọn láti ìgbà tí Sẹ́nífù ti lọ jáde kúrò ní ilẹ̀ nã, àní títí di ìgbà tí òun nã ti jáde kúrò nínú ilẹ̀ nã.
3 Ó sì tún sọ fún wọn àwọn ọ̀rọ̀ ìkẹhìn tí ọba Bẹ́njámínì ti kọ́ nwọn, ó sì ṣe àlàyé nwọn fún àwọn ènìyàn ọba Límháì, kí gbogbo ọ̀rọ̀ tí ó sọ lè yé nwọn.
4 Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí ó ti ṣe gbogbo eleyĩ, ni ọba Límháì tú àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã ká, tí ó sì mú kí olúkúlùkù padà lọ sí ilé rẹ.
5 Ó sì ṣe tí ó mú kí a gbé àwọn àwo àkọsílẹ̀ nã tí ó ní ìkọsílẹ̀ ti àwọn ènìyàn rẹ láti ìgbà tí nwọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, wá sí iwájú Ámọ́nì, kí òun lè kà nwọ́n.
6 Nísisìyí, ní kété tí Ámọ́nì ti ka àkọsílẹ̀ nã tán, ọba nã wádĩ lọ́wọ́ rẹ̀ láti mọ̀ bóyá ó lè túmọ̀ èdè, Ámọ́nì sì sọ fún un pé òun kò lè ṣe é.
7 Ọba sì wí fún un pé: Nítorípé èmi kẹ́dùn fún ìjìyà àwọn ènìyàn mi, mo mú kí ogójì àti mẹ́ta nínú àwọn ènìyàn mi mú ìrìnàjò pọ̀n lọ sínú aginjù, pé nípa bẹ̃ nwọ́n lè ṣe àwárí ilẹ̀ ti Sarahẹ́múlà, kí àwa kí ó lè ṣípẹ̀ fún àwọn arákùnrin wa pé kí nwọ́n tú wa sílẹ̀ nínú oko-ẹrú.
8 Nwọ́n sì sọnù nínú aginjù fún ìwọ̀n ọjọ́ pípẹ́, síbẹ̀ nwọ́n ní ãpọn, tí nwọn kò sì rí ilẹ̀ ti Sarahẹ́múlà, nwọ́n padà sí ilẹ̀ yí, tí nwọ́n ti rin ìrìnàjò nínú ilú kan tí ó wà lãrín omi púpọ̀, tí nwọ́n sì ṣe àwárí ilú kan tí ó kún fún àwọn egungun àwọn ènìyàn, àti ti ẹranko, àti ti àwọn ilé tí ó ti dí ahoro, ní ónírurú, tí nwọ́n sì ṣe àwárí ilú kan tí ènìyàn ti tẹ̀dó rí, tí nwọ́n sì pọ̀ bí àwọn ọmọ ogun Ísráẹ́lì.
9 Àti fún ẹ̀rí pé àwọn ohun tí nwọ́n ti sọ jẹ́ ọ̀títọ́, nwọ́n mú àwo àkọsílẹ̀ mẹ́rìnlélógún bọ̀, tí nwọ́n kún fún àwọn fífín, tí nwọ́n sì jẹ́ ti ojúlówó wúrà.
10 Ẹ sì kíyèsĩ, pẹ̀lú, nwọ́n mú àwọn ìgbàyà-ogun, tí nwọ́n tóbi, tí nwọ́n sì jẹ́ ti idẹ àti ti bàbà, tí nwọ́n sì wà ní pípé.
11 Àti pẹ̀lú, nwọ́n kó idà, ti ẽkù nwọ́n ti parun, tí ojú nwọn sì ti dípẹtà; kò sì sí ẹnì kan tí ó lè túmọ̀ èdè nã tàbí àwọn ohun fífín tí ó wà lára àwọn àwo nã. Nítorínã ni èmi fi wí fún ọ pé: Njẹ́ ìwọ lè ṣe ìtumọ̀?
12 Èmi sì tún wí fún ọ: Njẹ́ ìwọ mọ́ ẹnìkẹ́ni tí ó lè ṣe ìtumọ̀? Nítorítí èmi ní ìfẹ́ pé kí a túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyí sí èdè wa; nítorípé, bóyá, nwọn ó fún wa ní ìmọ̀ ìyókù àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n ti parun, ní ibití àkọsílẹ̀ wọ̀nyí ti wá; tàbí, bóyá nwọn ó fún wa ní ìmọ̀ nípa àwọn ènìà wọ̀nyí tí nwọ́n ti parun; èmi sì ní ìfẹ́ láti mọ́ ohun tí ó fa ìparun fún wọn.
13 Nísisìyí, Ámọ́nì sọ fun un: Èmi lè sọ dájúdájú fún ọ, A! ọba, nípa ọkùnrin kan tí ó lè túmọ̀ àwọn àkọsílẹ̀ nã; nítorí tí ó ní ohun tí ó lè wò, tí yíò fi túmọ̀ gbogbo àkọsílẹ̀ tí nwọ́n jẹ́ ti ìgbà àtijọ́; ó sì jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn nkan nã ni à npè ní olùtumọ̀, kò sì sí ẹni nã tí ó lè wo inú nwọn àfi bí a bá pã láṣẹ fún un láti wõ, kí ó má bã wo ohun tí kò yẹ fún un, kí ó si parun. Ẹnìkẹ́ni tí a bá sì pã láṣẹ fún, pé kí ó wo inú nwọn, òun nã ni à npè ní aríran.
14 Ẹ kíyèsĩ, ọba àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Sarahẹ́múlà ni ẹni tí a pa á láṣẹ fún kí ó ṣe àwọn nkan wọ̀nyí, tí ó sì ní ẹ̀bùn nlá yĩ láti ọwọ́ Ọlọ́run.
15 Ọba nã sì sọ wípé aríran tóbi ju wòlĩ lọ.
16 Ámọ́nì sì sọ wípé aríran jẹ́ olùfihàn àti wòlĩ pẹ̀lú; kò sì sí ẹ̀bùn tí ènìyàn lè ní tí ó ju èyí lọ, àfi bí ó bá ní agbára Ọlọ́run, èyítí kò sí ẹnití ó lè níi; síbẹ̀, ènìyàn lè ní agbára púpọ̀ tí a fifún un láti ọwọ́ Ọlọ́run.
17 Ṣùgbọ́n aríran lè mọ́ nípa àwọn ohun tí ó ti kọjá, àti àwọn ohun tí ó nbọ̀wá pẹ̀lú, àti nípasẹ̀ nwọn ni a ó fi ohun gbogbo hàn, tàbí pé, ní ohun ìkọ̀kọ̀ yíò kúkú di mímọ̀, tí ohun ìpamọ́ yíò wá sí ìmọ́lẹ̀, àti àwọn ohun tí a kò mọ̀, yíò di mímọ̀ nípasẹ̀ nwọn, àti pé àwọn ohun yíò di mímọ̀ nípasẹ̀ nwọn, àwọn èyítí bíkòjẹ́ bẹ̃, a kò lè mọ̀ nwọ́n.
18 Báyĩ, Ọlọ́run ti pèsè ọ̀nà pé, nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ènìyàn lè ṣe iṣẹ́ ìyanu nlá; nítorínã, ó jẹ́ ànfàní nlá fún àwọn ará rẹ̀.
19 Àti nísisìyí, nígbàtí Ámọ́nì sì ti parí ọ̀rọ̀ sísọ, ọba yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run, ó wípé: Láìsí àní-àní, ohun ìjìnlẹ̀ nlá ni ó wà nínú àwọn àwo wọ̀nyí àti, láìsí àní-àní, a sì ti pèsè àwọn olùtúmọ̀ wọ̀nyí fún ìfihàn gbogbo ohun ìjìnlẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn.
20 Á!, báwo ni ìyanu iṣẹ́ Olúwa ṣe pọ̀ tó, àti pé báwo ni yíò ṣe pẹ́ tó tí ìyọ́nú rẹ̀ fi wà fún àwọn ènìyàn rẹ̀; bẹ̃ni, àti pé báwo ni ìmọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn ṣe fọ́jú àti dití tó; nítorítí nwọn kò ní ṣe àfẹ́rí ọgbọ́n, bẹ̃ni nwọn kò sì ní ìfẹ́ pé kí ó jọba lórí nwọn!
21 Bẹ̃ni, nwọ́n dà bí ọ̀wọ́ ẹran àìtùlójú tí ó sáko kúrò lọ́dọ̀ olùṣọ́-àgùtàn, tí nwọ́n sì túká, tí a sì lé wọn, tí àwọn ẹranko búburú sì pa nwọ́n jẹ.