Orí 21
Àwọn ará Lámánì kọlũ àwọn ènìyàn Límháì, nwọ́n sì ṣẹ́gun nwọn—Àwọn ènìyàn Límháì bá Ámọ́nì pàdé, a sì yí nwọn lọ́kàn padà—Nwọ́n sọ nípa àwọn àwo-ìkọsílẹ̀ ti Járẹ́dì mẹ́rìnlélógún fún Ámọ́nì. Ní ìwọ̀n ọdún 122–121 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Ó sì ṣe tí Límháì àti àwọn ènìyàn rẹ padà sí ìlú ti Nífáì, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbé orí ilẹ̀ nã ní àlãfíà lẹ̃kan síi.
2 Ó sì ṣe, lẹ́hìn ọjọ́ pípẹ́ tí àwọn ará Lámánì tún bẹ̀rẹ̀sí rú ìbínú nwọn sókè sí àwọn ará Nífáì, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí wá sí agbègbè àlà ilẹ́ tí ó yí nwọn ká.
3 Nísisìyí nwọn kò pa nwọ́n, nítorí ti májẹ̀mú ti ọba nwọn ti dá pẹ̀lú Límháì; ṣùgbọ́n nwọn a máa gbá nwọn ní ẹ̀rẹ̀kẹ́, nwọ́n sì nfi ipá àti agbára bá nwọn lò; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbé ẹrù wúwo lé nwọn lẹ́hìn, nwọ́n sì ndà nwọ́n síwájú bí odi kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́—
4 Bẹ̃ni, a ṣe àwọn ohun wọ̀nyí kí ọ̀rọ̀ Olúwa lè ṣẹ.
5 Àti nísisìyí ìjìyà àwọn ará Nífáì pọ̀ jọjọ, kò sì sí ọ̀nà tí nwọ́n fi lè gba ara nwọn kúrò lọ́wọ́ nwọn, nítorítí àwọn ará Lámánì ti yí nwọn ká ní gbogbo ìhà.
6 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã bẹ̀rẹ̀sí kùn sí ọba nítorí ti ìjìyà nwọn; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí wá ọ̀nà àti kọlũ nwọ́n ní ogun. Nwọ́n sì ni ọba nã lára púpọ̀ pẹ̀lú ìráhùn nwọn; nítorínã ó gbà nwọ́n lãyè kí nwọ́n ṣe èyí tí ó tẹ́ nwọn lọ́run.
7 Nwọ́n sì tún kó ara nwọn jọ, nwọ́n gbé ìhámọ́ra nwọn wọ̀, nwọ́n sì kọjá lọ dojúkọ àwọn ará Lámánì, láti lé nwọn jáde kúrò lórí ilẹ̀ nwọn.
8 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì lù nwọ́n, nwọ́n sì dá nwọn padà, nwọ́n sì pa púpọ̀ nínú nwọn.
9 Àti nísisìyí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀fọ̀ àti ohùn-réré ẹkún ni ó wà lãrín àwọn ará Límháì, opó nṣọ̀fọ̀ ọkọ rẹ̀, ọmọkùnrin pẹ̀lú ọmọbìnrin nṣọ̀fọ̀ bàbá nwọn, àti arákùnrin fún arákùnrin nwọn.
10 Nísisìyí àwọn opó pọ̀ púpọ̀ ní ilẹ̀ nã, nwọ́n sì kígbe rara láti ọjọ́ dé ọjọ́, nítorítí ìbẹ̀rù àwọn ará Lámánì ti bò nwọ́n.
11 Ó sì ṣe tí igbe nwọn àìlópin rú ọkàn àwọn ènìyàn Límháì yókù sókè sí ìbínú sí àwọn ará Lámánì; nwọ́n sì tún lọ sí ógun, ṣùgbọ́n nwọ́n dá nwọn padà lẹ̃kan síi, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àdánù.
12 Bẹ̃ni nwọ́n tún lọ, àní ní ìgbà kẹ́ta, nwọ́n sì tún pàdánù bákannã; àwọn tí nwọn kò sì pa tún padà sí inú ìlú ti Nífáì.
13 Nwọ́n sì rẹ ara nwọn sílẹ̀, àní búrú-búrú, nwọ́n jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ fún àjàgà oko-ẹrú, nwọ́n jọ̀wọ́ ara nwọn fún ìfìyàjẹ, àti fún dídà sí ìhín àti sí ọ̀hún, àti ìgbé ẹrù wúwo lórí, gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú àwọn ọ̀tá nwọn.
14 Nwọ́n sì rẹ ara nwọn sílẹ̀ àní nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrẹ̀lẹ̀; nwọ́n sì kígbe pe Ọlọ́run gidigidi; bẹ̃ni, àní ní ọjọ́ gbogbo ni nwọ́n kígbe pe Ọlọ́run nwọn pé kí ó gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú nwọn.
15 Àti nísisìyí, Olúwa lọ́ra láti gbọ́ igbe nwọn nítorí àìṣedẽde nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa gbọ́ igbe nwọn, ó sì bẹ̀rẹ̀sí mú ọkàn àwọn ará Lámánì rọ̀, tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí dẹ àjàgà nwọn; síbẹ̀, Olúwa kò ì tĩ kà á sí ọgbọ́n láti yọ nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú.
16 Ó sì ṣe, tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lórí ilẹ̀ nã, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbin ọkà púpọ̀púpọ̀, nwọ́n sì ntọ́ agbo-ẹran, àti ọ̀wọ́-ẹran ọ̀sìn, tí ebi kò sì pa nwọ́n.
17 Nísisìyí àwọn obìnrin pọ̀ púpọ̀, ju àwọn ọkùnrin; nítorínã, Límháì ọba pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ọkùnrin máa ṣe ìrànlọ́wọ́ àwọn opó àti ọmọ nwọn, kí nwọn má bã parun pẹ̀lú ebi; èyí ni nwọ́n sì ṣe nítorítí àwọn tí nwọ́n ti pa nínú nwọn pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.
18 Nísisìyí àwọn ará Límháì sì dúró papọ̀ ní ọ̀kan gẹ́gẹ́bí ó ti ṣeéṣe fún nwọn, nwọ́n sì nkó àwọn ọkà nwọn pẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ẹran nwọn pamọ́;
19 Ọba pãpã kò gbóyà tó láti wà ní ẹ̀hìn odi ìlú, láìjẹ́wípé òun mú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ lọ́wọ́, ní ìbẹ̀rù pé ní ọ̀nà kan, òun lè bọ́ sọ́wọ́ àwọn ará Lámánì.
20 Ó sì mú kí àwọn ènìyàn rẹ̀ máa ṣọ́ ìlú nã yíká kiri, pé nípa ọ̀nà kan, nwọn lè mú àwọn àlùfã nnì tí nwọ́n ti sá lọ sínú aginjù, tí nwọ́n ti jí àwọn ọmọbìnrin Lámánì gbé, àti tí nwọ́n ti ṣeé tí ìparun nlá ti wá sórí nwọn.
21 Nítorítí nwọ́n fẹ́ láti mú nwọn kí nwọ́n lè fi ìyà jẹ nwọ́n; nítorítí nwọ́n wọ inú ìlú ti Nífáì ní àṣálẹ́, nwọ́n sì jí gbogbo ọkà nwọn gbé àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ nkan olówó iyebíye nwọn; nítorínã, nwọ́n ba pamọ́ dè nwọ́n.
22 Ó sì ṣe, tí ìrùkèrúdò dé òpin lãrín àwọn ará Lámánì àti àwọn ènìyàn Límháì, àní títí dé ìgbà tí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ fi wá sí ilẹ̀ nã.
23 Nígbàtí ọba sì wà ní ẹ̀hìn odi ìlú pẹ̀lú ẹ̀ṣọ́ rẹ, ó ṣe ìwárí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀; ó sì fi nwọ́n pe àlùfã Nóà, nítorínã ó pàṣẹ pé kí a mú nwọn, kí a sì dè nwọ́n, kí a sì sọ nwọ́n sínú tũbú. Tí nwọ́n bá sì jẹ́ àlùfã Nóà, ìbá ti pàṣẹ pé kí a pa nwọ́n.
24 Ṣùgbọ́n, nígbàtí ó rí i pé nwọn kìi ṣe é, ṣùgbọ́n pé arákùnrin òun ni nwọn íṣe, tí nwọ́n sì wá láti ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ó kún fún ayọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.
25 Nísisìyí ọba Límháì, kí Ámọ́nì tó dé, ti rán àwọn arákùnrin díẹ̀ láti lọ ṣe àwárí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà; ṣùgbọ́n nwọn kò ríi, nwọ́n sì sọnù nínú aginjù.
26 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n rí ilẹ̀ kan tí ènìyàn ti gbé inú rẹ̀ rí; bẹ̃ni ilẹ̀ tí egungun gbígbẹ borí rẹ̀; bẹ̃ni, ilẹ̀ tí ènìyàn ti gbé inú rẹ́ rí, tí nwọ́n sì ti parun; nítorítí nwọ́n sì fií pe ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n padà sí ilẹ̀ Nífáì, tí nwọ́n sì ti dé ìhà ilẹ̀ nã ní ọjọ́ díẹ̀ ṣãjú bíbọ̀ Ámmónì.
27 Nwọ́n sì gbé ìwé ìràntí kan wá, àní ìwé ìràntí àwọn ènìyàn nã tí nwọ́n rí egungun nwọn; a sì fín in sórí àwo irin àìpò.
28 Àti nísisìyí Límháì sì tún kún fún ayọ̀ nígbàtí ó gbọ́ láti ẹnu Ámọ́nì pé ọba Mòsíà ní ẹ̀bùn kan láti ọwọ́ Ọlọ́run, èyítí ó fi lè túmọ̀ irú fífín bẹ̃; bẹ̃ni, Ámọ́nì nã sì yọ̀.
29 Síbẹ̀, Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ kún fún ìrora-ọkàn nítorípé púpọ̀ nínú àwọn arákùnrin nwọn ni a ti pa;
30 Àti pẹ̀lú pé ọba Nóà àti àwọn àlùfã rẹ̀ ti jẹ́ kí àwọn ènìyàn nã dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀ àti àìṣedẽdé sí Ọlọ́run; nwọ́n sì ṣọ̀fọ̀ lórí ikú Ábínádì; àti pẹ̀lú jíjádelọ Álmà àti àwọn ènìyàn tí ó bá a lọ, tí nwọ́n ti kó ìjọ Ọlọ́run jọ nípasẹ̀ ipá àti agbára Ọlọ́run, àti ìgbàgbọ́ nínú ọ̀rọ̀ ti Ábínádì ti sọ.
31 Bẹ̃ni nwọ́n ṣọ̀fọ̀ fún lílọ tí nwọ́n lọ, nítorítí nwọn kò mọ́ ibi tí nwọ́n sálọ sí. Nísisìyí, nwọ́n ní ìfẹ́ láti darapọ̀ mọ́ nwọn, nítorítí àwọn pãpã ti wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run láti sìn ín àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.
32 Àti nísisìyí láti ìgbàtí Ámọ́nì ti dé, ọba Límháì pãpã ti bá Ọlọ́run dá májẹ̀mú, àti púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú, láti sìn ín, àti láti pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.
33 Ó sì ṣe tí ọba Límháì pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìfẹ́ fún ìrìbọmi; ṣùgbọ́n kò sí ẹnìkan ní ilẹ̀ nã tí ó ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ámọ́nì sì kọ̀ láti ṣe eleyĩ, nítorípé ó ka ara rẹ̀ kún ìránṣẹ́ aláìpé.
34 Nítorínã, nwọn kò kó ara nwọn jọ fún ìjọ ní ìgbà nã, nwọ́n sì dúró de Ẹ̀mí Olúwa. Nísisìyí nwọ́n ní ìfẹ́ láti dà bí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀, tí nwọ́n ti sá lọ sínú aginjù.
35 Nwọ́n ní ìfẹ́ kí a rì nwọn bọmi, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí àti ìjẹ̃rí pé nwọ́n ti jọ̀wọ́ ara nwọn fún sísin Ọlọ́run pẹ̀lú gbogbo ọkàn nwọn; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n sún àkókò nã síwájú; àkọsílẹ̀ ìrìbọmi nwọn ni a ó sọ láìpẹ́.
36 Àti nísisìyí, gbogbo èrò Ámọ́nì àti àwọn ènìyàn rẹ̀, pẹ̀lú ọba Límháì àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ni pé kí nwọ́n gba ara nwọn kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì àti kúrò nínú oko-ẹrú.