Ìtàn nípa Álmà àti àwọn ènìyàn Olúwa, àwọn ẹni tí a lé sínú aginjù nípa ọwọ́ àwọn ènìyàn Ọba Nóà.
Èyítí a kọ sí àwọn orí 23 àti 24.
Orí 23
Álmá kọ̀ láti jẹ́ ọba—Ó sìn gẹ́gẹ́bí olórí àlúfã—Olúwa bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí, àwọn ará Lámánì sì ṣẹ́gun ilẹ̀ ti Hẹ́lámì—Ámúlónì, olórí àwọn àlùfã búburú ti Ọba Nóà, ṣe ìjọba lábẹ́ àkóso ìjọba àwọn ará Lámánì. Ní ìwọ̀n ọdún 145 sí 121 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Nísisìyí Álmà, lẹ́hìn tí Olúwa ti kìlọ̀ fún un pé àwọn ọmọ ogun ọba Nóà yíò kọlù nwọ́n, àti lẹ́hìn tí ó ti sọ ọ́ fún àwọn ènìyàn rẹ̀, nítorínã, nwọn kó ọ̀wọ́ ohun ọ̀sìn nwọn, nwọ́n sì mú àwọn wóró irúgbìn nwọn, nwọ́n sì kọjá lọ sínú aginjù ṣíwájú ọmọ ogun ọba Nóà.
2 Olúwa sì fún nwọn ní agbára, tí àwọn ènìyàn ọba Nóà kò lè bá nwọn láti pa nwọ́n run.
3 Nwọ́n sì sá fún ìrìn-àjò ọjọ́ mẹ́jọ nínú aginjù.
4 Nwọ́n sì dé ilẹ̀ kan, bẹ̃ni, àní ilẹ̀ kan tí ó lẹ́wà púpọ̀ tí ó sì wuni, ilẹ̀ tí ó ní omi tí ó mọ́.
5 Nwọ́n sì pàgọ́ nwọn, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ síi dáko, nwọ́n bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ ilé; bẹ̃ni, nwọ́n lãpọn, nwọ́n sì nṣiṣẹ́ púpọ̀púpọ̀.
6 Àwọn ènìyàn nã sì ní ìfẹ́ kí Álmà jẹ́ ọba nwọn, nítorítí àwọn ènìyàn rẹ̀ ní ìfẹ́ ẹ rẹ̀.
7 Ṣùgbọ́n ó wí fún nwọn pé: Kíyèsĩ, kò tọ́ kí a ní ọba; nítorí báyĩ ni Olúwa wí: Ẹ̀yin kò gbọ́dọ̀ gbé ẹnìkan ga ju ẹlòmiràn, tàbí ẹnìkan kò gbọ́dọ̀ rò pé òun ga ju ẹlòmíràn lọ; nítorínã mo wí fún un yín pé kò tọ́ kí ẹ̀yin ní ọba.
8 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, tí ó bá ṣeéṣe kí ẹ̀yin ní ẹnití ó tọ́ láti jẹ́ àwọn ọba yín nígbà-gbogbo, yíò dára fún yín láti ní ọba.
9 Ṣùgbọ́n ẹ rántí àìṣedẽdé ọba Nóà, àti àwọn àlùfã rẹ̀; èmi pãpã kó sínú ìgbèkùn, tí mo sì ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun tí ó jẹ́ ìríra lójú Olúwa, lórí èyítí èmi ṣe ìrònúpìwàdà tí ó múná.
10 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú, Olúwa gbọ́ ẹ̀bẹ̀ mi, ó sì gbọ́ àdúrà mi, ó sì ti fi mí ṣe ohun èlò lọ́wọ́ rẹ fún mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ yín wá sínú ìmọ̀ ọ̀títọ́ ọ rẹ̀.
11 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nínú èyí èmi kò ṣògo, nítorítí kò tọ́ fún mi kí èmi kí ó yin ara mi.
12 Àti nísisìyí mo wí fún yín, ẹ̀yin ti wà nínú ìnilára ọba Nóà, ẹ̀yin sì ti wà nínú oko-ẹrú rẹ àti ti àwọn àlùfã rẹ̀, nwọn sì ti mú yín ṣe àìṣedẽdé; nítorínã, ẹ̀yin wà nínú ìdè àìṣedẽdé.
13 Àti nísisìyí, nítorítí a ti gbà yín kúrò nínú àwọn ìdè wọnyí nípa agbára Ọlọ́run; bẹ̃ni, àní kúrò lọ́wọ́ ọba Nóà àti àwọn ènìyàn rẹ, àti kúrò nínú ìdè àìṣedẽdé pẹ̀lú, bẹ̃ni èmi sì ní ìfẹ́ kí ẹ̀yin kí ó dúró ṣinṣin nínú òmìnira yĩ, nínú èyítí a ti sọ yín di òmìnira, kí ẹ̀yin má sì ṣe gbẹ́kẹ̀lé ẹnìkẹ́ni kí ó jọba lórí i yín.
14 Àti pẹ̀lú, ẹ máṣe gbẹ́kẹ̀lé ẹnìkẹ́ni láti jẹ́ olùkọ́ yín tàbí àlùfã yín, àfi tí ó bá jẹ́ ẹni Ọlọ́run, tí ó nrìn ní ọ̀nà rẹ, tí ó sì npa àwọn òfin rẹ̀ mọ́.
15 Báyĩ ni Álmà kọ́ àwọn ènìyàn rẹ̀, pé kí olúkúlùkù fẹ́ràn ọmọnìkéjì rẹ̀ gẹ́gẹ́bí ara rẹ̀, kí asọ̀ máṣe wà lãrín nwọn.
16 Àti nísisìyí, Álmà ni olórí àlùfã nwọn, ẹnití íṣe olùdásílẹ̀ ìjọ nwọn.
17 Ó sì ṣe, tí ẹnìkẹ́ni kò gba àṣẹ láti wãsù tàbí kọ́ni-lẹ́kọ̃, àfi nípasẹ̀ rẹ̀ láti ọwọ́ Ọlọ́run. Nítorínã, ó ya gbogbo àwọn àlùfã nwọn àti àwọn olùkọ́ni nwọn sí mímọ́; kò sì sí ẹnìkan tí a yà sí mímọ́ bíkòṣe ẹnití ó tọ́.
18 Nítorínã nwọ́n ṣọ́ àwọn ènìyàn nwọn, nwọ́n sì bọ́ nwọn pẹ̀lú ohun tĩ ṣe ti òdodo.
19 Ó sì ṣe tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ilẹ̀ nã; nwọ́n sì pe orúkọ ilẹ̀ nã ní Hẹ́lámì.
20 Ó sì ṣe tí nwọ́n bí sĩ, tí nwọ́n sì ṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀ ní ilẹ̀ ti Hẹ́lámì; nwọ́n sì kọ́ ìlú nlá kan, èyítí nwọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní ìlú-nlá Hẹ́lámì.
21 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa rí i pé ó tọ́ láti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ wí; bẹ̃ni, òun dán sũrù nwọn àti ìgbàgbọ́ nwọn wò.
22 Bíótilẹ̀ríbẹ̃—ẹnìkẹ́ni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé e, òun ni a o gbé sókè ní ọjọ́ ìkẹ́hìn. Bẹ̃ni, báyĩ ni ó sì rí fún àwọn ènìyàn yí.
23 Nítorí kíyèsĩ, èmi yíò fihàn yín pé a mú nwọn wá sínú oko-ẹrú, kò sì sí ẹni nã tí ó lè gbà nwọ́n àfi Olúwa Ọlọ́run nwọn, bẹ̃ni, àní Ọlọ́run Ábráhámù àti Ísãkì àti ti Jákọ́bù.
24 Ó sì ṣe, tí ó gbà nwọ́n, ó sì fi agbára nlá hàn nwọ́n, púpọ̀ sì ni àjọyọ̀ nwọn.
25 Nítorí kíyèsĩ, ó sì ṣe nígbàtí nwọ́n wà ní ilẹ̀ ti Hẹ́lámì, bẹ̃ni, nínú olú-ìlú ilẹ̀ Hẹ́lámì, tí nwọ́n ndáko yíká, kíyèsĩ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì wà ní ãlà ilẹ̀ nã.
26 Ó sì ṣe nísisìyí, tí àwọn arákùnrin Álmà sá lọ kúrò nínú oko nwọn, tí nwọ́n sì kó ara nwọn jọ nínú olú-ìlú ti Hẹ́lámì; ẹ̀rù sì bà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìfarahàn àwọn ará Lámánì.
27 Ṣùgbọ́n Álmà kọjá lọ ó sì dúró lãrín nwọn, ó sì gbà nwọ́n níyànjú pé kí nwọ́n máṣe bẹ̀rù, ṣùgbọ́n pé kí nwọn rántí Olúwa Ọlọ́run nwọn, òun yíò sì gbà nwọ́n.
28 Nítorínã nwọ́n mú ẹ̀rù nwọn kúrò, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí képe Olúwa, pé kí ó lè mú ọkàn àwọn ará Lámánì rọ̀, pé kí nwọ́n dá ẹ̀mí nwọn sí, àti àwọn ìyàwó nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn.
29 Ó sì ṣe, Olúwa sì mú kí ọkàn àwọn ará Lámánì rọ̀. Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sì kọjá lọ, nwọ́n sì jọ̀wọ́ ara nwọn sílẹ̀ lé nwọn lọ́wọ́; àwọn ará Lámánì sì ṣe ìkógun ilẹ̀ ti Hẹ́lámì.
30 Báyĩ àwọn ọmọ ogun àwọn Lámánì, tí nwọ́n ti sá tẹ̀lé àwọn ará ọba Límháì, ti sọnù nínú aginjù fún ọjọ́ púpọ̀.
31 Sì kíyèsĩ, nwọ́n ti rí àwọn àlùfã ọba Nóà, ní ibìkan tí nwọn npè ní Ámúlónì; nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀sí ṣe ìkógun ilẹ̀ Ámúlónì nwọ́n sì ndáko.
32 Nísisìyí orúkọ olórí àwọn àlùfã nã ni í ṣe Ámúlónì.
33 Ó sì ṣe tí Ámúlónì ṣìpẹ̀ pẹ̀lú àwọn ará Lámánì; ó sì tún rán àwọn ìyàwó nwọn, tí nwọn jẹ́ ọmọbìnrin àwọn ará Lámánì, kí nwọn ṣìpẹ̀ pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn, pé kí nwọ́n máṣe pa àwọn ọkọ nwọn.
34 Àwọn ará Lámánì sì ṣãnú fún Ámúlónì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, nwọn kò sì pa nwọ́n, nítorí àwọn ìyàwó nwọn.
35 Ámúlónì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ sì darapọ̀ mọ́ àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì nrin ìrìn-àjò nínú aginjù, tí nwọ́n nwá ilẹ̀ ti Nífáì, nígbàtí nwọ́n sì ṣe àwárí ilẹ̀ ti Hẹ́lámì, èyítí Álmà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ ṣe ìkógun rẹ̀.
36 Ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì ṣe ìpinnu fún Álmà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, wípé bí nwọ́n bá lè fi ọ̀nà hàn nwọ́n, èyítí ó lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì, nwọn yíò jọ̀wọ́ ẹ̀mí nwọn àti òmìnira nwọn fún nwọ́n.
37 Ṣùgbọ́n lẹ́hìn tí Álmà ti fi ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ ti Nífáì hàn nwọ́n tán, àwọn ará Lámánì kùnà láti pa ìpinnu nwọn mọ́; ṣùgbọ́n nwọ́n fi àwọn ìṣọ́ yí ilẹ̀ Hẹ́lámì ká kiri, sí orí Álmà àti àwọn arákùnrin rẹ̀.
38 Àwọn tí ó kù nínú nwọn sì lọ sínú ilẹ̀ ti Nífáì; òmíràn nínú nwọn padà sí ilẹ̀ Hẹ́lámì, nwọ́n sì mú wá pẹ̀lú nwọn àwọn ìyàwó pẹ̀lú àwọn ọmọ àwọn ìṣọ́ tí nwọ́n kù lẹ́hìn.
39 Ọba àwọn ará Lámánì sì ti gbà kí Ámúlónì jẹ́ ọba àti alákõso fún àwọn ènìyàn rẹ̀, tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Hẹ́lámì; bíótilẹ̀ríbẹ̃ pé kí yíò ní àṣẹ láti ṣe ohunkóhun tí ó lòdì sí ìfẹ́ ti ọba àwọn ará Lámánì.