Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 22


Orí 22

A gbèrò ọ̀nà fún àwọn ènìyàn nã láti yọ kúrò nínú oko-ẹrú àwọn ará Lámánì—A mú kí àwọn ará Lámánì mútípara—Àwọn ènìyàn nã yọ kúrò, nwọ́n padà sí Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì di ènìyàn ìlú lábẹ́ ọba Mòsíà. Ní ìwọ̀n ọdún 121 sí 120 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe, tí Ámọ́nì àti ọba Límháì bẹ̀rẹ̀síi wá ìdí ọ̀rọ̀ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn nã bí nwọn ó ṣe gba ara nwọn kúrò nínú oko-ẹrú; àti pẹ̀lú nwọn pàṣẹ kí gbogbo ènìyàn kó ara nwọn jọ; eleyĩ ni nwọ́n ṣe kí nwọn kí ó lè mọ ohùn àwọn ènìyàn nã nípa ọ̀rọ̀ nã.

2 Ó sì ṣe tí nwọn kò rí ọ̀nà tí nwọ́n lè gbà yọ ara nwọn kúrò nínú oko-ẹrú, àfi tí nwọ́n bá kó àwọn obìnrin nwọn, àti àwọn ọmọ, àti agbo àti ọ̀wọ́-ẹran, àti àgọ́ nwọn, kí nwọ́n sì kọjá lọ sínú aginjù; nítorítí àwọn ará Lámánì ti pọ̀ tó bẹ̃ tí kò sí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn Límháì lè dojú ìjà kọ nwọ́n, tí nwọ́n rò pé àwọn lè gba ara nwọn sílẹ̀ nínú oko-ẹrú pẹ̀lú idà.

3 Nísisìyí, ó sì ṣe tí Gídéónì kọjá lọ ó sì dúró níwájú ọba, ó sì wí fún un pé: Nísisìyí, A! ọba, ìwọ ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi títí dé ìhín, ní ìgbà púpọ̀ tí àwa nbá àwọn arákùnrin wa, àwọn ará Lámánì jà.

4 Àti nísisìyí, A! ọba, bí ìwọ kò bá kà mí kún ọmọ-ọ̀dọ̀ aláìlérè, tàbí tí ìwọ bá ti gbọ́ ọ̀rọ̀ mi títí dé ìhín, bí ó ti wù kí ó kéré tó, tí nwọ́n sì wúlò fún ọ, bẹ̃ nã sì ni èmi fẹ́ kí ìwọ tẹ́tí sí ọ̀rọ̀ mi ní ìgbà yĩ, èmi yíò sì jẹ́ ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ, èmi ó sì gba àwọn ènìyàn yí nínú oko-ẹrú.

5 Ọba sì gbà á lãyè láti sọ̀rọ̀. Gídéónì sì wí fún un pé:

6 Kíyèsí ọ̀nà tí ó wà lẹ́hìn, ní ipa odi tí ó wà lẹ́hìn, ní ìhà tí ó wà lẹ́hìn ìlú. Àwọn ará Lámánì tàbí àwọn ẹ̀ṣọ́ àwọn ará Lámánì, a máa mutí yó lálẹ́; nítorínã jẹ́ kí a ṣe ìkéde lãrín gbogbo àwọn ènìyàn yí, pé kí nwọ́n kó agbo àti ọ̀wọ́ ẹran nwọn jọ, kí nwọ́n sì dà nwọ́n lọ sínú aginjù ní àṣálẹ́.

7 Èmi yíò sì ṣe gẹ́gẹ́bí àṣẹ rẹ, èmi ó san owó-òde ìkẹhìn ní ti wáìnì fún àwọn ará Lámánì, nwọn ó sì mutí para; àwa yíò sì gba ọ̀nà ìkọ̀kọ̀ ní ìkọjá èyítí ó wà ní apá òsì ibùdó nwọn, nígbàtí nwọn yíò ti mutípara, tí nwọn yíò sì ti sùn lọ.

8 Báyĩ sì ni àwa yíò jáde kúrò pẹ̀lú àwọn obìnrin wa àti àwọn ọmọ wa, àwọn agbo ẹran wa àti àwọn ọ̀wọ́ ohun ọ̀sìn wa lọ sínú aginjù; àwa yíò sì rin ìrìn-àjò yípo ilẹ̀ ti Ṣílómù.

9 Ó sì ṣe, tí ọba nã gbọ́ran sí Gídéónì lẹ́nu.

10 Límháì ọba sì pàṣẹ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ kó àwọn agbo ẹran nwọn jọ; ó sì fi owó-òde ọtí wáìnì ránṣẹ́ sí àwọn ará Lámánì; òun sì fi ọtí wáìnì púpọ̀ ránṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ọrẹ sí nwọn; nwọ́n sì mu ọtí wáìnì nã, èyítí ọba Límháì fi ránṣẹ́ sí nwọn ní ámupara.

11 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn ọba Límháì sì jáde kúrò ní àṣálẹ́ lọ sínú aginjù pẹ̀lú agbo ẹran nwọn àti ọ̀wọ́ ohun ọ̀sìn nwọn, nwọ́n sì yípo ilẹ̀ Ṣílómù, nínú aginjù, nwọ́n sì yí ẹsẹ̀ padà sí ìhà ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, tí Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ sì ndarí nwọn.

12 Nwọ́n sì ti mú gbogbo wúrà, àti turàrí pẹ̀lú ohun ìní nwọn olówó-iyebíye, tí nwọ́n lè gbé, àti gbogbo ohun-ìpèsè nwọn pẹ̀lú nwọn, kọjá lọ sínú aginjù; nwọ́n sì tẹ̀síwájú ní ìrìnàjò nwọn.

13 Lẹ́hìn tí nwọ́n sì ti wà nínú aginjù fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọjọ́, nwọ́n dé ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Mòsíà, nwọ́n sì wà lábẹ́ ìjọba rẹ̀.

14 Ó sì ṣe, tí Mòsíà gbà nwọn tayọ̀-tayọ̀; ó sì tún gba ìwé ìrántí nwọn, àti ìwé-ìrántí èyítí àwọn ará Límháì ṣe àwárí rẹ̀.

15 Àti nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí àwọn ará Lámánì ti ní òye pé àwọn ènìyàn Límháì ti jáde kúrò ní ilẹ̀ nã ní àṣálẹ́, nwọ́n rán àwọn ọmọ ogun sínú aginjù láti lé nwọn bá;

16 Nígbàtí nwọ́n sì lé nwọn fún ọjọ́ méjì, nwọn kò lè tọ ipasẹ̀ ọ̀nà tí nwọ́n gbà mọ; nítorínã nwọ́n sọnù sínú aginjù.