Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 29


Orí 29

Mòsíà dá ìmọ̀ràn kí a yan àwọn adájọ́ dípò ọba—Àwọn ọba aláìṣòdodo a máa kó àwọn ènìyàn nwọn sínú ẹ̀ṣẹ̀—A yan Álmà kékeré ní onídàjọ́ gíga nípa ohùn àwọn ènìyàn—Ó sì tún íṣe olórí àlùfã lórí Ìjọ—Álmà àgbà àti Mòsíà kú. Ní ìwọ̀n ọdún 92 sí 91 kí a tobí Olúwa wa.

1 Nísisìyí, nígbàtí Mòsíà ti ṣe èyí, ó ránṣẹ́ jákè-jádò ilẹ̀ nã, lãrín àwọn ènìyàn, o fẹ láti mọ́ ìfẹ́ nwọn nípa ẹni tí yíò ṣe ọba nwọn.

2 Ó sì ṣe tí ọ̀rọ̀ àwọn ènìyàn dé, wípé: Àwa ní ìfẹ́ kí Áárọ́nì ọmọ rẹ̀ jẹ́ ọba àti olórí wa.

3 Nísisìyí, Áárọ́nì ti kọjá lọ sí ilẹ̀ Nífáì, nítorínã ọba kò lè gbé ìjọba lée lọ́wọ́; bẹ̃ sì ni Áárọ́nì kò ní gba ìjọba nã; bẹ̃ sì ni kò sí ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Mòsíà tí ó ní ìfẹ́ láti gba ìjọba nã.

4 Nítorínã, ọba Mòsíà tún ránṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nã; bẹ̃ni, àní ó kọ àwọn ọ̀rọ̀ nã sí àwọn ènìyàn nã. Èyí sì ni àwọn ọ̀rọ̀ tí ó kọ wípé:

5 Kíyèsĩ, A! ẹ̀yin ènìyàn mi, tàbí arákùnrin mi, nítorítí mo kà yín kún bẹ̃, èmi ní ìfẹ́ kí ẹ tún ọ̀rọ̀ nã rò, èyítí a pè yín kí ẹ rò—nítorítí ẹ ní ìfẹ́ láti ní ọba.

6 Nísisìyí, mo wí fún yín pé ẹnití ìjọba tọ́ sí ti kọ̃, kò sì ní gba ìjọba nã.

7 Àti nísisìyí, tí a bá sì yan ẹlòmíràn rọ́pò rẹ̀, kíyèsĩ, èmi bẹ̀rù pé ìjà yíò bẹ́ sílẹ̀ lãrín yín. Tani ó sì mọ̀ bóyá ọmọ mi, ẹnití ìjọba nã jẹ́ tirẹ̀ yíò bínú, tí yíò sì kó apá kan nínú àwọn ènìyàn yí lọ tẹ̀lée, èyítí yíò dá ogun àti ìjà sílẹ̀ lãrín yín, èyítí yíò sì fa ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti yíyí ọ̀nà Olúwa padà, bẹ̃ni, tí nwọ́n yíò sì pa ọkàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn run.

8 Nísisìyí mo wí fún yín, ẹ jẹ́ kí a gbọ́n kí a sì ro àwọn ohun wọ̀nyí, nítorí a kò ní ẹ̀tọ́ láti pa ọmọ mi run, bẹ̃ sì ni a kò gbọ́dọ̀ ní ẹ̀tọ́ láti pa ẹlòmíràn tí a bá yàn dípò o rẹ̀ run.

9 Bí ọmọ mi bá sì padà sí ipò agbéraga àti ohun asán, òun yíò sẹ́ ìrántí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti sọ, yíò sì gba ẹ̀tọ́ rẹ̀ sí ìjọba, èyítí yíò mú kí òun àti àwọn ènìyàn yí dá ẹ̀ṣẹ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀.

10 Àti nísisìyí, ẹ jẹ́ kí a jẹ́ ọlọgbọ́n, kí a sì fi ọkàn sí ohun wọ̀nyí, kí àwa kí ó sì ṣe èyítí yíò mú àlãfíà wà lãrín àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

11 Nítorínã, èmi yíò jẹ́ ọba yín fún ìyókù ọjọ́ ayé mi; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ jẹ́ kí a yan àwọn onídàjọ́, kí nwọ́n máa ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn wọ̀nyí gẹ́gẹ́bí òfin wa; àwa yíò sì ṣe ìlànà titun fún àkóso àwọn ènìyàn yí nítorítí àwa yíò yan àwọn ọlọ́gbọ́n ènìàn gẹ́gẹ́bí onídàjọ́, tí nwọn yíò ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn yí gẹ́gẹ́bí àwọn òfin Ọlọ́run.

12 Nísisìyí, ó sàn kí a ṣe ìdájọ́ ènìyàn nípa Ọlọ́run ju nípa ènìyàn, nítorítí awọn ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ èyítí ó tọ́ nígbà-gbogbo, ṣùgbọ́n awọn ìdájọ́ ènìyàn jẹ́ èyítí kò tọ́ nígbà-gbogbo.

13 Nítorínã, tí ó bá ṣẽṣe kí ẹ̀yin kí ó ní àwọn ènìyàn tí ó tọ́ láti jẹ́ àwọn ọba yín, tí nwọ́n yíò fi awọn òfin Ọlọ́run múlẹ̀, tí nwọn yíò sì ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn yí gẹ́gẹ́bí àwọn òfin rẹ̀, bẹ̃ni, bí ẹ̀yin bá lè ní àwọn ènìyàn láti jẹ́ àwọn ọba yín tí nwọn yíò ṣe àní gẹ́gẹ́bí bàbá mi Bẹ́njámínì ti ṣe fún àwọn ènìyàn yĩ—mo wí fún yín, bí ó bá lè rí báyĩ nígbà-gbogbo, nígbànã ni yíò tọ́ kí ẹ̀yin ní ọba nígbà-gbogbo láti jọba lórí yín.

14 Èmi pãpã ti tiraka pẹ̀lú gbogbo agbára àti ipá tí mo ní, láti kọ́ yín ní àwọn òfin Ọlọ́run, àti láti fi àlãfíà lélẹ̀ jákè-jádò ilẹ̀ nã, pé kí ogun tàbí ìjà má wà, kí ó má ṣe sí olè jíjà tàbí ìkógun, tàbí ìpànìyàn tàbí ìwà àìṣedẽdé, bí ó tilè wù kí ó rí;

15 Ẹnìkẹ́ni tí o bá sì ti hu ìwà àìṣedẽdé, òun ni èmi ti jẹ níyà gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó ṣẹ̀, gẹ́gẹ́bí òfin tí àwọn bàbá wa ti fún wa.

16 Nísisìyí, mo wí fún yín pé nítorítí gbogbo ènìyàn jẹ́ aláìṣõtọ́, kò tọ́ kí ẹ ní ọba tàbí àwọn ọba kí nwọ́n jọba lórí i yín.

17 Nítorí kíyèsĩ, báwo ni ìwà àìṣedẽdé ọba búburú yíò ti tó, bẹ̃ni, báwo ni ìparun nã yíò ti tóbi tó!

18 Bẹ̃ni, ẹ ṣe ìrántí ọba Nóà, ìwà búburú àti ìwà ìríra rẹ̀, àti ìwà búburú àti ìwà ìríra àwọn ènìyàn rẹ̀. Ẹ kíyèsĩ ìparun nlá tí ó wá sórí nwọn; àti pẹ̀lú, nítorí àìṣedẽdé nwọn, nwọn bọ́ sínú oko-ẹrú.

19 Bí kò bá sì ṣe nítorí àkóyọ Ẹlẹ́dã nwọn ẹnití ó gbọ́n jùlọ, àti pẹ̀lú ìrònúpìwàdà àtọkànwá nwọn, nwọn yíò wà nínú oko-ẹrú dandan títí àkokò yí.

20 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó gbà nwọ́n nítorípé nwọ́n rẹ ara nwọn sílẹ̀ níwájú rẹ̀; àti nítorípé nwọ́n kígbe pè é lọ́pọ̀lọpọ̀, ó sì gbà nwọ́n kúrò nínú oko-ẹrú; báyĩ sì ni Olúwa nṣiṣẹ́ nínú agbára rẹ̀ ní gbogbo ìgbà, lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, tí ó sì nna ọwọ́ ãnú rẹ̀ sí àwọn tí nwọ́n bá gbẹ́kẹ̀lé e.

21 Kíyèsĩ, nísisìyí mo wí fún yín, ẹ̀yin kò lè lé ọba aláìṣedẽdé kúrò lórí ìtẹ́ àfi nípa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìjà pẹ̀lú ìtàjẹ̀ sílẹ̀.

22 Nítorí kíyèsĩ ó ni àwọn ọ̀rẹ́ nínú àìṣedẽdé, òun sì fi ìṣọ́ ṣọ́ ara rẹ̀; òun sì yí òfin àwọn tí ó jọba nínú òtítọ́ ṣãjú rẹ̀ padà; ó sì ntẹ àwọn òfin Ọlọ́run mọ́lẹ̀ lábẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀;

23 Ó sì fi awọn òfin lélẹ̀, ó sì fi nwọ́n ránṣẹ́ sí ãrin àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, awọn òfin ní ìbámu pẹ̀lú ìwà-búburú rẹ̀; ẹnìkẹ́ni tí kò bá sì pa awọn òfin rẹ̀ wọ̀nyí mọ́, ni ó mú kí nwọ́n parun; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì ta kò ó, òun yíò rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti kọlũ ú ní ogun, tí ó bá sì lè ṣeé, yíò pa nwọ́n run; báyĩ sì ni ọba búburú nnì yíò ṣe yí ọ̀títọ́ gbogbo ọ̀nà òdodo padà.

24 Àti nísisìyí kíyèsĩ, mo wí fún yín, kò tọ̀nà pé kí irú awọn ìwà ìríra báyĩ kí ó wá sí órí yín.

25 Nítorínã, ẹ yan àwọn onídàjọ́ nípa ohùn àwọn ènìyàn wọ̀nyí, kí nwọ́n lè ṣe ìdájọ́ yín gẹ́gẹ́bí òfin èyítí a ti fún nyín nípasẹ̀ àwọn bàbá wa, èyítí ó pé, èyítí a sì ti fún nwọn nípa ọwọ́ Olúwa.

26 Nísisìyí, kò wọ́pọ̀ kí ohùn àwọn ènìyàn lè ní ìfẹ́ sí ohun tí ó lòdì sí èyítí ó tọ́; ṣùgbọ́n ó wọ́pọ̀ kí díẹ̀ nínú àwọn ènìyàn ní ìfẹ́ sí ohun tí kò tọ́; nítorínã, èyí yíi ni ẹ̀yin yíò gbà, tí ẹ̀yin yíò sì mú u ṣe òfin yín—kí ẹ̀yin kí ó ṣe àkóso ara yín nípa ohùn àwọn ènìyàn yín.

27 Tí àkokò nã bá sì dé tí ohùn àwọn ènìyàn bá yan àìṣedẽdé, nígbànã ní àkokò tí ìdájọ́ Ọlọ́run yíò wá sórí yín; bẹ̃ni, nígbànã ni òun yíò bẹ̀ yín wò pẹ̀lú ìparun nlá, àní bí ó ti bẹ ilẹ̀ yí wò ní ìgbà kan rí.

28 Àti nísisìyí bí ẹ̀yin bá ní àwọn adájọ́, tí nwọn kò sì ṣe ìdájọ́ yín gẹ́gẹ́bí òfin, èyítí a ti fún yín, ẹ̀yin lè ní kí adájọ́ tí ó ga jù ú ṣe ìdájọ́ rẹ̀.

29 Bí àwọn adájọ́ gíga yín kò bá sì ṣe ìdájọ́ òtítọ́, ẹ̀yin yíò mú kí díẹ̀ nínú àwọn adájọ́ kékeré yín kójọ pọ̀, nwọn yíò sì ṣe ìdájọ́ àwọn adájọ́ gíga yín, gẹ́gẹ́bí ohùn àwọn ènìyàn.

30 Mo sì pàṣẹ fún yín kí ẹ ṣe ohun wọ̀nyí nínú ìbẹ̀rù Olúwa; mo sí pàṣẹ fún yín kí ẹ ṣe àwọn ohun wọ̀nyí, pé kí ẹ̀yin máṣe ní ọba; pé bí àwọn ènìyàn yí bá dá ẹ́ṣẹ̀ àti tí nwọ́n ṣe àìṣedẽdé a ó sì bẹ̀ nwọ́n wò lórí ará nwọn.

31 Nítorí kíyèsĩ mo wí fún yín, ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ní ó jẹ́ wípé ìwà àìṣedẽdé awọn ọba nwọn ni ó fã; nítorínã, a o sì bẹ ìwà àìṣedẽdé nwọn wò lórí àwọn ọba nwọn.

32 Àti nísisìyí, mo ní ìfẹ́ kí àìdọ́gba yĩ dópin lórí ilẹ̀ yí, pãpã lãrín àwọn ènìyàn mi yí; ṣùgbọ́n mo fẹ́ kí ilẹ̀ yí jẹ́ ilẹ̀ òmìnira, olúkúlùkù yíò sì ní ẹ̀tọ́ àti ànfàní bákannã, títí dé ìgbàtí Olúwa yíò kã sí ọgbọ́n pé kí àwa kí ó yè kí a sì jogún ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, àní títí dé ìgbà tí àwọn ìran wa yíò fi wà lórí ilẹ̀ nã.

33 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun míràn ni ọba Mòsíà sì kọ sí nwọn, tí ó nfi hàn nwọ́n nípa gbogbo àdánwò àti lãlã ọba olódodo, bẹ̃ni, gbogbo lãlã ẹ̀mí fún àwọn ènìyàn rẹ̀, àti gbogbo ìráhùn àwọn ènìyàn sí ọba nwọn; ó sì fi gbogbo rẹ̀ yé nwọn.

34 Ó sì wí fún nwọn pé àwọn ohun wọ̀nyí kò yẹ kí ó rí bẹ̃; ṣùgbọ́n pé ẹrù yí yẹ kí ó jẹ́ ti gbogbo ènìyàn, kí olúkúlùkù lè faradà èyítí ó tọ́ sí i.

35 Ó sì tún sọ fún wọn nípa ìpalára èyítí yíò jẹ́ tiwọn, nípa níní ọba búburú lórí nwọn;

36 Bẹ̃ni, gbogbo àìṣedẽdé àti ìwà ìríra rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo ogun, àti ìjà, àti ìtàjẹ̀sílẹ̀, àti olè jíjà, àti ìkógun, àti ìwà àgbèrè, àti onírurú ìwà àìṣedẽdé èyítí a kò lè sọ—tí ó sì nsọ fún wọn pé kò yẹ kí àwọn ohun wọ̀nyí rí bẹ̃, pé nwọ́n lòdì pátápátá sí awọn òfin Ọlọ́run.

37 Àti nísisìyí ó sì ṣe, lẹ́hìn tí ọba Mòsíà ti ránṣẹ́ báyĩ sí àwọn ènìyàn nã, nwọ́n gbà pé ọ̀títọ́ ni awọn ọ̀rọ̀ rẹ̀.

38 Nítorínã, nwọn kọ ìfẹ́ láti ní ọba sílẹ̀, nwọ́n sì ṣe àníyàn lọ́pọ̀lọpọ̀ pé kí olúkúlùkù ní ànfàní ọgbọ̃gba jákè-jádò ilẹ̀ nã; bẹ̃ni, olúkúlùkù sì sọ ìfẹ́-inú rẹ̀ láti dáhùn sí ẹ̀ṣẹ̀ ara rẹ̀.

39 Nítorínã, ó sì ṣe tí nwọ́n kó ara nwọn jọ nísọrí-ìsọrí jákè-jádò ilẹ̀ nã, kí nwọ́n sọ nípa tani yíò ṣe olùdájọ́ nwọn, láti ṣe ìdájọ́ nwọn gẹ́gẹ́bí òfin tí a ti fún nwọn; nwọ́n sì yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí òmìnira èyítí a ti fún nwọn.

40 Nwọ́n sì tẹ̀ síwájú lọ́pọ̀lọpọ̀ nínú ìfẹ́ sí Mòsíà; bẹ̃ni, nwọ́n kà á kún kọjá ẹlòmíràn; nítorítí nwọn kò kà á sí aninilára, tí ó nwá ìfà fún ara rẹ̀, bẹ̃ni, fún ìfẹ́ owó, èyítí ó ndíbàjẹ́ ẹ̀mí; nítorítí kò gba ọrọ̀ lọ́wọ́ nwọn, kò sì ní inúdídùn sí ìtàjẹ̀sílẹ̀; ṣùgbọ́n ó ti fi àlãfíà lélẹ̀ lórí ilẹ̀ nã, ó sì ti gbà fún àwọn ènìyàn nã pé kí nwọ́n bọ́ lọ́wọ́ onírurú oko-ẹrú; nítorínã ni nwọ́n ṣe buyì fún, bẹ̃ni, lọ́pọ̀lọpọ̀ kọjá ìwọ̀n.

41 Ó sì ṣe, tí nwọ́n yan àwọn onídàjọ́ láti ṣe àkóso lórí nwọn, tàbí láti ṣe ìdájọ́ nwọn gẹ́gẹ́bí òfin; èyí ni nwọ́n sì ṣe jákè-jádò ilẹ̀ nã.

42 Ó sì ṣe tí a yan Álmà gẹ́gẹ́bí onídàjọ́ àgbà àkọ́kọ́, tí òun sì tún jẹ́ olórí àlùfã, nítorítí bàbá rẹ̀ ti gbé ìpè nã lé e lọ́wọ́, tí ó sì ti fún un ní àṣẹ lórí gbogbo ètò ìjọ-Ọlọ́run.

43 Ati nísisìyí ó sì ṣe, tí Álmà nrìn ní ọ̀nà Olúwa, ó sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, ó sì ṣe ìdájọ́ òdodo; àlãfíà sì wà títí lórí ilẹ̀ nã.

44 Báyĩ sì ni ìjọba àwọn onídàjọ́ bẹ̀rẹ̀ jákè-jádò ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, lãrín gbogbo àwọn ènìyàn tí à npè ní ará Nífáì; Álmà sì ni onídàjọ́ àgbà àkọ́kọ́.

45 Àti nísisìyí ni ó sì ṣe tí bàbá rẹ̀ kú, ní ọmọ ọgọ́rin àti ọdún méjì, lẹ́hìn tí ó ti gbé ìgbé ayé ní pípa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.

46 Ó sì ṣe tí Mòsíà nã kú, nínú ọgbọ̀n ọdún àti ìkẹ́ta ti ìjọba rẹ̀, tí ó sì jẹ́ ọmọ ọgọ́ta ọdún àti mẹ́ta; gbogbo rẹ̀ ní àpapọ̀ sì jẹ́ ọgọ́rún mãrún àti mẹ́sán ọdún láti ìgbà tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù.

47 Báyĩ sì ni ìjọba àwọn ọba lórí àwọn ènìyàn Nífáì dé òpin; báyĩ sì ni ọjọ́ ayé Álmà dé òpin, ẹnití ó jẹ́ olùdásílẹ̀ ìjọ nwọn.

Tẹ̀