Orí 16
Ọlọ́run nṣe ìràpadà fún ènìyàn kúrò nínú ipò ìpàdánù àti ìṣubú nwọn—Àwọn tí nwọ́n jẹ́ ti ara wà bí èyítí kò ní ìràpadà—Krístì mú wá sí ìmúṣẹ àjĩnde sí ìyè àìnípẹ̀kun tàbí sí ègbé àìnípẹ̀kun. Ní ìwọ̀n ọdún 148 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí Ábínádì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ yĩ ní ó na ọwọ́ rẹ̀ jáde, ó sì wípé: Àkokò nã mbọ̀wá tí ènìyàn gbogbo yíò rí ìgbàlà Olúwa; nígbàtí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti àwọn ènìyàn yíò ríi ni ójúkojú, nwọn ó sì jẹ́wọ́ níwájú Ọlọ́run pé ìdájọ́ rẹ̀ jẹ́ èyítí ó tọ́.
2 Nígbànã ni a ó ju àwọn ènìyàn búburú jáde, nwọn yíò sì pohùn réré, wọn yíò sì sọkún, nwọn yíò sì payín kéké; èyí yĩ nítorípé nwọn kò ní fetísílẹ̀ sí ohùn Olúwa; nítorínã Olúwa kò ní rà nwọ́n padà.
3 Nítorítí wọn jẹ́ ti ara, nwọ́n sì jẹ́ ti èṣù, èṣù sì lágbára lórí nwọn; bẹ̃ni, àní ejò ìgbà àtijọ́ nì, èyítí ó tan àwọn obí wa àkọ́kọ́ jẹ; èyítí ó sì jẹ́ ìdí ìṣubú nwọn; èyítí ó mú kí gbogbo ènìyàn jẹ́ ti ara, ti ayé, ti èṣù, tí nwọ́n sì mọ búburú yàtọ̀ sí rere, tí nwọ́n sì fi ara nwọn sílẹ̀ fún èṣù.
4 Báyĩ sì ni ènìyàn gbogbo ṣègbé: sì kíyèsĩ, nwọn kò bá sì ti ṣègbé títí láéláé, bíkòṣepé Ọlọ́run ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà kúrò nínú ipò ìparun àti ìṣubú nwọn.
5 Ṣùgbọ́n ẹ rántí pé ẹnití ó bá tẹ̀síwájú nínú ipò ti ara rẹ̀, tí ó sì lọ ní ipa ẹ̀ṣẹ̀ àti ìṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wà nínú ipò ìṣubú, èṣù sì ní gbogbo agbára lórí rẹ̀. Nítorínã ó wà bí ẹnití a kò ṣe ìràpadà, nítorítí òun jẹ́ ọ̀tá sí Ọlọ́run; bẹ̃ èṣù sì ni ọ̀tá Ọlọ́run.
6 Àti nísisìyí, tí kò bá jẹ́ pé Krístì wá sínú ayé, tí ó nsọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun èyítí mbọ̀ bí èyítí ó ti dé, kì bá ti sí ìràpadà.
7 Àti pé tí Krístì kò bá ti jínde kúrò nínú òkú, tàbí kí ó ti já ìdè ikú, kí ìsà-òkú má lè ní ìṣẹ́gun, àti kí ikú má lè ní oró, kì bá ti sí àjĩnde.
8 Ṣùgbọ́n àjĩnde wà, nítorínã, ìsà-òkú kò ní ìṣẹ́gun, oró ikú sì jẹ́ gbígbémì nínú Krístì.
9 Òun ni ìmọ́lẹ̀ àti ìyè ayé; bẹ̃ni, ìmọ́lẹ̀ tí ó wà láìnípẹ̀kun, tí a kò lè sọ di òkùnkùn; bẹ̃ni, àti pẹ̀lú iyé tí ó wà láìnípẹ̀kun, tí kò sì ní sí ikú mọ́.
10 Àti pãpã, ara kíkú yí, yíò gbé àìkú wọ̀, bẹ̃ni ìdíbàjẹ́ yĩ yíò gbé àìdíbàjẹ́ wọ̀, a ó sì mú u dúró níwájú itẹ Ọlọ́run kí a lè ṣe ìdájọ́ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ nwọn yálà rere ni nwọ́n tàbí búburú ni nwọ́n í ṣe—
11 Tí nwọ́n bá jẹ́ rere, sí àjĩnde ayé àti ayọ̀ tí kò lópin; tí nwọ́n bá sì jẹ́ búburú, sí àjĩnde sí ègbé áìnípẹ̀kun, tí a ti jọ̀wọ́ nwọn fún èṣù, tí òun sì jọba lé nwọn lórí, èyítí iṣe ègbé—
12 Nítorítí nwọ́n ti lọ sí ipa ìfẹ́-ara nwọn; tí nwọn kò sì ké pé Olúwa nígbàtí a na ọwọ́ ãnú sí nwọn; nítorítí a na ọwọ́ ãnú sí nwọn, nwọn kò sì gbà á; a kìlọ̀ fún nwọn nítorí ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, ṣùgbọ́n nwọn kò kọ̀ nwọ́n sílẹ̀; a sì pã láṣẹ pé kí ní wọ́n ronúpìwàdà, ṣùgbọ́n nwọn kò ronúpìwàdà.
13 Àti nísisìyí, njẹ́ kò ha yẹ kí ẹ̀yin wárìrì kí ẹ sì ronúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nyín, kí ẹ̀yin kí ó sì rántí pé nínú Krístì àti nípasẹ̀ rẹ̀ nìkan ni ẹ̀yin lè gbàlà bí?
14 Nítorínã, tí ẹ̀yin bá nkọ́ni ní òfin Mósè, kí ẹ̀yin kí ó sì máa kọ́ni wípé ẹ̀yà àwọn ohun tí mbọ̀ wá ni íṣe—
15 Kí ẹ ṣe ìkọ́ni pé ìràpadà wá nípasẹ̀ Krístì Olúwa, ẹnití iṣe Bàbá Ayérayé. Àmín.