Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 18


Orí 18

Álmà nwãsù ní ìkọ̀kọ̀—Ó ṣe ìlànà májẹ̀mú ìrìbọmi, ó sì nṣe rìbọmi nínú àwọn omi Mọ́mọ́nì—Ó ṣe ìkójọ ìjọ Krístì, ó sì yan àwọn àlùfã—Nwọ́n npèsè fún ara nwọn, nwọ́n sì nkọ́ àwọn ènìyàn ní ẹ̀kọ́—Álmà àti àwọn ènìyàn rẹ̀ sá kúrò níwájú Ọba Nóà, lọ sínú aginjù. Ní ìwọ̀n ọdún 147 sí 145 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí Álmà, ẹnití ó ti sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ ọba Nóà, ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àti àìṣedẽdé rẹ̀, ó sì nlọ ní ìkọ̀kọ̀ lãrín àwọn ènìyàn, ó sì bẹ̀rẹ̀sí nkọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́ ọ̀rọ̀ Ábínádì—

2 Bẹ̃ni, nípa èyítí nbọ̀ wá, àti pẹ̀lú nípa àjĩnde òkú, àti ìràpadà àwọn ènìyàn, èyítí a ó múṣẹ nípa agbára àti ìjìyà, àti ikú Krístì, àti àjĩnde òun ìgòkè re ọ̀run rẹ̀.

3 Àti gbogbo ẹnití ó gbọ́ ohùn rẹ̀ ni ó kọ́ ní ẹ̀kọ́. Ó sì kọ́ nwọn ní ìkọ̀kọ̀, pé kí ó má di mímọ̀ sí ọba. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni ó sì gba ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ gbọ́.

4 Ó sì ṣe, pé gbogbo ẹnití ó gbã gbọ́ ni ó lọ sí ibì kan tí a pè ní Mọ́mọ́nì, èyítí ó ti gba orúkọ rẹ̀ láti ọwọ́ ọba, tí ó wà ní ikangun ilẹ̀ nã, tí àwọn ẹranko búburú sì ngbé ibẹ̀ ní gbogbo ìgbà.

5 Ní báyĩ, orísun omi tí ó mọ́ kan wà ní Mọ́mọ́nì, Álmà sì kọjá lọ sibẹ̀, igbó ṣũrú kan sì wà ní ẹ̀gbẹ́ omi nã, níbití ó fi ara rẹ̀ pamọ́ sí ní ọ̀sán kúrò lọ́wọ́ ìwákiri ọba.

6 Ó sì ṣe, tí gbogbo ẹnití ó gbà á gbọ́ ni ó lọ sí ibẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀.

7 Ó sì ṣe lẹ́hìn ọjọ́ pípẹ́, àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn kó ara nwọn jọ sí ibi tí à npè ní Mọ́mọ́nì, láti gbọ́ ọ̀rọ̀ Álmà. Bẹ̃ni, gbogbo nwọn kójọ, àwọn tí nwọ́n gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, láti gbọ́ ọ. Ó sì kọ́ nwọn ní ẹ̀kọ́, ó sì wãsù sí nwọn fún ìrònúpìwàdà àti ìràpadà, àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa.

8 Ó sì ṣe, tí ó wí fún nwọn pé: Kíyèsĩ, àwọn wọ̀nyí ni omi Mọ́mọ́nì (nítorípé báyĩ ni à npè nwọ́n) ati nísisìyí, bí ẹ̀yin ti ṣe ní ìfẹ́ láti wá sínú agbo Ọlọ́run, kí a sì pè nyín ní ènìyàn rẹ̀, tí ẹ sì ṣetán láti fi ara dà ìnira ara nyín, kí nwọ́n lè fúyẹ́;

9 Bẹ̃ni, tí ẹ̀yin sì ṣetán láti ṣọ̀fọ̀ pẹ̀lú àwọn tí nṣọ̀fọ̀; bẹ̃ni, àti láti tu àwọn tí ó fẹ́ ìtùnú nínú, àti láti dúró gẹ́gẹ́bí àwọn ẹlẹ́rĩ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà àti nínú ohun gbogbo àti níbi gbogbo tí ẹ̀yin lè wà, àní títí dé ojú ikú, kí a lè rà yín padà nípasẹ̀ Ọlọ́run, kí a sì kà yín mọ́ ara àwọn tí ó ní àjĩnde èkíní, kí ẹ̀yin kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun—

10 Nísisìyí mo wí fún nyín, tí èyí bá jẹ́ ìfẹ́ ọkàn nyín, kíni ẹ̀yin ní tí ó jẹ́ ìdènà sí kí a rì nyín bọmi ní orúkọ Olúwa, gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí níwájú rẹ̀ wípé ẹ̀yin ti bá a dá májẹ̀mú, pé ẹ̀yin yíò máa sìn in, ẹ̀yin yíò sì pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́, kí Òun kí ó lè da Ẹ̀mí rẹ̀ lé nyín lórí lọ́pọ̀lọpọ̀?

11 Àti nísisìyí, nígbàtí àwọn ènìyàn nã ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, nwọ́n pàtẹ́wọ́ fún ayọ̀, nwọ́n sì kígbe sókè: Èyí ni ìfẹ́ ọkàn wa.

12 Àti nísisìyí ó sì ṣe, tí Álmà mú Hẹ́lámì, ẹnití ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn ẹni àkọ́kọ́, ó sì lọ dúró nínú omi nã ó sì ké rara, ó wípé: Á!, Olúwa, da Ẹ̀mí rẹ lé orí ọmọ-ọ̀dọ̀ rẹ, kí òun kí ó lè ṣe iṣẹ́ yĩ pẹ̀lú ọkàn mímọ́.

13 Nígbàtí ó sì ti sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ẹ̀mí Olúwa sì bà lée, ó wipe: Hẹ́lámì, Mo rì ọ́ bọmi, nítorítí èmi ní àṣẹ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Olódùmarè, fún ẹ̀rí pé ìwọ ti wọ inú májẹ̀mú láti sìn ín, títí dé ojú ikú ni ti ara; kí Ẹ̀mí Olúwa sì dà lé ọ lórí; kí òun kí ó sì fún ọ ní ìyè àìnípẹ̀kun, nípasẹ̀ ìràpadà ti Krístì, èyítí ó ti pèsè láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

14 Nígbatí Álmà sì ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Álmà àti Hẹ́lámì tẹ ara nwọn rì sínú omi nã; nwọ́n sì dìde sókè, nwọ́n sì jáde kúrò nínú omi pẹ̀lú àjọyọ̀, tí nwọ́n sì kún fún Ẹ̀mí.

15 Àti pẹ̀lú, Álmà mú ẹlòmíràn, ó sì kọjá lọ sínú omi nã lẹ̃kejì, ó sì rĩ bọmi gẹ́gẹ́bí ti ẹni àkọ́kọ́, àfi pé kò ri ara rẹ̀ bọmi mọ́.

16 Gẹ́gẹ́bí àpẹrẹ yí ni ó ṣe ìrìbọmi fun gbogbo ẹni tí ó kọjá lọ sí ibi ti Mọ́mọ́nì; nwọ́n sì pọ̀ tó ọgọ̃rún méjì àti mẹ́rin ènìyàn; bẹ̃ni, a sì rì nwọn bọmi nínú omi Mọ́mọ́nì, nwọ́n sì kún fún õre ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

17 A sì pè nwọ́n ní ìjọ Ọlọ́run tàbí ìjọ Krístì, láti ìgbà nã lọ. Ó sì ṣe, tí ẹnìkẹ́ni tí a bá ti ṣe ìrìbọmi fún nípasẹ̀ agbára àti àṣẹ Ọlọ́run ni a fi kún ìjọ rẹ̀.

18 Ó sì ṣe tí Álmà ẹ̀nití ó ní àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run, yan àwọn àlùfã; àní àlùfã kan fún ãdọ́tà nwọn, ni ó yàn láti wãsù sí nwọn, àti fún kíkọ́ nwọn nípa àwọn ohun ìjọba Ọlọ́run.

19 Ó sì pàṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n máṣe kọ́ ohunkóhun yàtọ̀ sí àwọn ohun èyítí òun ti kọ́, tí a sì ti sọ lati ẹnu àwọn wòlĩ mímọ́.

20 Bẹ̃ni, òun pẹ̀lú pàṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n máṣe wãsù ohun míràn tí ó yàtọ̀ sí ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Olúwa, ẹnití ó ti ra àwọn ènìyàn rẹ̀ padà.

21 Ó sì pàṣẹ fún nwọn pé kí asọ̀ máṣe wà lãrín nwọn, ṣùgbọ́n kí nwọ́n wo iwaju pẹ̀lú ojúkanna, nínú ìgbàgbọ́ kan, ìrìbọmi kan, pẹ̀lú ọkàn kan sí ara nwọn, ní ìṣọ̀kan àti ní ìfẹ́ ọ̀kan sí òmíràn.

22 Báyĩ ni ó sì ṣe pàṣẹ fún nwọn láti wãsù. Báyĩ ni nwọ́n sì di ọmọ Ọlọ́run.

23 Ó sì pàṣẹ fún nwọn pé kí nwọ́n rántí ọjọ́ ìsinmi, kí nwọ́n sì yà á sí mímọ́, àti pẹ̀lú lójojúmọ́, kí nwọ́n máa fi ọpẹ́ fún Olúwa Olọ́run nwọn.

24 Ó sì tún pàṣẹ fún nwọn pé kí àwọn àlùfã tí òun ti yàn máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ nwọn fún ohun ìtọ́jú ara nwọn.

25 Ọjọ́ kan sì wà nínú ọ̀sẹ̀ tí a yà sọ́tọ̀ pé kí nwọ́n kó ara nwọn jọ láti kọ́ àwọn ènìyàn nã, àti láti sin Olúwa Ọlọ́run nwọn, àti pẹ̀lú, nígbà-kũgbà tí ó bá ṣeéṣe fún nwọn, kí nwọ́n péjọ pọ̀.

26 Àwọn àlùfã nã kò sì gbọ́dọ̀ gbójúlé àwọn ènìyàn fún ìrànlọ́wọ́ nwọn; ṣùgbọ́n fún iṣẹ́-ìsìn nwọn, nwọn o rí õre-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run gbà, kí nwọn lè di alágbára nínú Ẹ̀mí, pẹ̀lú ìmọ̀ nwọ́n ní ìmọ̀ nínú Ọlọ́run, kí nwọn kí ó lè kọ́ni pẹ̀lú agbára àti àṣẹ láti ọwọ́ Ọlọ́run.

27 Àti pẹ̀lú, Álmà pàṣẹ pé kí àwọn ènìyàn ìjọ nã fifún ni nínú ohun ìní nwọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí èyítí ó ní; bí ó bá ní ọ̀rọ̀ púpọ̀, kí ó fífúnni púpọ̀; ẹnití ó sì ní díẹ̀, díẹ̀ ni kí ó fifúnni; kí a sì fifún ẹnití ó ṣe aláìní.

28 Báyĩ sì ní kí nwọ́n ṣe fifún ni nínú ohun ìní nwọn, pẹ̀lú ìfẹ́ àtinúwá pẹ̀lú inúrere sí Ọlọ́run, àti sí àwọn àlùfã tí nwọ́n ṣe aláìní, bẹ̃ ni, àti sí gbogbo aláìní, ẹnití ó wà ni ìhòhò.

29 Èyí ni ó sì wí fún nwọn, nítorítí Ọlọ́run ti pã láṣẹ fún un; nwọ́n sì nrìn ní ìdúróṣinṣin níwájú Ọlọ́run, nwọ́n sì nfifún olúkúlùkù ara nwọn, àwọn ohun ti ara àti ohun ti ẹ̀mí, gẹ́gẹ́bí àìní àti àìtó nwọn.

30 Àti nísisìyí, ó sì ṣe tí a ṣe gbogbo nkan wọ̀nyí ní Mọ́mọ́nì, bẹ̃ni, ní ẹ̀gbẹ́ odò Mọ́mọ́nì, nínú igbó èyítí ó wà ní itòsí odò Mọ́mọ́nì; bẹ̃ni, ibi Mọ́mọ́nì, odò Mọ́mọ́nì, igbó Mọ́mọ́nì, báwo ni nwọ́n ṣe lẹ́wà tó ní ojú àwọn tí nwọ́n ní ìmọ̀ Olùràpadà nwọn; bẹ̃ni, báwo sì ni nwọ́n ṣe jẹ́ alábùkún-fún tó, nítorí nwọn yíò máa kọrin ìyìn rẹ̀ títí láé.

31 Àwọn nkan wọ̀nyí ni a sì ṣe ní etí ìpínlẹ̀ nã, kí nwọn má bã di mímọ̀ sí ọba.

32 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, ó sì ṣe tí ọba ṣe àwàrí ìṣípòpadà kan lãrín àwọn ènìyàn nã, ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kí nwọ́n lọ ṣọ́ nwọn. Nítorínã, ní ọjọ́ tí nwọ́n npéjọpọ̀ pé kí nwọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, nwọ́n ṣe àwárí nwọn fún ọba.

33 Àti nísisìyí, ọba sọ wípé Álmà nrú àwọn ènìyàn sókè sí ìṣọ̀tẹ̀ sí òun; nítorínã ó rán àwọn ọmọ ogun rẹ̀ láti pa wọ́n run.

34 Ó sì ṣe tí Álmà àti àwọn ènìyàn Olúwa gbọ́ nípa bíbọ̀ àwọn ọmọ ogun ọba; nítorínã nwọ́n kó àgọ́ nwọn pẹ̀lú ẹbí nwọn, nwọ́n kọjá lọ sínú aginjù.

35 Nwọ́n sì tó ọgọ̃rún mẹ́rin àti ãdọ́ta ènìyàn.