Orí 26
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ọmọ Ìjọ nã ni a darí sínú ẹ̀ṣẹ̀ nípasẹ̀ àwọn aláìgbàgbọ́—Álmà gba ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun—Àwọn tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀, tí a sì rìbọmi gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀–Àwọn ọmọ ìjọ nínú ẹ̀ṣẹ̀, tí nwọ́n bá ronúpìwàdà tí nwọ́n sì jẹ́wọ́-ẹ̀ṣẹ̀ fún Álmà àti fún Olúwa ni a o dáríjì; bíkòṣe bẹ̃, a kì yíò kà nwọ́n mọ́ àwọn ènìyàn Ìjọ nã. Ní ìwọ̀n ọdún 120–100 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Nísisìyí, ó sì ṣe tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ìran tí ó ndìde kò lè ní òye àwọn ọ̀rọ̀ ọba Bẹ́njámínì, nítorítí nwọ́n wà ní kékeré nígbàtí ó bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀; nwọn kò sì gba àṣà àwọn bàbá nwọn gbọ́.
2 Nwọn kò sì gba ohun tí a sọ nípa àjĩnde òkú gbọ́, bẹ̃ni nwọn kò sì gbàgbọ́ nípa bíbọ̀ Krístì.
3 Àti nísisìyí, nítorí àìgbàgbọ́ nwọn, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò yé nwọn; ọkàn nwọn sì sé le.
4 Nwọn kò sì ṣe ìrìbọmi, bẹ̃ni nwọn kò darapọ̀ mọ́ ìjọ. Nwọ́n sì jẹ́ ènìyàn ìyàsọ́tọ̀ nítorí ìgbàgbọ́ ọ nwọn, nwọ́n sì rí báyĩ títí, àní nínú ipò àìpé àti ẹ̀ṣẹ̀ nwọn; nítorítí nwọn kò ní ké pe Olúwa Ọlọ́run nwọn.
5 Àti nísisìyí, ní àkokò ìjọba Mòsíà, nwọ́n kò pọ̀ tó ìdajì àwọn ènìyàn Ọlọ́run; ṣùgbọ́n nítorí ìyàpa lãrín àwọn arákùnrin wọn, nwọn pọ̀ síi.
6 Nítorí ó ṣe, tí nwọ́n tan ọ̀pọ̀lọpọ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn, àwọn tí nwọ́n wà nínú ìjọ, tí nwọ́n sì mú nwọn dẹ́ṣẹ̀ púpọ̀púpọ̀; nítorínã ó di ohun tí ó tọ́ pé kí àwọn tí nwọ́n ti dẹ́ṣẹ̀, tí nwọ́n sì wà nínú ìjọ, gba ìbáwí láti ọwọ́ ìjọ.
7 Ó sì ṣe tí a mú nwọn wá síwájú àwọn àlùfã, tí àwọn olùkọ́ni sì fi nwọ́n lé ọwọ́ àwọn àlùfã; àwọn àlùfã sì mú nwọn wá síwájú Álmà, ẹnití íṣe olórí àlùfã.
8 Nísisìyí, ọba Mòsíà ti fún Álmà ní àṣẹ lórí ìjọ-Ọlọ́run.
9 Ó sì ṣe tí Álmà kò mọ́ ohunkóhun nípa nwọn; ṣùgbọ́n àwọn ẹlẹ́rĩ wá sí nwọn; bẹ̃ni, àwọn ènìyàn nã dúró nwọ́n sì jẹ̃rí sí gbogbo àìṣedẽdé nwọn lọ́pọ̀lọpọ̀.
10 Nísisìyí, kò sí irú ìṣẹ̀lẹ̀ báyĩ tí ó ṣẹlẹ̀ rí nínú ìjọ; nítorínã, ọkàn Álmà dàrú nínú rẹ̀, ó sì ní kí nwọ́n mú nwọn wá síwájú ọba.
11 Ó sì wí fún ọba pé: Kíyèsĩ, àwọn wọ̀nyí ni àwa mú wá síwájú rẹ, tí àwọn arákùnrin nwọn ti fẹ̀sùnkàn nwọ́n; bẹ̃ni, nwọ́n sì ti mú nwọn nínú onírurú ìwà àìṣedẽdé. Nwọn kò sì ronúpìwàdà àìṣedẽdé nwọn; nítorínã ni àwa ṣe mú nwọn tọ̀ ọ́ wá, kí ìwọ kí ó lè ṣe ìdájọ́ nwọn gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ nwọn.
12 Ṣùgbọ́n ọba Mòsíà wí fún Álmà pé: Kíyèsĩ, èmi kò ní ṣe ìdájọ́ nwọn; nítorínã, èmi fi nwọ́n lé ọ lọ́wọ́ fún ìdájọ́.
13 Àti nísisìyí ọkàn Álmà tún dàrú nínú rẹ̀; ó sì lọ bẽrè lọ́wọ́ Olúwa nípa ohun tí òun yíò ṣe nípa ọ̀rọ̀ yí, nítorítí ó bẹ̀rù fún ṣíṣe ohun tí ó kùnà níwájú Olúwa.
14 Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí ó ti tú gbogbo ọkàn rẹ̀ jáde sí Ọlọ́run, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ̀ ọ́ wá, wípé:
15 Alábùkún-fún ni ìwọ, Álmà, alábùkún-fún sì ni àwọn tí a rìbọmi nínú omi Mọ́mọ́nì. Ìwọ jẹ́ alábùkún-fún nítorí títóbi ìgbàgbọ́ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ ìránṣẹ́ mi Ábínádì nìkanṣoṣo.
16 Alábùkún-fún sì ni nwọ́n nítorí títóbi ìgbàgbọ́ nwọn nínú ọ̀rọ̀ èyítí ìwọ ti sọ fún nwọn nìkanṣoṣo.
17 Alábùkún-fún sì ni ìwọ nítorí ìwọ ti ṣe ìdásílẹ̀ ìjọ-Ọlọ́run lãrín àwọn ènìyàn yí; a ó sì fi ìdí nwọn múlẹ̀, nwọn yíò sì jẹ́ ènìyàn mi.
18 Bẹ̃ni, alábùkún-fún ni àwọn ènìyàn yí tí nwọ́n ní ìfẹ́ sí jíjẹ́ orúkọ mi; nítorítí nínú orúkọ mi ni a o pè nwọ́n; tèmi sì ni nwọ́n íṣe.
19 Àti nítorípé ìwọ ti wádĩ lọ́wọ́ mi nípa olùrékọjá nnì, alábùkún-fún ni ìwọ.
20 Ìránṣẹ́ mi ni ìwọ íṣe; èmi sì bá ọ dá májẹ̀mú wípé ìwọ yíò ní ìyè àìnípẹ̀kun; ìwọ yíò sì sìn mí, ìwọ yíò sì jáde lọ ní orúkọ mi, ìwọ yíò sì gbá àwọn àgùtàn mi jọ.
21 Ẹnití ó bá gbọ́ ohùn mi ni yíò jẹ́ àgùtàn mi; òun ni ìwọ yíò sì gbà sínú ìjọ nã, òun nã ni èmi yíò sì gbà.
22 Nítorí kíyèsĩ, èyí ni ìjọ mi; ẹníkẹ́ni tí a bá ti rìbọmi ni a ó rìbọmi sí ìrònúpìwàdà. Ẹnìkẹ́ni tí ẹ̀yin bá sì gbà ni yíò gba orúkọ mi gbọ́; òun sì ní èmi yíò dáríjì ní ọ̀fẹ́.
23 Nítorípé èmi ni ẹni nã tí ó gbé ẹ̀ṣẹ̀ ayé rù ara mi; nítorípé èmi ni ẹni nã tí ó dá nwọn; èmi sì ni ẹni nã tí ó fifún ẹnití ó bá gbàgbọ́ dé òpin, ãyè ní apá ọ̀tún mi.
24 Nítorí kíyèsĩ, ní orúkọ mi ni a pè nwọ́n; tí nwọ́n bá sì mọ̀ mí, nwọn yíò jáde wá, nwọn yíò sì ní ãyè ayérayé ní apá ọ̀tún mi.
25 Yíò sì ṣe nígbàtí ìpè ìkejì yíò dún nígbànã ni àwọn tí nwọn kò mọ̀ mí rí yíò jáde wá, tí nwọn yíò sì dúró níwájú mi.
26 Nígbànã ni nwọn yíò sì mọ̀ wípé èmi ni Olúwa Ọlọ́run nwọn, pé èmi ni Olùràpadà nwọn; ṣùgbọ́n a kì yíò rà nwọ́n padà.
27 Nígbànã ni èmi yíò sì jẹ́wọ́ fún nwọn pé èmi kò mọ̀ nwọ́n rí; nwọn yíò sì kọjá sínú iná àìnípẹ̀kun èyítí a pèsè sílẹ̀ fún èṣù àti àwọn ángẹ́lì rẹ̀.
28 Nítorínã, mo wí fún yín, wípé ẹnití kò bá gbọ́ ohùn mi, òun ni ẹ̀yin kì yíò gbà sínú ìjọ mi, òun sì ni èmi kì yíò gbà ní ọjọ́ ìkẹhìn.
29 Nítorínã mo wí fún ọ, Lọ; ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì ré mi kọjá, òun ni ìwọ́ yíò ṣe ìdájọ́ fún gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ tí òun ti ṣẹ̀; tí ó bá sì jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ níwájú rẹ àti èmi, tí ó sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ tọkàn-tọkàn, òun ni ìwọ yíò dáríjì, èmi yíò sì dáríjĩ pẹ̀lú.
30 Bẹ̃ni, ní gbogbo ìgbà tí àwọn ènìyàn mi bá ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ ní èmi yíò dárí gbogbo ìrékọjá nwọn sí mi jì nwọ́n.
31 Ẹ̀yin nã pẹ̀lú yíò dárí àwọn ìrékọjá ji ara yín; nítorí lõótọ́ ni mo wí fún yín, ẹnití kò bá dárí ẹ̀ṣẹ̀ ji ọmọnìkejì rẹ̀ nígbàtí ó bá sọ wípé òun ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀, olúwarẹ̀ ti mú ara rẹ̀ wá sí ìdálẹ́bi.
32 Nísisìyí, mo wí fún ọ, Lọ; ẹnìkẹ́ni ti kò bá sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ, òun kannã ni a kì yíò kà mọ́ àwọn ènìyàn mi; èyí ni a ó sì kíyèsí láti ìsisìyí lọ.
33 Ó sì ṣe, nígbàtí Álmà ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó kọ nwọ́n sílẹ̀, kí òun lè ní nwọn, àti pẹ̀lú kí ó lè ṣe ìdájọ́ àwọn ènìyàn ìjọ nã gẹ́gẹ́bí òfin Ọlọ́run.
34 Ó sì ṣe tí Álmà lọ tí ó sì ṣe ìdájọ́ àwọn tí a ti mú nínú àìṣedẽdé, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Oluwa.
35 Ẹnìkẹ́ni tí ó bá sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó sì jẹ́wọ́ nwọn, àwọn ni ó kà mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ nã;
36 Àwọn tí nwọn kò bá sì jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn kí nwọ́n sì ronúpìwàdà àìṣedẽdé nwọn, àwọn kannã ni a kò kà mọ́ àwọn ènìyàn ìjọ nã, a sì pa orúkọ nwọn rẹ́.
37 Ó sì ṣe tí Álmà to gbogbo ìṣe ìjọ lẹ́sẹ̃sẹ; nwọ́n sì tún bẹ̀rẹ̀sí ní àlãfíà, nwọ́n sì nṣe rere lọ́pọ̀lọpọ̀ lórí ìṣe ìjọ nã, nwọ́n nrìn pẹ̀lú ìkíyèsára níwájú Ọlọ́run, nwọ́n ngba ọ̀pọ̀lọpọ̀, nwọ́n sì ri ọ̀pọ̀lọpọ̀ bọmi.
38 Àti nísisìyí, gbogbo ohun wọ̀nyí ni Álmà pẹ̀lú àwọn olùjọ-ṣiṣẹ́ rẹ̀ ṣe, tí nwọ́n wà lórí ìjọ nã, tí nwọn nrìn ní ọ̀nà ẹ̀tọ́, tí nwọn nkọ́ni lọ́rọ̀ Ọlọ́run nínú ohun gbogbo, tí nwọn nfarada onírurú ìpọ́njú, tí àwọn tí nwọn kì íṣe ara ìjọ Ọlọ́run nṣe inúnibíni sí nwọn.
39 Nwọ́n sì bá àwọn arákùnrin nwọn wí; gbogbo nwọn sì gba ìbáwí, olúkúlùkù nípa ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gẹ́gẹ́bí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tàbí bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ èyítí òun ṣẹ̀, tí Ọlọ́run sì ti pã láṣẹ fún nwọn kí nwọ́n gbàdúrà láìsinmi, kí nwọn sì máa dúpẹ́ nínú ohun gbogbo.