Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 27


Orí 27

Mòsíà fi òfin de inúnibíni òun sì pàṣẹ fún ìbamu lọ́gbọ̃gba—Álmà kékeré pẹ̀lú mẹ́rin nínú àwọn ọmọ Mòsíà lépa láti pa ìjọ nã run—Ángẹ́lì kan farahàn nwọ́n ó sì pa á láṣẹ kí nwọ́n dẹ́kun ibi ṣíṣe—Álmà ya odi—Gbogbo ènìyàn ni ó níláti di àtúnbí láti gba ìgbàlà—Álmà pẹ̀lú àwọn ọmọ Mòsíà nkede ìhìn ayọ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 100 sí 92 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí inúnibíni tí àwọn aláìgbàgbọ́ gbé ti ìjọ pọ̀ púpọ̀ tó bẹ̃ tí ìjọ bẹ̀rẹ̀sí kùn, tí nwọ́n sì nráhùn sí àwọn olórí nwọn nípa ọ̀rọ̀ nã; nwọ́n sì fi ọ̀rọ̀ nã sun Álmà. Álmà sì gbé ọ̀rọ̀ nã síwájú ọba nwọn, Mòsíà. Mòsíà sì fi ọ̀rọ̀ nã lọ àwọn àlùfã rẹ̀.

2 Ó sì ṣe tí Mòsíà ọba fi ìkéde ránṣẹ́ jákè-jádò ilẹ̀ nã pẹ̀lú gbogbo agbègbè rẹ̀, pé aláìgbàgbọ́ kankan kò gbọ́dọ̀ ṣe inúnibíni sí ẹnìkẹ́ni tí ó wà nínú ìjọ Ọlọ́run.

3 Àṣẹ tí ó múná sì wà jákè-jádò àwọn ìjọ pé kí inúnibíni kí ó máṣe wà lãrín nwọn, àti pé kí ìbámu lọ́gbọ̃gba wà lãrín gbogbo ènìyàn;

4 Pé kí nwọ́n máṣe jẹ́ kí ìgbéraga tàbí ìrera dí àlãfíà a nwọn lọ́wọ́; pé kí olúkúlùkù ka ọmọnìkejì rẹ̀ sí ara rẹ̀, kí nwọ́n sì máa ṣe iṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ ara nwọn fún ìpèsèfún ara nwọn.

5 Bẹ̃ni, kí gbogbo àwọn àlùfã àti àwọn olùkọ́ nwọn ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọwọ́ nwọn fún ìpèsè fún ara nwọn, ní gbogbo ìgbà àfi nínú àìlera, tàbí nínú àìní; lẹ́hìn tí wọ́n sì ti ṣe ohun wọ̀nyí, nwọn pọ̀ púpọ̀ nínú õre-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run.

6 Àláfíà púpọ̀ sì bẹ̀rẹ̀sí padà sórí ilẹ̀ nã; àwọn ènìyàn nã sì bẹ̀rẹ̀sí pọ̀ púpọ̀, nwọ́n sì ngbilẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé, bẹ̃ni, ní àríwá àti ní gúsù, ní ìlà-oòrùn, àti ní ìwọ̀-oòrùn, nwọ́n sì nkọ́ àwọn ìlú nlá-nlá pẹ̀lú ìletò ní gbogbo ẹ̀kún ìlú nã.

7 Olúwa sì bẹ̀ nwọ́n wò, ó sì ṣe rere fún nwọn, nwọ́n sì di ọ̀pọ̀ àti ọlọ́rọ̀ ènìyàn.

8 Nísisìyí, a ka àwọn ọmọkùnrin Mòsíà mọ́ àwọn aláìgbàgbọ́; àti pẹ̀lú, a ka ọ̀kan nínú àwọn ọmọ Álmà mọ́ nwọn, ẹnití à npe orúkọ rẹ̀ ní Álmà èyí tí íṣe ti bàbá rẹ̀, bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó ya ènìyàn búburú àti abọ̀rìṣà. Ẹnú rẹ̀ si dùn, ó sì nsọ ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn púpọ̀púpọ̀ fún àwọn ènìyàn; nítorínã ó darí ọpọlọpọ ninu àwọn ènìyàn nã lati ṣe àìṣedẽdé bí tirẹ̀.

9 Ó sì jẹ́ ìfàsẹ́hìn nlá sí ìlọsíwájú ìjọ Ọlọ́run; tí ó sì darí ọkàn àwọn ènìyàn lọ; tí ó sì jẹ́ kí ìyapa nlá wà lãrín àwọn ènìyàn nã; tí ãyè sì ṣí sílẹ̀ fún ọ̀tá Ọlọ́run láti lo agbára rẹ̀ lórí nwọn.

10 Àti nísisìyí, ó sì ṣe, nígbàtí ó nlọ kãkiri fún ìparun ìjọ Ọlọ́run, nítorítí ó nlọ kãkiri ní ìkọ̀kọ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ Mòsíà, tí o sì nwá láti pa ìjọ nã run, àti fún ìṣìlọ́nà àwọn ènìyàn Olúwa, ní ìlòdì sí àṣẹ́ Ọlọ́run, tàbí ti ọba pãpã—

11 Gẹ́gẹ́bí èmi sì ti wí fún nyín, bí nwọ́n ṣe nlọ kãkiri tí nwọ́n nṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, kíyèsĩ, ángẹ́lì Olúwa yọ sí nwọn; ó sì sọ̀kalẹ̀ bí ẹnipé ó wà nínú àwọ̀-sánmà; ó sì sọ̀rọ̀ gẹ́gẹ́bí ohùn àrá tí ó nsán, tí ó mú kí ilẹ̀ tí nwọ́n dúró le mi títí;

12 Ẹnu si yà nwọ́n púpọ̀púpọ̀, tí nwọ́n ṣubú lulẹ̀, ọ̀rọ̀ tí ó nbá nwọn sọ kò sì yé nwọn.

13 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ó tún kígbe, ó ní: Álmà; dìde, kí ó sì bọ́ síwájú, nítorí ìdí wo ni ìwọ fi nṣe inúnibíni sí ìjọ Ọlọ́run? Nítorítí Ọlọ́run ti sọ wípé: Èyí yĩ ni ìjọ mi, èmi yíò sì dã sílẹ̀; kò sì sí ohun tí yíò bĩ ṣubú, bíkòbájẹ́ ìwà ìrékọjá àwọn ènìyàn mi.

14 Àti pẹ̀lú, ángẹ́lì nã sọ wípé: Kíyèsĩ, Olúwa ti gbọ́ àdúrà àwọn ènìyàn rẹ̀, àti àdúrà ìránṣẹ́ rẹ̀, Álmà, ẹnití ìṣe bàbá rẹ; nítorítí ó ti gbàdúrà pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́ nípa rẹ, pé kí a lè mu ọ wá sínú ìmọ̀ òtítọ́ nnì; nítorínã, nítorí ìdí èyí ni èmi wá láti lè fún ọ ní ìdánilójú nípa agbára àti àṣẹ Ọlọ́run, kí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lè jẹ́ gbígbà gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ nwọn.

15 Àti nísisìyí, kíyèsĩ, njẹ́ ìwọ lè jiyàn agbára Ọlọ́run? Nìtorí kíyèsĩ, njẹ́ ohùn mi kò mi ayé? Njẹ́ ìwọ kò tilẹ̀ rí mi níwájú rẹ̀? A sì rán mi láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.

16 Nísisìyí mo wí fún ọ: Lọ, kí ó sì rántí ìgbèkun àwọn bàbá rẹ̀ ní ilẹ̀ Hẹ́lámì; àti ní ilẹ̀ Nífáì; kí ó sì rántí àwọn ohun nlá tí ó ti ṣe fún nwọn; nítorítí nwọ́n wà nínú oko-ẹrú, ó sì kó nwọn yọ. Àti nísisìyí, èmi wí fún ọ, Álmà, máa bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, kí ó sì dẹ́kun lílépa ìparun ìjọ nã, kí àdúrà nwọn lè gbà bí ìwọ yíò bá tilẹ̀ pa ara rẹ̀ run.

17 Àti nísisìyí, ó sì ṣe pé àwọn ohun wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ ìkẹhìn tí ángẹ́lì nã sọ fún Álmà, tí ó sì bá tirẹ̀ lọ.

18 Àti nísisìyí, Álmà pẹ̀lú àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tún ṣubú lulẹ̀, nítorí títóbi ni ìyanu nwọn; nítorípé, pẹ̀lú ojú ara nwọn ni nwọ́n rí ángẹ́lì Olúwa; ohùn rẹ̀ sì dàbí àrá, èyítí ó mi ilẹ̀; nwọ́n sì mọ̀ wípé kò sí ohun míràn bíkòṣe agbára Ọlọ́run tí ó lè mi ilẹ̀ tí yíò sì gbọ̀n tìtì bí èyítí yíò là sí méjì.

19 Àti nísisìyí ìyàlẹ́nu Álmà pọ̀ tóbẹ̃ gẹ̃ tí ó fi yadi, tí kò sì lè la ẹnu rẹ̀; bẹ̃ni, ó sì di aláìlágbára tó bẹ̃ tí kò lè gbé ọwọ́ rẹ̀; nítorínã àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ gbé e, nwọ́n sì gbé e láì le ran ara rẹ lọ́wọ́, àní títí nwọ́n fi tẹ́ ẹ sí iwájú bàbá rẹ̀.

20 Nwọ́n sì sọ gbogbo ohun tí ó ti ṣẹlẹ̀ sí nwọn fún bàbá rẹ̀; bàbá rẹ̀ sì yọ̀, nítorí ó mọ̀ wípé agbára Ọlọ́run ni.

21 Ó sì mú kí àwọn ènìyàn péjọ, kí nwọ́n lè jẹ́ ẹ̀rí sí ohun tí Olúwa ti ṣe fún ọmọ rẹ̀, àti pẹ̀lú fún àwọn tí nwọn wà pẹ̀lú rẹ̀.

22 Ó sì mú kí àwọn àlùfã péjọ pọ̀; nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gba ãwẹ̀, àti gbàdúrà sí Olúwa Ọlọ́run nwọn, pé kí ó la ẹnu Álmà, kí ó lè sọ̀rọ̀, àti kí ẹ̀yà ara rẹ̀ lè gba okun—kí ojú àwọn ènìyàn lè là, kí nwọ́n lè ri àti kí nwọ́n sì mọ̀ nípa dídára àti ògo Ọlọ́run.

23 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí nwọ́n ti gba ãwẹ̀, tí nwọ́n sì ti gbàdúrà fún ìwọ̀n ọjọ́ méjì àti òru méjì, ẹ̀yà-ara Álmà gba okun padà, ó sì dìde dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀sí ọ̀rọ̀ sísọ sí nwọn, pé kí nwọ́n tújúká:

24 Nítorítí, ó wípé, mo ti ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi, a sì ti rà mí padà nípa ti Olúwa; ẹ kíyèsĩ, a ti bí mi nípa ti Ẹ̀mí.

25 Olúwa sì wí fún mi pé: Máṣe jẹ́ kí ó yà ọ́ lẹ́nu pé gbogbo ènìyàn, bẹ̃ni, ọkùnrin àti obìnrin, gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè àti ènìyàn, níláti di àtúnbí; bẹ̃ni, kí a bí nwọn nípa ti Ọlọ́run, kí a yí nwọn padà kúrò ní ipò ara àti ìsubu tí nwọ́n wà, sí ipò ìwà-òdodo, nítorítí a ti rà nwọ́n padà nípa ti Ọlọ́run, tí nwọ́n sì di ọmọ rẹ̀ ọkùnrin àti obìnrin;

26 Báyĩ sì ni nwọ́n di ẹ̀dá titun; láì sì ṣe èyí, kò sí ọ̀nà tí nwọn yíò fi jogún ìjọba Ọlọ́run.

27 Mo wí fún nyín, bí kò bá rí báyĩ, a o gbé nwọn sọnù; mo sì mọ́ èyí, nítorípé díẹ̀ ni ó kù kí a gbé mi sọnù.

28 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn tí èmi ti la ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú kọjá, tí èmi sì ronúpìwàdà dé ẹnu ikú, Olúwa nínú ãnú ríi pé ó tọ́ kí òun kí ó gbà mí kúrò lọ́wọ́ jíjóná ayérayé, a sì bí mi nípa ti Ọlọ́run.

29 A ti ra ẹ̀mí mi padà kúrò lọ́wọ́ òrõró ìkorò, àti ìdè àìṣedẽdé. Mo wà nínú ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ èyítí ó ṣókùnkùn jùlọ; ṣùgbọ́n nísisìyí, mo rí ìmọ́lẹ̀ Ọlọ́run èyítí ó yani lẹ́nu. Oró ayérayé gba ọkàn mi; ṣùgbọ́n a já mi gbà, kò sì sí ìrora fún ọkàn mi mọ́.

30 Mo kọ Olùràpadà mi, mo sì sẹ́ èyí tí àwọn bàbá wa ti sọ nípa rẹ̀; ṣùgbọ́n nísisìyí, kí nwọn lè ríi pé ó nbọ̀wá, àti pé ó ṣe ìrántí gbogbo ẹ̀dá ọwọ́ rẹ̀, òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí ènìyàn gbogbo.

31 Bẹ̃ni, gbogbo ẽkún yíò wólẹ̀, gbogbo ahọ́n ni yíò sì jẹ́wọ́ níwájú rẹ̀. Bẹ̃ni, àní ní ọjọ́ ìkẹhìn, nígbàtí gbogbo ènìyàn yíò dúró kí òun lè ṣe ìdájọ́ nwọn, nígbànã ni nwọn yíò jẹ́wọ́ pé òun ni Ọlọ́run; nígbànã ni nwọn yíò jẹ́wọ́, àwọn tí nwọn ngbé ilé ayé ní àìní Ọlọ́run, pé ìdájọ́ ìyà títí ayé lórí nwọn jẹ́ èyítí ó tọ́; nwọn yíò sì gbọ̀n, nwọn yíò sì wárìrì, nwọn yíò sì súnrakì lábẹ́ ìwo ojú rẹ̀ tí ó nwò ohun gbogbo.

32 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí Álmà bẹ̀rẹ̀ láti àkokò yí lọ láti máa ṣe ìkọ́ni àwọn ènìyàn nã, àwọn tí nwọ́n sì wà pẹ̀lú Álmà nígbàtí ángẹ́lì farahàn nwọ́n, tí nwọ́n sì nṣe ìrìnàjò kãkiri nínú gbogbo ilẹ̀ nã, tí nwọ́n nkéde fún gbogbo àwọn ènìyàn nã, àwọn ohun tí nwọ́n ti gbọ́ àti èyí tí nwọ́n rí, tí nwọ́n sì nwãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nínú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú, nítorítí àwọn aláìgbàgbọ́ nṣe inúnibíni sí nwọn lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn sì nkọlù nwọ́n.

33 Ṣùgbọ́n láì ka gbogbo ohun wọ̀nyí sí, nwọ́n tu àwọn ènìyàn ìjọ-Ọlọ́run nínú púpọ̀púpọ̀, nwọ́n sì ntì nwọ́n lẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́ nwọn, tí nwọ́n sì ngbà nwọ́n níyànjú pẹ̀lú ìpamọ́ra, àti ọ̀pọ̀ lãlã láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́.

34 Mẹ́rin nínú nwọn ni ísì ṣe àwọn ọmọ Mòsíà; orúkọ nwọn sì ni Ámọ́nì, àti Áárọ́nì, Òmnérì, àti Hímnì; èyí ni orúkọ àwọn ọmọ Mòsíà.

35 Nwọ́n sì rin ìrìnàjò jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, àti lãrín àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà lábẹ́ ìjọba ọba Mòsíà, tí nwọ́n sì nfi tọkàn-tara lépa láti ṣe àtúnṣe àwọn ohun búburú tí nwọ́n ti ṣe sí ìjọ, tí nwọ́n sì njẹ́wọ́ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, tí nwọ́n nkéde gbogbo ohun tí nwọ́n ti rí, tí nwọ́n sì nṣe àlàyé àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ pẹ̀lú ìwé-mímọ́ sí gbogbo ẹnití ó fẹ́ láti gbọ́ nwọn.

36 Báyĩ ni nwọ́n sì ṣe jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ Ọlọ́run, fún mímú ọ̀pọ̀lọpọ̀ wá sí ìmọ̀ òtítọ́, bẹ̃ni, sí ìmọ̀ Olùràpadà nwọn.

37 Báwo sì ni nwọ́n ṣe jẹ́ alábùkún-fún tó! Nítorítí nwọn kéde àlãfíà; nwọ́n sì kéde ìhìn-rere ohun rere; nwọ́n sì wí fún àwọn ènìyàn nã pé Olúwa jọba.