Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 3


Orí 3

Ọba Bẹ́njámínì tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀—Olúwa Alèwílèṣe yíò ṣiṣẹ́ lãrín àwọn ènìyàn nínú àgọ́-ara erùpẹ̀—Ẹ̀jẹ̀ yíò jáde nínú gbogbo ojú ìlãgùn ara rẹ̀ bí ó ṣe nṣètùtù fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ayé—Orúkọ tirẹ̀ nìkan ni ipa èyítí ìgbàlà ńwá—Ènìyàn lè bọ́ ìwà ti ara sílẹ̀, kí nwọ́n sì di Àwọn Ènìyàn Mímọ́ nípasẹ̀ Ètùtù nã—Ìdálóró ẹlẹ́ṣẹ̀ yíò dàbĩ adágún iná àti imí ọjọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 124 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ẹ̀wẹ̀ ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi fẹ́ kí ẹ farabalẹ̀, nítorítí mo ní ohun tí ó kù láti bá yín sọ; nítorí ẹ kíyèsĩ, mo ní ohun látí bá nyín sọ nípa èyítí ó nbọ̀wá.

2 Àwọn ohun tí èmi yíò sọ fún yín sì jẹ́ mímọ̀ fún mi nípasẹ̀ ángẹ́lì kan láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Ó sì wí fún mi pé: Jí; èmi sì jí, sì wò o ó dúró níwájú mi.

3 Ó sì wí fún mi pé: Jí, kí o sì gbọ́ ọ̀rọ̀ tí èmi yíò sọ fún ọ; nítorí kíyèsĩ, èmi wá láti kéde ìròyìn ayọ̀ nlá nã fún ọ.

4 Nítorítí Olúwa ti gbọ́ àdúrà rẹ, ó sì ti ṣe ìdájọ́ òdodo rẹ, ó sì ti rán mi láti kéde fún ọ kí ìwọ kí ó lè yọ̀; kí o sì lè kéde fún àwọn ènìyàn rẹ, kí àwọn nã lè kún fún ayọ̀ pẹ̀lú.

5 Nítorí kíyèsĩ, àkokò nã yíò de, kò sì jìnà rárá, pé, pẹ̀lú agbára, Olúwa Alèwílèṣe, ẹnití ó jọba, tí ó ti wà, tí ó sì wà láti ayérayé dé ayérayé, yíò sọ̀kalẹ̀ wá láti ọ̀run sí ãrin àwọn ọmọ ènìyàn, yíò sì gbé nínú àgọ́-ara erùpẹ̀, yíò sì jáde lọ lãrín àwọn ènìyàn, yíò sì ṣiṣẹ́ ìyanu nlá, àwọn bĩ ìwòsàn aláìsàn, jíjí òkú dìde, mímú arọ rìn, afọ́jú kí ó ríran, àti odi kí ó gbọ́ràn, àti wíwo onírũrú àrùn.

6 Òun yíò sì lé àwọn èṣù jáde tàbí àwọn ẹ̀mí ibi tí ngbé inú ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn.

7 Ẹ sì wõ, yíò sì faradà àdánwò, àti ìrora ara, ebi, òùngbẹ, àti ãrẹ̀, pãpã ju èyítí ènìyàn lè faradà, àfi tí yíò jẹ́ sí ipa ikú; nítorí kíyèsĩ, ẹ̀jẹ̀ sun jáde láti inú gbogbo ojú ìlãgún ara rẹ̀, títóbi sì ni àròkàn rẹ̀ fún ìwà búburú àti àwọn ohun ìríra àwọn ènìyàn rẹ̀ yíò jẹ́.

8 A ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, Bàbá ọ̀run òun ayé, Ẹlẹ́dã ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀; a ó sì pe orúkọ ìyá rẹ̀ ní Màríà.

9 Ẹ sì wõ, ó wá láti wá bá àwọn tirẹ̀, kí ìgbàlà lè wá sọ́dọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn, àní nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; àti pãpã lẹ́hìn gbogbo eleyĩ nwọn yíò kã sí ènìyàn, nwọn ó sì sọ wípé ó ní èṣù, nwọn yíò sì nã, nwọn yíò sì kàn án mọ́ àgbélèbú.

10 Òun yíò sì dìde ní ọjọ́ kẹ́ta láti inú òkú; sì kíyèsĩ, ó dúró láti ṣe ìdájọ́ ayé; sì kíyèsĩ, a ṣe ohun gbogbo kí ìdájọ́ òdodo lè wá sórí àwọn ọmọ ènìyàn.

11 Nítorí kíyèsĩ, ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ pẹ̀lú ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí nwọ́n ti ṣubú nípasẹ̀ ìwàìrékọjá Ádámù, tí nwọ́n ti kú láìmọ ìfẹ́ Ọlọ́run nípa nwọn, tàbí tí nwọ́n ti ṣẹ̀ nínú àìmọ̀.

12 Ṣùgbọ́n ègbé, ègbé ni fún ẹni tí ó mọ̀ wípé ó ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run! Nítorítí ìgbàlà kò sí fún irú ẹni bẹ̃ àfi nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú Jésù Krístì Olúwa.

13 Olúwa Ọlọ́run sì ti rán àwọn wòlĩ mímọ́ rẹ̀ sí ãrin gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn, láti kéde àwọn nkan wọ̀nyí sí gbogbo ìbátan, orílẹ̀-èdè, àti ahọ́n, pé nípa báyĩ ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàgbọ́ pé Krístì nbọ̀, irú ẹni bẹ̃ lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, kí nwọn ó sì yọ̀ pẹ̀lú ayọ̀ nlá, tí yíò sì dà bí ẹni pé ó ti dé sí ãrín nwọn.

14 Síbẹ̀ Olúwa Ọlọ́run ríi pé àwọn ènìyàn rẹ̀ jẹ́ ọlọ́rùn líle ènìyàn, ó sì gbé òfin kan kalẹ̀ fún nwọn, àní òfin Mósè.

15 Àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ àmì, iṣẹ́ ìyanu, oríṣiríṣi, àti òjìji, ni ó sì fi hàn nwọ́n, nípa bíbọ̀ rẹ̀; àwọn wòlĩ mímọ́ nã sì bá nwọn sọ̀rọ̀ nípa bíbọ̀ rẹ̀; síbẹ̀síbẹ̀, nwọn sé ọkàn nwọn le, kò sì yé nwọn wípé òfin Mósè kò já mọ́ nkankan àfi nípasẹ̀ ètùtù ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.

16 Àti bí ó bá sì ṣeéṣe pé kí àwọn ọmọdé lè dẹ́ṣẹ̀, a kò lè gbà nwọ́n là; ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín, alábùkún-fún ni nwọ́n; nítorí kíyèsĩ, gẹ́gẹ́bí ti Ádámù, tàbí ti ara, nwọ́n ṣubú, síbẹ̀síbẹ̀, ẹ̀jẹ̀ Krístì ṣe ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ nwọn.

17 Àti pẹ̀lú, mo wí fún nyín, pé kì yíò sí orúkọ míràn tí a fún ni, tàbí ọ̀nà míràn, tàbí ipa èyítí ìgbàlà lè wá fún àwọn ọmọ ènìyàn, àfi nínú àti nípasẹ̀ orúkọ Krístì, Olúwa Alèwílèṣe.

18 Nítorí kĩyesi, ó nṣe ìdájọ́, ìdájọ́ rẹ̀ sì jẹ́ èyítí ó tọ́; ọmọ-ọwọ́ kò sì lè parun èyítí ó kú ní kékeré; ṣùgbọ́n ènìyàn nmu ègbé sórí ẹ̀mí ara nwọn, bíkòṣepé nwọ́n bá rẹ ara nwọn sílẹ̀, tí nwọ́n sì dàbí ọmọdé, tí nwọ́n sì gbàgbọ́ pé ìgbàlà ti wà rí, ó sì wà, ó sì mbọ̀ wá, nínú àti nípasẹ̀ ẹ̀jẹ̀ ètùtù Krístì, Olúwa Alèwílèṣe.

19 Nítorítí ènìà ẹlẹ́ran ara jẹ ọ̀tá Ọlọ́run, ó sì ti wà bẹ̃ láti ìgbà ìṣubú Ádámù, yíò sì wà bẹ̃ títí láéláé, bíkòṣepé ó jọ̀wọ́ ara rẹ̀ sílẹ̀ fún ònfà Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbé ìwà ti ara sílẹ̀, tí ó sì di ènìyàn mímọ́ nípasẹ̀ ètùtù Krístì Olúwa, tí ó sì dà bí ọmọdé, onítẹríba, oníwá-tútù, onírẹ̀lẹ̀, onísũrù, kíkún fún ìfẹ́, tí ó fẹ́ láti jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún ohun gbogbo èyítí Olúwa ríi pé ó tọ́ láti fi bẹ̃ wò, àní gẹ́gẹ́bí ọmọdé ṣe jọ̀wọ́ ara rẹ̀ fún bàbá rẹ̀.

20 Àti pẹ̀lú, mo wí fún nyín, pé àkokò nã yíò dé ti ìmọ̀ nípa Olùgbàlà kan yíò tàn ká gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, ahọ́n, àti ènìyàn.

21 Ẹ kíyèsĩ, nígbàtí àkokò nã bá dé, kò sí ẹnití yíò wà ní àìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run, àfi ti nwọ́n bá jẹ́ àwọn ọmọdé, nípasẹ̀ ìrònúpìwàdà àti ìgbàgbọ́ nínú orúkọ Olúwa Ọlọ́run Alèwílèṣe.

22 Àti ní àkokò yĩ pãpã, nígbàtí ìwọ yíò ti kọ́ àwọn ènìyàn rẹ ni ohun tí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pa láṣẹ fún ọ, àní nígbànã ni nwọn kò ní jẹ́ aláìlẹ́bi níwájú Ọlọ́run, àfi gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ èyítí èmi ti bá ọ sọ.

23 Àti nísisìyí èmi ti sọ awọn ọ̀rọ̀ èyítí Olúwa Ọlọ́run ti pa láṣẹ fún mi.

24 Báyĩ sì ni Olúwa wí: Nwọn yíò dúró gẹ́gẹ́bí ẹ̀rí tí ó mọ́lẹ̀ sí àwọn ènìyàn yí, ní ọjọ́ ìdájọ́; nípa èyítí a ó ṣe ìdájọ́ nwọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀, ìbã jẹ́ dáradára, tàbí búburú.

25 Bí nwọ́n bá sì jẹ́ búburú, a o là nwọn lójú kí nwọn lè rí ẹ̀ṣẹ̀ àti ìwà ìríra nwọn, èyítí ó jẹ́ kí nwọ́n sún sẹ́hìn kúrò ní iwájú Olúwa sí ipò ìbànújẹ́ àti oró àìnípẹ̀kun, nínú èyítí nwọn kò lè kúrò mọ́; nítorínã nwọn ti mu ègbé sórí ẹ̀mí ara nwọn.

26 Nítorínã, nwọ́n ti mu nínú ago ìbínú Ọlọ́run, aiṣegbe èyítí kò lè yẹ̀ lórí nwọn bí kò ṣe yẹ̀ pé Ádámù yíò ṣubú nítorítí ó jẹ nínú èso tí a kà lẽwọ̀; nítorínã ãnú kò lè wà fún nwọn títí láé.

27 Ìdálóró nwọn sì dà bí adágún iná àti imí ọjọ́, ẹ̀là iná èyítí a kò lè pa, àti ẽfín èyítí ó nrú sókè títí láéláé. Báyĩ ni Olúwa ti pã láṣẹ fún mi. Àmín.