Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 4


Orí 4

Ọba Bẹ́njámínì tẹ̀síwájú nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀–Ìgbàlà wá nítorí Ètùtù nã—Gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run kí a sì gbà ọ́ là–Dí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mú nípasẹ̀ ìṣòtítọ́—Fifún tálákà nínú ọ̀rọ̀ rẹ—Ṣe ohun gbogbo pẹ̀lú ọgbọ́n àti ètò. Ní ìwọ̀n ọdún 124 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe ti ọba Bẹ́njámínì ti parí ọ̀rọ̀ sísọ ní ti èyítí a fún un láti ọwọ́ ángẹ́lì Olúwa, ó sì wo àwọn ọ̀pọ̀ ènìyàn nã yíká, sì kíyèsĩ, nwọ́n ti ṣubú lulẹ̀, nítorítí ẹ̀rù Olúwa ti wá sórí nwọn.

2 Nwọ́n sì ti rí ara nwọn nínú ipò ara nwọn, èyítí ó kéré sí ẹrùpẹ̀ ilẹ̀. Gbogbo nwọ́n sì ké sókè pẹ̀lú ohùn kan wípé: A! ṣãnú, kí ó sì ro ti ẹ̀jẹ̀ ètùtù Krístì kí àwa lè gba ìdáríjì fún ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ọkàn wa sì di wíwẹ̀mọ́; nítorítí àwa gbàgbọ́ nínú Jésù Krístì, Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tí ó dá ọ̀run òhun ayé, àti oun gbogbo; tí yíò sọ̀kalẹ̀ wá lãrín àwọn ọmọ ènìyàn.

3 Ó sì ṣe, lẹ́hìn tí nwọ́n ti sọ̀rọ̀ wọ̀nyí, Ẹ̀mí Olúwa sọ̀kalẹ̀ sórí nwọn, nwọ́n sì kún fún ayọ̀, nígbàtí nwọ́n ti gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, tí nwọ́n sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn, nítorí ìgbàgbọ́ tí ó tayọ tí nwọ́n ní nínú Jésù Krístì ẹniti yio wá, gẹ́gẹ́bí awọn ọ̀rọ̀ èyítí ọba Bẹ́njámínì ti bá nwọn sọ.

4 Ọba Bẹ́njámínì sì tún la ẹnu rẹ̀ ó sì bẹ̀rẹ̀ sí bá nwọn sọ̀rọ̀, wípé: Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi àti arákùnrin mi, ẹ̀yin ìbátan mi àti ènìyàn mi, èmi yíò sì tún fẹ́ kí ẹ farabalẹ̀, kí ẹ lè gbọ́, ní àgbọ́yé èyítí ó kù nínú ọ̀rọ̀ mi tí èmi yíò bã yín sọ.

5 Nítorí kíyèsĩ, bí imọ nípa dídára Ọlọ́run ní àkokò yí bá ti ta yín jí sí ipò asán nyín, àti ipò aláìnílárí àti ìdíbàjẹ́ tí ẹ wa—

6 Mo wí fún nyín, bí ẹ̀yin bá ti ní ìmọ̀ nípa dídára Ọlọ́run, àti ti agbára rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́, àti ọgbọ́n rẹ̀, àti sũrù rẹ̀, àti ìpamọ́ra rẹ̀ sí àwọn ọmọ ènìyàn; àti pẹ̀lú, ètùtù èyítí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀sẹ̀ ayé, wípé nípa bẹ̃ ìgbàlà lè jẹ́ ti ẹni tí ó bá gbẹ́kẹ̀lé Olúwa, tí ó sì fi àìṣèmẹ́lẹ́ pa awọn òfin rẹ̀ mọ́, tí ó sì tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́ nã, àní títí dé òpin ayé rẹ̀, àní ayé ti ara kíkú—

7 Mo wípé èyí ni ẹni nã tí ó gba ìgbàlà, nípasẹ̀ ètùtù nã èyítí a ti pèsè láti ìpilẹ̀sẹ̀ ayé fún gbogbo aráyé, tí nwọ́n ti wà láti ìgbà ìṣubú ti Ádámù, tàbí tí nwọ́n wà tàbí tí yíò wà, àní títí dé òpin ayé.

8 Èyí sì ni ipa ọ̀nà ti ìgbàlà fi nwá. Kò sì sí ìgbàlà míràn bíkòṣe èyítí a ti sọ nípa rẹ̀; bẹ̃ni kò sì sí ipò míràn nípa èyítí a lè gba ènìyàn là àfi àwọn èyítí mo ti sọ fún un yín.

9 Gbàgbọ́ nínú Ọlọ́run; gbàgbọ́ pé ó wà, àti pé òun ni ó dá ohun gbogbo, ní ọ̀run àti ayé; gbàgbọ́ pé ó ní gbogbo ọgbọ́n, àti gbogbo agbára, ní ọ̀run àti ní ayé; gbàgbọ́ pé ènìyàn kò ní òye ohun gbogbo tí ó lè yé Olúwa.

10 Àti pẹ̀lú, gbàgbọ́ pé ẹ̀yin níláti ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ nyín kí ẹ sì kọ̀ wọ́n sílẹ̀, kí ẹ sì rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run; kí ẹ sì bẽrè pẹ̀lú ọkàn tõtọ́ pé kí ó dáríjì yín; àti nísisìyí, bí ẹ̀yin bá sì gba gbogbo nkan wọ̀nyí gbọ́, ẹ ríi pé ẹ ṣe nwọ́n.

11 Àti pẹ̀lú mo wí fún un yín gẹ́gẹ́bí mo ti sọ síwájú, pé bí ẹ̀yin ṣe ti ní ìmọ̀ nípa ògo Ọlọ́run, tabí tí ẹ̀yin ti mọ̀ nípa dídára rẹ, tí ẹ sì ti tọ́ ìfẹ́ rẹ̀ wò, tí ẹ sì ti gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nyín, èyítí ó fún nyín ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ayọ̀ ní ọkàn nyín, àní èmi fẹ́ kí ẹ̀yin rántí, kí ẹ sì fi ìrántí títóbi Ọlọ́run, àti ipò àìjámọ́-nkankan nyín, àti dídára àti ìfaradà rẹ̀ sí yín, ẹ̀dá aláìyẹ, kí ẹ sì rẹ ara yín sílẹ̀ ní ipò ìrẹ̀lẹ̀ púpọ̀, ní pípe orúkọ Olúwa lójõjúmọ́, ní dídúró ṣinṣin nínú ìgbàgbọ́ nínú èyítí ó nbọ̀wá, èyítí a sọ nípa rẹ̀ láti ẹnu ángẹ́lì nã.

12 Kí ẹ kíyèsĩ mo wí fún nyín pé bí ẹ̀yin bá ṣe eleyĩ, ẹ̀yin yíò máa yọ̀ nígbà-gbogbo, ẹ ó sì kún fún ìfẹ́ Ọlọ́run, ẹ ó sì ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nyín nígbà-gbogbo; ẹ̀yin yíò sì dàgbà nínú ìmọ̀ ògo ẹnití ó dáa yín, tàbí, nínú ìmọ̀ èyítí ó tọ́ àti tí ó sì jẹ́ òtítọ́.

13 Ẹ̀yin kò sì ní ní ọkàn láti pa ara nyín lára, ṣùgbọ́n láti gbé pọ̀ ní àlãfíà, àti láti fi fún ènìyàn gbogbo gẹ́gẹ́bí ó ṣe tọ́ síi.

14 Ẹ̀yin kò sì ní jẹ́ kí ebi kí ó pa àwọn ọmọ nyín, tàbí kí nwọ́n wà ní ìhòhò; ẹ̀yin kò sì ní jẹ́ kí nwọ́n ré òfin Ọlọ́run kọjá, kí nwọ́n ní ìjà tàbí ãwọ̀ lãrín ara nwọn, kí nwọ́n sì sin èṣù, ẹni tí ó jẹ́ olórí fún ẹ̀ṣẹ̀, tàbí tí ó jẹ́ ẹ̀mí ibi nnì tí àwọn bàbá wa ti sọ nípa rẹ̀, oun tí ó jẹ́ ọ̀tá sí gbogbo ìṣòtítọ́.

15 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin yíò kọ́ nwọn láti rìn nípa ọ̀nà òtítọ́ àti ìwà àìrékọjá; ẹ̀yin yíò kọ́ nwọn kí nwọ́n ní ìfẹ́ àra nwọn, kí nwọ́n sì máa sin ara nwọn.

16 Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin tìkarayín yíò ran àwọn tí à ndánwò lọ́wọ́; ẹ̀yin yíò fún àwọn aláìní nínú ọ̀rọ̀ nyín; ẹ̀yin kò sì ní jẹ́ kí ẹ̀bẹ̀ alágbe já sí asán, kí ẹ sì lée jáde láti parun.

17 Bóyá ẹ̀yin yíò wípé: Okùnrin nã ni ó mú ìyà yí wá sórí ara rẹ̀; nítorínã, èmiyíò dá ọwọ́ mi dúró, èmi kò sì ní fún un nínú oúnjẹ mi, tàbí kí èmi kí ó fún un nínú ọrọ̀ mi kí ó má bã jìyà, nítorítí ìyà rẹ jẹ́ èyítí ó tọ́—

18 Ṣùgbọ́n èmi wí fún ọ, A! ọmọ ènìyàn, ẹnìkẹ́ni tí ó bá ṣe eleyĩ, ní ìdí pàtàkì láti ronúpìwàdà; bí kò sì ronúpìwàdà kúrò nínú èyítí ó ti ṣe, yíò parun títí láé, kò sì ní ìpín nínú ìjọba Ọlọ́run.

19 Nítori kíyèsĩ, gbogbo wa kò ha íṣe alágbe bi? Njẹ́ a kì ha gbẹ́kẹ̀lé Ẹní nã, àní Ọlọ́run, fún gbogbo ọrọ̀ tí a ní, fún oúnjẹ àti aṣọ, àti fún wúrà, àti fún fàdákà, àti fún gbogbo dúkìá tí a ní lóríṣiríṣi?

20 Sì Kíyèsĩ, ní àkokò yí pãpã, ẹ̀yin ti nképe orúkọ rẹ̀, tí ẹ sì nbẹ̀bẹ̀ fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Njẹ́ ó gbà pé kí ẹ̀bẹ̀ nyín jẹ́ lásán? Rárá; ó ti tú Ẹ̀mí rẹ̀ lé orí nyín, ò sì ti mú kí ọkàn nyín kún fún ayọ̀, ó sì ti mú kí ẹnu yín pamọ́ kí ẹ̀yin má lè rí ọ̀rọ̀ sọ, bẹ̃ ni ayọ̀ ọ yín tóbi tó.

21 Àti nísisìyí, bí Ọlọ́run, ẹnití ó dá nyín, ẹnití ẹ̀yin gbára lé fún ẹ̀mí nyín, àti fún gbogbo ohun tí ẹ ní, àti tí ẹ jẹ́, tí ó sì fún nyín ní ohunkóhun tí ó tọ́ tí ẹ bá bẽrè, nínú ìgbàgbọ́, tí ẹ sì gbàgbọ́ pé ẹ ó ri gbà, A! njẹ́ nígbànã, ó yẹ kí ẹ̀yin bá ara nyín pín nínú ọrọ̀ yín.

22 Bí ìwọ bá sì ṣe ìdájọ́ fún ẹni nã tí o bẹ̀bẹ̀ fún ìní rẹ kí ó máa bã parun, tí ìwọ sì dáa lẹ́bi, báwo ni ìdálẹ́bi rẹ yíò ṣe jẹ́ èyítí ó tọ́ tó fún ìháwọ́ ohun-ìní rẹ, èyítí kĩ ṣe tìrẹ, bíkòṣe ti Ọlọ́run, ẹni tí ẹ̀mí rẹ jẹ́ pẹ̀lú; àti síbẹ̀ ìwọ kò bẹ̀bẹ̀, tàbí ronúpìwàdà fún àwọn ohun tí ìwọ ti ṣe.

23 Mo wí fún ọ, ègbé ni fún ẹni nã, nítorítí ohun-ìní rẹ̀ yíò parun pẹ̀lú rẹ̀; àti nísisìyí, èmi sì sọ ohun wọ̀nyí fún àwọn tí nwọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ nípa ohun ti ayé yĩ.

24 Àti pẹ̀lú, èmi wí fún àwọn tálákà, ẹ̀yin tí ẹ kò ní, ṣùgbọ́n síbẹ̀ tí ẹ ní ànító pé kí ẹ gbé ayé láti ọjọ́ dé ọjọ́; mo sọ wípé gbogbo ẹ̀yin tí ẹ kọ aláìní nnì, nítorítí ẹ̀yin kò ní; èmi ìbá fẹ́ kí ẹ wí nínú ọkàn nyín pé: èmi kò fifúnni nítorítí èmi kò ní, ṣùgbọ́n bí mo bá ní, èmi yíò fifúnni.

25 Àti nísisìyí, bí ẹ̀yin bá sọ eleyĩ nínú ọkàn nyín, ẹ̀yin wà ní àìlẹ́ṣẹ̀, bíkòjẹ́bẹ̃, a dá nyín lẹ́bi; ìdálẹ́bi rẹ sì tọ́ nítorítí ìwọ ṣe ojúkòkúrò sí èyítí ìwọ kò ì tĩ gbà.

26 Àti nísisìyí, nítorí àwọn ohun wọ̀nyí tí èmi ti bá nyín sọ—àní, nítorí gbígba ìdáríjì-ẹ̀ṣẹ̀ nyín lójojúmọ́, kí ẹ̀yin kí ó lè rìn láìlẹ́ṣẹ̀ níwájú Ọlọ́run—èmi ìbá fẹ́ kí ẹ fi nínú ohun-ìní nyín fún àwọn tálákà, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí èyítí ó ní, gẹ́gẹ́bí bíbọ́ àwọn tí ebi npa, dídá aṣọ bò àwọn tí ó wà ní ìhòhò, bíbẹ àwọn aláìsàn wò, àti pípèsè fún ìtura nwọn, nípa ti ẹ̀mí àti ara, gẹ́gẹ́bí àìní nwọn.

27 Kí ẹ̀yin sì ríi pé ẹ ṣe àwọn nkan wọ̀nyí ní ipa ọgbọ́n àti ètò; nítorípé kò tọ́ kí ènìyàn sáré ju bí ó ṣe lágbára. Àti pẹ̀lú, ó jẹ́ ohun ẹ̀tọ́ pé kí ó lãpọn, kí ó bã lè gba èrè nã; nítorínã, a níláti ṣe ohun gbogbo létò-letò.

28 Èmi ìbá sì fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí pé ẹnìkẹ́ni nínú nyín tí ó bá yá ohun kan lọ́wọ́ aládũgbò rẹ níláti dá ohun nã padà tí ó yá, gẹ́gẹ́bí ó ti ṣẹ àdéhùn, àìjẹ́bẹ̃, ìwọ ti dẹ́ṣẹ̀; bóyá ìwọ yíò sì jẹ́ kí aládũgbò rẹ dẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú.

29 Àti lakotan, èmi kò lè sọ gbogbo ohun tí ó lè jẹ́ kí ẹ dẹ́ṣẹ̀; nítorípé onírurú ọ̀nà àti ipá ni ó wà, nwọ́n pọ̀ tóbẹ̃, tí èmi kò lè kà nwọ́n.

30 Ṣùgbọ́n mo lè sọ èyí fún un yín, pé bí ẹ kò bá kíyèsĩ ara nyín, àti èrò ọkàn nyín, àti ọ̀rọ̀ sísọ yín, àti iṣẹ́ nyín, kí ẹ sì pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, kí ẹ sì tẹ̀síwájú nínú ìgbàgbọ́ nínú èyítí ẹ̀yin tí gbọ́ nípa bíbọ̀wá Olúwa, àní títí dé òpin ayé nyín, ẹ̀yin yíò parun. Àti nísisìyí, A! ọmọ ènìyàn, rántí, má sì parun.