Àwọn Ìwé Mímọ́
Mòsíà 5


Orí 5

Àwọn Ènìyàn Mímọ́ di ọmọ Krístì nípasẹ̀ ìgbàgbọ́—A sì nfi orúkọ Krístì pè nwọ́n—Ọba Bẹ́njámínì gbà nwọ́n níyànjú kí nwọ́n ní ìtẹramọ́ àti ìdúróṣinṣin nínú iṣẹ́ rere. Ní ìwọ̀n ọdún 124 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe nígbàtí ọba Bẹ́njámínì sì ti bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ báyĩ, ó ránṣẹ́ lãrín nwọn, kí ó lè mọ̀ bóyá àwọn ènìyàn rẹ̀ gba àwọn ọ̀rọ̀ tí ó ti bá nwọn sọ gbọ́.

2 Gbogbo nwọn sì kígbe lóhùn kan, wípé: Bẹ̃ni, àwa gba gbogbo ọ̀rọ̀ tí ìwọ ti bá wa sọ gbọ́; àwa sì mọ̀ nípa ìdánilójú àti òtítọ́ nwọn, nítorí Ẹ̀mí Olúwa Alèwílèṣe, tí ó ti mú ìyípadà nlá bá wa, tàbí nínú ọkàn wa, tí àwa kò sì ní ẹ̀mí àti ṣe búburú mọ́, ṣùgbọ́n láti máa ṣe rere títí.

3 Àti àwa tìkarawa, pẹ̀lú, nípa dídára àìníye Ọlọ́run, àti ìfihàn Ẹ̀mí rẹ, ní òye nlá nípa èyítí nbọ̀ wá; tí ó bá sì tọ́, àwa lè ṣe ìsọtẹ́lẹ̀ ohun gbogbo.

4 Ìgbàgbọ́ tí àwa sì ti ní nínú ohun tí ọba wa sọ fún wa ni ó mú wa ní ìmọ̀ nlá yĩ, nípa èyí tí àwa nyọ̀ pẹ̀lú irú ayọ̀ nlá bẹ̃.

5 Àwa sì fẹ́ láti dúró lórí májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ, àti láti ṣe ìgbọ́ran sí àwọn òfin rẹ̀ nínú ohun gbogbo tí yíò paláṣẹ fún wa, ní gbogbo ìyókù ayé wa, kí àwa kí ó má bã mú oró tí kò nípẹ̀kun bá ara wa, gẹ́gẹ́bí ángẹ́lì nã ti sọ, kí àwa máṣe mu nínú ago ìbínú Ọlọ́run.

6 Àti nísisìyí àwọn wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ tí ọba Bẹ́njámínì fẹ́ kí nwọ́n sọ; nítorínã ó wí fún wọn pé: Ẹ̀yin ti sọ ọ̀rọ̀ tí mo fẹ́; májẹ̀mú tí ẹ̀yin sì ti dá jẹ́ májẹ̀mú òtítọ́.

7 Àti nísisìyí, nítorí májẹ̀mú tí ẹ̀yin sì ti dá a ó máa pè yín ní ọmọ Krístì, ọmọ rẹ̀ lọ́kùnrin, àti ọmọ rẹ̀ lóbìnrin; nítorí ẹ kíyèsĩ, ní òní yí ni ó ti bí nyín nínú ẹ̀mí; nítorítí ẹ̀yin wípé ọkàn nyín ti yípadà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀; nítorínã, a bí nyín nínú rẹ ẹ̀yin sì ti di ọmọ rẹ̀ l’ọ́kùnrin àti l’óbìnrin.

8 Àti ní abẹ́ orí yĩ ni ẹ̀yin ti di òmìnira, kò sì sí orí míràn nípasẹ̀ èyítí a lè sọ yín di òmìnira. Kò sí orúkọ míràn tí a fún ni nípasẹ̀ èyítí ìgbàlà yíò wá; nítorínã, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ gbé orúkọ Krístì lé oríi yín, gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti wọ inú májẹ̀mú pẹ̀lú Ọlọ́run kí ẹ̀yin kí ó lè ṣe ìgbọ́ran títí dé òpin ayé nyín.

9 Yíò sì ṣe, ẹnikẹ́ni tí ó bá ṣe eleyĩ ni a ó bá ní ọwọ́ ọ̀tun Ọlọ́run, nítorítí òun yíò mọ orúkọ nã tí à fi npè é; nítorítí a ó fi orúkọ Krístì pè é.

10 Àti nísisìyí yíò sì ṣe, ẹnìkẹni tí kò bá gbé orúkọ Krístì ka orí ara rẹ̀, ni a ó fi orúkọ míràn pè; nítorínã, yíò bá ara rẹ̀ ní ọwọ́ òsì Ọlọ́run.

11 Èmi ìbá sì fẹ́ kí ẹ̀yin ó rántí pẹ̀lú, pé èyí ni orúkọ tí èmi wípé èmi yíò fún un yín èyítí kò ní parẹ́ láéláé, bíkòṣe nípasẹ̀ ìrékọjá; nítorínã, ẹ ṣọ́ra kí ẹ̀yin kí ó máṣe rékọjá, kí orúkọ nã má ṣe parẹ́ kúrò l’ọ́kàn nyín.

12 Mo wí fún nyín, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ rántí láti mú orúkọ nã dúró ní kíkọ lé oókan àyà nyín nígbà-gbogbo, kí a má bã bá a yín ní ọwọ́ òsì Ọlọ́run, ṣùgbọ́n pé kí ẹ gbọ́ kí ẹ sì mọ ohùn ìpè nã èyítí a ó fi pè nyín, àti pẹ̀lú, orúkọ nã èyítí yíò pè yín.

13 Nítorí báwo ni ènìyàn yíò ṣe mọ Olúwa rẹ̀, èyítí kò tĩ sìn, tí ó sì jẹ́ àjòjì síi, tí ó sì jìnà sí èrò àti ète ọkàn rẹ̀?

14 Àti pẹ̀lú, njẹ́ ènìyàn lè mú kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí íṣe ti aladugbo rẹ̀, kí ó fi pamọ́? Mo wí fún nyín, Rárá; kò tilẹ̀ ní jẹ́ kí ó jẹ nínú agbo rẹ̀, ṣùgbọ́n yíò lé e, yíò sì sọ ọ́ sóde. Mo wí fún nyín, wípé bẹ̃ ni yíò rí lãrín yín bí ẹ̀yin kò bá mọ́ orúkọ èyítí à fi npè yín.

15 Nítorínã, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó ní ìtẹramọ́ àti ìdúróṣinṣin, kí ẹ kúnfún iṣẹ́ rere nígbà-gbogbo, kí Krístì, Olúwa Ọlọ́run Alèwílèṣe, lè fi èdìdí dì yín mọ́ra rẹ̀, kí a lè mú u yín wá sí ọ̀run, kí ẹ̀yin lè ní ìgbàlà àìlópin àti ìyè àìnípẹ̀kun, nípasẹ̀ ọgbọ́n, àti agbára, àti àiṣègbè, àti ãnú rẹ̀, ẹnití ó dá ohun gbogbo, ní ọ̀run òun ayé, tí ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ga jù ohun gbogbo lọ. Àmín.