Ori 12
Nífáì rí ilẹ̀ ìlérí nínú ìran; ó rí òdodo, àìṣedẽdé, àti ìṣubú àwọn olùgbé rẹ̀; bíbọ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run lãrín wọn; bí àwọn Ọmọ-ẹ̀hìn méjẽjìlá àti àwọn Àpóstélì méjẽjìlá yíò ṣe ìdájọ́ fún Isráẹ́lì; àti ipò ẹlẹ́gbin àti elẽrí àwọn tí wọ́n rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Ó sí ṣe tí angẹ́lì ná à wí fún mi: Wò ó, sì kíyèsí irú-ọmọ rẹ, àti irú-ọmọ arákùnrin rẹ pẹ̀lú. Mo sì wò mo sì kíyèsí ilẹ̀ ìlérí ná à; mo sì kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn, bẹ̃ni, àní bí ó ti rí ní iye, tí wọn pọ̀ bí iyanrìn òkun.
2 Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí wọ́n kórajọ láti jagun, tí ọ̀kan ndojúkọ èkejì; mo sì kíyèsí ogun, àti ìdàgìrì ogun, àti ìpakúpa nlá pẹ̀lú idà lãrín àwọn ènìyan mi.
3 Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran tí ó rékọjá, nípasẹ̀ ọ̀nà àwọn ogun àti àwọn ìjà ní ilẹ̀ nã; mo sì kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá, bẹ̃ni, àní tí n kò ka iye wọn.
4 Ó sì ṣe tí mo rí ìkũku ní ojú ilẹ̀ ìlérí; mo sì rí àwọn mọ̀nàmọ́ná, mo sì gbọ́ sísán àwọn àrá, àti ilẹ̀ rírì àti gbogbo onírurú àwọn ariwo rúdurùdu; mo sì rí ilẹ̀ àti àwọn àpáta, tí wọ́n sán; mo sì rí àwọn òkè gíga tí wọ́n sì nwó lulẹ̀; mo sì rí àwọn pẹ̀tẹ́lẹ̀ aiyé, tí wọ́n fọ́ sí wẹ́wẹ́; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìlú-nlá tí wọ́n rì; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n fi iná jó; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tí wọ́n wó lulẹ̀, nítorí ti gbígbọ̀n-rìrì rẹ̀.
5 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo rí àwọn nkan wọ̀nyí, mo rí ikũkù òkùnkùn ná à, tí ó kọjá kúrò ní ojú àgbáyé; sì kíyèsĩ, mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn tí kò tí ì ṣubú nítorí ìdájọ́ nlá àti tí ó lẹ́rù ti Olúwa.
6 Mo sì rí àwọn ọ̀run tí wọn ṣí sílẹ̀, Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ná à sì nsọ̀kalẹ̀ láti ọ̀run; ó sì wá sísàlẹ̀ ó sì fi ara rẹ̀ hàn sí wọn.
7 Mo sì tún rí mo sì jẹ́rĩ pé Ẹ̀mí Mímọ́ bà sórí àwọn méjìlá míràn; a sì ṣe Ìlànà wọn nípa Ọlọ́run, a sì yàn wọ́n.
8 Angẹ́lì ná à sì bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsí àwọn ọmọ-èhìn méjẽjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, tí a yàn láti ṣe ìránṣé fún irú-ọmọ rẹ.
9 Ó sì wí fún mi: Ìwọ rántí àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn bí? Kíyèsĩ, àwọn ni wọn yíò ṣe ìdájọ́ àwọn ẹ̀yà méjẽjìlá ti Isráẹ́lì; nítorí-èyi, àwọn ìránṣẹ́ méjìlá ti irú-ọmọ rẹ ni a ó ṣe ìdájọ́ fún nípa ọwọ́ wọn; nítorí ará ilé Isráẹ́lì ni ìwọ.
10 Àwọn ìránṣẹ́ méjìlá tí ìwọ sì rí yí yíò ṣe ìdájọ́ irú-ọmọ rẹ. Sì kíyèsĩ, wọ́n jẹ́ olódodo títí láé; fún nítorí ti ìgbàgbọ́ wọn nínú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run àwọn ẹ̀wù wọn ni a sọ di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀.
11 Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Wò ó! Mo sì wò, mo sì rí ìran mẹ́ta tí ó rékọjá nínú òdodo; àwọn ẹ̀wù wọn sì funfun tí ó tilẹ̀ dàbí Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run. Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Àwọn wọ̀nyí ni a sọ di funfun nínú ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn, nítorí ti ìgbàgbọ́ wọn nínú rẹ̀.
12 Èmi, Nífáì, sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìran kẹrin pẹ̀lú tí ó rékọjá nínú òdodo.
13 Ó sì ṣe tí mo rí ọ̀pọ̀ ènìyàn ayé tí wọ́n jùmọ̀ péjọ.
14 Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Kíyèsí irú-ọmọ rẹ, àti irú-ọmọ arákùnrin rẹ pẹ̀lú.
15 Ó sì ṣe tí mo wò tí mo sì rí àwọn ènìyàn irú-ọmọ mi tí wọ́n jùmọ̀ péjọ tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ dojúkọ iru-ọmọ arákùnrin mi; wọ́n sì jùmọ̀ péjọ láti jagun.
16 Angẹ́lì ná à sì bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsí orísun omi eléerí èyí tí bàbá rẹ rí; bẹ̃ni, àní odò èyí tí ó sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀; ibú èyí ná à sì jẹ́ ibú ọ̀run àpãdì.
17 Òwúsúwusù òkùnkùn nã sì jẹ́ ìdánwò ti èṣù, èyí tí ó fọ́ni lójú, tí ó sé àyà àwọn ọmọ ènìyàn le, tí ó sì tọ́ wọn kúrò sínú àwọn ọ̀nà gbõrò, tí wọ́n ṣègbé tí wọ́n sì sọnù.
18 Ilé tí ó tóbi tí ó sì gbõrò nã, èyí tí bàbá rẹ rí, jẹ́ ìrò asán àti ìgbéraga àwọn ọmọ ènìyàn. Ọ̀gbun nlá tí ó sì banilẹ́rù kan sì pín wọn; bẹ̃ni, àní ọ̀rọ̀ àìṣègbè Ọlọ́run Ayérayé, àti ti Messia ẹni tí ó jẹ́ Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, nípa ẹni tí Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́ ẹ̀rí, láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé títí di ìgbà yí, àti láti ìgbà yí lọ àti títí láé.
19 Ní àkókò tí angẹ́lì nã sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, mo kíyèsí mo sì ríi wípé irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi dojú ìjà kọ irú-ọmọ tèmi, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ angẹ́lì ná à; àti nítorítí ìgbéraga irú-ọmọ mi, àti ìdánwò èṣù, mo kíyèsĩ i pé irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi borí àwọn ènìyàn irú-ọmọ mi.
20 Ó sì ṣe tí mo kíyèsĩ, tí mo sì rí àwọn ènìyàn irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi tí wọ́n ti ṣẹ́gun irú-ọmọ mi; wọ́n sì ńkàkiri ní ọ̀gọ̃rọ̀ ènìyàn lórí ojú ilẹ̀.
21 Mo sì rí wọn tí wọ́n jùmọ̀ péjọ ní ọ̀gọ̃gọ̀ ènìyàn; mo sì rí ogun àti ìró ogun lãrín wọn; nínú ogun àti ìró ogun ni mo sì rí ọ̀pọ̀ ìran tí wọ́n kọjá kúrò.
22 Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Kíyèsĩ àwọn wọ̀nyí yíò rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́.
23 Ó sì ṣe tí mo kíyèsĩ i, lẹ́hìn tí wọn ti rẹ̀hìn nínú ìgbàgbọ́ wọ́n di dúdú, àti ẹlẹ́gbin, àti elẽrí ènìyàn, tí ó kún fún ìmẹ́lẹ́ ati onirũru ohun ìríra.