Ori 22
A ó tú Isráẹ́lì ká sórí gbogbo ojú àgbáyé—Àwọn Kèfèrí yíò tọ́jú, wọ́n ó sì bọ́ Isráẹ́lì pẹ̀lú ìhìn-rere ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—A ó kó Isráẹ́lì jọ a ó sì gbà á là, àwọn ènìyàn búburú yíò sì jóná bí àkékù koríko—Ìjọba èṣù ni a ó parun, Sátánì ni a ó sì dè. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, ti ka àwọn ohun wọ̀nyí èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ, àwọn arákùnrin mi wá sọ́dọ̀ mi wọ́n sì wí fún mi: Kíni àwọn ohun wọ̀nyí túmọ̀ sí èyí tí ìwọ ti kà? Kíyèsĩ i, ṣé kí á mọ̀ wọn gẹ́gẹ́bí àwọn ohun ti ẹ̀mí, èyí tí mbọ̀ wá kọjá gẹ́gẹ́bí ti ẹ̀mí tí kì í ṣè ti ẹran ara?
2 Èmi, Nífáì, sì wí fún wọn: Kíyèsĩ i a fi wọ́n hàn si wòlĩ nì nípasẹ̀ ohùn ti Ẹ̀mí; nítorí nípasẹ̀ Ẹ̀mí ni a fi sọ ohun gbogbo di mímọ̀ fún àwọn wòlĩ, èyí tí yíò wá sórí àwọn ọmọ ènìyàn gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara.
3 Nítorí-èyi, àwọn ohun nã nípa èyí tí mo ti kà jẹ́ àwọn ohun tí n ṣe ti ayé yí àti ti ẹ̀mí; nítorí ó ṣe bíẹnipé, bí ó pẹ́ bí ó yá, a ó tú ará ilé Isráẹ́lì ká sórí gbogbo ojú àgbáyé, àti pẹ̀lú lãrín gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè.
4 Sì kíyèsĩ i, ọ̀pọ̀ ni ó wà tí ó ti sọnù nísisìyí kúrò ní ìmọ̀ àwọn wọnnì tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù. Bẹ̃ni, ipa tí ó jùlọ ti gbogbo àwọn ẹ̀yà ni a ti tọ́ kúrò; a sì tú wọn ká síwájú àti ṣẹ́hìn lórí erékùṣù òkun; ibi tí wọ́n wà kò sí ẹnìkan nínú wa tí ó mọ̀, àfi pé a mọ̀ pé a ti tọ́ wọn kúrò.
5 Láti ìgbà tí a sì ti tọ́ wọn kúrò, àwọn ohun wọ̀nyí ni a ti sọ tẹ́lẹ̀ nípa wọn, àti pẹ̀lú nípa gbogbo àwọn tí a ó tú ká tí a ó sì fọnka lẹ́hìn èyí, nítorí ti Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; nítorí wọ́n ó sé ọkàn wọn le sí; nítorí-èyi, a ó tú wọn ká lãrín gbogbo àwọn orílẹ-èdè gbogbo ènìyàn yíò sì kórìra wọn.
6 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, lẹ́hìn ti àwọn Kèfèrí yíò tọ́jú wọn, tí Olúwa sì ti gbé ọwọ́ rẹ̀ sókè sí órí àwọn Kèfèrí ti ó sì ti gbé wọn sókè fún ọ̀págún, ti a sì ti gbé àwọn ọmọ wọn ní apá wọn, ti a sì ti gbé àwọn ọmọbìnrin wọn sí órí èjìká wọn, kíyèsĩ àwọn ohun wọ̀nyí nípa èyí tí a sọ̀ jẹ́ ti ayé yí; nítorí báyĩ ni awọn májẹ̀mú Olúwa pẹ̀lú àwọn bàbá wa; ó sì tọ́ka sí àwọn ọjọ́ tí ńbọ̀ fún wa, àti pẹ̀lú àwọn arákùnrin wa gbogbo tí ó jẹ́ ti ará ilé Isráẹ́lì.
7 Ó sì túmọ̀ sí pé àkókò nã mbọ̀wá lẹ́hìn tí a bá ti tú gbogbo ará ilé Isráẹ́lì ká tí a sì fọn wọn ka, tí Olúwa Ọlọ́run yíò gbé orílẹ̀-èdè alágbára sókè lãrín àwọn Kèfèrí, bẹ̃ni, àní lórí ojú ilẹ̀ yí; nípasẹ̀ wọn sì ni a o tú irú-ọmọ wa ká.
8 Lẹ́hìn tí a bá sì ti tú irú-ọmọ wa ká, Olúwa Ọlọ́run yíò tẹ̀ síwájú láti ṣe iṣẹ́ ìyanu lãrín àwọn Kèfèrí, èyí tí yíò jẹ́ ti iye nlá sí irú-ọmọ wa; nítorí-èyi, a fi wé bíbọ wọn nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí àti gbígbé wọn ní apá wọn àti sórí èjìká wọn.
9 Yíò sì jẹ́ ìtóye pẹ̀lú sí àwọn Kèfèrí; kì í sì í ṣe sí àwọn Kèfèrí nìkan ṣùgbọ́n sí gbogbo ará ilé Isráẹ́lì, sí mímú wá sí ìmọ̀ àwọn májẹ̀mú ti Bàbá ọ̀run sí Ábráhámù, tí ó wípé: Nínú irú-ọmọ rẹ ni a ó bùkún fún gbogbo ìbátan ayé.
10 Èmi sì fẹ́, ẹ̀yin arákùnrin mi, pé kí ẹ̀yin mọ̀ pé a kò lè bùkún fún gbogbo ìbátan ayé bíkòṣepé òun bá fi apá rẹ̀ hàn ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè.
11 Nítorí-èyi, Olúwa Ọlọ́run yíò tẹ̀ síwájú láti fi apá rẹ̀ hàn ní ojú àwọn orílẹ̀-èdè, ní mímú awọn májẹ̀mú rẹ̀ àti ìhìn-rere rẹ̀ wá kãkiri sí àwọn tí ó jẹ́ ará ilé Isráẹ́lì.
12 Nítorí-èyi, òun yíò tún mú wọn jáde wá láti ìgbèkun, a ó sì jùmọ̀ kó wọn jọ sí àwọn ilẹ̀ ìní wọn; a ó sì mú wọn jáde wá láti ìṣókùnkùn àti jáde láti òkùnkùn; wọn yíò sì mọ̀ pé Olúwa ni Olùgbàlà wọn àti Olùràpadà wọn, Ẹni Alágbára Isráẹ́lì.
13 Èjẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, èyí tí í ṣe àgbèrè gbogbo ayé, yíò sì yípadà sórí ara wọn; nítorí wọn yíò jagun lãrín àwọn tìkaláawọn, idà ti ọwọ́ ara wọn yíò sì wá sórí ara wọn, wọn yíò sì mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn ní àmupara.
14 Orílẹ̀-ede gbogbo tí yíò dìde ogun sí ọ, A! ará ilé Isráẹ́lì, ni wọn yíò dojúkọ ara wọn, wọn yíò sì ṣubú sínú kòtò èyí tí wọ́n gbẹ́ láti dẹkùn mú àwọn ènìyàn Olúwa. Gbogbo àwọn tí ó bá sì dojú ìjà kọ Síónì ni a ó parun, àti àgbèrè nlá nì, ẹni tí ó ti yí àwọn ọ̀nà títọ́ ti Olúwa padà, bẹ̃ni, ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára nì, yíò ṣubú sí erùpẹ̀; títóbi sì ni ìṣubú rẹ̀ yíò jẹ́.
15 Nítorí kíyèsĩ i, ni wòlĩ nã wí, àkókò nã mbọ̀wá kíákíá tí Sátánì kì yíò ní agbára mọ́ lórí ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn; nítorí ọjọ́ nã yíò dé láìpẹ́ tí gbogbo àwọn agbéraga àti àwọn tí ó nṣe búburú yíò dà bí àkékù koríko; ọjọ́ nã sì ńbọ̀wá tí a kò ní ṣe àìjó wọn.
16 Nítorí àkókó yíò dé láìpẹ́ tí a ó tú ẹ̀kún ìbínú Ọlọ́run jáde sórí gbogbo àwọn ọmọ ènìyàn; nítorí òun kì yíò yọ̃da kí ènìyàn búburú run olódodo.
17 Nítorí-èyi, òun yíò pa olódodo mọ́ nípasẹ̀ agbára rẹ̀, àní bí ó bá jẹ́ pé ẹ̀kún ìbínú rẹ̀ kò lè ṣe àìwá, olódodo ni a ó sì pa mọ́, àní sí ìparun àwọn ọ̀tá wọn nípasẹ̀ iná. Nítorí-èyi, kò yẹ kí olódodo bẹ̀rù; nítorí báyĩ ni wòlĩ nã wí, a ó gbá wọ́n là, àní bí ó bá tilẹ̀ jẹ́ nípasẹ̀ iná.
18 Kíyèsĩ i, ẹ̀yin arákùnrin mi, mo wí fún yín, pé àwọn ohun wọ̀nyí kò lè ṣe àìwá láìpẹ́; bẹ̃ni, àní, ẹ̀jẹ́, àti iná, àti ìkũkú ẽfín kò lè ṣe àìwá; o di dandan ki o wa si ori ilẹ ayé yi; ó sì nwá sọ́dọ̀ àwọn ènìyàn gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara bí ó bá jẹ́ pé àwọn yí sé ọkàn wọn le sí Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì.
19 Nítorí kíyèsĩ i, olódodo kì yíò ṣègbé; nítorí àkókò nã dájúdájú kò lè ṣe àìdé tí a ó ké gbogbo àwọn ẹni tí ndojú ìjà kọ Síónì kúrò.
20 Dájúdájú Olúwa yíò sì pèsè ọ̀nà fún àwọn ènìyàn rẹ̀, sí mímú àwọn ọ̀rọ̀ Mósè ṣẹ, èyí tí ó sọ, wípé: Wòlĩ kan ni Olúwa Ọlọ́run yín gbé sókè sí yín, bí èmi; òun ni kí ẹ̀yin kí ó má gbọ́ ní ohun gbogbo tí yíò má sọ fún yín. Yíò sì ṣe pé gbogbo àwọn ẹni tí kò bá gbọ́ wòlĩ nã ni a ó ké kúrò nínú àwọn ènìyàn.
21 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, sì sọ fún yín, pé wòlĩ yí nípa ẹni tí Mósè sọ̀rọ̀ jẹ́ Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; nítorí-èyi, òun yíò ṣe ìdájọ́ ní òdodo.
22 Kò si yẹ kí olódodo bẹ̀rù, nítorí àwọn ni ẹnití a kò ní parun. Ṣùgbọ́n ìjọba ti èṣù ni, èyí tí a ó kọ́ sókè lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, ìjọba èyí tí a fi kalẹ̀ lãrín wọn tí ó wà nínú ẹran ara—
23 Nítorí àkókò nã yíò dé kánkán tí àwọn ìjọ onígbàgbọ́ gbogbo èyí tí a kọ́ sókè láti ní èrè, àti gbogbo àwọn wọnnì tí a kọ́ sókè láti gba agbára lórí ẹran ara, àti àwọn wọnnì tí a kọ́ sókè láti ni ókìkí ní ojú ayé, àti àwọn wọnnì tí nwá ìfẹ́kúfẹ̃ ti ẹran ara àti àwọn ohun ayé kiri, àti láti ṣe irú àìṣedẽdé gbogbo; bẹ̃ni, ní àkópọ̀, gbogbo àwọn wọnnì tí nṣe ti ìjọba èṣù ni àwọn tí ó yẹ kí ó bẹ̀rù, kí wọ́n sì wàrìrì, kí wọ́n sì gbọ̀n; àwọn ni àwọn wọnnì tí a kò lè ṣe àìmú rẹlẹ̀ nínú ekuru; àwọn ni àwọn wọnnì tí a kò lè ṣe àìrun bí àkékù koríko; èyí sì jẹ́ gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ wòlĩ.
24 Àkókò nã nbọ̀wá kánkán tí a kò lè ṣe àìtọ́ olódodo sókè bí àwọn ẹgbọrọ màlũ inú agbo, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì kò sì lè ṣe àìjọba ní ìjọba, àti agbára, àti ipá, àti ògo nlá.
25 Ó sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ jọ láti igun mẹ́rẹ̀rin ayé; ó sì kaye àgùtàn rẹ̀, wọ́n sì mọ̀ ọ́; yíò sì jẹ́ agbo kan àti olùṣọ́-àgùtàn kan; òun yíò sì bọ́ àwọn àgùtàn rẹ̀, nínú rẹ̀ ni wọn ó sì rí koríko.
26 Àti nítorí ti òdodo àwọn ènìyàn rẹ̀, Sàtánì kò ní agbára; nítorí-èyi a kò lè tú u sílẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún púpọ̀; nítorí kò ní agbára lórí ọkàn àwọn ènìyàn, nítorí wọ́n wà ní òdodo, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì sì njọba.
27 Àti nísisìyí kíyèsĩ, èmi, Nífáì, wí fún yín pé gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí kò lè ṣe àìwá gẹ́gẹ́bí ti ẹran ara.
28 Ṣugbọn, kíyèsĩ i, àwọn orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn gbogbo yíò gbé láìléwu nínú Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì bí ó bá ṣe pé wọ́n ronúpìwàdà.
29 Àti nísisìyí èmi, Nífáì, sì ṣe é dé òpin; nítorí èmí kò tí gbọ́dọ̀ sọ̀rọ̀ síwájú sí i nípa àwọn ohun wọ̀nyí.
30 Nítorí-èyi, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin rò ó wò pé àwọn ohun èyí tí a ti kọ si órí àwọn àwo idẹ jẹ́ òtítọ́; wọ́n sì jẹ́rĩ pé ènìyàn kò lè ṣàì ní ígbọ́ran sí àwọn òfin Ọlọ́run.
31 Nítorí-èyi, kò yẹ kí ẹ ṣèbí pé èmi àti bàbá mi ni ó jẹ́ àwa nìkan tí ó ti jẹ́rĩ, tí ó sì kọ́ wọn pẹ̀lú. Nítorí-èyi, bí ẹ̀yin bá ní ígbọ́ran sí àwọn òfin, tí ẹ sì forítì í dé òpin, a ó gbà yín là ní ọjọ́ ìkẹhìn. Báyĩ ni ó sì rí. Àmín.