Ori 9
Nífáì ṣe ìwé ìrántí sí ọ̀nà méjì—À n pe ọ̀kọ̃kan ní àwọn àwo ti Nífáì—Àwọn àwo nlá ní ìwé ìtàn ti ayé nínú; àwọn kékeré nĩ ṣe pẹ̀lú àwọn ohun mímọ́. Níwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí sì ni bàbá mi rí, tí ó sì gbọ́, tí ó sì sọ, bí ó ṣe gbé nínú àgọ́, ní àfonífojì Lẹ́múẹ́lì, àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nlá sí i, èyí tí kò ṣe é kọ sórí àwọn àwo wọ̀nyí.
2 Àti nísisìyí gẹ́gẹ́ bí mo ti sọ nípa àwọn àwo wọ̀nyí, kíyèsĩ i wọn kì í ṣe àwọn àwo èyí tí mo ṣe kíkún ìwé ìtàn ti ìrántí àwọn ènìyàn mi sórí wọn; nítorí àwọn àwo èyí tí mo ṣe ìwé ìtàn kíkún àwọn ènìyàn mi sórí wọn ni mo ti fún ní orúkọ Nífáì; nítorí-èyi, à n pè wọ́n ní àwọn àwo ti Nífáì, ní àpètẹ̀lé orúkọ tèmi; àwọn àwo wọ̀nyí sì ni à n pè ní àwọn àwo ti Nífáì.
3 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ Olúwa pé kí èmi kí ó ṣe àwọn àwo wọ̀nyí, fún àkànṣe ète pé kí ìwé ìtàn tí a fín nípa ti iṣẹ́ ìránṣẹ́ àwọn ènìyàn mi le wà.
4 Lórí àwọn àwo kejì ni kí a fín ìwé ìtàn ìjọba àwọn ọba sí, àti àwọn ogun àti ìjà àwọn ènìyàn mi; nítorí-èyi àwọn àwo wọ̀nyí wà fún èyí tí ó pọ̀jù ní iṣẹ́ ìránṣẹ́ nã; àwọn àwo kejì sì wà fún èyí tí ó pọ̀jù ní ìjọba àwọn ọba àti àwọn ogun àti ìjà àwọn ènìyàn mi.
5 Nítorí-èyi Olúwa ti pàṣẹ fún mi láti ṣe àwọn àwo wọ̀nyí fún ète òye nínú rẹ̀, ète èyí tí èmi kò mọ̀.
6 Ṣùgbọ́n Olúwa mọ́ ohun gbogbo láti ìbẹ̀rẹ̀; nítorí-èyi, ó pèsè ọ̀nà láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ parí lãrín àwọn ọmọ ènìyàn; nítorí kíyèsĩ i, ó ní gbogbo agbára sí mímú gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ. Báyĩ ni ó sì rí. Àmín.