Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 16


Ori 16

Àwọn ènìyàn búburú ka òtítọ́ sí líle—Àwọn ọmọkùnrin Léhì gbé àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní ìyàwó—Liahónà tọ́ wọn sí ọ̀ná nínú aginjù—Wọ́n nkọ àwọn ọ̀rọ̀ láti ọ̀dọ̀ Olúwa sórí Liahónà láti ìgbà dé ìgbà—Íṣmáẹ́lì kú; ìdílé rẹ̀ nkùn nítorí ìpọ́njú. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, tí fi òpin sí sísọ̀rọ̀ fún àwọn arákùnrin mi, kíyèsĩ wọ́n wí fún mi: Ìwọ ti kéde sí wa àwọn ohun líle, ju èyí tí àwa lè faradà.

2 Ó sì ṣe tí mo wí fún wọn pé mo mọ̀ pé mo ti sọ àwọn ohun líle lòdì sí àwọn ènìyàn búburú, gẹ́gẹ́bí sí òtítọ́; àwọn olódodo sì ni mo ti dá láre, tí mo sì ti ṣe ìjẹ́rì í pé a ó gbé wọn sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn; nítorí èyí, ẹlẹ́ṣẹ̀ ka òtítọ́ sí líle, nítorí ó gún wọn ní ara.

3 Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, bí ẹ̀yin bá ní ódodo tí ẹ sì nfẹ́ láti fetísílẹ̀ sí òtítọ́, tí ẹ sì ní ìkíyèsí sí i, pé kí ẹ̀yin lè rìn dẽdé níwájú Ọlọ́run, njẹ́ ẹ̀yin kò ní kùn nítorí òtítọ́, kí ẹ wípé: Ìwọ sọ àwọn ohun líle lòdì sí wa.

4 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, gba àwọn arákùnrin mi níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ãpọn, láti pa òfin Olúwa mọ́.

5 Ó sì ṣe tí wọn rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa; tóbẹ̃ tí mo ní ayọ̀ àti ìrètí nlá sí wọn, pé kí wọ́n lè rìn ní ọ̀nà òdodo.

6 Nísisìyí, gbogbo nkan wọ̀nyí ni a sọ tí a sì ṣe bí bàba mi ṣe ngbé nínú àgọ́ ní àfonífojì èyí tí ó pè ní Lẹ́múẹ́lì.

7 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, gbé ọ̀kan nínú àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní aya; àti pẹ̀lú, àwọn arákùnrin mi gbé nínú àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní aya; àti pẹ̀lú Sórámù gbé àkọ́bí ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ní aya.

8 Báyĩ í sì ni bàbá mi ti mú gbogbo òfin Olúwa ṣẹ èyí tí a ti fi fún un. Àti pẹ̀lú, èmi, Nífáì, ni Olúwa ti bùkún fún lọ́pọ̀lọpọ̀.

9 Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa wí fún bàbá mi ní òru, ó sì pàṣẹ fún un pé ní ọ̀la kí ó mú ọ̀nà àjò rẹ̀ pọ̀n sínú aginjù.

10 Ó sì ṣe bí bàbá mi ti dìde ní òwúrọ̀, tí ó sì lọ sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ rẹ̀, sí ìyalẹnù rẹ ńlá, o kíyèsí bọ́ọlù àyíká kan ní orí ilẹ, tí ó ní iṣẹ́ ọnà; ó sì jẹ́ ti idẹ tí ó dára. Nínú bọ́ọlù nã sì ni kẹ̀kẹ́ méjì wà; ọ̀kan sì tọ́ka sí ọ̀nà èyítí àwa yíò tọ̀ lọ sínú aginjù.

11 Ó sì ṣe tí a kó jọ lákõpọ̀ àwọn ohun èyíkéyĩ tí àwa yíò gbé lọ sínú aginjù; àti gbogbo ìyókù àwọn ìpèsè tẹ́lẹ̀ èyí tí Olúwa ti fifún wa; a sì mu irúgbìn irú gbogbo tí a lè gbé lọ sínú aginjù.

12 Ó sì ṣe tí a mú àwọn àgọ́ wa tí a sì lọ kúrò sínú aginjù, rékọjá odò Lámánì.

13 Ó sì ṣe tí a rìn ìrìn-àjò fun ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́rin, o fẹ́rẹ̀ jẹ́ níhà agbedeméjì gũsù àti ìlà oòrùn gũsù, ni a sì tún pa àgọ́ wa sí; a sì pe orúkọ ibẹ̀ ní Ṣésà.

14 Ó sì ṣe tí a mú àwọn ọrún wa àti àwọn ọfà wa, a sì jáde lọ sínú aginjù láti pa onjẹ fún àwọn ìdílé wa; lẹ́hìn tí ti pa onjẹ fún àwọn ìdílé wa, a tún padà sí ọ̀dọ̀ àwọn ìdílé wa ní aginjù, sí ibi Ṣésà. A sì tún jáde lọ ní aginjù, à ntẹ̀lé ìhà kannã, à ńtọ apákan aginjù tí ó lọ̃rá jùlọ, èyí tí ó wà ní àwọn etí nítòsí Òkun Pupa.

15 Ó sì ṣe tí a rin ìrìn-àjò fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, à npa onjẹ lẹ́bã ọ̀nà, pẹ̀lú àwọn ọrún wa àti àwọn ọfà wa àti àwọn òkúta wa àti àwọn kànnà-kànnà wa.

16 A sì tẹ̀lé àwọn ìhà bọọlu nã, èyítí ó tọ́ wa ní àwọn apákan aginjù tí o ní ọ̀rá jùlọ.

17 Lẹ́hìn tí a sì ti rin ìrìn-àjó fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, a pa àgọ́ wa fún ìwọ̀n ìgbà díẹ̀, kí àwa tún lè simi kí á sì ní onjẹ fún àwọn ìdílé wa.

18 Ó sì ṣe tí, bí èmi, Nífáì, ti jáde lọ láti pa onjẹ, kíyèsĩ i, mo ṣẹ́ ọrun mi èyítí a fi irin tí ó dára ṣe; àti pé lẹhin tí mo ṣẹ́ ọrun mi, kíyèsĩ i, àwọn arákùnrin mi bínú sí mi nítori àdánù ti ọrun mi, nítorí a kò ní onjẹ.

19 Ó sì ṣe tí a padà láìsí onjẹ sọ́dọ̀ àwọn ìdílé wa, nítorípé wọ́n sì ṣe ãrẹ̀ púpọ̀, nítorí ìrìn àjò wọn, wọ́n jìyà púpọ̀ nítorí àìní onjẹ.

20 Ó sì ṣe tí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì àti àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì bẹ̀rẹ̀sí kùn lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ìjìyà àti ìpọ́njú wọn ní aginjù; àti bàbá mi pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀sí kùn sí Olúwa Ọlọ́run rẹ̀; bẹni, gbogbo wọn sì kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀, gẹ́gẹ́bí wọn ti nkùn sí Olúwa.

21 Nísisìyí ó ṣe tí èmi, Nífáì, nítorí tí mo ti rí ìpọ́njú pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi nítorí ti àdánù ọrun mi, àti nítorí tí àwọn ọrun wọn ti pàdánù nínà wọn, ó bẹ̀rẹ̀sí nira lọ́pọ̀lọpọ̀, bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí a kò lè rí onjẹ.

22 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ̀rọ̀ púpọ̀ sí àwọn arákùnrin mi, nítorí tí wọn tún ti sé àyà wọn le, àní tí wọ́n fi nráhùn sí Olúwa Ọlọ́run wọn.

23 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, láti ara igi mo ṣe ọrun, àti ọfà láti ara igi tí kò wọ́; nítorí-èyi, mo gbé ara mí dì pẹ̀lú ọrun àti ọfà, pẹ̀lú kànnà-kànnà àti pẹ̀lú àwọn òkúta. Mo sì wí fún bàbá mi: Níbo ni èmi yíò lọ láti rí onjẹ?

24 Ò sì ṣe tí ó bèrè lọ́wọ́ Olúwa, nítorí wọ́n ti rẹ ara wọn sílẹ̀ nítorí ti àwọn ọ̀rọ̀ mi; nítorí mo sọ àwọn ohun púpọ̀ sí wọn ní okun-inú ọkàn mi.

25 Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa tọ bàbá mi wá; a sì bá a wí nítõtọ́ nítorí ti kíkùn rẹ̀ sí Olúwa, tóbẹ̃ tí a rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀ sínú ìjìnlẹ̀ ìbànújẹ́.

26 Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa wí fún un: Yí ojú sórí bọ́ọ́lù ná à, kí o sì kíyèsĩ àwọn ohun èyí tí a kọ.

27 Ó sì ṣe tí nígbàtí bàbá mi kíyèsĩ àwọn ohun èyí tí a kọ sórí bọ́ọ́lù ná à, ó bẹ̀rù ó sì wárìrì lọ́pọ̀lọpọ̀, àti àwọn arákùnrin mi àti àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì àti àwọn aya wa pẹ̀lú.

28 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kíyèsĩ àwọn afọ̀nàhàn èyí tí ó wà nínú bọ́ọ́lù ná à, tí wọ́n nṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àti ãpọn àti ìṣọ́ra èyí tí a fifún wọn.

29 Ìkọ̀wé titun ni a sì kọ sórí wọn pẹ̀lú, èyí tí ó ṣe kerekere láti kà, èyí tí ó fún wa ní ìmọ̀ nípa ti àwọn ọ̀nà Olúwa; a sì kọ ọ́ a sì yí i padà láti ìgbà dé ìgbà, gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ àti ãpọn èyítí a fifún wọn. Báyĩ sì ni a rí i pé nípasẹ̀ ọ̀nà kékeré Olúwa lè mú àwọn ohun nlá wá.

30 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, jáde sókè lọ sí orí òkè gíga, gẹ́gẹ́bí ìtọ́ sí ọ̀nà èyí tí a fún wa lórí bọọlu.

31 Ó sì ṣe tí mo pa àwọn ẹranko ìgbẹ́, tóbẹ̃ tí mo rí onjẹ fún àwọn ìdílé wa.

32 Ó sì ṣe tí mo padà sí àgọ́ wa, tí mo gbé àwọn ẹranko èyí tí mo ti pa; àti nísisìyí nígbàtí wọ́n kíyèsĩ i pé mo ti rí onjẹ, báwo ni ayọ̀ wọn ṣe pọ̀ tó! Ó sì ṣe tí wọ́n rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, wọ́n sì fi opẹ́ fún un.

33 Ó sì ṣe tí a tún mú ìrìn-àjò wa pọ̀n, tí à fẹ́rẹ̀ má a rìn ipa ọ̀nà kannã bí ti ìbẹ̀rẹ́ wá; lẹ́hìn tí a sì ti rin ìrìn-àjò fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀ a tún pa àwọn àgọ́ wa, kí á lè dúró lẹ́hìn fún ìwọ̀n ìgbà díẹ̀.

34 Ó sì ṣe tí Íṣmáẹ́lì kú, tí a sì sin ín ní ibi èyí tí à npè ní Néhọ́mù.

35 Ó sì ṣe tí àwọn ọmọbìnrin Íṣmáẹ́lì ṣọ̀fọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí ti òfò ti bàbá wọn, àti nítorí ti ìpọ́njú wọn ní aginjù; wọ́n sì nkùn sí bàbá mi, nítorí ó ti mú wọn jáde wá láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, wọ́n nwípé: Bàbá wa ti kú; bẹ̃ni, a sì ti rìn kiri púpọ̀ ní aginjù, a sì ti faradà ìpọ́njú, ebi, òùngbẹ, àti ãrẹ̀ púpọ̀; lẹ́hìn gbogbo ìjìyà wọ̀nyí a ó sì ṣègbé ní aginjù pẹ̀lú ebi.

36 Báyí sì ni wọ́n kùn sí bàbá mi, àti sí mi pẹ̀lú; wọ́n sì ní ìfẹ́ láti tún padà sí Jerúsálẹ́mù.

37 Lámánì sì wí fún Lẹ́múẹ́lì àti pẹ̀lú fún àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì: Kíyèsĩ i, ẹ jẹ́kí á pa bàbá wa, àti arákùnrin wa Nífáì, ẹni tí ó fi fún ara rẹ̀ láti jẹ́ alákõso wa àti olùkọ́ wa, àwa tí a jẹ́ ẹ̀gbọ́n rẹ̀.

38 Nísisìyí, ó nwípé Olúwa ti sọ̀rọ̀ pẹ̀lú òun, àti pẹ̀lú pé àwọn angẹ́lì ti ṣe ìránṣẹ́ fún òun. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ, a mọ̀ pé ó npurọ́ fún wa; ó sì nsọ àwọn ohun wọ̀nyí, ó sì nṣe àwọn ohun púpọ̀ nípasẹ̀ àwọn ọgbọ́n àrékérekè rẹ̀, kí ó lè tan ojú wa jẹ, ó nronú, bóyá, pé òun lè tọ́ wa kúrò sínú aginjù àjèjì kan; lẹ́hìn tí ó bá sì ti tọ́ wa kúrò, ó ti ronú láti fi ara rẹ̀ ṣe ọba àti alákõso lórí wa, kí ó lè ṣe pẹ̀lú wa gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ àti fãjì rẹ̀. Ní ọ̀nà eleyĩ sì ni arákùnrin mi Lámánì ṣe rú ọkàn wọn sókè sí ìbínú.

39 Ó sì ṣe tí Olúwa wà pẹ̀lú wa, bẹ̃ni, àní ohùn Olúwa wá ó sì sọ àwọn ọ̀rọ̀ púpọ̀ sí wọn; ó sì bá wọn wí lọ́pọ̀lọpọ̀; lẹ́hìn tí a sì bá wọn wí nípasẹ̀ ohùn Olúwa wọ́n yí ìbínú wọn padà kuro, wọ́n sì ronúpìwàdà àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tóbẹ̃ tí Olúwa tún bùkún wa pẹ̀lú onjẹ, tí àwa kò ṣègbé.