Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 2


Ori 2

Léhì mú ìdílé rẹ̀ lọ sínú ijù lẹ́bã Òkun Pupa—Wọ́n fi ohun ìní wọn sílẹ̀—Léhì rúbọ sí Olúwa ó sì kọ́ àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ láti pa àwọn òfin mọ́—Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì kùn sí bàbá wọn—Nífáì ṣe ígbọràn ó sì gbàdúrà ní ìgbàgbọ́; Olúwa bã sọ̀rọ̀, a sì yàn án láti jọba lórí àwọn arákùnrin rẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 600 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Nítorí kíyèsĩ i, ó sì ṣe tí Olúwa bá bàbá mi sọ̀rọ̀, bẹ̃ni, àní nínú àlá, ó sì sọ fún un: Alábùkún fún ni ìwọ Léhì, nítorí àwọn ohun èyí tí ìwọ ti ṣe; àti nítorí ìwọ ti jẹ́ olóotọ́ tí ìwọ sì ti kéde sí àwọn ènìyàn wọ̀nyí, àwọn ohun èyí tí mo pàṣẹ fún ọ, kíyèsĩ i, wọ́n n wá láti mú ẹ̀mí rẹ kúrò.

2 Ó sì ṣe tí Olúwa pàṣẹ fún bàbá mi, àní nínú àlá, pé kí ó mú ìdílé rẹ̀ kí ó sì lọ kúrò sínú ijù.

3 Ó sì ṣe tí ó ṣe ígbọràn sí ọ̀rọ̀ Olúwa, nítorí-èyi, ó ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún un.

4 Ó sì ṣe tí ó lọ kúrò sínú ijù. Ó sì fi ilé rẹ̀ sílẹ̀, àti ilẹ̀ ìní rẹ̀, àti wúrà rẹ̀, àti fàdákà rẹ̀, àti àwọn ohun oníyebíye rẹ̀, kò sì mú ohunkóhun pẹ̀lú rẹ̀, àfi ìdílé rẹ̀, àti àwọn èsè, àti àwọn àgọ́, ó sì lọ kúrò sínú ijù.

5 Ó sì wá sísàlẹ̀ ní ẹ̀bá itòsí èbúté Òkun Pupa; ó sì rin ìrìn-àjo nínú ijù ní ẹ̀bá èyí tí ó wà nítòsí Òkun Pupa; ó sì rin ìrìn-àjò nínú ijù pẹ̀lú ìdílé rẹ̀, èyí tí i ṣe ìyá mi, Sáráíà, àti àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, tí wọ́n jẹ́ Lámánì, Lẹ́múẹ́lì, àti Sãmú.

6 Ó sì ṣe pé nígbà tí ó ti rin ìrìn-àjò ọjọ́ mẹ́ta nínú ijù, ó tẹ àgọ́ rẹ̀ sí àfonífojì lẹ́bã ẹ̀gbẹ́ odò omi kan.

7 Ó sì ṣe tí ó kọ́ pẹpẹ òkúta kan, ó sì ṣe ọrẹ kan sí Olúwa, ó sì fi ọpẹ́ fún Olúwa Ọlọ́run wa.

8 Ó sì ṣe tí ó pe orúkọ odò nã ní, Lámánì, ó sì n ṣàn sínú Òkun Pupa; àfonífojì nã sì wà ní ẹ̀bá itòsí ẹnu rẹ̀.

9 Àti nígbàtí bàbá mi sì rí i wí pé omi odò nã nṣàn sínú ìsun Òkun Pupa, ó wí fún Lámánì, wí pé: À! ìwọ ìbá lè dàbí odò yĩ, tí ó nṣan títí sínú orísun gbogbo ìwà òdodo!

10 Ó sì tún wí fún Lẹ́múẹ́lì: À! ìwọ ìbá lè dàbí àfonífojì yĩ, tí ó wà gbọn-in tí ó sì dúróṣinṣin, tí kò sì lè mì ní pípa àwọn òfin Olúwa mọ́!

11 Nísisìyí èyí ni ó wí nítorí ti ọrùn líle Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì; nítorí kíyèsĩ i wọ́n n kùn sínú ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sí bàbá wọn, nítorí tí ó jẹ́ aríran ọkùnrin, ó sì ti tọ́ wọn jáde ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, láti kúrò ní ilẹ̀ ìní wọn, àti wúrà wọn, àti fàdákà wọn, àti àwọn nkan oníyebíye wọn, láti ṣègbé nínú ijù. Èyí sì ni wọ́n sọ wí pé ó ti ṣe nítorí ti ìrò aláìgbọ́n ọkàn rẹ̀.

12 Báyĩ sì ni Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì, tí wọ́n jẹ́ agba, kùn sì bàbá wọn. Wọ́n sì kùn nítorí tí wọn kò mọ́ ìbálò Ọlọ́run nì, ẹni tí ó dá wọn.

13 Bẹ̃ni wọn kò gbàgbọ́ wí pé Jerúsálẹ́mù, ìlú nla nì, lè parun gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ àwọn wòlĩ. Wọ́n sì dàbí àwọn Jũ tí ó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí wọ́n n wá láti mú ẹ̀mí bàbá mi kúrò.

14 Ó sì ṣe tí bàbá mi bá wọn sọ̀rọ̀ ní àfonífojì Lẹ́múẹ́lì, pẹ̀lú agbára, nítorí tí ó kún fún Ẹ̀mí, títí di ìgbà tí ara wọ́n fi gbọ̀n níwájú rẹ̀. Ó sì dãmú wọn, tí wọn kò fi lè sọ̀rọ̀ lòdì sí i; nítorí-èyi, wọ́n ṣe bí ó ṣe pàṣẹ fún wọn.

15 Bàbá mi sì gbé nínú àgọ́ kan.

16 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, nítorí tí mo jẹ ọmọdé lọ́pọ̀lọpọ̀, bíótilẹ̀ríbẹ̃ tí mo tóbi ní ìnà sókè ènìyàn, àti pẹ̀lú nítorí tí mo ní ìfẹ́ nlá láti mọ̀ nípa àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run, nítorí-èyi, mo kígbe pe Olúwa; sì kíyèsĩ i ó sì bẹ̀ mí wò, ó sì mú ọkàn mi rọ̀ tí mo fi gba gbogbo àwọn ọ̀rọ̀ nã gbọ́, èyí tí bàbá mi ti sọ; nítorí-èyi, èmi kò ṣọ̀tẹ̀ sí i gẹ́gẹ́ bí àwọn arákùnrin mi.

17 Mo sì bá Sãmú sọ̀rọ̀, mo jẹ́ kí ó mọ̀ nípa àwọn ohun tí Olúwa ti fihàn sí mi nípasẹ̀ Ẹ̀mí Mímọ́ rẹ̀. Ó sì ṣe tí ó gba àwọn ọ̀rọ̀ mi gbọ́.

18 Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì kò fẹ́ fetísílẹ̀ sí awọn ọ̀rọ̀ mi; nítorí tí inú mi sì bàjẹ́ nítorí líle ọkàn wọn mo kígbe pe Olúwa fún wọn.

19 Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi, wí pé: Alábùkún-fún ni ìwọ, Nífáì, nítorí ìgbàgbọ́ rẹ, nítorí ìwọ ti wá mi lẹ́sọ̀lẹsọ̀, pẹ̀lú ìrẹ̀lẹ̀ ọkàn.

20 Níwọ̀n bí ìwọ bá sì n pa àwọn òfin mi mọ́, ìwọ yíò ṣe rere, a ó sì ṣe amọ̀nà rẹ lọ sí ilẹ̀ ìlérí kan; bẹ̃ni, àní ilẹ̀ èyí tí mo ti pèsè fún ọ; bẹ̃ni, ilẹ̀ èyí tí ó jẹ́ àṣàyàn ju gbogbo àwọn ilẹ̀ míràn.

21 Níwọ̀n bí àwọn arákùnrin rẹ bá sì n ṣọ̀tẹ̀ sí ọ, a ó gé wọn kúrò níwájú Olúwa.

22 Níwọ̀n bí ìwọ bá sì n pa àwọn òfin mi mọ́, a ó fi ọ́ ṣe alákòso àti olùkọ́ lórí àwọn arákùnrin rẹ.

23 Nítorí kíyèsĩ i, ní ọjọ́ nã tí wọ́n bá ṣọ̀tẹ̀ sí mi, èmi yíò fi wọ́n bú àní pẹ̀lú ìfibú kíkan, nwọn kì yíò sì ní agbára lórí irú-ọmọ rẹ àfi tí wọ́n ó bá ṣọ̀tẹ̀ sí èmi nã pẹ̀lú.

24 Bí ó bá sì ṣe pé wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí mi, wọn yíò jẹ́ pàṣán fún irú-ọmọ rẹ, láti rú wọn sókè ní àwọn ọ̀nà ìrantí.