Ori 17
A pàṣẹ fún Nífáì láti kan ọkọ̀—Àwọn arákùnrin rẹ̀ takò ó—O gbà wọ́n níyànjú nípa ṣíṣe ìtúnsírò ìwé ìtàn ìbálò Ọlọ́run pẹ̀lú Ísráẹ́lì—Nífáì kún fún agbára Ọlọ́run—A ka a lẽwọ̀ fún àwọn arákùnrin rẹ̀ láti fọwọ̀ kàn án, kí wọ́n má bà á rẹ̀ bí ifefe gbígbẹ. Ní ìwọ̀n ọdún 592 sí 591 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Ó sì ṣe tí a tún mú ìrìn-àjò wa pọ̀n sí aginjù; a rin ìrìn-àjò síhà tí ó fẹ́rẹ́ jẹ́ ìlà oòrùn láti ìgbà ná à lọ. A sì rin ìrìn-àjò, a sì fi ìṣòro rìn já ìpọ́njú púpọ̀ ní aginjù; àwọn obìnrin wa sì bí àwọn ọmọ ní aginjù.
2 Títóbi báyĩ sì ni ìbùkún Olúwa lórí wa, pé nígbàtí ẹran tútù jẹ́ oúnjẹ wa ní aginjù, àwọn obìnrin wa fi ọpọ̀lọpọ̀ ọmú fún àwọn ọmọ wọn, wọ́n sì lágbára, bẹ̃ni, àní dàbí àwọn ọkùnrin; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí faradà àwọn rínrin ìrìn-àjò wọn láìsí ìkùnsínú.
3 Báyĩ ni a sì rí i pé àwọn òfin Ọlọ́run ni a gbọ́dọ̀ mú ṣẹ. Bí ó bá sì jẹ́ pé àwọn ọmọ ènìyàn npa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, ó nbọ́ wọn, ó sì nfún wọn ní agbára, ó sì npèsè ọ̀nà nípa èyí tí wọ́n lè ṣe ohun èyí tí ó ti pàṣẹ fún wọn parí; nítorí-èyi, ó pèsè ọ̀nà fún wa nígbàtí a ṣe àtìpó ní aginjù.
4 A sì ṣe àtìpó fún ìwọ̀n ọdún púpọ̀, bẹ̃ni, àní ọdún méjọ ní aginjù.
5 A sì dé ilẹ̀ èyí tí a pè ní Ibi-Ọ̀pọ̀, nítorí ti èso púpọ̀ rẹ̀ àti oyin ìgan pẹ̀lú; gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí sì ni Olúwa pèsè kí àwa má bà á ṣègbé. A sì kíyèsí òkun, èyí tí a pè ní Irreántúmì, èyí tí, ní ìtumọ́, jẹ́ omi púpọ̀.
6 Ó sì ṣe tí a pa àwọn àgọ́ wa sí ẹ̀bá òkun; àti l’áiṣírò a ti jìyà ìpọ́njú púpọ̀ àti ìṣòro púpọ̀, bẹ̃ni, àní púpọ̀ gan an tí a kò lè kọ gbogbo wọn, a mú wa yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀ nígbàtí a dé ẹ̀bá òkun; a sì pe ibi ná à ní Ibi-Ọ̀pọ̀, nítorí ti èso púpọ̀ rẹ̀.
7 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí èmi, Nífáì, ti wà ní ilẹ̀ Ibi-Ọ̀pọ̀ fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, ohùn Olúwa wá sọ́dọ́ mi, wípé: Dìde, kí o sì gun òkè gíga lọ. Ó sì ṣe tí mo dìde tí mo sì gòkè lọ sí òkè gíga, tí mo sì kígbe pe Olúwa.
8 Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi, wípé: Ìwọ yíò kan ọkọ̀ kan, ní ọ̀nà èyí tí èmi yíò fi hàn ọ́, kí emí kí ó lè kó àwọn ènìyàn rẹ rékọjá omi wọ̀nyí.
9 Mo sì ní: Olúwa, níbo ni èmi yíò lọ kí èmi lè rí irin àìpò tútù láti yọ́, kí èmi lè ṣe àwọn ohun èlò láti kan ọkọ̀ ná à ní ọ̀nà èyí tí ìwọ ti fi hàn mí?
10 O sì ṣe tí Olúwa sọ fún mí ibi tí èmi yíò lọ kí èmi lè rí irin àìpò tútù, kí èmi kí o lè ṣe àwọn ohun èlò.
11 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, ṣe ẹwìrì kan pẹ̀lú èyí tí a ó fẹ́ iná ná à, ti awọ ara àwọn ẹranko; lẹ́hìn tí mo sì ti ṣe ẹwìrì, kí èmi lè ní nkan láti fẹ́ ina ná à, mo lu òkúta méjì mọ́ra kí èmi lè ṣe iná.
12 Nítorí Olúwa títí di ìsisìyĩ kò ì tĩ gbà kí àwa kí ó ṣe iná púpọ̀, bí a ṣe nrin ìrìn-àjò ní aginjù; nítorí ó ní: Èmi yíò mú onjẹ yín di dídùn, tí ẹ̀yin kò ní sè é;
13 Èmi yíò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ yín ní aginjù pẹ̀lú; èmi yíò sì pèsè ọ̀nà níwájú yín, bí ó bá ṣe pé ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́; nítorí-èyi, níwọ̀n bí ẹ̀yin bá pa àwọn òfin mi mọ́ a ó tọ́ yín síhà ilẹ̀ ìlérí; ẹ̀yin yíò sì mọ̀ pé nípasẹ̀ mi ni a fi tọ́ yín.
14 Bẹ̃ni, Olúwa sì sọ pẹ̀lú pé: Lẹ́hìn tí ẹ̀yin bá ti dé ilẹ̀ ìlérí, ẹ̀yin yíò mọ̀ pé èmi, Olúwa, ni Ọlọ́run; àti pé èmi, Olúwa, gbà yín lọ́wọ́ ìparun; bẹ̃ni, tí mo mú yín jáde wá láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù.
15 Nítorí-èyi, èmi, Nífáì, gbìyànjú láti pa àwọn òfin Olúwa mọ́, mo sì gbà àwọn arákùnrin mi ní ìyànjú sí ìṣòtítọ́ àti ãpọn.
16 Ó sì ṣe tí mo ṣe àwọn ohun èlò ní ti irin tútù tí mo yọ́ láti inú àpáta.
17 Nígbàtí àwọn arákùnrin mi sì ríi pé mo ti fẹ́ má a kan ọkọ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀sí kùn sí mi, wípé: Arákùnrin wa jẹ́ aṣiwèrè, nítorí ó rò pé òun lè kan ọkọ̀; bẹ̃ni, ó sì rò pẹ̀lú pé òun lè dá omi nlá wọ̀nyí kọjá.
18 Báyĩ sì ni àwọn arákùnrin mi ráhùn sí mi, ti wọ́n sì nfẹ́ pé kí àwọn má lè ṣiṣé, nítorí wọn kò gbàgbọ́ pé mo lè kan ọkọ̀; bẹ̃ni wọn kò fẹ́ gbàgbọ́ pé a fi àṣẹ fún mi nípa ọwọ́ Olúwa.
19 Àti nísisìyí ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kún fún ìbànújẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ti líle ọkàn wọn; àti nísisìyí nígbàtí wọ́n ríi pé mo bẹ̀rẹ̀sí kún fún ìbànújẹ́ wọ́n yọ̀ ní ọkàn wọn, tóbẹ̃ tí wọ́n yọ̀ lórí mi, wípé: Àwa mọ̀ pé ìwọ kò lè kan ọkọ̀, nítorí àwa mọ̀ pé ìwọ ṣe aláìní òye; nítorí-èyi, ìwọ kò lè ṣe iṣẹ́ nlá báyĩ í parí.
20 Ìwọ sì dàbí bàbá wa, tí a tọ́ kúrò nípasẹ̀ èrò aṣiwèrè ti ọkàn rẹ̀; bẹ̃ni, òun ti tọ́ wa jáde kúrò ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, a sì ti sáko ní aginjù fún àwọn ọdún púpọ̀ wọ̀nyí; àwọn obìnrin wa sì ti ṣe lãlã, nítorí tí wọ́n tóbi fún oyún; wọ́n sì ti bí ọmọ ní aginjù; wọ́n sì jìyà ohun gbogbo, àfi ikú; ìbá sì ti dárajù kí wọ́n ti kú kí wọ́n tó jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù ju láti jìyà ìpọ́njù wọ̀nyí.
21 Kíyèsĩ i, ní àwọn ọdún púpọ̀ wọ̀nyí àwa ti jìyà ní aginjù, àkókò èyí ti àwa ìbá ti gbádùn àwọn ìní wa àti ilẹ̀ ogún wa; bẹ̃ni, àwa ìbá sì ti ní inúdídùn.
22 A sì mọ̀ pé àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù jẹ́ olódodo ènìyàn; nítorí wọ́n pa ìlànà àti ìdájọ́ Olúwa mọ́, àti gbogbo àṣẹ rẹ̀, gẹ́gẹ́bí òfin Mósè; nítorínã, àwa mọ̀ pé wọ́n jẹ́ olódodo ènìyàn; bàbá wa sì ti dá wọn léjọ́, ó sì ti tọ́ wa kúrò nítorí tí a fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀; bẹ̃ni, arákùnrin wa sì dàbí òun. Ní irú èdè báyĩ sì ni àwọn arákùnrin mi kùn tí wọ́n sì ráhùn sí wa.
23 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, wí fún wọn, wípé: Ẹ̀yin ha gbàgbọ́ pé a lè tọ́ àwọn bàbá wa, tí wọ́n jẹ́ àwọn ọmọ Isráẹ́lì, jáde kúrò ní ọwọ́ àwọn ará Égíptì bí wọn kò bá fetí sí àwọn ọ̀rọ̀ Olúwa?
24 Bẹ̃ni, ẹ̀yin ha ṣebí à bá ti lè tọ́ wọn jáde ní oko ẹrú, bí Olúwa kò bá pàṣẹ fún Mósè pé kí ó tọ́ wọn jáde ní oko ẹrú?
25 Nísisìyí ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ọmọ Isráẹ́lì wa ní oko ẹrú; ẹ̀yin sì mọ̀ pé a di ẹrù lé wọn pẹ̀lú iṣẹ́, èyí tí o ṣòro láti rù; nítorí-èyi, ẹ̀yin mọ̀ pé ohun rere ni fún wọn ti o si di dandan, pé kí á mú wọn jáde ní oko ẹrú.
26 Nísisìyí ẹ̀yin mọ̀ pé Olúwa pàṣẹ fún Mósè láti ṣe iṣẹ́ nlá nì; ẹ̀yin sì mọ̀ pé nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ àwọn omi Òkun Pupa ni a pín síhĩn àti sọ́hũn, wọ́n sì kọjá lórí ilẹ̀ gbígbẹ.
27 Ṣùgbọ́n ẹ̀yin mọ̀ pé àwọn ará Égíptì rì sínú omi Òkun Pupa, tí wọ́n jẹ́ àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Fáráò.
28 Ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú pe a fi mánnà bọ́ wọn ní aginjù.
29 Bẹ̃ni, ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú pé Mósè, nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́bí agbára Ọlọ́run èyí tí ó wà nínú rẹ̀, lu àpáta, omi sì jáde wá, kí àwọn ọmọ Ísráẹ́lì lè pa òùngbẹ wọn.
30 Àti l’áìṣírò à ntọ́ wọn, tí Olúwa Ọlọ́run wọn, Olùràpadà wọn, nlọ níwájú wọn, tí ó ntọ́ wọn ní ọ̀sán tí ó sì ńfi ìmọ́lẹ̀ fún wọn ní òru, tí ó sì ńṣe ohun gbogbo fún wọn èyí tí ó jẹ́ yíyẹ fún ènìyàn láti gbà, wọ́n sé ọkàn wọn le wọ́n sì fọ́ ojú inú wọn, wọ́n sì nkẹ́gàn Mósè àti Ọlọ́run òtítọ́ àti alãyè.
31 Ó sì ṣe gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó pawọ́n run; ati gẹgẹbi ọrọ rẹ, otọ́ wọn; àti gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó ṣe ohun gbogbo fún wọn; kò sì sí ohun kóhun tí a ṣe bíkòṣe tí ó jẹ nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀.
32 Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti ré odò Jordánì kọjá ó ṣe wọ́n ní alágbára sí dídà sóde àwọn ọmọ ilẹ̀ nã, bẹ̃ni, sí títúká wọn sí ìparun.
33 Àti nísisìyí, ẹ̀yin ha ṣebí àwọn ọmọ ilẹ̀ yí, tí ó wà ní ilẹ̀ ìlérí, tí a dà sóde nípasẹ̀ àwọn bàbá wa, ẹ̀yin ha ṣebí pé wọ́n jẹ́ olódodo? Kíyèsĩ i, mo wí fún yín, Bẹ̃kọ́.
34 Ẹ̀yin ha ṣebí àwọn bàbá wa yíò ti jẹ́ àṣàyàn jùlọ jù wọ́n bí wọ́n bá ti jẹ́ olódodo? Mo wí fún yín, Bẹ̃kọ́.
35 Kíyèsĩ i, Olúwa kà gbogbo ẹran ara sí ọ̀kan; ẹni tí ó bá jẹ́ olódodo yíò rí ojúrere Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, àwọn ènìyán yí ti kọ gbogbo ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì gbó nínú àìṣedẽdé; ẹkún ìbínú Ọlọ́run sì wà lórí wọn; Olúwa sì fi ilẹ̀ nã bú sí wọn, ó sí bùkún fun àwọn bàbá wa; bẹ̃ni, ó fi bú sí wọn sí ìparun wọn, ó sì bùkún un fún àwọn bàbá wa sí gbígba agbára lórí rẹ̀.
36 Kíyèsĩ i, Olúwa ti dá ayé pé kí á lè gbé inú rẹ̀; ó sì ti dá àwọn ọmọ rẹ̀ pé kí wọ́n lè jogún rẹ̀.
37 Ó sì gbé orílẹ̀-èdè olódodo dìde, ó sì pa àwọn orílẹ̀-èdè ènìyan búburú run.
38 Ó sì tọ́ olódodo kúrò sínú àwọn ojúlówó ilẹ̀, ènìyàn búburú ni ó parun, ó sì fi ilẹ̀ bú sí wọn nítorí wọn.
39 Ó jọba níbi gíga ní ọ̀run, nítorípé ó jẹ́ ìtẹ́ rẹ̀, ayé yí sì jẹ́ àpótí ìtìsẹ̀ rẹ̀.
40 Ó sì fẹ́ràn àwọn tí ó bá fẹ́ ẹ láti jẹ́ Ọlọ́run wọn. Kíyèsĩ i, ó fẹ́ràn àwọn bàbá wa, ó sì dá májẹ̀mú pẹ̀lú wọn, bẹ̃ni, àní Ábráhámù, Ísãkì, àti Jákọ́bù; ó sì rántí awọn májẹ̀mú èyítí ó ti ṣe; nítorí-èyi, ó mú wọn jáde kúrò ní ilẹ̀ Égíptì.
41 Ó sì ni wọ́n lára ní aginjù pẹ̀lú ọ̀pá rẹ̀; nítorí wọ́n sé ọkàn wọn le, àní gẹ́gẹ́bí ẹ̀yin ti ṣe; Olúwa sì ni wọ́n lára nítorí àìṣedẽdé wọn. Ó rán àwọn ejò oníná tí nfò sí ãrín wọn; lẹ́hìn tí wọ́n sì ti bù wọ́n ṣán ó pèsè ọ̀nà kí a lè mú wọn lára dá; iṣẹ́ tí wọ́n sì ní láti ṣe ni láti wò; nítorí ti ìrọ̀rùn ọ̀nà nã, tàbí àìnira rẹ̀, ọ̀pọ̀ ni ó wà tí ó ṣègbé.
42 Wọ́n sì sé ọkàn wọn le láti àkókò dé àkókò, wọ́n sì nkẹ́gàn Mósè, àti Ọlọ́run pẹ̀lú; bíótilẹ̀ríbẹ̃, ẹ̀yin mọ̀ pé a tọ́ wọn jáde nípasẹ̀ agbára rẹ̀ aláìlẹ́gbẹ́ sí ilẹ̀ ìlérí.
43 Àti nísisìyí, lẹ́hìn gbogbo àwọn ohun wọ̀nyí, àkókò nã ti dé tí wọ́n ti di búburú, bẹ̃ni, ó kù díẹ̀ sí gbígbó; ó sì lè jẹ́ òtítọ́ pé ní ọjọ́ òní a ti fẹ́ pa wọ́n run; nítorí mo mọ̀ pé ọjọ́ nã yíò dé dájúdájú tí a ó pa wọ́n run, àfi àwọn díẹ̀ péré, tí a ó tọ́ kúrò sí ìgbèkun.
44 Nítorí-èyi, Olúwa pàṣẹ fún bàbá mi pé kí ó lọ kúrò sínú aginjù; àwọn Jũ nã sì nwá láti mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ pẹ̀lú; bẹ̃ni, ẹ̀yin pẹ̀lú sì ti wá láti mú ẹ̀mí rẹ̀ lọ; nítorí-èyi, ẹ̀yin jẹ́ apànìyàn ní ọkàn yín ẹ̀yin sì dábí àwọn.
45 Ẹ̀yin yára láti ṣe àìṣedẽdé ṣùgbọ́n ẹ lọ́ra láti rántí Olúwa Ọlọ́run yín. Ẹ̀yin ti rí angẹ́lì kan, ó sì sọ̀rọ̀ sí yín; bẹ̃ni, ẹ̀yin ti gbọ́ ohùn rẹ̀ láti àkókò dé àkókò; ó sì ti sọ̀rọ̀ sí yín ní ohùn kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ kékeré, ṣùgbọ́n àyà yín le rékọjá, tí ẹ kò lé mọ́ àwọn ọ̀rọ̀ rẹ̀ lára; nítorínã, ó ti sọ̀rọ̀ sí yín tí ó dàbí sísán ãrá, èyí tí ó mú ayé láti mì bí ẹni pé yíò pínníyà.
46 Ẹ̀yin sì mọ̀ pẹ̀lú pé nípasẹ̀ agbára ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ó lágbára jùlọ ó lè mú ayé kí ó rékọjá; bẹ̃ni, ẹ̀yin sì mọ̀ pé nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ ó lè mú àwọn ibi pálapàla láti di dídán, àwọn ibi dídán ni a ó sì fọ́. Njẹ́, nígbànã, ẽṣe, tí ẹ̀yin fi le báyĩ ní ọkàn yín?
47 Kíyèsĩ i, ẹ̀mí mi ni a fà ya pẹ̀lú ìrora nítorí yín, ọkàn mi sì kẹ́dùn; mo bẹ̀rù kí á máṣe ṣá yín tì láéláé. Kíyèsĩ i, mo kún fún Ẹ̀mí Ọlọ́run, tóbéẹ̀ tí ara mi kò ní agbára.
48 Àti nísisìyí sì ṣe pe nígbàtí mo ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ́n bínú sí mi, wọ́n sì fẹ́ láti jù mí sínú ibú òkun; bí wọ́n sì ti wá síwájú láti gbé ọwọ́ lé mi mo wí fún wọn, wípé: Ní orúkọ Ọlọ́run Olódùmarè, mo pàṣẹ fún yín kí ẹ máṣe fọwọ́ kàn mí, nítorí mo kún fún agbára Ọlọ́run, àní sí jíjẹ ẹran ara mi tán; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbé ọwọ́ lé mi yíò gbẹ àní bí ìye gbígbẹ; òun yíò sì jẹ́ bí asán níwájú agbára Ọlọ́run, nítorí Ọlọ́run yíò lù ú.
49 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, wí fún wọn pé kí wọ́n máṣe kùn mọ́ sí bàbá wọn; bẹ̃ni wọn kò gbọ́dọ̀ dá iṣẹ́ wọn dúró fún mi, nítorí Ọlọ́run ti pàṣẹ fún mi pé kí èmi kí ó kan ọkọ̀.
50 Mo sì wí fún wọn: Bí Ọlọ́run bá ti pàṣẹ fún mi láti ṣe ohunkóhun èmi lè ṣe wọ́n. Bí ó bá pàṣẹ fún mi pé kí èmi kí ó wí fún omi yĩ, ìwọ di ilẹ̀, òun yíò di ilẹ̀; bí èmi bá sì sọ ọ́, a ó ṣe é.
51 Àti nísisìyí, bí Olúwa bá ní irú agbára nlá nã, tí ó sì ti ṣe iṣẹ́ ìyanu púpọ̀ lãrín àwọn ọmọ ènìyàn, báwo ní òun kò ní lè fi àṣẹ fún mi, pé kí èmi kí ó kan ọkọ̀ kan?
52 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, sọ àwọn ohun púpọ̀ sí àwọn arákùnrin mi, tóbẹ̃ tí wọ́n dãmú tí wọn kò sì lè dọjú ìjà kọ mí; bẹ̃ni wọn kò gbọ́dọ̀ gbé ọwọ́ wọn lé mi tàbí kí wọ́n tọ́ mi pẹ̀lú àwọn ìka ọwọ́ wọn, àní fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀. Àti nísisìyí wọn kò gbọ́dọ̀ ṣe eleyĩ kí wọ́n má bà á gbẹ níwájú mi, báyĩ ni Ẹ̀mí Ọlọ́run lágbára tó; báyĩ ni ó sì ti ṣe lórí wọn.
53 Ó sì ṣe tí Olúwa wí fún mi: Na ọwọ́ rẹ jáde lẹ̃kejì sí àwọn arákùnrin rẹ, wọn kì yíò sì gbẹ níwájú rẹ, ṣùgbọ́n èmi yíò mú wọn wárìrì, ni Olúwa wí, èyí sì ni èmi yíò ṣe, kí wọn lè mọ̀ pé èmi ni Olúwa Ọlọ́run wọn.
54 Ó sì ṣe tí mo na ọwọ́ mi jáde sí àwọn arákùnrin mi, tí wọn kò sì gbẹ níwájú mi; ṣùgbọ́n Olúwa mì wọ́n, àní gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ èyí tí ó ti sọ.
55 Àti nísisìyí, wọ́n ní: Àwa mọ̀ pẹ̀lú ìdánilójú pè Olúwa wà pẹ̀lu rẹ, nítorí àwa mọ̀ pé agbára Olúwa ni o mì wá. Wọ́n sì wólẹ̀ níwájú mi, wọ́n sì fẹ́ má a foríbalẹ̀ fún mi, ṣùgbọ́n èmi kò yọ̃da fún wọn, mo ní: Mo jẹ́ arákùnrin yín, bẹ̃ni, àní arákùnrin àbúrò yín; nítorí-èyi, ẹ foríbalẹ̀ fún Olúwa Ọlọ́run yín, kí ẹ sì bọ̀wọ̀ fún bàbá òun ìyá yín, kí ọjọ́ yín kí ó lè pẹ́ ní ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín yíò fi fún yín.