Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 13


Ori 13

Nífáì rí ìjọ onígbàgbọ́ ti èṣù tí a gbékalẹ̀ lãrín àwọn Kèfèrí nínú ìran, ó rí àwárí àti ìtẹ ilẹ dó Amẹ́ríkà, ìpàdánù ọ̀pọ̀lopọ̀ abala Bíbélì èyítí ó rí kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye, ipò ìparí ìṣubú-kúrò nínú òtítọ́ àwọn Kèfèrí, ìmúpadà sípò ìhìn-rere, bíbọ̀ jáde ìwé-mímọ́ ti ọjọ́ ìkẹhìn, àti kíkọ́ sókè Síónì. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Wò ó! Mo sì wò mo sì kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìjọba.

2 Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Kíni ìwọ se àkíyèsí? Mo sì wípé: Mo kíyèsí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn ìjọba.

3 Ó sì wí fún mi: Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ-èdè àti àwọn ìjọba àwọn Kèfèrí.

4 Ó sì ṣe tí mo rí ìdásílẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ nlá kan lãrín àwọn orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí.

5 Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Kíyèsí ìdásílẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ kan, èyí tí ó rínilára jùlọ tayọ gbogbo àwọn ìjọ onígbàgbọ́ míràn, èyi tí ó pa àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, bẹ̃ni, tí ó sì fi iya jẹ wọn àti tí ó dè wọ́n mọ́lẹ̀, àti tí ó fi àjàgà kọ́rùn wọn pẹ̀lú àjàgà irin, àti tí ó rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ sínú ìgbèkun.

6 Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára yí; mo sì rí èṣù pé òun ni olùdásílẹ̀ rẹ̀.

7 Bẹ̃gẹ́gẹ́ ni mo sì rí wúrà, àti fàdákà, àti àwọn aṣọ ṣẹ́dà, àti àwọn aláwọ̀ òdòdó, àti aṣọ ọ̀gbọ tí ìlọ́pọ̀ rẹ̀ dára, àti oríṣiríṣi aṣọ wíwọ̀ oníyebíye; mo sì rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn panṣágà obìnrin.

8 Angẹ́lì ná à sì bá mi sọ̀rọ̀ wípé: Kíyèsí wúrà nã, àti fàdákà nã, àti àwọn aṣọ ṣẹ́dà nã, àti àwọn aláwọ òdòdó nã, àti aṣọ ọ̀gbọ tí ìlọ́pọ̀ rẹ̀ dára nã, àti asọ̀ wíwọ̀ oníyebíye nã, àti àwọn panṣágà obìnrin nã, wọ́n jẹ́ ìfẹ́ ijọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára yí.

9 Àti pẹ̀lú nítorí ìyìn ayé ni wọ́n fi run àwọn ènìyàn mímọ́ Ọlọ́run, tí wọ́n sì rẹ̀ wọ́n sílẹ̀ sínú ìgbèkun.

10 Ó sì ṣe tí mo wò tí mo sì kíyèsí omi púpọ̀; wọ́n sì pín àwọn Kèfèrí kúrò ní irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi.

11 Ó sì ṣe tí angẹ́lì ná à wí fún mi: Kíyèsĩ, ìbínú Ọlọ́run wà lórí irú-ọmọ àwọn arákùnrin rẹ.

12 Mo sì wò mo sì kíyèsí ọkùnrin kan lãrín àwọn Kèfèrí nì, ẹni tí omi púpọ̀ nì yà-sọ̀tọ̀ kuro ní irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi; mo sì kíyèsí Ẹ̀mí Ọlọ́run, tí ó sọ̀kalẹ̀ tí ó sì siṣẹ́ lórí ọkùnrin nã; ó sì jáde lọ sórí omi púpọ̀, àní sí ọ̀dọ̀ irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi, tí wọ́n wà ní ilẹ̀ ìlérí.

13 Ó sì ṣe tí mo kíyèsí Ẹ̀mí Ọlọ́run, tí ó siṣẹ́ lórí àwọn Kèfèrí míràn; wọ́n sì ti ìgbèkun jáde wá, sórí omi púpọ̀ nã.

14 Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ọjọ̃rọ àwọn Kèfèrí lórí ilẹ̀ ìlérí; mo sì kíyèsí ìbínú Ọlọ́run, tí ó wà lórí irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi; a sì tú wọn ká níwájú àwọn Kèfèrí, a sì pa wọ́n run.

15 Mo sì kíyèsí Ẹ̀mí Olúwa, tí o wà lórí àwọn Kèfèrí ná à, wọ́n sì ṣe rere, wọ́n sì gba ilẹ̀ ná à fún ìní wọn; mo sì kíyèsĩ pé wọ́n funfun, wọ́n sì dára, wọ́n sì lẹ́wà lọ́pọ̀lọpọ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn mi kí a tó pa wọ́n.

16 Ó sí ṣe tí èmi, Nífáì, kíyèsĩ i, tí àwọn Kèfèrí tí ó ti jáde lọ kúrò nínú ìgbèkun rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa; agbára Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn.

17 Mo sì kíyèsĩ i pé àwọn ìyá Kèfèrí wọn jùmọ̀ péjọ sórí omi, àti sórí ilẹ̀ pẹ̀lú, láti dojú ìjà kọ wọ́n.

18 Mo sì kíyèsĩ i pé agbára Ọlọ́run wà pẹ̀lú wọn, àti pẹ̀lú pé ìbínú Ọlọ́run wà lórí gbogbo àwọn tí wọ́n jùmọ̀ péjọ láti dojú ìjà kọ wọ́n.

19 Èmi, Nífáì, sì kíyèsĩ i pé àwọn Kèfèrí tí ó tí lọ kúrò nínú ìgbèkun ni a gbà nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run kúrò ní ọwọ́ gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè míràn.

20 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, kíyèsĩ i pe wọ́n ṣe rere ní ilẹ̀ ná à; mo sì kíyèsí ìwé kan, a sì gbé e kiri lãrín wọn.

21 Angẹ́lì ná à sì wí fún mi: Ìwọ́ mọ́ ìtumọ̀ ìwé ná à bí?

22 Mo sì wí fún un: Èmi kò mọ̀.

23 Ó sì wí pé: Kíyèsĩ i, ó jáde láti ẹnu Jũ kan. Èmi, Nífáì, sì kíyèsĩ; ó sì wí fún mi: Ìwé tí ìwọ kíyèsĩ jẹ́ ìwé-ìrántí àwọn Jũ, èyí tí ó ní májẹ̀mú Olúwa nínú, èyí tí ó ti ṣe sí ará ilé Isráẹ́lì; ó sì tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ìsọtẹ́lẹ́ àwọn wòlĩ mímọ́ nínú; ó sì jẹ́ ìwé-ìrántí tí ìfín tí ó wà lórí àwọn àwo idẹ, àfi pé kò pọ̀ tó bẹ̃; bíótilẹ̀ríbẹ̃, wọ́n ní awọn májẹ̀mú Olúwa nínú, èyí tí ó ti ṣe sí ará ilé Isráẹ́lì; nítorí-èyi, wọ́n jẹ́ iye nlá sí àwọn Kèfèrí.

24 Angẹ́lì Olúwa ná à sì wí fún mi: Ìwọ ti kíyèsĩ i pé ìwé ná à jáde kúrò láti ẹnu Jũ kan; nígbàtí ó sì jáde kúrò láti ẹnu Jũ kan ó kún fún ẹ̀kún ìhìn-rere Olúwa, nípa ẹnití àwọn àpóstélì méjẽjìlá jẹ́rĩ; wọ́n sì jẹ́rĩ gẹ́gẹ́bí òtítọ́ èyítí mbẹ nínú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run.

25 Nítorí-èyi, àwọn ohun wọ̀nyí jáde lọ lọ́wọ́ àwọn Jũ ní mímọ́ sí àwọn Kèfèrí, gẹ́gẹ́bí òtítọ́ èyí tí ó mbẹ nínú Ọlọ́run.

26 Lẹ́hìn tí wọ́n sì jáde lọ láti ọ́wọ́ àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, láti ọwọ́ àwọn Jũ sí àwọn Kèfèrí, ìwọ rí ìdásílẹ̀ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára, èyí tí o rínilára ga ju gbogbo àwọn ìjọ onígbàgbọ́ míràn lọ; nítorí kíyèsĩ i, wọ́n ti mú kúrò nínú ìhìn-rere Ọ̀dọ́-àgùtàn ọ̀pọ̀lọpọ̀ abala èyítí ó rí kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye jùlọ; àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ májẹ̀mú Olúwa ni wọ́n ti mú kúrò.

27 Gbogbo èyí ni wọ́n sì ti ṣe kí wọn kí ó lè yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po, kí wọn kí ó lè fọ́ ojú, kí wọ́n sì sé àyà àwọn ọmọ ènìyàn le.

28 Nítorí-èyi, ìwọ rí wípé lẹ́hìn tí ìwé ná à ti jáde lọ nípa ọwọ́ ìjọ onígbàgbọ́ nlá tí ó sì rínilára ná à, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun tí wọ́n rí kerekere tí wọ́n sì jẹ́ iyebíye ni ó wà tí a mú kúrò nínú ìwé ná à, èyí tí ó jẹ́ ìwé Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run.

29 Lẹ́hìn tí a sì ti mú àwọn ohun kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye wọ̀nyí kúrò, ó jáde lọ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí; lẹ́hìn tí ó sì jáde lọ sí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè àwọn Kèfèrí tán, bẹ̃ni, àní rékọjá omi púpọ̀ èyí tí ìwọ ti rí pẹ̀lú àwọn Kèfèrí èyí tí ó ti jáde lọ kúrò ní ìgbèkun, ìwọ rí i—nítorítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ohun kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye èyí tí a ti mú kúrò nínú ìwé ná à, èyí tí ó wà kerekere sí ìmọ̀ àwọn ọmọ ènìyàn, gẹ́gẹ́bí ti kerekere èyí tí ó wà nínú Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run—nítorí ti àwọn ohun wọ̀nyí tí a mú jáde kúrò nínú ìhìn-rere Ọ̀dọ́-àgùtàn, ọ̀pọ̀ nlá lọ́pọ̀lọpọ̀ ni ó kọsẹ̀, bẹ̃ni, tóbẹ̃ tí Sátánì ní agbára nlá lórí wọn.

30 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, ìwọ kíyèsí pé àwọn Kèfèrí tí o ti jáde lọ kuro nínú ìgbèkun, tí a sì ti gbé sókè nípasẹ̀ agbára Ọlọ́run ga ju gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè míràn lọ, lórí ojú ilẹ̀ èyí tí ó jẹ́ àsàyàn ga ju gbogbo àwọn ilẹ̀ míràn lọ, èyí tí ó jẹ́ ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run ti fi dá májẹ̀mú pẹ̀lú bàbá rẹ pé irú-ọmọ rẹ̀ yíò ní i fún ilẹ̀ ogún wọn; nítorí-èyi, ìwọ rí i pé Olúwa Ọlọ́run kì yíò jẹ ki àwọn Kèfèrí pa àdàpọ̀ irú-ọmọ rẹ run pátápátá, èyí tí o wà lãrín àwọn arákùnrin rẹ.

31 Bẹ̃ni òun kì yíò jẹ́ kí àwọn Kèfèrí pa irú-ọmọ àwọn arákùnrin rẹ run.

32 Bẹ̃ni Olúwa Ọlọ́run kì yíò jẹ́ kí àwọn Kèfèrí dúró títí láé nínú ipò ìfọ́jú búburú nã, èyí tí ìwọ kíyèsĩ pé wọ́n wà nínú rẹ̀, nítorítí àwọn abala ìhìn-rere Ọ̀dọ́-àgùtàn tí ó rí kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye jùlọ èyí ti ìjọ onígbàgbọ́ tí ó rínilára ná à ti pamọ́ sẹ́hìn, ìdásílẹ̀ èyí tí ìwọ ti rí.

33 Nítorí-èyi ni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run sọ wípé: Èmi yíò ni ãnú sí àwọn Kèfèrí, sí bíbẹ̀wò ìyókù ará ilé Isráẹ́lì ní ìdájọ́ nlá.

34 Ó sì ṣe tí angẹ́lì Olúwa ná à bá mi sọ̀rọ̀, wípé: Kíyèsĩ, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ná à wí, lẹ́hìn tí mo bá ti bẹ ìyókù ará ilé Isráẹ́lì wò—ìyókù yí nípa ẹni tí èmi sọ̀rọ̀ sì jẹ́ irú-ọmọ bàbá rẹ—nítorí-èyi, lẹ́hìn tí mo bá bẹ̀ wọ́n wò ní ìdájọ́, tí a sì kọlũ wọ́n nípa ọwọ́ àwọn Kèfèrí, lẹ́hìn tí àwọn Kèfèrí ná à sì kọsẹ̀ làpọ̀jù, nítorí ti àwọn abala ìhìn-rere Ọ̀dọ́-àgùtàn tí o rí kerekere tí ó sì jẹ́ iyebíye jùlọ èyí tí a ti pamọ́ sẹ́hìn nípa ọwọ́ ìjọ onígbàgbọ́ tí o rínilára ná à, èyí tí ó jẹ́ ìyá àwọn panṣágà obìnrin, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à wí—Èmi yíò ni ãnú sí àwọn Kèfèrí ní ọjọ́ ná à, tóbẹ̃ tí èmi yíò mú jáde sí wọn, ní agbára ọwọ́ ara tèmi, púpọ̀ nínú ìhìn-rere mi, èyí tí yíò jẹ́ kerekere àti iyebíye, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à wí.

35 Nítorí, kíyèsĩ, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à wí: Èmi yíò fi ara mi hàn sí irú-ọmọ rẹ, tí wọn yíò kọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun èyí tí èmi yíò jíṣẹ́ sí wọn, èyí tí yíò jẹ́ kerekere àti iyebíye; lẹ́hìn tí a bá sì pa irú-ọmọ rẹ run, tí wọ́n sì rẹ́hìn nínú ìgbàgbọ́, àti irú-ọmọ àwọn arákùnrin rẹ pẹ̀lú, kíyèsĩ, àwọn ohun wọ̀nyí ni wọn yíò pamọ́, láti jáde wá sí àwọn Kèfèrí, nípasẹ̀ ẹ̀bùn àti agbára Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à.

36 Nínú wọn ni a ó sì kọ ìhìn-rere mi sí, ni Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à wí, àpáta mi àti ìgbàlà mi.

37 Alábùkún-fún ni àwọn ẹni tí yíò wá láti mu Síónì mi jáde wá ní ọjọ́ ná à, nítorí wọn ó ní ẹ̀bùn àti agbára Ẹ̀mí Mímọ́; bí wọ́n bá sì rọ́jú dé òpin a ó gbé wọn sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn, a ó sì gbà wọ́n là ní ìjọba àìlópin Ọ̀dọ-àgùtàn; ẹnikẹ́ni tí ó bá sì kéde àlãfíà, bẹ̃ni, ìhìn ayọ̀ nlá, báwo ni wọn yíò lẹ́wà tó lórí àwọn òkè gíga.

38 Ó sì ṣe tí mo kíyèsí ìyókù irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi, àti pẹ̀lú ìwé Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run, èyí tí ó ti jáde lọ síwájú láti ẹnu àwọn Jũ, pé ó jáde wá lọ́wọ́ àwọn Kèfèrí sí ìyókù irú-ọmọ àwọn arákùnrin mi.

39 Lẹ́hìn tí ó sì ti jáde wá sí wọn mo kíyèsí àwọn ìwé míràn, èyí tí o jáde wá nípasẹ̀ agbara Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à, láti ọwọ́ àwọn Kèfèrí sí wọn, sí yíyí lọ́kàn padà àwọn Kèfèrí àti ìyóku iru-ọmọ àwọn arákùnrin mi, àti pẹ̀lú àwọn Jũ ti a túká sórí gbogbo ori ilẹ àgbáyé, pe àwọn ìwé ìrántí ti àwọn wòlĩ àti ti àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn jẹ́ òtítọ́.

40 Angẹ́lì ná à sì wí fún mi, wípé: Àwọn ìwé ìrántí ìkẹhìn wọ̀nyí, èyí tí ìwọ ti rí lãrín àwọn Kèfèrí, yíò fi ìdí òtítọ́ ti èkíní mulẹ̀, èyí ti o jẹ́ ti àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn, yíò sì sọ àwọn ohun kerekere àti iyebíye náà di mímọ̀ èyí tí a ti gbà kúrò lọ́wọ́ wọn; tí a ó sì sọ di mímọ̀ sí gbogbo àwọn ìbátan, èdè, àti ènìyàn, pé Ọ̀dọ́-àgùtàn Ọlọ́run ná à jẹ́ Ọmọ Bàbá Ayérayé, àti Olùgbàlà ayé; àti pé gbogbo ènìyàn gbọ́dọ̀ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, bíbẹ̃kọ́ a kò lè gbà wọ́n là.

41 Wọ́n sì gbọ́dọ̀ wá gẹ́gẹ́bí àwọn ọ̀rọ̀ èyí tí a ó fi múlẹ̀ lati ẹnu Ọ̀dọ́-àgùtàn; àwọn ọ̀rọ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à ni a ó sì sọ di mímọ̀ nínú àwọn ìwé ìrántí irú-ọmọ rẹ, àti gẹ́gẹ́ bẹ̃ ná à nínú àwọn ìwé ìrántí àwọn àpóstélì méjìlá ti Ọ̀dọ́-àgùtàn ná à; nítorí-èyi àwọn méjẽjì ni a ó fi múlẹ̀ nínú ẹyọ̀kan; nítorí Ọlọ́run kan àti Olùṣọ́-àgùtàn kan ni ó wà lórí gbogbo ayé.

42 Ìgbà ná à sì mbọ̀ tí òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí gbogbo orílẹ̀-èdè, àti sí àwọn Jũ àti pẹ̀lú sí àwọn Kèfèrí; lẹ́hìn tí ó bá sì ti fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn Jũ àti pẹ̀lú sí àwọn Kèfèrí, nígbànã ni òun yíò fi ara rẹ̀ hàn sí àwọn Kèfèrí àti pẹ̀lú sí àwọn Jũ, àwọn ẹni ìkẹ́hìn yíò sì di ti àkọ́kọ́, ti àkọ́kọ́ yíò sì di ti ìkẹhìn.