Ori 5
Sáráíà ráhùn sí Léhì—Àwọn méjẽjì yọ̀ lórí ìpadàbọ̀ àwọn ọmọkùnrin wọn—Wọ́n rú ẹbọ—Àwọn àwo idẹ nã ní àkọsílẹ̀ ti Mósè àti àwọn wòlĩ nínú—Àwọn àwo nã fihàn pé Léhì jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù—Léhì sọtẹ́lẹ̀ nípa irú-ọmọ rẹ̀ àti nípa ìpamọ́ àwọn àwo nã. Ní ìwọ̀n ọdún 600 sí 592 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí a ti sọ̀kalẹ̀ sínú ijù sí ọ̀dọ̀ bàbá mi, kíyèsĩ i, ó kún fún ayọ̀, àti ìyá mi, Sáráíà pẹ̀lú, yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, nítorí nítõtọ́ ó ti ṣọ̀fọ̀ nítorí wa.
2 Nítorí ó ti ṣèbí a ti ṣègbé nínú ijù; ó sì tún ti ráhùn sí bàbá mi, tó sọ fún un wí pé a-ríran ọkùnrin ni; ó wí pé: Kíyèsĩ i ìwọ ti tọ́ wa kúrò nínú ilẹ̀ ìní wa, àwọn ọmọkùnrin mi kò sì sí mọ́, a sì ṣègbé nínú ijù.
3 Irú èdè báyĩ sì ni ìyá mi ti fi ráhùn sí bàbá mi.
4 Ó sì ti ṣe tí bàbá mi sọ fún un, wí pé: Mo mọ̀ wí pé mo jẹ́ aríran ọkùnrin; nítorí bí kò bá ṣe pé èmi ti rí àwọn ohun Ọlọ́run nínú ìran èmi ìbá má mọ́ õre Ọlọ́run, ṣùgbọ́n èmi ìbá ti dúró-lẹ́hìn ní Jerúsálẹ́mù, èmi ìbá sì ti ṣègbé pẹ̀lú àwọn arákùnrin mi.
5 Ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, èmi ti gba ilẹ̀ ìlérí, nínú àwọn ohun èyí tí mo n yọ̀; bẹ̃ni, èmi sì mọ̀ wí pé Olúwa yíò gba àwọn ọmọkùnrin mi kúrò ní ọwọ́ Lábánì, yíò sì tún mú wọn sọ̀kalẹ̀ sí ọ̀dọ̀ wa nínú ijù.
6 Irú èdè báyĩ sì ni bàbá mi, Léhì, fi tu ìyá mi, Sáráíà, nínú nípa wa, ní àkókò tí a rin ìrìn-àjò nínú ijù sókè lọ sí ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù, láti gba ìwé ìrántí àwọn Jũ.
7 Nígbà tí a sì ti padà sí àgọ́ bàbá mi, kíyèsĩ i ayọ̀ wọn kún, a sì tu ìyá mi nínú.
8 Ó sì sọ̀rọ̀, wí pé: Nísisìyí mo mọ̀ ní ìdánilójú wí pé Olúwa ti pá láṣẹ fún ọkọ mi láti sá sí inú ijù; bẹ̃ni, mo sì tún mọ̀ ní ìdánilójú wí pé Olúwa ti dãbò bò àwọn ọmọkùnrin mi, ó sì gbà wọ́n kúrò ní ọwọ́ Lábánì, ó sì ti fún wọn ní agbára nípa èyí tí wọ́n lè fi parí ohun tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn. Irú èdè báyĩ ni ó sì sọ.
9 Ó sì ṣe tí wọ́n sì yọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, wọ́n sì rú ẹbọ àti ẹbọ-ọrẹ sísun sí Olúwa; wọ́n sì fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Isráẹ́lì.
10 Lẹ́hìn tí wọ́n sì ti fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run Isráẹ́lì, bàbá mi, Léhì, gba àwọn ìwé ìrántí nã èyí tí a fín sórí àwọn àwo idẹ, ó sì yẹ̀ wọ́n wò láti ìbẹ̀rẹ̀.
11 Ó sì ṣe àkíyèsí wí pé wọ́n ní àwọn ìwé márun ti Mósè nínú, èyí tí ó pèsè ìwé ìtàn ẹ̀dá ayé àti pẹ̀lú ti Ádámù àti Éfà, àwọn tí wọ́n jẹ́ òbí wa èkíní;
12 Àti pẹ̀lú ìwé ìrántí àwọn Jũ láti àtètèkọ́ṣe, àní títí di ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sẹdẹkíàh, ọba Júdà;
13 Àti pẹ̀lú àwọn ìsọtẹ́lẹ̀ àwọn wòlĩ mímọ́, láti àtètèkọ́ṣe, àní títí di ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Sẹdẹkíàh; àti pẹ̀lú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìsọtẹ́lẹ̀ èyí tí a ti sọ láti ẹnu Jeremíàh.
14 Ó sì ṣe pé bàbá mi, Léhì, tún rí ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀ lórí àwọn àwo idẹ nã; nítorí-èyi ó mọ̀ wí pé òun jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù; bẹ̃ ni, àní Jósẹ́fù nì, ẹni tí ó jẹ́ ọmọ Jákọ́bù, ẹni tí a tà sí Égíptì, ẹni tí a sì pamọ́ nípa ọwọ́ Olúwa, kí ó lè ṣe ìpamọ́ bàbá rẹ̀, Jákọ́bù, àti gbogbo agbolé rẹ̀ kúrò nínú ṣíṣègbé pẹ̀lú ìyàn.
15 A sì tọ́ wọn kúrò ní ìgbèkun àti kúrò ní ilẹ̀ Égíptì, nípa ọwọ́ Ọlọ́run kan nã ẹni tí ó ti pa wọ́n mọ́.
16 Báyĩ sì ni bàbá mi, Léhì, ṣe mọ̀ nípa ìtàn ìdílé àwọn bàbá rẹ̀. Lábánì sì jẹ́ àtẹ̀lé Jósẹ́fù pẹ̀lú, nítorínã ni òun àti àwọn bàbá rẹ̀ ṣe tọ́jú àwọn ìwé ìrántí nã.
17 Àti nísisìyí nígbà tí bàbá mi rí gbogbo àwọn nkan wọ̀nyí, ó kún fún Ẹ̀mí, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sọtẹ́lẹ̀ nípa irú-ọmọ rẹ̀—
18 Wí pé àwọn àwo idẹ wọ̀nyí yíò jáde lọ sí gbogbo orílẹ̀-èdè, ìbátan, èdè, àti ènìyàn tí ó jẹ́ ti irú-ọmọ rẹ̀.
19 Nítorí-èyi, ó sọ wí pé àwọn àwo idẹ wọ̀nyí kì yíò ṣègbé láé; bẹ̃ni wọn kì yíò farasin ní ọ̀nàkọnà nípasẹ̀ àkókò. Ó sì sọtẹ́lẹ̀ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun nípa irú-ọmọ rẹ̀.
20 Ó sì ṣe tí títí di báyĩ èmi àti bàbá mi ti pa àwọn òfin nã mọ́ èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa.
21 A sì ti gba àwọn ìwé ìrántí nã èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa, a sì ti yẹ̀ wọ́n wò fínni-fínni a sì ri wí pé wọ́n yẹ ní fífẹ́; bẹ̃ni, àní wọ́n jẹ́ iye nlá sí wa, níwọ̀n tí àwa fi lè ṣe ìtọ́jú àwọn òfin Olúwa fún àwọn ọmọ wa.
22 Nítorí-èyi, ó jẹ́ ọgbọ́n nínú Olúwa wí pé kí á gbé wọn pẹ̀lú wa, bí a ṣe n rin ìrìn-àjò nínú ijù síhà ilẹ̀ ìlérí.