Ori 20
Olúwa fi àwọn èté rẹ̀ hàn sí Isráẹ́lì—A ti yan Isráẹ́lì nínú ìlérú ìpọ́njú, yíò sì jáde lọ kúrò ní Bábílọ́nì—Fi wé Isaiah 48. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa.
1 Fetísílẹ̀ kí ẹ sì gbọ́ èyí, A! ilé Jákọ́bù, ẹ̀yin tí à nfi orúkọ Isráẹ́lì pe, tí ó sì ti inú omi Júdà wọnnì jáde wá, tàbí ti inú omi ìrìbọmi wá, tí ó nfi orúkọ Olúwa búra, tí ó sì ndárúkọ Ọlọ́run Isráẹ́lì, síbẹ̀síbẹ̀ wọn kò búra ní òtítọ́ tàbí ní òdodo.
2 Bíótilẹríbẹ̃, wọ́n npe ara wọn ní ti ìlú mímọ́ nì, ṣùgbọ́n wọn kò gbé ara wọn lé Ọlọ́run Isráẹ́lì, ẹni tí o jẹ́ Olúwa àwọn Ọmọ-ogun; bẹ̃ni, Olúwa àwọn Ọmọ-ogun ni orúkọ rẹ̀.
3 Kíyèsĩ i, èmi ti kéde ohun ti ìṣãjú wọnnì láti ìpilẹ̀sẹ̀; wọ́n sì jáde lọ láti ẹnu mi, mo sì fi wọ́n hàn. Èmi fi wọ́n hàn lójijì.
4 Èmi sì ṣe é nítorí mo mọ̀ pé olórí-líle ni ìwọ, ọrùn rẹ sì jẹ́ iṣan irin, àti iwájú rẹ idẹ;
5 Mo sì tilẹ̀ ti kede fún ọ láti ìbẹ̀rẹ̀ wa; kí ó tó ṣẹlẹ̀ ni èmi ti fi wọ́n hàn ọ́; èmi sì fi wọ́n hàn kí ìwọ má bà á wípé—òrìṣà mi ni ó ṣe wọ́n, àti ère mi gbígbẹ́, àti ère mi dídà ni ó ti pàṣẹ fún wọn.
6 Ìwo sì ti rí, ati ti o si gbọ gbogbo ohun yi; ìwọ ki yíò sì ha kede wọ́n? Àti pé èmi ti fi awọn ohun titun hàn ọ́ láti ìgbà yí lọ, àní awọn ohun tí ó pamọ, ìwọ ko sì mọ̀ wọ́n.
7 A dá wọn nísisìyí, kì í sì ṣe ni àtètèkọ́ṣe, àní ṣãjú ọjọ́ tí ìwọ kò gbọ́ wọn a kede wọ́n fún ọ, kí ìwọ má bà á wípé—Kíyèsĩ i èmi mọ̀ wọ́n.
8 Bẹ̃ni, ìwọ kò sì gbọ́; bẹ̃ni, ìwọ kò mọ̀; bẹ̃ni, láti ìgbà nã etí rẹ kò ṣí; nítorí tí èmi mọ̀ pè íwọ yíò hùwà àrékérekè gan-an, a sì pè ọ ní olùrékọjá láti inú wá.
9 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, nítorí orúkọ mi èmi ó mú ìbínú mi pẹ́, àti nítorí ìyìn mi, èmi o fàsẹ́hìn kúrò lọ́dọ̀ rẹ, kí èmi má bà á ké ọ kúrò.
10 Nítorí, kíyèsĩ i, èmi ti tún ọ́ dá, èmi ti yàn ọ nínú iná ìlérú ìpọ́njú.
11 Nítorí èmi tìkárãmi, bẹ̃ni, nítorí èmi tìkárãmi ni èmi yíò ṣe èyí, nítorí èmi kì yíò jẹ́ kí á bá orúkọ mi jẹ́, èmi kì yíò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn.
12 Fetísílẹ̀ sí mi, A! Jákọ́bù, àti Isráẹ́lì ẹni-ìpè mi, nítorí èmi nã ni; èmi ni ẹni-ìkíní, èmi sì ni ẹni-ìkẹhìn pẹ̀lú.
13 Ọwọ́ mi ti fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ pẹ̀lú, àtẹ́lewọ́ ọ̀tún mi sì ti na àwọn ọ̀run. Mo pè wọ́n, wọ́n sì jùmọ̀ dìde dúró.
14 Gbogbo yín, ẹ péjọ, ẹ sì gbọ́; tani nínú wọn tí ó ti sọ nkan wọ̀nyí sí wọn? Olúwa ti fẹ́ ẹ; bẹ̃ni, òun yíò sì mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ èyí tí ó ti kéde nípasẹ̀ wọn; òun yíò sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀ ní Bábílọ́nì, apá rẹ̀ yíò sì wá sí órí àwọn ará Káldéà.
15 Bẹ̃gẹ́gẹ́, ni Olúwa wí; èmi Olúwa, bẹ̃ni, èmi ti sọ̀rọ̀; bẹ̃ni, èmi ti pẽ láti kede, èmi ti mú u wá, òun yíò sì mú ọ̀nà rẹ̀ ṣe dẽdé.
16 Ẹ súnmọ́ ọ̀dọ̀ mi; èmi kò sọ̀rọ̀ ní ìkọ̀kọ̀; láti ìpílẹ̀sẹ̀, láti ìgbà tí a ti kéde rẹ̀ ni èmi ti sọ ọ́; Olúwa Ọlọ́run àti Ẹ̀mí rẹ̀, ni ó rán mi.
17 Báyĩ sì ni Olúwa wí, Olùràpadà rẹ, Ẹní Mímọ́ Isráẹ́lì; èmi ti rán an, Olúwa Ọlọ́run rẹ ẹni tí ó kọ́ ọ láti jèrè, ẹni tí o tọ́ ọ ní ọ̀nà tí ó yẹ kí ìwọ lọ, ti ṣe é.
18 A! ìbá ṣe pé ìwọ fi etí sí awọn òfin mi—nígbànã ni àlãfíà rẹ ìbá dàbí odò, àti òdodo rẹ bí àwọn ìgbì-omi òkun.
19 Irú-ọmọ rẹ pẹ̀lú ìbá dàbí iyanrìn; ọmọ-bíbí inú rẹ bí tãrá rẹ̀; a kì bá ti ké orúkọ rẹ̀ kúrò tabi párun níwájú mi.
20 Ẹ jáde kúrò ní Bábílọ́nì, ẹ sá kúrò lọ́dọ̀ àwọn ará Káldéà, pẹ̀lú ohùn orin ẹ kede, sọ èyí, sọ́ jáde títí dé òpin ayé; ẹ wípé: Olúwa ti ra Jákọ́bù ìránṣẹ́ rẹ̀ padà.
21 Òungbẹ kò sì gbẹ wọ́n; ó mú wọn la aginjù wọnnì já; ó mú omi ṣàn jáde láti inú àpáta fún wọn; ó sán àpáta pẹ̀lú, omi sì tú jáde.
22 Àti l’áìṣírò ó ti ṣe gbogbo èyí, àti èyítí ó tóbijũ pẹ̀lú, àlãfíà kò sí, ni Olúwa wí, fún àwọn ènìyàn búburú.