Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 18


Ori 18

A parí ọkọ́ nã—A ṣe ìrántí ìbí Jákọ́bù àti Jósẹ́fù—Ọ̀wọ́ nã wọkọ̀ fún ilẹ̀ ìlérí—Àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì àti àwọn aya wọn dàpọ̀ ní àríyá-aláriwo àti ọ̀tẹ̀—A di Nífáì, ẹ̀fũfù nlá kan tí ó banilẹ́rù sì darí ọkọ̀ nã sẹ́hìn—A sọ Nífáì di ẹni òmìnira, nípasẹ̀ àdúrà rẹ̀ ìjì nã sì dáwọ́dúró—Àwọn ènìyàn nã dé ilẹ̀ ìlérí. Ní ìwọ̀n ọdún 591 sí 589 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí wọ́n foríbalẹ̀ fún Olúwa, tí wọ́n sì jáde lọ pẹ̀lú mi; a sì ṣe àwọn igi rírẹ́ ni aláràbarà iṣẹ́ ọnà. Olúwa sì nfi hàn mí láti àkókò dé àkókò bí èmi yíò ṣe ṣe àwọn igi rírẹ́ ọkọ̀ nã.

2 Nísisìyí èmi, Nífáì, kò ṣe àwọn igi rírẹ́ nã bí èyí tí àwọn ènìyàn kọ́, ní ìkọ́ṣẹ́ bẹ̃ni èmi kò kan ọkọ̀ nã bí ti àwọn ènìyàn; ṣùgbọ́n mo kan bí èyí tí Olúwa tí fi hàn sí mi; nítorí-èyi, kì í ṣe bí ti àwọn ènìyàn.

3 Èmi, Nífáì, sì lọ sí òkè nígbà púpọ̀, mo sì gbàdúrà nígbà púpọ̀ sí Olúwa; nítorí-èyi Olúwa fi àwọn ohun nlá hàn sí mi.

4 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí mo ti parí ọkọ̀ nã, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ Olúwa, àwọn arákùnrin mi kíyèsĩ i pé ó dára, àti pé iṣẹ́ nã dára lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorí-èyi, wọ́n tún rẹ ara wọn sílẹ̀ níwájú Olúwa.

5 Ó sì ṣe tí ohùn Olúwa sì tọ bàbá mi wá, pé kí á dìde kí á sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọkọ̀ nã.

6 Ó sì ṣe ní ọjọ́ kejì, lẹ́hìn tí a ti pèsè ohun gbogbo, àwọn èso púpọ̀ àti ẹran láti aginjù, àti oyin ní ọ̀pọ̀, àti ìpèsè sílẹ̀ gẹ́gẹ́bí èyí tí Olúwa ti pàṣẹ fún wa, a sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọkọ̀, pẹ̀lú gbogbo ohun wa tí a dì àti àwọn irú-ọmọ wa, àti ohun èyíkéyĩ tí a ti mú wá pẹ̀lú wa, olúkúlùkù ènìyàn gẹ́gẹ́bí ọjọ́ orí rẹ̀; nítorí-èyi, gbogbo wa sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọkọ̀, pẹ̀lú àwọn aya wa àti àwọn ọmọ wa.

7 Àti nísisìyí, bàbá mi ti bí àwọn ọmọkùnrin méjì ní aginjù; èyí ẹ̀gbọ́n ni a pè ni Jákọ́bù àti èyí àbúrò Jósẹ́fù.

8 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí a ti sọ̀kalẹ̀ lọ sínú ọkọ̀, tí a sì mú pẹ̀lú wa àwọn ìpèsè-sílẹ̀ wa àti àwọn ohun èyí tí a pàṣẹ fún wa, a ṣí ọkọ̀ jáde sínú òkun, afẹ́fẹ́ sí ndarí wa jáde síhà ilẹ̀ ìlérí.

9 Lẹ́hìn tí afẹ́fẹ́ sì ti darí wa jáde fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, kíyèsĩ i, àwọn arákùnrin mi àti àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì àti àwọn aya wọn pẹ̀lú bẹ̀rẹ̀sí ṣe àjọyọ̀ tó bẹ̃gẹ́ tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí njó, tí wọ́n sì nkọrin, tí wọ́n sì ńsọ̀rọ̀ pẹ̀lú ìwà àimòye púpọ̀, bẹ̃ni, àní tí wọ́n gbàgbé nípasẹ̀ agbára èwo ni a ti fi mú wọn wá síbẹ̀ nã; a gbé wọn sókè sí ìwà àimòye tí ó pàpọ̀jù.

10 Èmi, Nífáì, sì bẹ̀rẹ̀sí bẹ̀rù lọ́pọ̀lọpọ̀ kí Olúwa má bà á bínú sí wa, kí ó sì lù wá nítorí ti àìṣedẽdé wa, kí a gbé wa mì ní ibú òkun; nítorínã, èmi, Nífáì, bẹ̀rẹ̀sí sọ̀rọ̀ sí wọn pẹ̀lú ìwà pẹ̀lẹ́ púpọ̀; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i wọ́n bínú sí mi, wọn wí pé: Àwa kò ní gbà kí arákùnrin àbúrò wa ṣe alákõso lórí wa.

11 Ó sì ṣe tí Lámánì àti Lẹ́múẹ́lì mú mi tí wọ́n sì dì mí pẹ̀lú okùn, wọ́n sì hùwà sí mi pẹ̀lú ìrorò púpọ̀; bíótilẹ̀ríbẹ̃, Olúwa yọ̃da rẹ̀, kí ó lè fi agbára rẹ̀ hàn jáde, sí mímú ọ̀rọ̀ rẹ̀ èyí tí ó ti sọ nípa àwọn ènìyàn búburú ṣẹ.

12 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí wọ́n ti dì mí tóbẹ̃ tí èmi kò lè ṣípòpadà, ẹ̀rọ àyíká, èyí tí Olúwa ti pèsè, dáwọ́dúró láti ṣiṣẹ́.

13 Nítorí-èyi, wọn kò mọ́ ibi ti o yẹ ki wọn kí ó tọ́ ọkọ̀, tóbẹ̃ tí ìjì nlá kan dìde, bẹ̃ni, ẹ̀fũfùlile nlá kan tí ó sì banilẹ́rù, ó sì darí wa sẹ́hìn lórí omi fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́ta; wọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí fòyà lọ́pọ̀lọpọ̀ kí wọ́n má bà á rì sínú omi ní òkun; bíótilẹ̀ríbẹ̃ wọn kò tú mi sílẹ̀.

14 Ní ọjọ́ kẹrin, èyí tí a ti darí wa sẹ́hìn, ẹ̀fũfùlíle nã sì bẹ̀rẹ̀sí di kíkan lọ́pọ̀lọpọ̀.

15 Ó sì ṣe tí a fẹ́rẹ̀ ẹ́ gbé wa mì ní ibú òkun. Lẹ́hìn tí a sì ti darí wa sẹ́hìn lórí omi fún ìwọ̀n ọjọ́ mẹ́rin, àwọn arákùnrin mi bẹ̀rẹ̀sí rí i pé ìdájọ́ Ọlọ́run wà lórí wọn, àti pé wọ́n kò le ṣe àìṣègbé àfi tí wọ́n bá ronúpìwàdà ní ti àìṣedẽdé wọn; nítorí-èyi, wọ́n wá sọ́dọ̀ mi, wọ́n sì tú àwọn èdídì èyí tí ó wà ní àwọn ọrùn-ọwọ́ mi, sì kíyèsĩ i wọ́n ti wú lọ́pọ̀lọpọ̀; àti ọrùn-ẹsẹ̀ mi pẹ̀lú wú púpọ̀, nlá sì ni ẹ̀dùn èyí nã.

16 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, mo yí ojú sí Ọlọ́run mi, mo sì yìn ín ní gbogbo ọjọ́ nã; èmi kò sì kùn sí Olúwa nítorí ti ìpọ́njú mi.

17 Nísisìyí bàbá mi, Léhì, ti sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun sí wọn, àti pẹ̀lú sí àwọn ọmọkùnrin Íṣmáẹ́lì; ṣùgbọ́n kíyèsĩ i, wọ́n nmí ìmí-ìkìlọ̀ púpọ̀ sí ẹnikẹ́ni tí ìbá fẹ́ sọ̀rọ̀ nítorí tèmi; àwọn òbí mi nítorí wọ́n sì ti di arúgbó, àti nítorí tí wọ́n ti faradà ìbànújẹ́ púpọ̀ nítorí ti àwọn ọmọ wọn, a mú wọ́n sọ̀kalẹ̀, bẹ̃ni, àní lórí ibùsùn àìsàn wọn.

18 Nítorí ti ìbànújẹ́ àti ìkãnú púpọ̀ wọn, àti àìṣedẽdé àwọn arákùnrin mi, a mú wọn sùnmọ́ àní láti gbé wọn jáde kúrò ní àkókò yí láti pàdé Ọlọ́run wọn; bẹ̃ni, ewú orí wọn ni à ńbọ̀wá mu sọ̀kalẹ̀ láti dùbúlẹ̀ nínú erùpẹ̀; bẹ̃ni, àní wọ́n súnmọ́ pé kí a jù wọ́n sínú isà òkú olómi pẹ̀lú ìbànújẹ́.

19 Àti Jákọ́bù àti Jósẹ́fù pẹ̀lú, nítorí wọ́n jẹ́ ọmọdé, tí wọ́n ní àìní níti bíbọ́ púpọ̀, ni a mú kẹ́dùn nítorí ti ìpọ́njú ìyá wọn; àti pẹ̀lú aya mi, pẹ̀lú omijé àti àdúrà rẹ̀, àti pẹ̀lú àwọn ọmọ mi, kò mú ọkàn àwọn arákùnrin mi rọ̀ tí àwọn yíò tú mi sílẹ̀.

20 Kò sì sí nkan àfi tí ó bá jẹ́ agbára Ọlọ́run, èyí tí ó dẹ́rùbà wọ́n pẹ̀lú ìparun, ni ó lè mú ọkàn wọn rọ̀; nítorí-èyi, nígbà tí wọ́n rí i pé a ti ńbọ̀wá gbé wọn mì ní ibú òkun, wọ́n ronúpìwàdà ní ti ohun èyí tí wọ́n ti ṣe, tóbẹ̃ tí wọ́n tú mi sílẹ̀.

21 Ó sì ṣe lẹhìn tí wọ́n ti tú mi sílẹ̀, mo mú ẹ̀rọ olùtọ́nisọ́nà nã, ó sì ṣiṣẹ́ níbi tí mo bá tí fẹ́ ẹ. Ó sì ṣe tí mo gbàdúrà sí Olúwa; lẹ́hìn tí mo sì ti gbàdúrà, afẹ́fẹ́ nã dáwọ́dúró, ìjì nã sì dáwọ́dúró, ìparọ́rọ́ nlá kan sì wà.

22 Ó sì ṣe tí èmi, Nífáì, tọ́ ọkọ̀ nã sí ọ̀nà, tí a tún ṣíkọ̀ síhà ilẹ̀ ìlérí.

23 Ó sì ṣe lẹ́hìn tí a ti ṣíkọ̀ fún ìwọ̀n ọjọ́ púpọ̀, a dé ilẹ̀ ìlérí nã; a sì jáde lọ sórí ilẹ̀ nã, a sì pa àwọn àgọ́ wa dó; a sì pè é ní ilẹ̀ ìlérí.

24 Ó sì ṣe tí a bẹ̀rẹ̀sí ro ilẹ̀, a sì bẹ̀rẹ̀sí gbin àwọn irúgbìn; bẹ̃ni, a fi gbogbo àwọn irúgbìn wa bọnú ilẹ̀, èyí tí a ti mú wá láti ilẹ̀ Jerúsálẹ́mù. Ó sì ṣe tí wọn hù lọ́pọ̀lọpọ̀; nítorí-èyi a bùkún wa ní ọ̀pọ̀.

25 Ó sì ṣe tí a rí lórí ilẹ̀ ìlérí, bí a ṣe nrin ìrìn-àjò ní aginjù, pé àwọn ẹranko wà nínú àwọn igbó ni oríṣiríṣi, àti abo màlũ àti màlũ, àti kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ àti ẹṣin, àti ewúrẹ́ àti ewúrẹ́ ìgbẹ́, àti irú àwọn ẹranko ìgbẹ́ gbogbo, èyí tí ó wà fún ìlò àwọn ènìyàn. A sì rí irú irin àìpò tútù gbogbo, àti ti wúrà, àti ti fàdákà, àti ti bàbà.