Àwọn Ìwé Mímọ́
1 Nífáì 21


Ori 21

Messia nì yíò jẹ́ ìmọ́lè fún àwọn Kèfèrí, yíò sì sọ àwọn ẹlẹ́wọ̀n di òmìnira—A ó kó Isráẹ́lì jọ pẹ̀lú agbára ní àwọn ọjọ́ ìkẹhìn—Àwọn ọba ni yíò jẹ́ àwọn bàbá olùtójú wọn—Fi wé Isaiah 49. Ní ìwọ̀n ọdún 588 sí 570 kí á tó bí Olúwa wa.

1 Àti lẹ̃kansĩ: Fetísílẹ, A! Ìwọ ará ilé Isráẹ́lì, gbogbo ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ kúrò tí a sì ti lé sóde nítorí ti ìwà búburú àwọn olùṣọ́-àgùntàn àwọn ènìyàn mi; bẹ̃ni, gbogbo ẹ̀yin tí a ti ṣẹ́ kúrò, tí a ti túká sẹ́hìn odi, tí ó jẹ́ ti àwọn ènìyàn mi, A! Ìwọ ará ilé Isráẹ́lì. Ẹ gbọ́ ti èmi, ẹ̀yin erékùṣù; kí ẹ sì fi etí sílẹ̀, ẹ̀yin ènìyàn láti ọ̀nà jíjìn wá; Olúwa ti pè mí láti inú wá; láti inú ìyá mi ni ó ti dá orúkọ mi.

2 Ó sì ti ṣe ẹnu mi bí idà mímú; nínú òjìji ọwọ́ rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́, ó sì sọ mí di ọfà dídán; nínú apó rẹ̀ ni ó ti pa mí mọ́;

3 Ó sì wí fún mi pé: Ìwọ ni ìránṣẹ́ mi, A! Isráẹ́lì, nínú ẹni tí a ó yìn mí lógo.

4 Nígbànã ni mo wípé, èmi ti ṣiṣẹ́ lásán, èmi ti lo agbára mi lófò àti lásán; nítõtọ́ ìdájọ́ mi nbẹ lọ́dọ̀ Olúwa, àti iṣẹ́ mi lọ́dọ̀ Ọlọ́run mi.

5 Àti nísisìyí, ni Olúwa wí—ẹni tí ó mọ́ mí láti inú wá kí èmi lè ṣe ìránṣẹ́ rẹ̀, láti mú Jákọ́bù padà wá sọ́dọ̀ rẹ̀—bíótilẹ̀jẹ́pé a lè má ṣa Isráẹ́lì jọ, síbẹ̀ èmi yíò ní ògo lójú Olúwa, Ọlọ́run mi yíò sì jẹ́ agbára mi.

6 Ó sì wípé: Ó jẹ́ ohun kékeré kí ìwọ ṣe ìránṣẹ́ mi láti gbé àwọn ẹ̀yà Jákọ́bù dìde, àti láti mú àwọn ìpamọ́ Isráẹ́lì padà. Èmi yíò fi ọ́ ṣe ìmọ́lẹ̀ àwọn Kèfèrí wípé kí ìwọ kí ó lè ṣe ìgbàlà mi títí dé ìkangun ayé.

7 Báyĩ ni Olúwa, Olùràpadà Isráẹ́lì, Ẹní Mímọ́ rẹ̀ wi, fún ẹni tí ènìyàn ngàn, fún ẹni tí àwọn orílẹ̀-èdè kórìra, fún ìránṣẹ́ àwọn olórí: Àwọn ọba yíò rí, wọ́n ó sì dìde, àwọn ọmọ-aládé pẹ̀lú yíò foríbalẹ̀, nítorí Olúwa tí íṣe olóotọ́.

8 Báyĩ ni Olúwa wí: Ní àkókò ìtẹ́wọ́gbà, èmi ti gbọ́ tìrẹ, A! ẹ̀yin erékùṣù òkun, àti ní ọjọ́ ìgbàlà mo ti ràn ọ́ lọ́wọ́; èmi yíò sì pa ọ́ mọ́, èmi ó sì fi ìwọ ìránṣẹ́ mi ṣe májẹ̀mú àwọn ènìyàn, láti fi ìdí ayé múlẹ̀, láti mú ni jogún àwọn ahoro ilẹ̀ ìní;

9 Kí ìwọ kí ó lè wí fún àwọn ẹlẹ́wọ̀n: Ẹ jáde lọ; fún àwọn tí ó jókò ní òkùnkùn: Ẹ fí ara yín hàn. Wọn ó jẹ ní ọ̀nà wọnnì, pápá ìjẹ wọn yíò sì wà ní gbogbo ibi gíga.

10 Ebi kì yíò pa wọ́n tàbí kí òùngbẹ gbẹ wọ́n, bẹ̃ni õru tàbí õrùn kì yíò sì pa wọ́n; nítorí ẹni tí ó ti ṣe ãnú fún wọn yíò tọ́ wọn, àní níhà ìsun omi ni yíò ṣe amọ̀nà wọn.

11 Èmi yíò sì sọ gbogbo àwọn òkè gíga mi wọnnì di ọ̀nà, a ó sì gbé àwọn ọ̀nà òpópó mi wọnnì ga.

12 Àti nígbànã, A! ará ilé Isráẹ́lì, kíyèsĩ i, àwọn wọ̀nyí yíò wá láti ọ̀nà jíjìn, sì wò ó, àwọn wọ̀nyí láti àríwá wá àti láti ìwọ̀-oòrùn wá; àti àwọn wọ̀nyí láti ilẹ̀ Sínímù wá.

13 Kọrin, A! ẹ̀yin ọ̀run; kí o sì yọ̀, A! ìwọ ayé; nítorí ẹsẹ̀ àwọn tí ó wà ní ìlà-oòrùn ni a ó fi múlẹ̀; sì bú jáde nínú orin kíkọ, A! ẹ̀yin òkè gíga; nítorí a kò ní lù wọ́n pa mọ́; nítorí Olúwa ti tu àwọn ènìyàn rè nínú, yíò sì ṣe ãnú fún àwọn olùpọ́njú rẹ̀.

14 Ṣùgbọ́n, kíyèsĩ i, Síónì ti wípé: Olúwa ti kọ̀ mí silẹ̀, Olúwa mi sì ti gbàbgé mi—ṣùgbọ́n òun yíò fi hàn pé òun kò tí ì ṣe bẹ̃.

15 Nítorí obìnrin ha lè gbàgbé ọmọ ọmú rẹ̀ bí, tí kì yíò fi ṣe ìyọ́nú sí ọmọ inú rẹ̀? Bẹ̃ni, wọ́n lè gbàgbé, síbẹ̀ èmi kì yíò gbàgbé rẹ, A! ará ilé Isráẹ́lì.

16 Kíyèsĩ i, èmi ti kọ ọ́ sí àtẹ́lẹwọ́ mi; àwọn odi rẹ ńbe títílọ níwájú mi.

17 Àwọn ọmọ rẹ yíò yára dojúkọ àwọn olùparun rẹ; àwọn tí ó fi ọ́ ṣòfò yíò sì ti ọ̀dọ̀ rẹ jáde.

18 Gbé ojú rẹ sókè yí kákiri kí o sì kíyèsĩ i; gbogbo àwọn wọ̀nyí kó ara wọn jọ, wọn yíò sì wá sí ọ́dọ̀ rẹ. Bí mo sì ti wà, ni Olúwa wí, dájúdájú ìwọ ó fi gbogbo wọn bò ara rẹ, bí ohun ọ̀ṣọ́, ìwọ ó sì há wọn mọ́ ara àní bí ìyàwó.

19 Nítorí ibi òfò àti ibi ahoro rẹ̀ wọnnì, àti ilẹ̀ ìparun rẹ, yíò tilẹ̀ há jù nísisìyí nítorí àwọn tí ngbé inú wọn; àwọn tí ó gbé ọ mì yíò sì jìnà réré.

20 Àwọn ọmọ tí ìwọ yíò ní, lẹ́hìn tí ìwọ bá ti sọ ti ìsãjú nù, ní etí rẹ yíò tún wípé: Àyè nã há pọ̀jù fún mi; fi àyè fún mi kí èmi lè gbé.

21 Nígbànã ni ìwọ yíò wí ní ọkàn rẹ pé: Tani ó bí àwọn wọ̀nyí fún mi, nítorí mo ti ṣòfò àwọn ọmọ mi, tí mo sì di ahoro, ìgbèkun, tí mo sì nṣí lọ ṣí bọ̀? Tani ó sì ti tọ́ àwọn wọ̀nyí dàgbà? Kíyèsĩ i, a fi èmi nìkan sílẹ̀; àwọn wọ̀nyí, níbo ni wọ́n ha ti wà?

22 Báyĩ ni Olúwa Ọlọ́run wí: Kíyèsĩ i, èmi yiò gbé ọwọ́ mi sókè sí àwọn Kèfèrí, èmi ó sì gbé ọ̀págún mi sókè sí àwọn ènìyàn; wọn yíò sì gbé àwọn ọmọkùnrin rẹ wá ní apá wọn, a ó sì gbé àwọn ọmọbìnrin rẹ ní èjìká wọn.

23 Àwọn ọba yíò jẹ́ bàbá olùtọ́jú rẹ, àti àwọn ayaba wọn yíò sì jẹ́ ìyá olùtọ́jú rẹ; wọn yíò tẹríba fún ọ ní ìdojúbolẹ̀, wọn ó sì lá ekuru ẹsẹ̀ rẹ; ìwọ yíò sì mọ̀ pé èmi ni Olúwa; nítorí ojú kì yíò ti àwọn tí ó bá dúró dè mí.

24 Nítorí a ha lè gba ìkógun lọ́wọ́ alágbára bí, tàbí àwọn ondè lọ́wọ́ àwọn ẹni tí wọ́n tọ́ fún?

25 Ṣùgbọ́n báyĩ ni Olúwa wí, a ó tilẹ̀ gba àwọn ondè kúrò lọ́wọ́ àwọn alágbára, a ó sì gba ìkógun lọ́wọ́ àwọn ẹni-ẹ̀rù; nítorí èmi yíò bá a jà ẹni tí ó bá bá ọ jà, èmi yíò sì gba àwọn ọmọ rẹ là.

26 Èmi yíò sì bọ́ àwọn tí ó ni ọ́ lára pẹ̀lú ẹran ara wọn; wọn ó mu ẹ̀jẹ̀ ara wọn ní àmuyó bí ọtí-wáínì dídùn; gbogbo ẹran-ara yíò sì mọ̀ pé èmi, Olúwa, ni Olùgbàlà rẹ àti Olùràpadà rẹ, Ẹni Alágbára ti Jákọ́bù.