Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 13


Orí 13

A yan àwọn ènìyàn sí ipò olórí àlùfã nítorí ìgbàgbọ́ nwọn tí ó pọ̀ àti iṣẹ́ rere nwọn—Nwọ́n wà láti kọ́ni ní àwọn òfin-Ọlọ́run—nípa ìwà òdodo a sọ nwọ́n di mímọ́, nwọ́n sì bọ́ sínú ìsinmi Olúwa—Mẹ́lkisédékì jẹ́ ọ̀kan nínú nwọn—Àwọn ángẹ́lì sì nmú ìhìn-rere ayọ̀ wá jákè-jádò ilẹ̀ nã—Nwọn yíò fi ìgbà bíbọ̀ Krístì nítõtọ́ hàn. Ní ìwọ̀n ọdún 82 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Àti pẹ̀lú, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi yíò sún ọkàn an yín síwájú sí àkokò ti Olúwa Ọlọ́run fún àwọn ọmọ rẹ̀ ni àwọn òfin wọ̀nyí; èmi yíò sì fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rántí pé Olúwa Ọlọ́run yan àwọn àlùfã, ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ mímọ́ rẹ̀, èyítí ó wà ní ẹgbẹ́ ti Ọmọ rẹ̀, láti kọ́ àwọn ènìyàn nã ni àwọn nkan wọ̀nyí.

2 A sì yan àwọn àlùfã nnì ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ ti Ọmọ rẹ̀, ní ọ̀nà tí àwọn ènìyàn nã yíò fi mọ́ ọ̀nà ti wọn yio gbà ní ìrètí nínú Ọmọ rẹ̀ fún ìràpadà.

3 Báyĩ ṣì ni ipa ọ̀nà tí a ṣe yàn nwọ́n—tí a ti pè nwọ́n, tí a sì múra nwọn sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run, nítorí ìgbàgbọ́ nwọn tí ó pọ̀ tayọ àti iṣẹ́ rere nwọn; ní ọ̀nà èkíní, tí a fi nwọ́n sílẹ̀ láti yan rere tàbí búburú; nítorínã nígbàtí nwọ́n ti yàn rere, tí nwọ́n sì fi ìgbàgbọ́ tí ó tayọ hàn, a sì pè nwọ́n pẹ̀lú ìpè mímọ́, bẹ̃ni, pẹ̀lú ìpè mímọ́ nnì èyítí a ti múra rẹ̀ sílẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú ìràpadà tí a ti ṣe ìmúrasílẹ̀ rẹ̀ fún irú nwọn.

4 Báyĩ sì ni a ti pè nwọ́n sí ìpè mímọ́ yí ní ìbámu pẹ̀lú ìgbàgbọ́ nwọn, nígbàtí àwọn míràn kẹ̀hìn sí Ẹ̀mi Ọlọ́run nítorí líle ọkàn nwọn àti ìfọ́jú inú nwọn, nítorí tí kò bá jẹ́ fún ìdí èyí, nwọn ìbá ní ọ̀pọ̀ ànfãní gẹ́gẹ́bí ti àwọn arákùnrin nwọn.

5 Tàbí ní àkótán, ní ọ̀nà èkíní, nwọ́n wà bákannã pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn; báyĩ sì ni ìpè mímọ́ yí, tí a ti pèsè sílẹ̀ láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé fún àwọn ẹnití kò ní se ọkàn nwọn le, èyítí ó wà tĩ sì íṣe nípasẹ̀ ètùtù Ọmọ Bíbí Kanṣoṣo, ẹníti a ti pèsè sílẹ̀—

6 Tí a sì ti pè nwọ́n báyĩ nípa ìpè mímọ́ yí, tí a sì yàn nwọ́n sí ipò-àlùfã gíga ti ẹgbẹ́ mímọ́ Ọlọ́run, láti kọ́ àwọn ọmọ ènìyàn ní àwọn òfin rẹ̀, kí nwọ́n sì lè bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀—

7 Ipò-àlùfã gíga yĩ tí ó jẹ́ ti ẹgbẹ́ Ọmọ rẹ̀, ẹgbẹ́ èyítí ó ti wà láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé; tàbí kí a wípé, ó jẹ́ èyítí kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọdún, tí a ti pèsè rẹ̀ sílẹ̀ láti ayérayé dé ayérayé, gẹ́gẹ́bí ìmọ̀tẹ́lẹ̀ rẹ̀ lórí ohun gbogbo—

8 Báyĩ ni a ṣe yàn nwọ́n ní ipa ọ̀nà yí—tí a pè nwọ́n pẹ̀lú ìpè mímọ́, tí a sì yàn nwọ́n pẹ̀lú ìlànà mímọ́, tí nwọ́n sì gba ipò-àlùfã gíga ti ẹgbẹ́ mímọ́, ìpè àti yíyàn, àti ipò-àlùfã gíga sì wà láìní ìbẹ̀rẹ̀ tàbí òpin—

9 Báyĩ ni nwọ́n sì jẹ́ olórí àlùfã títí láéláé, ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ ti Ọmọ, ẹnítí íṣe Bíbí kanṣoṣo ti Bàbá, ẹnití kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́ tàbí òpin ọdún, ẹnití ó kún fún õre-ọ̀fẹ́, ìṣòtítọ́ àti òtítọ́. Bẹ̃ sì ni ó rí. Àmin.

10 Nísisìyí, gẹ́gẹ́bí èmi ti sọ nípa ti ẹgbẹ́ mímọ́ nnì, tàbí ipò olórí àlùfã yí, a yan ọ̀pọ̀lọpọ̀, nwọ́n sì di àlùfã gíga ti Ọlọ́run; èyítí íṣe nípasẹ̀ títóbi ìgbàgbọ́ nwọn àti ìrònúpìwàdà, àti òdodo nwọ́n níwájú Ọlọ́run, nítorítí nwọ́n yàn láti ronúpìwàdà kí nwọ́n sì ṣe iṣẹ́ òdodo, kí nwọ́n má bã ṣègbé;

11 Nítorínã ni a fi pè nwọ́n ní ti ẹgbẹ́ mímọ́ yí, tí a sì yà nwọ́n sí mímọ́, tí a sì fọ aṣọ nwọn mọ́ di funfun nípa ẹ̀jẹ̀ Ọ̀dọ́-àgùtàn.

12 Nísisìyí, lẹ́hìn tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti yà nwọ́n sí mímọ́, tí aṣọ nwọn ti di funfun, tí ó sì ti mọ́, tí ó sì wà láìlẽrĩ níwájú Ọlọ́run, nwọn kò lè bojú wo ẹ̀ṣẹ̀ àfi pẹ̀lú ìkóríra; àwọn púpọ̀ sí wà, tí nwọ́n pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, tí a sọ di mímọ́ tí nwọ́n sì ti bọ́ sínú ìsinmi Olúwa Ọlọ́run nwọn.

13 Àti nísisìyí, ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi ìbá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, kí ẹ̀yin sì so èso tí ó yẹ fún ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin nã lè bọ́ sínú ìsinmi nã.

14 Bẹ̃ni, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ àní gẹ́gẹ́bí àwọn ènìyàn nnì, ní ìgbà Mẹ́lkisédékì, ẹnití íṣe olórí àlùfã pẹ̀lú, ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ kannã èyítí mo ti sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ẹnití ó gba oyè-àlùfã gíga nnì títí láé.

15 Mẹ́lkisédékì yĩ kannã ni Ábráhámù san ìdámẹ̃wá fún; bẹ̃ni, àní bàbá wa Ábráhámù san ìdámẹ́wá lórí ohun iní rẹ gbogbo.

16 Nísisìyí, àwọn ìlànà yí ni a gbé kalẹ̀ ní ọ̀nà yí, pé kí àwọn ènìyàn lè fojúsọ́nà sí Ọmọ Ọlọ́run nã, èyítí íṣe irú ẹgbẹ́ tirẹ̀ kan, tàbí tĩ ṣe ẹgbẹ́ tirẹ̀, èyí sì rí bẹ̃ kí nwọ́n lè fojúsọ́nà síi fún ìràpadà lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, kí nwọn kí ó lè wọ inú ìsinmi Olúwa.

17 Nísisìyí, Mẹ́lkisédékì yĩ jẹ́ ọba lórí ilẹ̀ Sálẹ́mù; àwọn ènìyàn rẹ̀ sì ti hu ìwà àìṣedẽdé àti ẽrí lọ́pọ̀lọpọ̀; bẹ̃ni, nwọ́n ti ṣáko lọ; nwọ́n sì kún fún onírurú ìwà búburú;

18 Ṣùgbọ́n nítorítí Mẹ́lkisédékì ní ìgbàgbọ́ púpọ̀, tí ó sì gboyè ipò-àlùfã gíga ní ìbámu pẹ̀lú ẹgbẹ́ mímọ́ Ọlọ́run, ó sì wãsù ìrònúpìwàdà sí àwọn ènìyàn rẹ̀. Sì kíyèsĩ, nwọ́n ronúpìwàdà; Mẹ́lkisédékì sì fi àlãfíà lélẹ̀ ní orí ilẹ̀ nã ní gbogbo ọjọ́ rẹ̀; nítorínã ni a ṣe pẽ ní ọmọ-aládé àlãfíà, nítorítí òun ní í ṣe ọba Sálẹ́mù; òun sì jọba lábẹ́ bàbá rẹ̀.

19 Nísisìyí, àwọn ti nwọ́n wà ṣãjú rẹ̀ pọ̀, àti pẹ̀lú, àwọn tí nwọ́n wà lẹ́hìn rẹ pọ̀, ṣùgbọ́n kò sí èyítí ó tóbi jũ; nítorínã, nípa rẹ̀ ni a ti kọ àkọsílẹ̀ ju ti ẹlòmíràn lọ.

20 Nísisìyí, kò sí ìdí fún mi láti tẹnumọ́ ohun yĩ; èyí tí èmi ti sọ ti tó. Kíyèsĩ, àwọn ìwé mímọ́ wà níwájú yín; tí ẹ̀yin bá sì yí nwọn po, yíò já sí ìparun fún yín.

21 Àti nísisìyí, ó sì ṣe, nígbàtí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún nwọn, ó na ọwọ́ rẹ jáde sí nwọn, ó sì kígbe ní ohùn rara, wípé: Àsìkò ti tó láti ronúpìwàdà, nítorítí ọjọ́ ìgbàlà ti dé tán;

22 Bẹ̃ ni, ohùn Olúwa láti ẹnu àwọn ángẹ́lì, sì kéde fún gbogbo orílẹ̀-èdè; bẹ̃ni, ó kéde rẹ̀, pé kí nwọ́n lè ní ìró ayọ̀ inú dídùn púpọ̀púpọ̀; bẹ̃ni, ó sì nró ìró ayọ̀ nlá yĩ lãrín àwọn ènìyàn rẹ̀ gbogbo, bẹ̃ni, àní sí àwọn tí a fọ́nká kiri yíká gbogbo orí ilẹ̀ ayé; nítorí-eyi ni nwọ́n ṣe tọ̀ wá wá.

23 Nwọ́n sì fi nwọ́n yé wa yékéyéké kí ó bá lè yé wa pé àwa kò lè ṣẹ̀; èyí sì rí bẹ̃ nítorípé àwa jẹ́ aṣáko nínú ilẹ̀ àjòjì; nítorínã, àwa rí ọ̀pọ̀ ọjú rere Olúwa, nítorítí àwa ní ìró ayọ̀ yí tí nwọ́n kéde fún wa nínú gbogbo ọgbà àjàrà wa.

24 Nítorí kíyèsĩ, àwọn ángẹ́lì nkéde rẹ̀ sí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ní àkokò yĩ ní orí ilẹ̀ wa; èyí sì wà fún ìpalẹ̀mọ́ ọkàn àwọn ọmọ ènìyàn láti gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ ní àkokò nã tí yíò dé nínú ògo rẹ̀.

25 Àti nísisìyí àwa ndúró láti gbọ́ ìkéde ìròhìn ayọ̀ nã láti ẹnu àwọn ángẹ́lì nípa bíbọ̀ rẹ̀; nítorítí àkokò nã nbọ̀, àwa kò mọ̀ bí yíò ṣe yá sí. Olúwa ìbá sì jẹ́ kí ó ṣẹlẹ̀ ní ìgbà tèmi; ṣùgbọ́n bí ó tilẹ̀ rí bẹ̃ ṣãjú ìgbà yí, tàbí lẹ́hìn rẹ̀, nínú èyí ni èmi yíò yọ̀.

26 Yíò sì jẹ́ mímọ̀ fún àwọn ẹni títọ́ àti mímọ́, láti ẹnu àwọn ángẹ́lì, ní àkokò bíbọ̀ rẹ̀, kí ọ̀rọ̀ àwọn bàbá wa lè ṣẹ, gẹ́gẹ́bí èyítí nwọ́n ti sọ nípa rẹ̀, èyítí íṣe nípa ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀ tí ngbé inú nwọn.

27 Àti nísisìyí ẹ̀yin arákùnrin mi, èmi nfẹ́ tọkàn-tọkàn, bẹ̃ni, pẹ̀lú ọ̀pọ̀ àníyàn ọkàn títí fi dé ìrora, pé kí ẹ̀yin fi ètí sílẹ̀ sí àwọn ọ̀rọ̀ mi, kí ẹ̀yin sì fi ẹ̀ṣẹ̀ sílẹ̀, kí ẹ ṣíwọ́ ìfàsẹhìn ìrònúpìwàdà yín;

28 Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin rẹ ara yín sílẹ̀ níwájú Olúwa, kí ẹ̀yin sì pe orúkọ rẹ̀ mímọ́, kí ẹ máa ṣọ́nà kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà-gbogbo, kí a má bã dán yín wò ju agbára yín lọ, kí ẹ̀yin lè gba ìtọ́sọ́nà Ẹ̀mí Mímọ́ báyĩ, kí ẹ̀yin sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀-ọkàn, oníwà-pẹ̀lẹ́, aláìgbéraga, ìfaradà, kí ẹ kún fún ìfẹ́, àti ìlọ́ra gbogbo;

29 Kí ẹ̀yin kí ó ní ìgbàgbọ́ nínú Olúwa; kí ẹ̀yin kí ó ní ìrètí pé ẹ̀yin yíò gba ìyè àìnípẹ̀kun; kí ẹ̀yin ó sì ní ìfẹ́ Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà nínú ọkàn yín, kí a lè gbé yín sókè ní ọjọ́ ìkẹhìn kí ẹ̀yin sì bọ́ sínú ìsinmi rẹ̀.

30 kí Olúwa kí ó fún yín ní ìrònúpìwàdà, kí ẹ̀yin kí ó máṣe fa ìbínú rẹ̀ sọ̀kalẹ̀ sóríi yín, kí ẹ̀yin kí ó má sì ṣe wà ní dídè nínú ìdè ọ̀run àpãdì; kí ẹ̀yin kí ó máṣe jìyà ikú kejì.

31 Álmà sì sọ ọ̀rọ̀ púpọ̀ síwájú si sí àwọn ènìyàn nã, èyítí a kò kọ sínú ìwé yĩ.