Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 15


Orí 15

Álmà àti Ámúlẹ́kì lọ sí Sídómù, nwọ́n sì dá ìjọ-Ọlọ́run sílẹ̀—Álmà wo Sísrọ́mù sàn, ẹnití ó sì darapọ̀ mọ́ ìjọ-Ọlọ́run—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ṣe ìrìbọmi fún, ìjọ Ọlọ́run sì ní ìlọsíwájú—Álmà àti Ámúlẹ́kì lọ sí Sarahẹ́múlà. Ní ìwọ̀n ọdún 81 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe tí a paá laṣẹ fún Álmà àti Ámúlẹ́kì lati jáde ní ìlú nã; nwọ́n sì jáde, nwọ́n sì wá sínú ilẹ̀ Sídómù; sì kíyèsĩ, níbẹ̀ ni nwọ́n ti rí àwọn ènìyàn tí nwọ́n ti jáde kúrò ní ilẹ̀ Amonáíhà, tí nwọ́n ti lé jáde tí nwọ́n sì sọ ní ókúta, nítorípé nwọ́n gba ọ̀rọ̀ Álmà gbọ́.

2 Nwọ́n sì sọ gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ìyàwó àti ọmọ nwọn fún nwọn, àti nípa ara nwọn nã pẹ̀lú, àti nípa ti agbára ìdásílẹ̀ lórí nwọn.

3 Sísrọ́mù dùbúlẹ̀ lórí àìsàn ní Sídómù, pẹ̀lú akọ ibà, èyítí ó rí bẹ̃ nípasẹ̀ ìbànújẹ́ ọkàn an rẹ̀ nítorí ìwà búburú rẹ̀, nítorípé òun rò pé Álmà àti Ámúlẹ́kì kò sí lãyè mọ́; òun sì rò pé a ti pa nwọ́n nítorí ìwà ẹ̀ṣẹ̀ òun. Ẹ̀ṣẹ̀ nla yĩ, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ míràn sì gbọgbẹ́ lọ́kàn rẹ̀ títí ó fi njẹ̀rora, nítorítí kò ní ìdásílẹ̀, nítorínã, akọ ooru sì bẹ̀rẹ̀ síí jo.

4 Nísisìyí, nígbàtí ó ti gbọ́ pé Álmà àti Ámúlẹ́kì wà nínú ilẹ̀ Sídómù, ó bẹ̀rẹ̀sí ní ìgboyà; ó sì rán iṣẹ́ sí nwọn lọ́gán, pé òun fẹ́ kí nwọ́n wá sọ́dọ̀ òun.

5 Ó sì ṣe tí nwọ́n lọ lógán, ní ìgbọràn sí iṣẹ́ èyítí ó rán sí nwọn; nwọ́n sì wọ inú ilé Sísrọ́mù lọ; nwọ́n sì bã lórí ibùsùn rẹ, nínú àìsàn, tí ó sì wà ní ìdùbúlẹ̀ gan pẹ̀lú akọ ibà; ọkàn rẹ̀ sì gbọgbẹ́ lọ́pọ̀lọpọ̀ nítorí ìwà àìṣedẽdé rẹ̀; nígbàtí ó sì rí wọn ó na ọwọ́ rẹ̀ sí wọn, ó sì bẹ̀ nwọ́n pé kí nwọn wo òun sàn.

6 Ó sì ṣe tí Álmà wí fún un, bí ó ṣe mú ọwọ́ rẹ: Njẹ́ ìwọ gbàgbọ́ nínú agbára Krístì sí ìgbàlà bí?

7 Òun sì dahun ó sì wípé: Bẹ̃ni, mo gba gbogbo ọ̀rọ̀ naa tí ẹ̀yin ti kọ́ ni gbọ́.

8 Álmà sì wípé: Bí ìwọ bá gbàgbọ́ nínú ìràpadà Krístì ìwọ lè rí ìwòsàn.

9 Ó sì wípé: Bẹ̃ni, mo gbàgbọ́, gẹ́gẹ́bí ọ̀rọ̀ rẹ.

10 Nigbànã ni Álmà kígbe sí Olúwa, wípé: Á!, Olúwa Ọlọ́run wa, ṣãnú fún ọkùnrin yí, kí ó sì wõ sàn gẹ́gẹ́bí ìgbàgbọ́ rẹ̀, èyítí ó wà nínú Krístì.

11 Lehìn tí Álmà ti sọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí tán, Sísrọ́mù fò dìde, ó sì bẹ̀rẹ̀sí rìn; èyí sì jẹ́ ohun ìyàlẹ́nu nlá fún gbogbo àwọn ènìyàn nã; ìmọ̀ yĩ sì tàn ká kiri gbogbo ilẹ̀ Sídómù.

12 Álmà sì ṣe ìrìbọmi fún Sísrọ́mù sí ọ̀nà Olúwa; ó sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgbà nã lọ, láti wãsù sí àwọn ènìyàn nã.

13 Álmà sì fi ìjọ-onígbàgbọ́ kan lọ́lẹ̀ ní ilẹ̀ Sídómù, ó sì ya àwọn àlùfã sọ́tọ̀, pẹ̀lú àwọn olùkọ́ni ní ilẹ̀ nã, láti ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkẹ́ni tí ó bá fẹ́ ṣe ìrìbọmi, sí Olúwa.

14 Ó sì ṣe tí nwọ́n di púpọ̀; nítorítí nwọ́n wá ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ láti gbogbo agbègbè tí ó yí Sídómù ka, sì rì nwọn bọmi.

15 Ṣùgbọ́n ní ti àwọn ènìyàn tí ó wà ní ilẹ̀ Amonáíhà, nwọn ṣì wà nípò ọlọ́kàn-líle àti ọlọ́rùn-líle ènìyàn; nwọn kò sì ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ nwọn, tí nwọn sì nwípé agbára èṣù ni Álmà àti Ámúlẹ́kì nlò; nítorítí nwọ́n jẹ́ ipa ti Néhórì, tí nwọn kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìrònúpìwàdà kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ nwọn.

16 Ó sì ṣe, tí Álmà àti Ámúlẹ́kì, lẹ́hìn tí Ámúlẹ́kì ti kẹ̀hìnsí gbogbo wúrà, fàdákà, àti àwọn ọrọ̀ rẹ, èyítí ó wà ní ilẹ̀ Amonáíhà, fún ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, nígbàtí àwọn tí nwọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ tẹ́lẹ̀ àti bàbá rẹ̀, àti ìbátan rẹ̀ ti kọ̃ sílẹ̀;

17 Nítorínã, lẹ́hìn tí Álmà ti fi ìjọ-onígbàgbọ́ lọ́lẹ̀ ní Sídómù, tí òun sì ríi pé ìkìwọ̀ nlá ti wà, àní, tí ó ríi pé àwọn ènìyàn nã ti ki ara nwọn wọ nípa ìgbéraga ní ọkàn nwọn, tí nwọ́n sì ti bẹ̀rẹ̀sí rẹ ara nwọn sílẹ̀ níwájú Ọlọ́run, tí nwọn sì nkó ara nwọn jọ ní ibi-mímọ́ nwọn láti sin Ọlọ́run níwájú pẹpẹ, tí nwọn nṣọ́nà tí nwọ́n sì ngbàdúrà nígbà-gbogbo, pe ki nwọ́n lè bọ́ lọ́wọ́ Sátánì, àti lọ́wọ́ ikú, àti kúrò nínú ìparun—

18 Nísisìyí gẹ́gẹ́bí èmi ti wí, nígbàtí Álmà ti rí gbogbo ohun wọ̀nyí, nítorínã ni ó mú Ámúlẹ́kì, o sì kọjá wá sí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà ó sì múu lọ sí ilé tirẹ, tí ó sì gbã níyànjú nínú wàhálà àti ìdánwò rẹ̀, tí ó sì múu lọ́kàn le nínú Olúwa.

19 Báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀wá ìjọba àwọn ọnídàjọ̃ lórí àwọn ará Nífáì dé òpin.