Orí 23
A ṣe ìkéde òmìnira ẹ̀sìn—Àwọn ará Lámánì tí ó wà ní ilẹ̀ àti ìlú-nlá méje ni a yí lọ́kàn padà—Nwọ́n pe ara nwọn ní Kòṣe-Nífáì-Léhì, a sì dá nwọn nídè kúrò nínú ègún nã—Àwọn ará Ámálẹ́kì àti àwọn ará Ámúlónì kọ òtítọ́ nã sílẹ̀. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Kíyèsĩ, báyĩ ni ó sì ṣe tí ọba àwọn ará Lámánì ṣe ìkéde lãrín gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀, pé kí nwọn máṣe fi ọwọ́ kan Ámọ́nì, tàbí Áárọ́nì, tàbí Òmnérì, tàbí Hímnì, tàbí èyíkéyĩ nínú àwọn arákùnrin nwọn tí yíò bá lọ wãsù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní ibikíbi tí wọ́n lè wà lórí ilẹ̀ nwọn.
2 Bẹ̃ni, ó sì fi àṣẹ ránṣẹ́ lãrín nwọn pé nwọn kò gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ kan nwọ́n láti dè nwọ́n, tàbí láti gbé nwọn sínú tũbú; bẹ̃ni nwọn kò gbọ́dọ̀ tu itọ́ sí nwọn lára, tàbí lù nwọ́n, tàbí lé nwọn jáde kúrò nínú sínágọ́gù nwọn, tàbí kí nwọ́n nà nwọ́n ní pàṣán; nwọn kò gbọ́dọ̀ sọ nwọ́n ní òkúta, ṣùgbọ́n pé kí nwọ́n máa wọ ilé nwọn láìní ìdíwọ́, àti tẹ́mpìlì nwọn pẹ̀lú, àti àwọn ibi-mímọ́ nwọn.
3 Báyĩ nwọn yíò sì lè lọ wãsù ọ̀rọ̀ nã gẹ́gẹ́bí ìfẹ́ inú nwọn, nítorítí a ti yí ọkàn ọba padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, àti gbogbo agbo ilé rẹ̀; nítorínã, ó fi ìkéde rẹ̀ nã ránṣẹ́ jákè-jádò ilẹ̀ nã sí àwọn ènìyàn rẹ̀, pé kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máṣe ní ìdènà, ṣùgbọ́n pé kí ó lọ jákè-jádò ilẹ̀ nã, kí àwọn ènìyàn rẹ̀ lè gba ìdánilójú nípa àṣà búburú àwọn bàbá nwọn, àti pé kí nwọ́n lè mọ̀ dájú pé arákùnrin ni gbogbo nwọn jẹ́ fún ara nwọn, àti pé nwọn kò gbọ́dọ̀ pànìyàn, tàbí ṣe ìkógun, tàbí jalè, tàbí ṣe àgbèrè, tàbí hùwà búburú kankan.
4 Àti nísisìyí ó sì ṣe lẹ́hìn tí ọba ti fi ìkéde nã ránṣẹ́, ni Áárọ́nì pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀ jáde lọ láti ìlú dé ìlú, àti láti ilé ìjọsìn kan dé òmíràn, tí nwọ́n sì ndá ìjọ̀-onígbàgbọ́ sílẹ̀, tí nwọ́n sì nyan àwọn àlùfã àti olùkọ́ni sọ́tọ̀ jákè-jádò ilẹ̀ nã lãrín àwọn ará Lámánì, láti wãsù àti láti kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lãrín nwọn; báyĩ ni nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣe àṣeyọrí púpọ̀púpọ̀.
5 A sì mú ẹgbẹ̃gbẹ̀rún wá sí ìmọ̀ Olúwa, bẹ̃ni, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ni a mú láti gbàgbọ́ nínú àṣà àwọn ará Nífáì; a sì kọ́ nwọn ní àkọsílẹ̀ àti ìsọtẹ́lẹ̀ èyítí à ngbé lé nwọn lọ́wọ́, àní títí di òní.
6 Bí Olúwa sì ti wà lãyè, bẹ̃ni ó sì dájú, tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, tàbí tí gbogbo àwọn tí a mú wá sí ìmọ̀ òdodo nípa ìwãsù Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, nípasẹ̀ ẹ̀mí ìfihàn àti ti ìsọtẹ́lẹ̀, àti agbára Ọlọ́run tí ó nṣe iṣẹ́ ìyanu nínú nwọn—bẹ̃ni, mo wí fún nyin, bí Olúwa ti wà lãyè, gbogbo àwọn ará Lámánì tí nwọ́n gbàgbọ́ nínú ìwãsù nwọn, tí nwọ́n sì yípadà sí ọ̀dọ̀ Olúwa, kò ṣubú kúrò lọ́nà nã mọ́.
7 Nítorítí nwọ́n di ènìyàn olódodo; nwọ́n sì kó ohun ìjà ọ̀tẹ̀ nwọn lélẹ̀, tí nwọn kò bá Ọlọ́run jà mọ́, tàbí ẹnìkẹ́ni nínú arákùnrin nwọn.
8 Nísisìyí, àwọn wọ̀nyí ni àwọn tí a yí lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa:
9 Àwọn ènìyàn Lámánì tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì;
10 Àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn Lámánì tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Mídónì;
11 Àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn Lámánì tí nwọ́n wà ní ìlú-nlá ti Nífáì;
12 Àti pẹ̀lú àwọn ènìyàn Lámánì tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Ṣílómù, àti tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Ṣẹ́múlónì, àti nínú ìlú-nlá Lémúẹ́lì, àti nínú ìlú-nlá Ṣímnílọ́mù.
13 Àwọn wọ̀nyí sì ni orúkọ àwọn ìlú-nlá àwọn ará Lámánì tí a yí lọ́kàn padà sí ọ̀dọ̀ Olúwa; àwọn sì ni nwọ́n kó àwọn ohun ìjà ọ̀tẹ̀ nwọn sílẹ̀, bẹ̃ni, gbogbo ohun ìjà ogun nwọn; ará Lámánì sì ni gbogbo nwọn í ṣe.
14 Àwọn ará Ámálẹ́kì kò sì yípadà, àfi ẹnìkan ṣoṣo; bẹ̃ni kò sì sí nínú àwọn ará Ámúlónì; ṣùgbọ́n nwọ́n sé àyà nwọn le, àti àyà àwọn ará Lámánì ní apá ìhà ilẹ̀ nã níbikíbi tí nwọ́n gbé, bẹ̃ni, àti gbogbo ìletò nwọn, àti gbogbo ìlú-nlá wọn.
15 Nítorínã, a ti dárúkọ gbogbo àwọn ìlú-nlá àwọn ará Lámánì inú èyítí nwọ́n bá ti ronúpìwàdà, tí nwọ́n sì wá sínú ìmọ̀ òdodo; tí nwọ́n sì yípadà.
16 Àti nísisìyí ó sì ṣe, tí ọba àti gbogbo àwọn tí a ti yí lọ́kàn padà ní ìfẹ́ láti ní orúkọ, èyítí a ó fi mọ̀ nwọ́n yàtọ̀ sí àwọn arákùnrin nwọn; nítorínã, ọba jíròrò pẹ̀lú Áárọ́nì àti púpọ̀ nínú àwọn àlùfã nwọn, lórí orúkọ tí nwọn yíò jẹ́, kí nwọ́n fi lè yàtọ̀.
17 Ó sì ṣe tí nwọ́n pe orúkọ ara nwọn ní Kòṣe-Nífáì-Léhì; a sì nfi orúkọ yĩ pè nwọ́n, a kò sì pè nwọ́n ní àwọn ará Lámánì mọ́.
18 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí ṣiṣẹ́ tara-tara; bẹ̃ni, nwọ́n sì bá àwọn ará Nífáì rẹ́pọ̀; nítorínã, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀ àjọṣepọ̀ pẹ̀lú nwọn, ègún Ọlọ́run kò sì tẹ̀lé wọn mọ́.