Orí 25
Ìwà-ìfinràn àwọn ará Lámánì ńtànkálẹ̀ síi—Àwọn irú-ọmọ àwọn àlùfã Nóà ṣègbé gẹ́gẹ́bí Ábínádì ti sọtẹ́lẹ̀—Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn ará Lámánì ni a yí lọ́kàn padà tí nwọ́n sì darapọ̀ mọ́ àwọn Kòṣe-Nífáì-Léhì—Nwọ́n gba Krístì gbọ́, nwọ́n sì pa òfin Mósè mọ́. Ní ìwọ̀n ọdún 90 sí 77 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Sì kíyèsĩ, báyĩ ni ó sì ṣe tí àwọn ará Lámánì nì bínú púpọ̀ si nítorítí nwọ́n pa àwọn arákùnrin nwọn; nítorínã nwọ́n ṣe ìbúra láti gbẹ̀san lára àwọn ará Nífáì; nwọn kò sì gbìyànjú láti pa àwọn ará Kòṣe-Nífáì-Léhì mọ́ nígbà nã.
2 Ṣùgbọ́n nwọ́n kó àwọn ọmọ ogun nwọn, nwọ́n sì kọjá lọ sínú ibi agbègbè ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, nwọ́n sì kọlũ àwọn ènìyàn tí nwọ́n wà ní ilẹ̀ Amonáíhà nwọ́n sì pa nwọ́n run.
3 Lẹ́hìn èyí nnì, nwọ́n ja ọ̀pọ̀lọpọ̀ ogun pẹ̀lú àwọn ará Nífáì, nínú èyítí nwọ́n lé nwọn, tí nwọ́n sì pa nwọ́n.
4 Nínú àwọn ará Lámánì tí nwọ́n sì pa ni ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé gbogbo àwọn irú-ọmọ Ámúlónì wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin rẹ̀, tí nwọ́n jẹ́ àlùfã fún Nóà, àwọn nã ní a sì pa nípasẹ̀ ọwọ́ àwọn ará Nífáì;
5 Àwọn tí ó sì kù, lẹ́hìn tí nwọ́n ti sá lọ sínú aginjù tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn, tí nwọ́n sì ti gba agbára àti àṣẹ kúrò lọ́wọ́ àwọn ará Lámánì, kí nwọ́n pa púpọ̀ nínú àwọn ará Lámánì nã run pẹ̀lú iná nítorí ìgbàgbọ́ nwọn—
6 Nítorítí púpọ̀ nínú nwọn, lẹ́hìn tí nwọ́n ti pàdánù ohun púpọ̀, tí nwọ́n sì ti rí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìpọ́njú, bẹ̀rẹ̀sí rú sókè ní ìrántí àwọn ọ̀rọ̀ tí Áárọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀ ti wãsù fún nwọn ní ilẹ̀ nwọn; nítorínã, nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ṣe àìgbàgbọ́ sí gbogbo àwọn àṣà bàbá nwọn, tí nwọ́n sì gba Olúwa gbọ́, àti pé òun ni ó fún àwọn ará Nífáì ní agbára títóbi; báyĩ sì ni a yí púpọ̀ nínú nwọn lọ́kàn padà nínú aginjù nã.
7 Ó sì ṣe tí àwọn olórí nnì, tí nwọn jẹ́ ìyókù àwọn ọmọ Ámúlónì mú kí a pa nwọ́n, bẹ̃ni, gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ nínú ohun wọ̀nyí.
8 Nísisìyí, ikú-ajẹ́rĩkú yí mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn arákùnrin nwọn ru sókè ní ìbínú; ìjà sì bẹ̀rẹ̀ nínú aginjù; àwọn ará Lámánì sì bẹ̀rẹ̀sí lépa ẹ̀mí àwọn irú-ọmọ Ámúlónì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa nwọ́n; nwọ́n sì sá wọ inú aginjù èyítí ó wà ní apá ìlà-oòrùn.
9 Sì kíyèsĩ, àwọn ará Lámánì nlépa ẹ̀mí nwọn títí di òní. Báyĩ sì ni ọ̀rọ̀ Ábínádì ṣẹ, èyítí ó sọ nípa irú-ọmọ àwọn àlùfã nnì tí nwọ́n ṣe é tí ó fi kú nípasẹ̀ iná.
10 Nítorítí ó wí fún nwọn pé: Ohun tí ẹ̀yin yíò ṣe fún mi yíò jẹ́ ẹ̀yà irú ohun tí nbọ̀.
11 Àti nísisìyí Ábínádì ni ẹni àkọ́kọ́ tí ó kú nípasẹ̀ iná nítorí ìgbàgbọ́ tí ó ní nínú Ọlọ́run; báyĩ, èyí ni ìtumọ̀ ohun tí ó sọ, pé ọ̀pọ̀lọpọ̀ yíò kú nípasẹ̀ iná, gẹ́gẹ́bí ó ti rí fún òun.
12 Ó sì wí fún àwọn àlùfã Nóà pé irú-ọmọ nwọn yíò mú kí á pa ọ̀pọ̀lọpọ̀ gẹ́gẹ́bí a ṣe pa òun, àti pé a ó fọ́n nwọn ká ilẹ̀ òkẽrè, a ó sì pa nwọ́n, àní bí ẹranko búburú ṣe nlé àgùtàn tí kò ní olùṣọ́ tí sì pa; àti nísisìyí kíyèsĩ, àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ṣẹ, nítorítí àwọn ará Lámánì lé nwọn, nwọ́n sì dọdẹ nwọn, nwọ́n sì pa nwọ́n.
13 Ó sì ṣe, nígbàtí àwọn ará Lámánì ríi pé nwọn kò lè borí àwọn ará Nífáì, nwọ́n tún padà lọ sí ilẹ̀ nwọn; ọ̀pọ̀lọpọ̀ nwọn sì kọjá sí ilẹ̀ Íṣmáẹ́lì láti gbé inú rẹ̀ àti ilẹ̀ Nífáì, nwọ́n sì da ara nwọn pọ̀ mọ́ àwọn ènìyàn Ọlọ́run, tí nwọ́n íṣe ará Kòṣe-Nífáì-Léhì.
14 Àwọn nã sì ri àwọn ohun ìjà-ogun nwọn mọ́lẹ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn arákùnrin nwọn ti ṣe, nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí jẹ́ ènìyàn rere; tí nwọ́n sì rìn ní ọ̀nà Olúwa, tí nwọ́n sì gbiyanju láti pa àwọn òfin àti àwọn ilana rẹ̀ mọ́.
15 Bẹ̃ni, nwọ́n sì pa òfin Mósè mọ́; nítorípé ó tọ́ pé kí nwọ́n sì máa pa òfin Mósè mọ́ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ síbẹ̀, nítorítí a kò tĩ múu ṣẹ tán. Ṣùgbọ́n l’áìṣírò òfin Mósè, nwọ́n ṣã fojúsọ́nà sì bíbọ̀ Krístì, nítorípé nwọ́n ka òfin Mósè sí ẹ̀yà bíbọ̀ rẹ, nwọ́n sì gbàgbọ́ pé nwọ́n níláti pa àwọn ohun wọnnì mọ́, èyítí o hán sí gbangba, títí di àkokò nã tí a ó fihàn sí nwọ́n.
16 Nísisìyí kĩ ṣe pé nwọn rò pé nípa òfin Mósè ní ìgbàlà ṣe wà; ṣùgbọ́n pé òfin Mósè dúró fún èyítí yíò mú ìgbàgbọ́ nwọn nínú Krístì dúró ṣinṣin; báyĩ ni nwọ́n sì gba ìrètí nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, sí ìgbàlà ayérayé, tí nwọ́n sì gbẹ́kẹ̀lé ẹ̀mí ìsọtẹ́lẹ̀, tí ó nsọ nípa àwọn ohun èyítí nbọ̀.
17 Àti nísisìyí kíyèsĩ, Ámọ́nì, àti Áárọ́nì, àti Òmnérì, àti Hímnì, pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn yọ̀ púpọ̀púpọ̀, fún àṣeyọrí tí nwọ́n ní lãrín àwọn ará Lámánì, nítorítí nwọ́n ríi pé Olúwa ti gbọ́ àdúrà nwọn, àti pé ó ti jẹ́rĩ sí òtítọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ sí nwọn ní gbogbo ọ̀nà.