Orí 28
A ṣẹ́gun àwọn ará Lámánì nínú ogun nlá kan—Ẹgbẹgbẹ̀rún ni a pa—Ìpín ènìyàn búburú ni ipò ìbànújẹ́ àìlópin; olódodo yíò sì gba ayọ̀ tí kò lópin. Ní ìwọ̀n ọdún 77 sí 76 kí a tó bí Olúwa wa.
1 Àti nísisìyí, ó sì ṣe lẹ́hìn tí àwọn ènìyàn Ámọ́nì ti gbilẹ̀ ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, tí a sì ti dá ìjọ kan sílẹ̀ ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì, tí àwọn ọmọ ogun àwọn ará Nífáì sì ti yí ilẹ̀ Jẹ́ṣónì ká, bẹ̃ ni, ní gbogbo agbègbè tí ó yí ilẹ̀ Sarahẹ́múlà ká; kíyèsĩ, àwọn ọmọ ogun àwọn ará Lámánì ti tẹ̀lé àwọn arákùnrin nwọn lọ sínú aginjù nã.
2 Báyĩ sì ni ogun líle bẹ́ sílẹ̀; bẹ̃ni, àní irú èyítí a kò rí rí lãrín gbogbo àwọn ènìyàn tí ó ti wà ní ilẹ̀ nã láti ìgbà tí Léhì ti jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù; bẹ̃ni, ẹgbẹgbẹ̀run àwọn ará Lámánì ni a sì pa, tí àwọn míràn sì fọ́nká sí ilẹ̀ òkẽrè.
3 Bẹ̃ni, nwọ́n sì pa púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn Nífáì nã; bíótilẹ̀ríbẹ̃, nwọ́n lé àwọn ará Lámánì, nwọ́n sì fọ́n nwọn ká, àwọn ènìyàn Nífáì sì tún padà lọ sí ilẹ̀ nwọn.
4 Àti nísisìyí, àkokò yĩ sì jẹ́ èyítí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀fọ̀ pẹ̀lú ohùn-réré ẹkún gba ilẹ̀ nã jákè-jádò, lãrín àwọn ènìyàn Nífáì—
5 Bẹ̃ni, igbe ẹkún àwọn opó tí nṣọ̀fọ̀ fún àwọn ọkọ nwọn, àti ti àwọn bàbá tí nwọn nṣọ̀fọ̀ fún àwọn ọmọ nwọn, àti ti ọmọbìnrin fún arákùnrin rẹ̀, bẹ̃ni, ti ọmọkùnrin fún bàbá rẹ̀; báyĩ sì ni igbe ẹkún ọ̀fọ̀ gba ãrin nwọn gbogbo, tí nwọn nṣọ̀fọ̀ fún àwọn ìbátan nwọn tí a ti pa.
6 Àti nísisìyí, dájúdájú ọjọ́ ìbànújẹ́ ni èyí jẹ́; bẹ̃ni, àkokò ìrònú, àti àkokò fún ọ̀pọ̀ ãwẹ̀ àti àdúrà.
7 Báyĩ sì ni ọdún kẹẹ̀dõgún ìjọba àwọn onídàjọ́ lórí àwọn ènìyàn Nífáì dópin;
8 Èyí sì ni ìtàn nípa Ámọ́nì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, ìrìn-àjò nwọn ní ilẹ̀ Nífáì, ìyà tí ó jẹ nwọ́n ní ilẹ̀ nã, ìbànújẹ́ nwọn, àti ìpọ́njú nwọn, pẹ̀lú ayọ̀ nwọn tí kò lè yé ni, àti gbígbà àti ìdábòbò àwọn arákùnrin nã ní ilẹ̀ Jẹ́ṣónì. Àti nísisìyí kí Olúwa, tí í ṣe Olùràpadà gbogbo ènìyàn, bùkún ẹ̀mí nwọn títí láéláé.
9 Eyĩ sì ni ìtàn nípa àwọn ogun àti ìjà lãrín àwọn ará Nífáì, àti àwọn ogun lãrín àwọn ará Nífáì pẹ̀lú àwọn ará Lámánì; ọdún kẹẹ̀dõgún ìjọba àwọn onídàjọ́ sì dópin.
10 Ní ãrín ọdún kíni sí ọdún kẹẹ̀dõgún sì ni ẹgbẹ̃gbẹ̀rún ẹ̀mí parun; bẹ̃ni, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìtàjẹ̀sílẹ̀ búburú ni ó wáyé ní àkokò yĩ.
11 Ẹgbẹgbẹ̀rún òkú ènìyàn ni a sì gbé sin sínú ilẹ̀, tí ẹgbẹ̃gbẹ̀rún òkú ènìyàn jẹrà lórí òkìtì lójú àgbáyé; bẹ̃ni, ẹgbẹ̃gbẹ̀rún sì nṣọ̀fọ̀ ìpàdánù àwọn ìbátan nwọn; nítorípé, gẹ́gẹ́bí Olúwa ti ṣe ìlérí, nwọ́n bẹ̀rù pé nwọn ti gba ìpín sí ipò ìbànújẹ́ àìlópin.
12 Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹgbẽgbẹ̀rún míràn nṣọ̀fọ̀ àdánù àwọn ìbátan nwọn nítõtọ́, síbẹ̀síbẹ̀, nwọ́n nyọ̀ nwọ́n sì nṣọ̀fọ̀ nínú ìrètí, àti pé nwọ́n mọ̀, gẹ́gẹ́bí àwọn ìlérí Olúwa, pé a ó gbé nwọn dìde tí nwọn ó sì máa gbé ní apá ọ̀tún Ọlọ́run, nínú ipò ayọ̀ tí kò lópin.
13 Báyĩ àwa sì ríi bí ipò aidọgba ènìyàn ṣe jẹ́ nípa ẹ̀ṣẹ̀ àti ìrékọjá àti agbára èṣù, èyítí ó rí báyĩ nípa ọ̀nà àrékérekè tí ó ti pète rẹ̀ láti mú ọkàn ènìyàn nínú ìkẹkùn.
14 Báyĩ ni àwa sì rí ìpè nlá nnì sí ìtẹramọ́ iṣẹ́ nínú ọgbà àjàrà Olúwa; bayĩ ni àwa si rí ìdí nlá fún ìbànújẹ́, àti fún ayọ̀—ìbànújẹ́ nítorí ikú àti ìparun lãrín àwọn ènìyàn, àti ayọ̀ nítorí ìmọ́lẹ̀ Krístì sí ìyè.