Àwọn Ìwé Mímọ́
Álmà 2


Orí 2

Ámlísì wá ọ̀nà láti jẹ ọba, a sì kọ̀ọ́ nípa ohùn àwọn ènìyàn—Àwọn ọmọ-ẹ̀hin rẹ̀ fi jọba—Àwọn ará Ámlísì bá àwọn ará Nífáì jà, a sì ṣẹ́gun nwọn—Àwọn ará Lámánì pẹ̀lú àwọn ará Ámlísì dára pọ̀ a sì ṣẹ́gun nwọn—Álmà pa Ámlísì. Ní ìwọ̀n ọdún 87 kí a tó bí Olúwa wa.

1 Ó sì ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún karũn ìjọba nwọn tí ìjà bẹ̀rẹ̀ lãrín àwọn ènìyàn nã; nítorítí ọkùnrin kan tí à npè ní Ámlísì, tí òun sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n-àrekérekè ènìyàn, bẹ̃ni, ọlọ́gbọ́n ènìyàn gẹ́gẹ́bí ogbọ́n ayé, tí òun sì jẹ́ ẹ̀yà ti ọkùnrin nì èyítí ó pa Gídéónì pẹ̀lú idà, ẹnití a pa gẹ́gẹ́bí òfin—

2 Nísisìyí Ámlísì yí, nípa ọgbọ́n-àrekérekè rẹ̀, ti fa ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sọ́dọ̀ rẹ̀; àní tóbẹ̃ tí nwọ́n bẹ̀rẹ̀sí ní agbára; tí nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí gbìyànjú láti fi Ámlísì jọba lórí àwọn ènìyàn nã.

3 Nísisìyí, èyí jẹ́ ìdágìrì fún àwọn ènìyàn ìjọ-Ọlọ́run, àti fún gbogbo àwọn tí nwọ́n tẹ̀lé ẹ̀tàn Ámlísì; nítorítí nwọ́n mọ̀ pé gẹ́gẹ́bí òfin nwọn, irú ohun báyĩ níláti jẹ́ ṣíṣe nípa ohùn àwọn ènìyàn nã.

4 Nítorínã, tí ó bá ṣeéṣe kí Ámlísì rí àtìlẹhìn àwọn ènìyàn nã nípa ohùn nwọn, gẹ́gẹ́bí ó ti jẹ́ ènìyàn búburú, òun yíò fi ẹ̀tọ́ àti ànfàní nwọn nínú ìjọ-Ọlọ́run dù nwọ́n; nítorítí ó jẹ́ ète rẹ̀ láti pa ìjọ-Ọlọ́run run.

5 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn nã kó ara nwọn jọ papọ̀ jákè-jádò gbogbo ilẹ̀ nã, olúkúlùkù gẹ́gẹ́bí èrò ọkàn rẹ̀, yálà fún ìfaramọ́ tàbí atakò Ámlísì, ní àjọ ọ̀tọ̀tọ̀, tí nwọ́n sì ní àríyànjiyàn àti asọ̀ tí ó yanilẹ́nu ní ãrin ara nwọn.

6 Báyĩ sì ni nwọ́n péjọ̀ láti di ìbò nípa ọ̀rọ̀ nã; a sì gbée síwájú àwọn onídàjọ́.

7 Ó sì ṣe, tí ohùn àwọn ènìyàn tako Ámlísì, tí a kò sì fi ṣe ọba lórí àwọn ènìyàn nã.

8 Nísisìyí, eleyĩ mú kí àwọn tí ó tako ó láyọ̀ púpọ̀ lọ́kàn nwọn; ṣùgbọ́n Ámlísì rú àwọn tí ó fẹ́ẹ sókè sí ìrunú àwọn tí kò fẹ́ ẹ.

9 Ó sì ṣe tí nwọn kó ara nwọn jọ, tí nwọ́n sì ya Ámlísì sọ́tọ̀ láti jẹ ọba nwọn.

10 Nísisìyí nígbàtí a fi Ámlísì jọba lórí nwọn, ó pàṣẹ pé kí nwọ́n dìhámọ́ra ogun ní ìdojúkọ àwọn arákùnrin wọn; èyí ni ó sì ṣe láti tẹ̀ wọ́n lori bá lábẹ́ ara rẹ̀.

11 Nísisìyí àwọn ènìyàn Ámlísì jẹ́ ìyàtọ̀ nípa orúkọ Ámlísì, a sì npè nwọ́n ní àwọn ará Ámlísì; àwọn tí ó kù ni a sì npè ní àwọn ará Nífáì, tàbí àwọn ènìyàn Ọlọ́run.

12 Nítorínã àwọn ará Nífáì ní ìmọ̀ ète àwọn ará Ámlísì, nítorínã nwọ́n gbáradì sílẹ̀ láti dojúkọ nwọ́n; bẹ̃ni, nwọ́n gbáradì pẹ̀lú idà, àti pẹ̀lú dòjé-ìjà, àti pẹ̀lú ọrún, àti pẹ̀lú ọ̀kọ̀, àti pẹ̀lú òkúta, àti pẹ̀lú kànnà-kànnà, àti pẹ̀lú onírũrú ohun ìjà ogun gbogbo.

13 Báyĩ sì ni nwọ́n ṣe gbáradì láti dojúkọ àwọn ará Ámlísì ní àkokò tí nwọn bá dé. Nwọ́n sì yan àwọn balógun, àti àwọn balógun gíga, àti àwọn balógun agba, gẹ́gẹ́bí pípọ̀sí àwọn ọmọ ogun nwọn.

14 Ó sì ṣe tí Ámlísì ṣe ìgbáradì fún àwọn ènìyàn rẹ̀ pẹ̀lú onírũrú ohun ìjà ogun gbogbo; ó sì yan olórí àti olùdarí lé àwọn ènìyàn rẹ̀ lórí, láti darí nwọn lọ sógun ní ìdojúkọ àwọn arákùnrin nwọn.

15 Ó sì ṣe tí àwọn ará Ámlísì wá sí orí òkè Ámníhù, èyítí ó wà ní ìhà ìlà õrùn odò Sídónì, tí ó ṣàn létí ilẹ̀ ti Sarahẹ́múlà, níbẹ̀ ni nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí jagun pẹ̀lú àwọn ará Nífáì.

16 Nísisìyí, Álmà, nítorítí ó jẹ́ onídàjọ́ agba, àti gómìnà àwọn ènìyàn Nífáì, nítorínã ó kọjá lọ sókè pẹ̀lú àwọn ènìyàn rẹ̀, bẹ̃ni, pẹ̀lú àwọn balógun rẹ̀, àti àwọn balógun àgbà, bẹ̃ni, ní ipò olórí àwọn ọmọ ogun rẹ̀, ní ìdojúkọ àwọn ará Ámlísì lógun.

17 Nwọ́n sì bẹ̀rẹ̀sí pa àwọn ará Ámlísì lórí òkè nã ní ìhà apá ilà-oòrùn Sídónì. Àwọn ará Ámlísì sì dojúkọ àwọn ará Nífáì pẹ̀lú ọ̀pọ̀ agbára, tó bẹ̃ tí púpọ̀ nínú àwọn ará Nífáì ṣubú níwájú àwọn ará Ámlísì.

18 Bíótilẹ̀ríbẹ̃ Olúwa fún àwọn ará Nífáì ní agbára, tí nwọ́n sì pa àwọn ará Ámlísì ní ìpakúpa, tí nwọ́n sì nsálọ kúrò níwájú nwọn.

19 Ó sì ṣe, tí àwọn ará Nífáì súré lé àwọn ará Ámlísì ní gbogbo ọjọ́ nã, nwọ́n sì pa nwọ́n ní ìpakúpa, tó bẹ̃ tí a fi pa àwọn ẹgbẹ̀rún méjìlá àti ọgọ̃rún mãrún àti ọgbọ̀n àti méjì lára àwọn ará Ámlísì; à sì pa ẹgbẹ̀rún mẹ́fà àti ọgọ̃rún mãrún àti ọgọ̃ta àti méjì lára àwọn ará Nífáì.

20 Ó sì ṣe nígbàtí àwọn ọmọ ogun Álmà kò lè sáré lé àwọn ará Ámlísì mọ́, ó pàṣẹ kí àwọn ènìyàn rẹ̀ pàgọ́ nwọ́n sì àfonífojì Gídéónì, àfonífojì èyítí a fi orúkọ Gídéónì nnì sọ, ẹnití Néhórì pa pẹ̀lú idà; nínú àfonífojì yíi sì ni àwọn ará Nífáì pàgọ́ nwọn sí ní alẹ́ ọjọ́ nã.

21 Álmà sí rán àwọn amí tẹ̀lé àwọn ìyókù àwọn ará Ámlísì, kí òun kí ó lè mọ́ èrò nwọn pẹ̀lú rìkíṣí nwọn, kí ó lè ṣe ìdãbò bò ara rẹ̀, kí òun lè pa àwọn ènìyàn rẹ̀ mọ́ kúrò nínú ìparun.

22 Nísisìyí, àwọn tí ó rán jáde láti ṣọ́ ibùdó àwọn ará Ámlísì ni a pè ní Sérámù, àti Ámnórì, àti Mántì, àti Límhérì; àwọn wọ̀nyí ni ó jáde lọ pẹ̀lú àwọn arákùnrin nwọn, láti ṣọ́ ibùdó àwọn ará Ámlísì.

23 Ó sì ṣe, ní ọjọ́ kejì tí nwọ́n sì padà sí ibùdó àwọn ará Nífáì ní ìkánjú, nítorítí ẹnu yà nwọ́n lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹ̀rù sì bà wọ́n gidigidi, nwọ́n wípé:

24 Kíyèsĩ, àwa tẹ̀lé àgọ́ ará Ámlísì, ó sì jẹ́ ìyàlẹ́nu fún wa pé ní ilẹ̀ Mínọ́nì, ní apá òkè ilẹ̀ Sarahẹ́múlà, ní ọ̀nà tí ó lọ sí ilẹ̀ Nífáì, àwa rí ọ̀pọ̀ ọmọ ogun àwọn ará Lámánì; sì wõ, àwọn ará Ámlísì ti darapọ̀ mọ́ nwọn;

25 Nwọ́n sì ti kọlũ àwọn arákùnrin wa ní ilẹ̀ nã; nwọ́n sì nsá kúrò níwájú nwọn pẹ̀lú àwọn agbo-ẹran nwọn, àti àwọn aya nwọn, àti àwọn ọmọ nwọn, síhà ìlú-nlá wa; àti pé tí àwa kò bá ṣe kánkán nwọn yíò gba ìlú-nlá wa, àti àwọn bàbá wa, àti àwọn aya wa, àti àwọn ọmọ wa ní nwọn yíò pa.

26 Ó sì ṣe tí àwọn ènìyàn Nífáì kó àgọ́ nwọn, tí nwọ́n sì jáde kúrò nínú àfonífojì Gídéónì, sí ìhà ìlú-nlá nwọn, èyítí íṣe ìlú-nlá Sarahẹ́múlà.

27 Sì kíyèsĩ, bí nwọ́n ṣe ndá odò Sídónì kọjá ni àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Ámlísì, tí nwọ́n pọ̀ bĩ yanrìn òkun, kọlũ nwọ́n láti pa nwọ́n run.

28 Bíótilẹ̀ríbẹ̃, gẹ́gẹ́bí a ti fi agbára fún àwọn ará Nífáì láti ọwọ́ Olúwa, nígbàtí nwọ́n ti gbàdúrà tagbára-tagbára síi kí ó lè gbà nwọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá nwọn, nítorínã Olúwa sì gbọ́ igbe nwọn, ó sì fún nwọn ní ágbára, àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Ámlísì sì ṣubú níwájú nwọn.

29 Ó sì ṣe tí Álmà bá Ámlísì ja pẹ̀lú idà, tí nwọ́n dojúkọ ara nwọn; nwọ́n sì jà kíkan-kíkan, ọ̀kan pẹ̀lú ìkejì.

30 Ó sì ṣe, tí Álmà ẹnití íṣe ìránṣẹ́ Ọlọ́run tí ó sì kún fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbàgbọ́, kígbe, wípé: A! Olúwa, ṣãnú, kí o s‘idá ẹ̀mí mi sí, kí èmi kí ó lè jẹ́ ohun èlò ní ọwọ́ rẹ fún ìgbàlà àti ìpamọ́ àwọn ènìyàn yíi.

31 Nísisìyí, nígbàtí Álmà ti sọ̀rọ̀ wọ̀nyí ó tún lọ bá Ámlísì jà; a sì fún un ní ágbára, tóbẹ̃ tí ó pa Ámlísì pẹ̀lú idà.

32 Ó sì tún bá ọba àwọn ará Lámánì jà; ṣùgbọ́n ọba àwọn ará Lámánì sá padà kúrò níwájú Álmà, ó sì rán àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀ láti bá Álmà jà.

33 Ṣùgbọ́n Álmà, pẹ̀lú àwọn ẹ̀ṣọ́ rẹ̀, bá àwọn ẹ̀ṣọ́ ọba Lámánì jà títí nwọn fi pa nwọ́n tí nwọ́n sì lé nwọn padà.

34 Ó sì pa ilẹ̀ nã mọ́, tàbí kí a wípé bèbè nã, èyítí ó wà ní ìhà ìwọ oòrùn odò Sídónì, ó sì ju òkú àwọn ará Lámánì tí a ti pa sínú omi Sídónì, kí àwọn ènìyàn rẹ̀ lè rí ọ̀nà láti kọjá lọ bá àwọn ará Lámánì àti àwọn ará Ámlísí jà ní ìhà ìwọ oòrùn odò Sídónì.

35 Ó sì ṣe, nígbàtí nwọ́n sì ti dá odò Sídónì kọjá, ni àwọn ará Lámanì àti àwọn ará Ámlísì bẹ̀rẹ̀sí sálọ kúrò níwájú nwọn, l’áìṣírò nwọ́n pọ̀ púpọ̀ tó bẹ̃ tí a kò lè kà nwọ́n.

36 Nwọ́n sì sá kúrò níwájú àwọn ará Nífáì síhà aginjù tí ó wà ní apá ìwọ oòrùn àti apá àríwá, jáde kúrò ní agbègbè ilẹ̀ nã; àwọn ará Nífáì sì lé nwọn pẹ̀lú agbára nwọn, nwọ́n sì pa nwọ́n.

37 Bẹ̃ni, nwọ́n kọlũ nwọ́n ní gbogbo ọ̀nà, nwọ́n pa nwọ́n, nwọ́n sì lé nwọn lọ, títí nwọ́n fi túká ní apá ìwọ oòrùn, àti ní apá gúsù, títí nwọ́n fi dé inú aginjù èyítí nwọ́n pè ní Hámọ́ntì; eleyĩ sì ni apá aginjù nã tí ó kún fún àwọn ẹranko búburú.

38 Ó sì ṣe, tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kú nínú aginjù fún ọgbẹ́ nwọn, tí àwọn ẹranko búburú nnì sì jẹ nwọ́n, pẹ̀lú àwọn igún ojú ọ̀run; nwọ́n sì ti ri àwọn egungun nwọn, nwọ́n sì kó nwọn jọ sórí ilẹ̀.